ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 6/8 ojú ìwé 31
  • Ó Yẹ Ká Kó Ahọ́n Wa Níjàánu Bíi Tẹṣin

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Yẹ Ká Kó Ahọ́n Wa Níjàánu Bíi Tẹṣin
  • Jí!—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Máa Fi Ìfẹ́ Àti Ọ̀wọ̀ Hàn Fún Ara Yín Nípa Kíkó Ahọ́n Yín Níjàánu
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìgbàgbọ́ Ń sún Wa Ṣiṣẹ́!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Jí!—2004
g04 6/8 ojú ìwé 31

Ó Yẹ Ká Kó Ahọ́n Wa Níjàánu Bíi Tẹṣin

Sólómọ́nì, ọlọgbọ́n Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì sọ pé: “Ẹṣin ni ohun tí a pèsè sílẹ̀ fún ọjọ́ ìjà ogun.” (Òwe 21:31) Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń lo àwọn agẹṣinjagun tó pọ̀ láti lè jagunmólú. Látìgbà láéláé làwọn jagunjagun ti máa ń lo ìjánu láti darí bí wọ́n ṣe fẹ́ kí ẹṣin máa ṣe àti bí wọ́n ṣe fẹ́ kó rọ́kú tó.

Ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica pè ní ìjánu ni “àpapọ̀ àwọn okùn tẹ́ẹ́rẹ́ tí wọ́n so mọ́ irin tí wọ́n fi há ẹṣin lẹ́nu kó bàa lè ṣeé darí bí wọ́n bá ṣe ń fa àwọn okùn náà.” Àwọn ìjánu ayé àtijọ́ ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí tòde òní, wọ́n sì wúlò gan-an ni tá a bá fẹ́ tu ẹṣin lójú kó lè ṣeé darí, ká sì máa gùn ún.

Ọba Dáfídì tó jẹ́ bàbá Sólómọ́nì ṣe bí ẹní ń sọ bí ìjánu ti ṣe pàtàkì tó nígbà tó kọ̀wé pé: “Ẹ má sọ ara yín di ẹṣin tàbí ìbaaka tí kò ní òye, tí ó jẹ́ pé ìjánu tàbí okùn ẹran ni a fi ń ki ìtapọ́n-ún-pọ́n-ún rẹ̀ wọ̀.” (Sáàmù 32:9) Téèyàn bá ti tu ẹṣin lójú báyìí, ó lè dọ̀rẹ́ tó ń báni tálẹ́. Alẹkisáńdà Ńlá fẹ́ràn ẹṣin rẹ̀ tó ń jẹ́ Bucephalus tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi sọ orúkọ ìlú kan tó wà ní Íńdíà ní orúkọ ẹṣin yẹn kó lè fi máa rántí rẹ̀.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé látọdúnmọ́dún làwọn èèyàn ti ń tu ẹṣin lójú tí wọ́n sì ń darí rẹ̀, àtidarí ẹran ara wa aláìpé yìí ti dogun dọdẹ. Kristẹni ọmọlẹ́yìn náà, Jákọ́bù, ṣàkíyèsí pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé, tí ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ pẹ̀lú níjàánu.” (Jákọ́bù 3:2) Èwo nínú wa gan-an ló lè sọ pé òun ò tí ì sọ̀rọ̀ láìronújinlẹ̀ rí, tàbí tí kò tíì sọ̀rọ̀ kòbákùngbé tàbí ọ̀rọ̀ ìbínú rí?

Kí ló wá dé tá a fi ń da ara wa láàmú lórí kíkó ahọ́n wa níjàánu nígbà tó jẹ́ pé ‘kò sí ẹnikẹ́ni tó lè kó o níjàánu’? (Jákọ́bù 3:8) Ìdí rèé o, àwọn èèyàn lè lo àkókò tó pọ̀, wọ́n sì lè ṣòpò nítorí àtikó ẹṣin níjàánu, nítorí wọ́n mọ̀ pé táwọn bá kọ́ ọ dáadáa, ó wúlò fáwọn. Bákan náà, bá a bá ṣe lè dárí ahọ́n wa tó tàbí bá a bá ṣe lè kó o níjàánu tó bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa wúlò fún wa tó.

Ọ̀rọ̀ tá a bá fi ìgbatẹnirò sọ lè tu àwọn ọ̀rẹ́ wa, àwọn alábàáṣiṣẹ́ wa àtàwọn ìbátan wa lára, ó sì lè fún wọn níṣìírí. (Òwe 12:18) Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lè mú kí ìgbésí ayé àwọn tó wà ní sàkáání wa tù wọ́n lára. Àmọ́, ahọ́n tá ò bá kó níjàánu máa ń dá họ́ùhọ́ù sílẹ̀. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Fi ìṣọ́ ṣọ́ . . . ahọ́n rẹ kí o bà a lè pa ara rẹ mọ́ kúrò nínú ìjàngbọ̀n.” (Òwe 21:23, The New English Bible) Bá a bá ṣe rí ahọ́n wa kó níjàánu tó, bẹ́ẹ̀ la ṣe máa ran ara wa àtàwọn tó ń fetí sí wa lọ́wọ́ tó.a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó dùn mọ́ni pé Bíbélì rán àwọn Kristẹni létí pé ohun tó ń jáde lẹ́nu wọn kò ṣeé yà kúrò lára ìjọsìn wọn. Ó sọ pé: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí lójú ara rẹ̀ bá dà bí olùjọsìn ní irú ọ̀nà kan, síbẹ̀ tí kò kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu, ṣùgbọ́n tí ó ń bá a lọ ní títan ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ, ọ̀nà ìjọsìn ọkùnrin yìí jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.”—Jákọ́bù 1:26.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Alẹkisáńdà Ńlá

[Credit Line]

Alinari/Art Resource, NY

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́