Kí Ló Dé Tí Ọ̀fìnkìn Tí Nǹkan Tó Ń Kù Ń Fà fi Ń Yọ Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lẹ́nu?
Látọwọ́ òǹkọ̀wé Jí! ní Sípéènì
OJÚ ń yún ọ, ó sì ń ṣomi, ò ń sín ṣáá, ikun sì ń dà nímú rẹ, imú rẹ dí, ó sì ń ṣòro fún ọ láti mí. Kí ló ń ṣẹlẹ̀? Bóyá ọ̀fìnkìn ló ń ṣe ọ́. Ṣùgbọ́n bó bá ń ṣe ọ́ báyìí nígbà tó o bá wà nítòsí àwọn nǹkan lẹ́búlẹ́bú tó ń kù, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀fìnkìn tí nǹkan tó ń kù ń fà, ìyẹn hay fever, ló ń dà ọ́ láàmú. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ pọ̀ lẹ́nu ẹ̀. Ńṣe ni iye àwọn tí wọ́n rí pé wọ́n ní irú ọ̀fìnkìn yìí ń pọ̀ sí i lọ́dọọdún.
Ìwé ìròyìn Mujer de Hoy ròyìn pé: “Ohun tó ń fa irú ọ̀fìnkìn yìí ò ju bí ara wa ṣe máa ń ṣe tí nǹkan tó kà sí eléwu bá ti wọbẹ̀. Àwọn èèyàn kan wà tí ọ̀pọ̀ nǹkan ò bá lára mu, agbára ìgbóguntàrùn irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ò lè gba àwọn nǹkan tó bá kà sí àjèjì mọ́ra, títí kan àwọn ohun lẹ́búlẹ́bú tó wà lára àwọn ewéko, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan wọ̀nyí ò fi bẹ́ẹ̀ léwu.” Bó bá sì wá di pé agbára ìgbóguntàrùn rí báyìí, ó lè fa àwọn àmì àìsàn irú èyí tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ́ yìí.
Lọ́dún 1819, oníṣègùn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà John Bostock ṣàpèjúwe ohun tó ń jẹ́ hay fever, ìyẹn ọ̀fìnkìn tí nǹkan tó ń kù máa ń fà. Òun lẹni tó kọ́kọ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Bostock ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn àmì àrùn tó rí lásìkò tí irú ọ̀fìnkìn yìí máa ń jà. Ó gbà pé ohun tó kù sí òun nímú nígbà tó lọ gé ìjẹ ẹran ló fà á. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí i pé oríṣiríṣi nǹkan lẹ́búlẹ́bú tó ń kù ló ń fa irú ọ̀fìnkìn yìí. Níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún ìwọ̀nba èèyàn kéréje ni Bostock rí pé wọ́n láìsàn yìí lára nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
Kí ló wá dé tí ọ̀fìnkìn tí nǹkan tó ń kù máa ń fà fi ń ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí? Dókítà Javier Subiza tó jẹ́ olùdarí Ibùdó fún Ìtọ́jú Ikọ́ Òsúkè àti Àwọn Àìsàn tí Nǹkan Tí Ò Báni Lára Mu Ń Fà ní Madrid ní Sípéènì mẹ́nu kan àbá méjì tí wọ́n ń ṣèwádìí nípa ẹ̀. Àbá kan ni pé àwọn ẹ́ńjìnnì tó ń lo epo dísù ló ń fà á. Wọ́n gbà pé èéfín tó ń tara àwọn ẹ́ńjìnnì tó ń lo epo dísù jáde lè mú káwọn èròjà tí ò bá wa lára mú wọlé sí àgọ́ ara wa, ó sì lè máa dà wá láàmú. Dókítà Juan Kothny Pommer, onímọ̀ nípa àwọn ohun tó ṣàjèjì lára sọ pé “láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà, ọ̀fìnkìn tí nǹkan tó ń kù ń fà ń da ìdámárùn-ún àwọn aráàlú láàmú nítorí pé wọ́n sábàá máa ń lọ sáwọn ìlú ńlá.”
Àbá kejì fi hàn pé ohun tó ń fà á kò ju àpọ̀jù ìmọ́tótó. Dókítà Subiza ṣàlàyé pé: ‘Ilé ìwòsàn tó mọ́ nigín-nigín ni wọ́n bí wa sí, oúnjẹ tó mọ́ tónítóní là ń jẹ, à ń gba abẹ́rẹ́ àjẹsára nítorí ọ̀pọ̀ àrùn, tára wa ò bá sì yá, kíá la ó ti gbé oògùn tí ń gbógun ti kòkòrò àrùn lura. Nítorí náà, láti kékeré la ti kọ́ agbára ìgbóguntàrùn wa láti má lè mú ọ̀pọ̀ nǹkan mọ́ra.’
Bí irú ọ̀fìnkìn yìí bá ń ṣe ọ nítorí pé ara rẹ ò ríbi gba ẹ̀gbin kankan sí, má bọkàn jẹ́! Pẹ̀lú àyẹ̀wò àti ìtọ́jú tó tọ́, ó ṣeé ṣe láti dín bó ṣe ń dà ọ́ láàmú tó àti bó ṣe ń ṣe ọ́ lemọ́lemọ́ kù.