Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Ni Mo Lè Ṣe Láti Mú Kí Ọ̀rẹ́kùnrin Mi Dẹ́kun Fífìyà Jẹ Mí?
“Lónìí yìí ni ọ̀rẹ́kùnrin mi lù mí fún ìgbà àkọ́kọ́. Ó bẹ̀ mí o, àmọ́ mi ò tíì mọ nǹkan tí mà á ṣe báyìí.” —Stella.a
ÀPILẸ̀KỌ kan nínú ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association sọ pé: “Ìdámárùn-ún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ obìnrin ló sọ pé ẹni táwọn jọ ń fẹ́ra àwọn ti lu àwọn tàbí kó ti bá àwọn lò pọ̀ rí láìṣe pé ó tinú àwọn wá tàbí kó ti ṣe méjèèjì rí.” Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Jámánì láàárín àwọn ọ̀dọ́ tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́tàdínlógún sí ogún ọdún, ó ju ìdámẹ́rin lọ lára wọn tó sọ pé wọ́n ti bá àwọn lò pọ̀ tipátipá rí, nípa lílo ọ̀rọ̀ dídùn tàbí ìhàlẹ̀, nípa lílo oògùn olóró tàbí ọtí líle káwọn má bàa lágbára tó láti kọ̀ ọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí mìíràn tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Amẹ́ríkà ṣe fi hàn, ìdáméjì nínú márùn-ún àwọn ọ̀dọ́ tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́tàlá sí ogún ọdún ló sọ pé àwọn ti rí ibi tí àwọn ọmọ kíláàsì àwọn ti “sọ̀rọ̀ burúkú sí ẹní tí wọ́n jọ ń fẹ́ra wọn sọ́nà.”b
Ṣé ọ̀dọ́ ni ẹ́, tó ò ń múra àtiṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ẹnì kan tó máa ń sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí ẹ tàbí tó máa ń jágbe mọ́ ẹ, tàbí tí kì í kà ẹ́ sí, tó máa ń tì ẹ́ dà nù tàbí tó ń gbá ẹ létí? Àpilẹ̀kọ kan tá a tẹ̀ jáde ṣáájú eléyìí fi hàn pé ṣíṣe obìnrin níṣekúṣe bẹ́ẹ̀ ń pọ̀ sí i ni.c Ó tún fi hàn pé inú Jèhófà Ọlọ́run ò dùn sí ọ̀rọ̀ èébú tàbí fífìyàjẹni bẹ́ẹ̀ àti pé kò yẹ káwọn tí wọ́n ń hu irú ìwàkiwà bẹ́ẹ̀ sí gbà á bí ohun tí ò burú tàbí kí wọ́n máa rò pé ẹ̀bi àwọn ni. (Éfésù 4:31) Síbẹ̀ náà, àtimọ ohun tó yẹ kéèyàn ṣe nírú ipò bẹ́ẹ̀ ò rọrùn. Ìfẹ́ ọ̀rẹ́kùnrin ẹ ṣì lè wà lọ́kàn ẹ, láìfi ti gbogbo bó ṣe ń hùwà yẹn pè. Èyí tó tún wá burú jù bẹ́ẹ̀ lọ ni pé ẹ̀rù ohun tó lè ṣe tó o bá ta kò ó lè máa bà ẹ́. Kí ló wá yẹ kó o ṣe o?
Ṣàyẹ̀wò Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Látòkèdélẹ̀
Lákọ̀ọ́kọ́, sinmẹ̀dọ̀ kó o sì fojú inú wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀. (Oníwàásù 2:14) Ṣé lóòótọ́ la lè kà ẹ́ kún ẹni tí wọ́n ń nà ní pàṣán ọ̀rọ̀? Ṣé ọ̀rẹ́kùnrin ẹ mọ̀ọ́mọ̀ ń ni ẹ́ lára ni, àbí ṣe ló kàn “ń sọ̀rọ̀ láìronú”? (Òwe 12:18) Báwo ló ṣe máa ń ṣe é lemọ́lemọ́ sí? Ṣé àṣìṣe ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo tó o kàn lè gbójú fò dá ni? Àbí ó ti mọ́ ọn lára láti máa sọ̀rọ̀ àbùkù tàbí ọ̀rọ̀ játijàti sí ẹ?
Tí ò bá dá ẹ lójú bóyá èrò ẹ tọ̀nà tàbí kò tọ̀nà, o lè fọ̀rọ̀ náà lọ ẹnì kan tó dàgbà tó sì tún gbọ́n jù ẹ́ lọ, kì í ṣe ẹni tẹ́ ẹ jọ jẹ́gbẹ́. O sì tún lè fi ohun tó ń ṣẹlẹ̀ tó àwọn òbí ẹ tàbí Kristẹni míì tó dàgbà dénú létí. Nígbà tíwọ àti irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá jọ sọ̀rọ̀ wà á lè rí i bóyá ìwọ lò ń gba ọ̀rọ̀ kanrí ju bó ṣe yẹ lọ, tàbí bóyá ìṣòro tó lágbára wà.
Tí ò bá ní wu ẹ́ léwu, ó lè wáyè láti bá ọ̀rẹ́kùnrin ẹ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. (Òwe 25:9) Fi sùúrù sọ fún un bí ìwà tó ń hù sí ẹ ṣe rí lára ẹ. Sọ ìdí tó fi ń bí ẹ nínú fún un. Sọ nǹkan tó o lè fara mọ́ àtèyí tó ò lè fara mọ́. Kí ló ṣe nígbà tó o sọ fún un? Ṣé ó kàn fi gbígbọ́ ṣaláì gbọ́ èrò inú ẹ tó o sọ fún un ni, àbí ńṣe ló tún fìbínú da ọ̀rọ̀ burúkú sílẹ̀? Tó bá ṣe báyẹn, ẹ̀rí tó ṣe kedere nìyẹn pé kò fẹ́ yí padà.
Àmọ́, tó bá wá fìwà ìrẹ̀lẹ̀ tòótọ́ hàn tó sì kábàámọ̀ tọkàntọkàn ńkọ́? A jẹ́ pé ó lè ṣeé ṣe kí ìfẹ́rasọ́nà yín má forí ṣánpọ́n nìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ṣọ́ra o! Àwọn ẹlẹ́rẹ̀kẹ́ èébú máa ń pá kúbẹ́kúbẹ́ bí ẹni pé wọ́n kábàámọ̀ ohun tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n bá ti sọ máà-tán-ńlẹ̀ ọ̀rọ̀ sí ẹnì kan tán, tó sì jẹ́ pé tínú bá ti bí wọn pẹ́nrẹ́n báyìí, wọ́n á tún máa da ọ̀rọ̀ kòbákùngbé wọn sílẹ̀ ni. Á pẹ́ díẹ̀ kó o tó lè mọ̀ bóyá ó ti yí padà lóòótọ́. Ara nǹkan tó lè ṣe tí wà á fi mọ̀ pé lóòótọ́ ló fẹ́ yí padà ni tó bá múra tán láti wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristẹni.—Jákọ́bù 5:14-16.
Fi sọ́kàn pé “gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Ò báà wá a dọ̀la o ò ní í rí ẹni tó pé o. Gbogbo tọkọtaya tó ti ṣègbéyàwó ló máa ní “ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn” dé ìwọ̀n àyè kan nítorí jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ aláìpé. (1 Kọ́ríńtì 7:28) Nǹkan tó o máa ṣe tó o bá rò ó lọ rò ó bọ̀ ni pé o ní láti pinnu bóyá wà á lè fara mọ́ àwọn ìkùdíẹ̀–káàtó tiẹ̀ tí wà á sì láyọ̀. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ohun tó dáa jù ni pé kó o jẹ́ kí àkókò tó pọ̀ tó lọ dáadáa kó o tó pinnu èyí.
Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe Bí Ìwà Ipá Bá Wọ̀ Ọ́
Àmọ́ ṣá o, ọ̀rọ̀ á tún yàtọ̀ díẹ̀ tó bá jẹ́ pé ìwà ipa tó ń hù ti bá a débi kó máa tú ọ̀rọ̀ burúkú dà sílẹ̀ tàbí kó máa halẹ̀, tàbí tó bá ti di pé ó tiẹ̀ ti ń taari ẹ dà nù, tàbí tó ń fọ́ ẹ létí. Ìyẹn fi hàn pé kò ní ìkóra ẹni níjàánu nìyẹn, ó sì léwu; ó sì lè di pé kí ìwà ipá tó lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ wọ̀ ọ́.
Ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ fáwọn méjì tí wọ́n ò tíì ṣègbéyàwó ni pé kí wọ́n má máa wà pọ̀ láwọn nìkan níbi tójú ti pofírí. Ṣùgbọ́n fún ìdí kan ṣá, tó bá ṣẹlẹ̀ pé o bá ara ẹ níwọ nìkan pẹ̀lú ọkùnrin kan tínú ẹ̀ ń ru, o ò gbọ́dọ̀ “fi ibi san ibi.” (Róòmù 12:17) Rántí pe: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.” (Òwe 15:1) Ṣe jẹ́ẹ́. Ní kó jẹ́ kó o padà sílé. Tó bá di kàráǹgídá rọra kúrò níbẹ̀, tàbí kó o sá lọ!
Tí ọkùnrin kan bá fẹ́ fagídí bá obìnrin kan lò pọ̀ ńkọ́? Àtìbẹ̀rẹ̀ pàá ló ti yẹ káwọn méjì tí wọ́n ń fẹ́ra wọn sọ́nà ti jọ mọ ibi táwọn méjèèjì lè fìfẹ́ hàn síra wọn dé. (1 Tẹsalóníkà 4:3-5) Tí ọ̀dọ́kùnrin kan bá fẹ́ sún ọ̀dọ́bìnrin kan ṣe ohun tó tako ìlànà Bíbélì, ó yẹ kó sọ fún un láìfọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀ pé òun ò ní ṣe irú ẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 39:7-13) Anne tí ọmọkùnrin kan sún lọ́nà bẹ́ẹ̀ débi tó fi bá a lò pọ̀ sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ gbà. Fira ẹ sípò ọ̀wọ́. Jọ̀ọ́ má ṣe àṣìṣe yìí bó ti wù kó o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ tó!” Tó bá kọ̀ láti gbà pẹ̀lú ẹ pé o ò ṣe, sọ fún un pé tó bá ṣe kọjá ohun tó ṣe yẹn wà á kà á sí ẹni tó fẹ́ fipá bá ẹ lò pọ̀. Síbẹ̀ tí ò bá dáwọ́ dúró, pariwo sókè káwọn èèyàn lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o sì tì í dànù bó o ṣe máa ti ẹni tó bá fẹ́ fipá bá ẹ lò pọ̀.d
Èyí ó wù kó jẹ́ nínú ọ̀ràn méjèèjì tá a sọ yìí, ìmọ̀ràn Bíbélì tó wà nínú Òwe 22:24 bá a mu wẹ́kú pé: “Má ṣe bá ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ara fún ìbínú kẹ́gbẹ́; má sì bá ènìyàn tí ó máa ń ní ìrufùfù ìhónú wọlé.” Kò sí ìdí kankan fún ẹ láti kú sọ́rùn ẹni tó ń hùwà burúkú sí ọ pé dandan òun ni wà á fẹ́. Ó dájú pé bí ẹní ń forí ọká họmú ni bó o bá dá nìkan lọ bá ọkùnrin tó ń fìyà jẹ ẹ́ pé o ò fẹ́ ẹ mọ́. Bóyá ohun tó máa dáa jù lọ ni pé kó o jẹ́ káwọn òbí ẹ mọ nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran ara, wọ́n á bínú á sì dùn wọ́n bí wọ́n bá gbọ́ nípa nǹkan tó ṣe fún ẹ. Àmọ́, wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun míì tó tún yẹ ní ṣíṣe.e
Gbígbìyànjú Láti Yí I Padà
Bí ti í wù ó rí, iṣẹ́ ẹ kọ́ ni láti yí ọ̀rẹ́kùnrin ẹ padà. Irena sọ pé: “O lè rò pé o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ pé wà á mọ àtiṣe ara ẹ, o sì lè ràn án lọ́wọ́. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé o ò lẹ́mìí ẹ̀.” Nadine náà jẹ́wọ́ pé: “Mo máa ń rò pé mo lè yí i padà.” Òótọ́ ibẹ̀ ni pé òun fúnra ẹ̀ ló lè ‘yí èrò inú ara rẹ̀ padà’ kó sì yí padà. (Róòmù 12:2) Kì í sì í ṣe iṣẹ́ ọjọ́ kan nìyẹn, kódà á ṣòro díẹ̀.
Nítorí náà dúró lórí ìpinnu tó o bá ṣe, ṣe bí ẹni tó ò gbọ́ gbogbo ọgbọ́n yòówù tó bá fẹ́ dá láti fà ẹ́ lọ́kàn mọ́ra. Gbìyànjú láti gbé ọkàn rẹ kúrò lára ẹ̀ kó o sì jìnnà sí i pátápátá bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Máà jẹ́ kó kó ọ̀rọ̀ dídùn sí ẹ lágbárí tàbí kó bẹ̀ ẹ́ tàbí kó halẹ̀ mọ́ ẹ kó o bà a lè gbà kẹ́ ẹ tún padà máa fẹ́ra yín. Nígbà tí Irena sọ fún ọ̀rẹ́kùnrin ẹ̀ oníjàgídíjàgan pé òun ò fẹ́ ẹ mọ́, ọ̀rẹ́kùnrin ẹ̀ sọ pé òun á para òun. Dájúdájú, irú ẹni bẹ́ẹ̀ nílò ìrànlọ́wọ́, àmọ́ kì í wá ṣe ìrànlọ́wọ́ tìẹ. Ìrànlọ́wọ́ tó dáa jù tó o lè ṣe fún un ni pé kó o ta ko ìwà tí ò yẹ Kristẹni tó ń hù. Tó bá fẹ́ yí padà, ó lè wá ìrànlọ́wọ́ lọ síwájú.
Àmọ́, àwọn kan máa ń rò pé ìgbéyàwó á fòpin sí ìṣòro yẹn. Olùwádìí kan sọ pé: “Ìyàlẹ́nu ló sábà máa ń jẹ́ fáwọn tí wọ́n pàpà fẹ́ àfẹ́sọ́nà wọn tó máa ń fìyà jẹ wọ́n láti rí i pé wọn ò jáwọ́ nínú ìwà ipá tí wọ́n ń hù tẹ́lẹ̀. Àwọn kan gba èrò èké náà gbọ́ pé táwọn bá ti kiwọ́ bọ̀wé àdéhùn ìgbéyàwó pẹ́nrẹ́n, gbogbo irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ á ròkun ìgbàgbé ni. Máà báwọn gbarú ẹ̀ gbọ́.” Òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé ó ṣeé ṣe kí ẹni tó bá ń fìyà jẹ ẹni tó ń fẹ́ sọ́nà gbé irú ìwà bẹ́ẹ̀ wọnú ìgbéyàwó.
Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:3) Á ṣòro láti fòpin sí ìfẹ́ tó wà láàárín ìwọ àti ẹnì kan tí ọ̀rọ̀ ẹ̀ wà lọ́kàn ẹ. Ṣùgbọ́n á ṣòro jù bẹ́ẹ̀ lọ téèyàn bá kọrùn bọ ìgbéyàwó níbi tó ti ń jìyà. Yàtọ̀ sí ìyẹn, kò yẹ kó o má bẹ̀rù pé o ò ní rí ẹlòmíì tó bá ẹ mu fẹ́. Bí ojú ẹ ti ṣe wá là sí i báyìí, wà á lè mọ bí wà á ṣe wá ẹni tó jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́, onínúure, àti ẹni tó lè kóra ẹ̀ níjàánu ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
Bí Ọgbẹ́ Ọkàn Náà Yóò Ṣe San
Béèyàn bá ti fojú winá fífọ̀rọ̀ nani lẹ́gba tàbí líluni rí, ràbọ̀ràbọ̀ ẹ̀ kì í kúrò lára bọ̀rọ̀. Ẹnì kan tírú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí rí tó ń jẹ́ Mary sọ pé: “Wá ẹni tá á ràn ẹ́ lọ́wọ́, tètè wá ẹnì sọ fún. Mo rò pé mo lè dá yanjú ìṣòro náà fúnra mi ni, ṣùgbọ́n sísọ tí mo báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ti ràn mí lọ́wọ́.” Finú han àwọn òbí ẹ, ọ̀rẹ́ ẹ kan tó dàgbà dénú tàbí alàgbà kan nínú ìjọ Kristẹni.f
Àwọn kan ti rí i pé ó ṣèrànwọ́ fáwọn láti máa ṣe àwọn nǹkan bíi kíkàwé tó gbámúṣé, ṣíṣeré ìdárayá tàbí fífi nǹkan kan kọ́ra. Irena rántí pé: “Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé.”
Dájúdájú Jèhófà ò fọwọ́ sí kéèyàn máa sọ̀rọ̀ èébú sí ẹlòmíì tàbí kó máa lù ú. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, o lè dènà kí ẹnì kan máa ṣe ẹ́ níṣekúṣe.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tọkùnrin tobìnrin ló ṣeé ṣe kí wọ́n máa bú kí wọ́n sì máa lù, Ibùdó Ìkáwọ́ àti Ìdènà Àrùn ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé, “àwọn obìnrin tọ́ràn yìí sábà máa ń ṣẹlẹ̀ sí pọ̀ fíìfíì ju ọkùnrin lọ.” Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kí ohun tá à ń sọ bà a lè ṣe kedere, a ó máa sọ̀rọ̀ bíi pé ọkùnrin lẹni tó ń fìyà jẹni.
c Wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Kí Ló Fà Á Tó Fi Ń Hu Irú Ìwà Yìí sí Mi?” tó wà nínú Jí! June 8, 2004.
d Jí! March 8, 1993, láwọn àlàyé lórí béèyàn ṣe lè dènà ìfipábánilòpọ̀.
e Nínú àwọn ọ̀ràn kan, irú bí ìgbìdánwò láti fipá báni lò pọ̀, àwọn òbí ẹ lè pinnu láti fọ̀rọ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá létí. Èyí lè dènà káwọn ọmọbìnrin míì fojú winá irú ẹ̀.
f Tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà bá fa hílàhílo, àwọn mìíràn lè pinnu láti lọ gbàtọ́jú lọ́dọ̀ oníṣègùn kan tàbí olùtọ́jú ọpọlọ tó níwèé àṣẹ ìjọba.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ó ṣeé ṣe kí ẹni tó bá ń fìyà jẹ ẹni tó ń fẹ́ sọ́nà gbé irú ìwà bẹ́ẹ̀ wọnú ìgbéyàwó
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Má ṣe jẹ́ kẹ́nikẹ́ni fipá tì ẹ́ sínú fífìfẹ́ hàn lọ́nà tí ò bójú mu