Ayọ̀ àti Ìṣòro Ìgbà Ìbàlágà
ÌGBÀ ìbàlágà lè jẹ́ àkókò tó gbádùn mọ́ni gan-an. Bó sì ṣe rí fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà nìyẹn. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti dàgbà sì máa ń láyọ̀ gan-an nígbà tí wọ́n bá rántí bí ìgbà ọ̀dọ́ àwọn ṣe rí.
Àmọ́ ṣá, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé “àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” là ń gbé nínú ẹ̀ yìí o. (2 Tímótì 3:1) Ìyẹn ló sì fà á tí ìṣòro tó ń bá àwọn ọ̀dọ́ fínra fi ń pọ̀ sí i, àwọn ìṣòro yìí sì yàtọ̀ sí tàwọn ará àtijọ́. Bóyá ohun tó fà á rèé tí Sabrina Solin Weill, olóòtú àgbà ìwé ìròyìn kan tó wà fáwọn ọ̀dọ́, fi sọ pé ẹnú-kọ̀ròyìn gbáà lohun tójú àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà ń rí. Ńṣe ló dà bí ẹní ń rìn lórí okùn tẹ́ẹ́rẹ́ tí wọ́n so mọ́ igi méjì tó ga fíofío tó sì jẹ́ pé bí ẹsẹ̀ rẹ̀ bá yẹ̀ gẹ̀rẹ́ báyìí orí ilẹ̀ fìfo ló ń bọ̀. Láìṣe àníàní, àkókò ìbàlágà tí ọkàn kì í sábà lélẹ̀ bọ̀rọ̀ yìí máa ń mú kéèyàn ronú pé ohun ò mọ nǹkan ṣe, ó máa ń múni ṣàníyàn, ó sì máa ń mú kéèyàn má mọ èwo ni ṣíṣe. Gẹ́gẹ́ bí Weill ṣe sọ nínú ìwé tó kọ, “nǹkan kì í fi bẹ́ẹ̀ rọgbọ fáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà bí wọ́n ti ń fi ìgbà ọmọdé sílẹ̀ tí wọ́n sì ń mókè àgbà gùn.”
Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà, báwo lo ṣe lè kojú àwọn ìṣòro tó o bá bá pàdé? Bó o bá jẹ́ òbí ọmọ kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà, kí ló lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rántí báwọn ọdún oní-ságbà-súlà ti ìgbà ọ̀dọ́ ṣe rí kó o bàa lè lóye ohun tí ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ ń fojú winá rẹ̀? Nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí, a ké sí tọmọdé tàgbà láti bá wa ká lọ bá a ti ń yiiri ọ̀rọ̀ nípa ìbàlágà sọ́tùn-ún, tá à ń yiiri ẹ̀ sósì. Èyí á ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti forí rọ́ ìṣòro tó ń bá ìgbà ìbàlágà rìn, àti pé wọ́n á tún lè ṣe é láṣeyọrí.