Ẹ Káàbọ̀ sí Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn”
◼ Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló máa pésẹ̀ sí àwọn ọgọ́rọ̀ọ̀rún ibi tá ó ti ṣe àpéjọ àgbègbè yìí jákèjádò ayé. Àkọ́kọ́ nínú àwọn àpéjọ ọlọ́jọ́ mẹ́ta yìí, tí a ó ṣe méjìlélógóje [142] rẹ̀ ní Nàìjíríà, yóò wáyé ní October 8 sí 10, 2004, èyí tó máa jẹ́ àṣekágbá rẹ̀ yóò sì wáyé ní January 14 sí 16, 2005. Ó ṣeé ṣe kí ọ̀kan lára àwọn ìkórajọ ọlọ́jọ́ mẹ́ta yìí, tá a sábà máa ń ṣe ní ọjọ́ Friday sí ọjọ́ Sunday wáyé ní ìlú kan tó sún mọ́ ibi tí ò ń gbé.
Láwọn ibi tó pọ̀ jù lọ, a ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ohun orin tí a ó fi ṣí ìpàdé ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ní agogo mẹ́sàn-án àbọ̀ òwúrọ̀. Ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ Friday ni “Èyí Ni Ọ̀nà. Ẹ Máa Rìn Nínú Rẹ̀.” Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀ náà, “A Kóra Jọ Kí Jèhófà Lè Kọ́ Wa ní Ọ̀nà Rẹ̀,” a óò gbọ́ apá kan tí wọ́n á ti fọ̀rọ̀ wá àwọn tí wọ́n ń fi ìdúróṣinṣin bá Ọlọ́run rìn lẹ́nu wò. Lẹ́yìn tá a bá gbọ́ àwọn àwíyé náà, “Ẹ Máa Wádìí Ohun Tí Ẹ̀yin Fúnra Yín Jẹ́” àti “Máa Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Tọ́ Ìṣísẹ̀ Rẹ Lójoojúmọ́,” a óò wá gbọ́ lájorí ọ̀rọ̀ àwíyé tá ó fi kádìí ìjókòó àárọ̀ nílẹ̀, àkòrí rẹ̀ ni “Bá Ọlọ́run Rìn Nígbà Hílàhílo.”
Lára àwọn nǹkan tá a máa gbádùn lọ́sàn-án Friday ni àpínsọ àsọyé alápá-mẹ́ta náà, “Àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà Ń Fún Wa Níṣìírí Láti Bá Ọlọ́run Rìn.” Àwọn àsọyé tí yóò tẹ̀ lé e ni “Má Ṣe Ya ‘Ohun Tí Ọlọ́run Ti So Pọ̀’” àti “Bíbọ̀wọ̀ fún Àwọn Ìpéjọpọ̀ Wa Mímọ́.” Àsọyé tí yóò kádìí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ náà nílẹ̀, “Ìhìn Rere fún Àwọn Èèyàn Gbogbo Orílẹ̀-Èdè,” yóò fún wa níṣìírí láti wàásù ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tó ń sọ gbogbo èdè.
Ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ Saturday ni “Ẹ Máa Ṣọ́ra Lójú Méjèèjì Nípa Bí Ẹ Ṣe Ń Rìn.” Àpínsọ àsọyé tá a óò gbọ́ ní àárọ̀ ọjọ́ yẹn ni, “Títẹ̀síwájú Gẹ́gẹ́ bí Òjíṣẹ́,” ó ní apá kan tí yóò fún wa láwọn àbá lórí bá a ṣe lè dé ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n ń sọ èdè mìíràn. Ọ̀rọ̀ pàtàkì kan tí yóò kádìí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àárọ̀ ọjọ́ náà ni “Bíbá Jèhófà Rìn Nípa Àdéhùn,” lẹ́yìn ọ̀rọ̀ yìí làwọn tó tóótun láti ṣèrìbọmi yóò láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Lára àwọn àsọyé tá a óò gbọ́ lọ́sàn-án Saturday ni “Yàgò fún ‘Ohunkóhun Tó Lè Fa Ìkọ̀sẹ̀’” àti “Àwọn Ìgbòkègbodò Gbígbámúṣé Tó Ń Mára Tuni.” A óò gbádùn àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó ń fúnni níṣìírí nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀rọ̀ mẹ́tà tó tẹ̀ lé e yìí tí àkòrí wọn jẹ́, “Jèhófà Ni Olùṣọ́ Àgùntàn Wa,” “Ríra Àkókò Tí Ó Rọgbọ Padà,” àti “Rírìn ní Ọ̀nà Ìmọ́lẹ̀ Tó Túbọ̀ Ń Mọ́lẹ̀ Sí I.” Àsọyé tó ń múni ronú jinlẹ̀ tí yóò kádìí ìjókòó ọjọ́ náà ni “‘Ẹ Máa Ṣọ́nà’—Wákàtí Ìdájọ́ Ti Sún Mọ́lé.”
Àsọyé náà, “Ẹ̀yin Èwe—Ẹ Máa Rìn ní Ọ̀nà Òdodo,” yóò tẹnu mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Sunday, ìyẹn ni, “Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Rírìn Nínú Òtítọ́.” Lẹ́yìn náà la óò wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ kan tó dá lórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nínú èyí tí wọ́n ti múra bí àwọn ará ìgbàanì. Àsọyé kan tí yóò ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà la óò gbọ́ tẹ̀ lé e. Lọ́sàn-án ọjọ́ yìí, a óò gbọ́ àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí àkòrí rẹ̀ jẹ́, “Bíbá Ọlọ́run Rìn Ń Ṣe Wá Láǹfààní Nísinsìnyí àti Títí Ayé.”
Tó o bá fẹ́ mọ èyí tó sún mọ́ ilé rẹ jù lára ibi tá ó ti ṣe àpéjọ yìí, o lè lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kó o kọ̀wé béèrè lọ́wọ́ àwọn tó ń tẹ ìwé ìròyìn yìí.