Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
July 8, 2004
Fífàyà Rán Ìṣòro Ìgbà Ìbàlágà
Ohun tójú àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà ń rí dà bíi ti ‘ẹni tó ń rìn lórí okùn tẹ́ẹ́rẹ́ tí wọ́n so mọ́ igi méjì tó ga fíofío.’ Báwo ni wọ́n ṣe lè borí ìṣòro náà?
10 “Kò Yẹ Kí Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìlú Gbófin Tara Ẹ̀ Kalẹ̀”
17 Ìdí Tí Mo Fi Gba Bíbélì Gbọ́ Onímọ̀ Nípa Agbára Átọ́míìkì Sọ Ìtàn Ara Rẹ̀
30 Wíwo Ayé
32 Ìyá Tó Mòye
Àwọn Ìnira Ìgbà Ogun Mú Mi Gbára Dì fún Bá A Ṣeé Gbé Ìgbésí Ayé 12
Bá wa ká lọ bá a ti ń sọ ìtàn alárinrin nípa ọkùnrin kan tí ìgbésí ayé ẹ̀ nira láti kékeré, nígbà tí ogun ń jà nílẹ̀ Yúróòpù, títí tó fi di míṣọ́nnárì nílẹ̀ Áfíríkà níbi tó ti nírìírí kíkàmàmà.
Béèyàn bá ń pẹ́ lẹ́yìn nígbà gbogbo, ó lè dá rúdurùdu sínú ìgbésí ayé èèyàn, ó sì tún lè mú kéèyàn ní ìṣòro lẹ́nu iṣẹ́. Àwọn ìmọ̀ràn díẹ̀ tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o má bàa máa pẹ́ lẹ́yìn wà nínú àpilẹ̀kọ yìí.