‘Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Mi Yìí?’
“Ó dà bí ẹni pé mo tají lọ́jọ́ kan báyìí, gbogbo nǹkan sì ti yí padà látòkèdélẹ̀. Ó wá ń ṣe mí bí ẹni pé ńṣe ni mo gbé ara mìíràn wọ̀.”—Sam.
KÍ LÓ ń jẹ́ ìgbà ìbàlágà? Ká sọ ọ́ lọ́nà tó lè tètè yéni, ó jẹ́ àkókò tó wà láàárín ìgbà ọmọdé àtìgbà téèyàn di àgbàlagbà. Ó jẹ́ àkókò táwọn ìyípadà pípabanbarì máa ń wáyé nínú ìdàgbàsókè ara, ìrònú àti pàápàá nínú àjọṣe ẹni pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Lédè kan, ìgbà ìbàlágà máa ń gbádùn mọ́ni gan-an ni. Ó ṣe tán, ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ni pé àgbà ti ń kan ìwọ náà. Ohun mìíràn ni pé, ní àkókò tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà yìí, oríṣiríṣi èrò lá a máa sọ sí ẹ lọ́kàn, àwọn kan lára wọn lè mú kí gbogbo nǹkan tojú sú ọ, wọ́n tiẹ̀ lè mú àyà rẹ já pàápàá.
Àmọ́ o, ìyẹn ò wá ní kí ìgbà ìbàlágà máa já ọ láyà o. Lóòótọ́ ni pé àwọn wàhálà kan máa ń bá ìgbà yìí rìn. Ṣùgbọ́n, àǹfààní àgbàyanu ló jẹ́ fún ọ láti fìgbà ọmọdé sílẹ̀ kó o sì kẹ́sẹ járí bó o ti ń mókè àgbà gùn. Jẹ́ ká wo ọ̀nà tó o lè gbé e gbà nípa kíkọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ìṣòro táwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà máa ń bá yí.
Nígbà Tó O Bá Bẹ̀rẹ̀ Sí Bàlágà
Nígbà ìbàlágà, ara rẹ á bẹ̀rẹ̀ sí yí padà kó bàa lè ṣeé ṣe fún ọ láti mú ọmọ jáde nípasẹ̀ ìbálòpọ̀. Ó máa ń gba ọ̀pọ̀ ọdún kí ìyípadà tí wọ́n ń pè ní ìbàlágà yìí tó parí, a sì máa tó rí i pé ó tún nípa tó ń kó lórí ìdàgbàsókè míì nínú ara yàtọ̀ sí ti ẹ̀yà ìbímọ.
Àwọn obìnrin sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ sí bàlágà láàárín ọdún mẹ́wàá sí méjìlá, ìbàlágà tàwọn ọkùnrin sì máa ń bẹ̀rẹ̀ láàárín ọdún méjìlá sí mẹ́rìnlá. Ìpíndọ́gba lásán lèyí ṣá o, ó ṣeé ṣe kó yá tàbí kó pẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ nígbà míì. Gẹ́gẹ́ bí ìwé The New Teenage Body Book ṣe sọ, “ọ̀nà tí ara ẹnì kọ̀ọ̀kan ń gbà ṣiṣẹ́ yàtọ̀ tó fi jẹ́ pé ìgbà tí ìyípadà kọ̀ọ̀kan máa ń wáyé béèyàn bá ń bàlágà kì í dọ́gba.” Ó wá fi kún un pé: “Kò sí ìgbà kan pàtó tá a lè fọwọ́ sọ̀yà pé ó dáa jù lọ kí ìbàlágà bẹ̀rẹ̀.” Kò sí láburú kankan bó o bá bẹ̀rẹ̀ sí bàlágà ṣáájú àwọn ọ̀gbà rẹ, tàbí lẹ́yìn tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀.
Nígbà yòówù tí ìbàlágà bá bẹ̀rẹ̀, ó lè mú kí ìrísí rẹ, ìmọ̀lára rẹ àti ojú tó o fi ń wo àwọn ohun tó yí ọ ká yí padà. Bá wa ká lọ bá a ti ń ṣàyẹ̀wò àkókò aláìlẹ́gbẹ́ yìí nínú ìgbésí ayé ẹ̀dá. Ó láwọn ìṣòro nínú o, àmọ́ ó dùn joyin lọ.
‘Kí Ló Dé Tára Mi Ń Yí Padà?’
Bí àwọn omi kan nínú ara tó ń súnná sí ìdàgbàsókè bá ti ń pọ̀ sí i, ìbàlágà bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Àwọn omi wọ̀nyí ni omi estrogen lára àwọn obìnrin àti omi testosterone lára àwọn ọkùnrin. Ìyípadà tó jẹ mọ́ pípọ̀ tí omi inú ara yìí ń pọ̀ sí i wà lára ohun tó ń fà á tó fi máa ń dà bí ẹni pé ara ń yí padà lọ́nà àgbàyanu. Kódà, lẹ́yìn tó o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí bàlágà, ńṣe ni ara rẹ á wá máa yára dàgbà sí i ju ti ìgbà tó o wà lọ́mọdé lọ.
Lákòókò yìí, àwọn ẹ̀yà ìbímọ rẹ á bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà, ṣùgbọ́n apá kan ṣoṣo péré nínú ìdàgbà àwọn ẹ̀yà ara nìyẹn jẹ́ o. O tún lè bẹ̀rẹ̀ sí yára ga sí i, èyí ni wọ́n sábà máa ń pè ní ìwúdàgbà. Nígbà tó jẹ́ pé nígbà ọmọdé nǹkan bíi gígùn àtàǹpàkò ọwọ́ lo fi ń ga sí i lọ́dọọdún, lákòókò ìwúdàgbà yìí ṣọ̀ọ̀ ni wà á máa ga sí i ní ìlọ́po méjì ìyẹn.
Ní gbogbo àkókò yìí, kò ní ṣaláì máa ṣe ẹ́ bí ẹni pé ara rẹ rí págunpàgun. Kò lè ṣe kó máà rí bẹ́ẹ̀. Rántí pé, àwọn apá ibì kan lára rẹ lè máa yára dàgbà ju àwọn mìíràn lọ. Ó sì lè mú kára rí gánkugànku. Ṣùgbọ́n na sùúrù sí i. Aburú kankan ò ní ṣẹlẹ̀ sí ọ. Gbogbo págunpàgun ìgbà ìbàlágà máa tó kọjá lọ.
Nígbà ìbàlágà, àwọn obìnrin á bẹ̀rẹ̀ sí í rí nǹkan oṣù, ìyẹn ni ìsunjáde ẹ̀jẹ̀ àti awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó ṣí kúrò lára ilé ọmọ.a Nítorí ẹ̀jẹ̀ tó ń jáde lára, inú máa ń kan àwọn obìnrin kan gbínrín gbínrín bí wọ́n bá ń ṣe nǹkan oṣù, sísun àwọn omi inú ara sì máa ń dín kù. Níwọ̀n bí àwọn ìyípadà yìí ti máa ń nípa lórí ìṣesí àti ìrònú ẹni, ara ẹni kì í balẹ̀ nígbà tí nǹkan oṣù bá bẹ̀rẹ̀. Teresa, tó ti di ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún báyìí rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Wẹ́rẹ́ báyìí ni ìyípadà tá à ń wí yìí wáyé. Inú mi dà rú, ìrora ibẹ̀ sì pọ̀. Bó sì ṣe ń ṣẹlẹ̀ lóṣooṣù nìyẹn!”
Tó o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń rí nǹkan oṣù, kò sí ìdí kankan fún ọ láti máa gbọ̀n jìnnìjìnnì. Ó ṣe tán, ọ̀nà kan tó o lè gbà mọ̀ pé ara rẹ ń ṣiṣẹ́ dáadáa nìyẹn. Bó bá yá, wà á mọ nǹkan tó o lè ṣe nípa àwọn ìnira tó máa ń bá nǹkan oṣù rìn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ti rí i pé ṣíṣe eré ìdárayá déédéé máa ń dín kíkan tí inú máa ń kan wọ́n kù. Ṣùgbọ́n, ara yàtọ̀ sí ara o. O lè rí i pé ṣe ló yẹ kó o dín sá sókè sá sódò kù pátápátá nígbà tó o bá ń ṣe nǹkan oṣù. Máa kíyè sí ara ẹ, kó o sì fún un ní ohun tó bá ń fẹ́.
Nígbà ìbàlágà, àtọkùnrin àtobìnrin ni wọ́n máa ń ṣàníyàn gan-an nípa ìrísí wọn. Teresa sọ fún wa láṣìírí pé: “Ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí bàlágà ni mo dẹni tó ń ṣàkíyèsí ara mi, tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí bìkítà nípa ojú táwọn ẹlòmíì fi ń wo ìrísí mi.” Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Síbẹ̀ náà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìrísí mi kì í tẹ́ mi lọ́rùn. Irun orí mi máa ń dà rú, aṣọ mi máa ń ṣe gbàgẹ̀rẹ̀, mo sì fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè rí aṣọ tó wù mí mọ́!”
Ohun tó ò retí tún lè máa ṣẹlẹ̀ nínú ara ẹ. Bí àpẹẹrẹ, ara rẹ á máa ṣẹ́ òógùn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ nígbà ìbàlágà, ìyẹn sì lè mú kó o túbọ̀ máa làágùn wọ̀rùwọ̀rù. O lè dín òórùn ara kù nípa wíwẹ̀ tàbí bíbomi ṣanra déédéé, àti fífọ aṣọ rẹ mọ́ tónítóní. Bákan náà, lílo lọ́fínńdà àti ìpara tó ń dín òógùn kù ò ní jẹ́ kí ara máa ṣíyàn-án.
Nígbà ìbàlágà ibi tí òróró ti ń sun jáde lára náà máa ń lágbára sí i, ìyẹn sì lè mú kó o ní irorẹ́. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Ann sọ ohun tó máa ń dùn ún pé: “Ìgbà tí mo bá fẹ́ kójú mi gún régé jù gan-an ló dà bí ẹni pé mo máa ń ní irorẹ́. Ṣé èmi ni mò ń rò bẹ́ẹ̀, àbí ohun kan wà tó máa ń kọ lẹ́tà sáwọn irorẹ́ wọ̀nyẹn pé kí wọ́n bò mí lójú nígbà tí mi ò tiẹ̀ fẹ́ rí wọn rárá ni?” Irorẹ́ ò jẹ́ kí Teresa náà gbádùn. Ó sọ pé: “Ó máa ń bà mí lójú jẹ́, á sì dà bíi pé èmi ni gbogbo èèyàn dojú bò, nítorí pé nígbà táwọn èèyàn bá wo apá ọ̀dọ̀ mi, màá rò pé òun ni wọ́n ń wò!”
Nǹkan lè lé sáwọn ọkùnrin náà lára ṣá o. Kódà, àwọn ògbógi kan sọ pé nǹkan máa ń tètè sú sáwọn ọkùnrin lára ju àwọn obìnrin lọ. Yálà o jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin tàbí ọ̀dọ́bìnrin, ohun tó máa pé ẹ jù lọ ni pé kó o máa fọ àwọn ibi tó bá ń ṣòróró lára rẹ déédéé, títí kan ojú, ọrùn, èjìká, ẹ̀yìn àti àyà rẹ. Ìyẹn nìkan kọ́ o, fífọ irun orí rẹ déédéé tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti má ṣe jẹ́ kí òróró tibẹ̀ sun lọ sára ẹ. Bákan náà, àwọn nǹkan ìtọ́jú ara wà tí wọ́n ṣe fún pípa irorẹ́. Teresa sọ pé: “Àwọn òbí mi bá mi wá ìpara àtàwọn òróró àgbéléṣe tí mo fi ń ṣíra. Wọn kì í tún jẹ́ kí n jẹ àpọ̀jù oúnjẹ párupàru. Tí mi ò bá sì jẹ oúnjẹ párupàru tí mo ń mu omi tó pọ̀, irorẹ́ mi sábà máa ń lọ.”
Ohun mìíràn tó tún máa ń yí padà, pàápàá jù lọ lára àwọn ọkùnrin, ni ohùn wọn. Ó ṣeé ṣe kí àwọn okùn ohùn (tán-án-ná) rẹ nípọn kí wọ́n sì gùn sí i nígbà ìbàlágà, èyí á sì mú kí ohùn rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Bill gan-an nìyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò kíyè sí i bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Mi ò mọ̀ pé ohùn mi ti yí padà, àfi ti pé àwọn èèyàn ò rò pé màmá mi tàbí ẹ̀gbọ́n mi ló ń sọ̀rọ̀ mọ́ nígbà tí mo bá lọ gbé fóònù láti dá ẹni tó tẹ̀ wá láago lóhùn.”
Nígbà míì, ohùn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ máa yí padà lè máa há, ó sì lè ṣàdédé lọ sókè nígbà téèyàn bá ń sọ̀rọ̀. Bí Tyrone ṣe ń níran ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó sọ pé: “Kò sí ohun tó ti èèyàn lójú tó o. Ìgbàkigbà tí ojora bá mú mi, tàbí tí inú mi bá dùn jù ló máa ń ṣẹlẹ̀. Mo máa ń gbìyànjú láti má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun da ọkàn mi rú, àmọ́ ọ̀rọ̀ ṣì máa ń rí bẹ́ẹ̀.” Tyrone fi kún un pé: “Lẹ́yìn ọdún kan tàbí méjì ṣá, kò tún ní ṣẹlẹ̀ mọ́.” Bí ohùn tìẹ náà bá ń há, má ṣe jáyà! Ohùn tìẹ náà ò ní pẹ́ débi tí ò ti ní kẹ̀ sí i mọ́.
‘Kí Ni Gbogbo Èyí Tó Ń Ṣẹlẹ̀ sí Mi Yìí?’
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló sábà máa ń kó àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà lọ́kàn sókè. Bí àpẹẹrẹ, o lè rí i pé àjọṣe tó wà láàárín ìwọ àti ọ̀rẹ́minú ìgbà èwe rẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí dín kù. Kì í ṣe pé bóyá ẹ jà o. Ó kàn lè jẹ́ pé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ohun tó wá ń wu olúkúlùkù báyìí ni. Kódà, àwọn òbí rẹ, tó o máa ń sá lọ bá nígbà kan tó o bá nílò ìtùnú àti ààbò, lè dà bí ẹni tí ò rọ́ọ̀ọ́kán mọ́ àtẹni tí ò ṣeé fọ̀rọ̀ lọ̀.
Gbogbo èyí lè mú kí ọ̀dọ́ kan dà bí ẹni tí kò rẹ́ni bá rìn. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Àwọn olùṣèwádìí kan sọ pé ìgbà ìbàlágà ni ìṣòro dídá wà máa ń pọ̀ tó sì máa ń ṣe lemọ́lemọ́ ju ìgbà téèyàn wà lọ́mọdé tàbí ìgbà tó ti dàgbà lọ.” Nítorí ìbẹ̀rù pé àwọn ẹlòmíràn lè máa wò ọ́ bí ẹni tọ́rọ̀ ẹ̀ ò bá ti ẹgbẹ́ ẹ̀ mu, ó lè máa ṣe ọ́ bíi kó o má finú han àwọn ẹlòmíràn. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe lò ń lọ́ tìkọ̀ láti fìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn, nítorí pé lódò ikùn rẹ̀ lọ́hùn-ún ò ń ronú pé kò sẹ́ni tá á fẹ́ bá ọ ṣọ̀rẹ́.
Ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà tó fi dórí ọ̀pọ̀ àwọn tó ti dàgbà ni wọ́n máa ń ní ìṣòro dídá wà. Ohun tó ṣe pàtàkì láti fi sọ́kàn ni pé, bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, irú èrò báwọ̀nyí á wábi gbà.b Rántí o, nítorí pé o ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo nǹkan pátá ló ń yí padà lára rẹ. Lemọ́lemọ́ sì lojú tó o fi ń wo ìgbésí ayé, tó o fi ń wo àwọn ẹlòmíràn, àtèyí tó o fi ń wo ara rẹ pàápàá á máa yí padà. Àní sẹ́, ìwọ fúnra ẹ lè dà bí àjèjì síra ẹ nígbà mìíràn tó o bá wo dígí! Ọ̀rọ̀ rẹ lè dà bíi ti Steve, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, tó ní òun gbà pé, “Ó ṣòro gan-an láti sọ pé o mọ bí ara ẹ ṣe rí, nígbà tó jẹ́ pé yíyí lara ọ̀hún ń yí padà lemọ́lemọ́.”
Ọ̀kan lára ọ̀nà tó dára jù lọ téèyàn lè gbà kojú dídá wà ni pé kó tọ àwọn ẹlòmíràn lọ. Èyí lè túmọ̀ sí pé kó o sún mọ́ àwọn míì tí ò sí lára àwọn ẹgbẹ́ ẹ. Ṣé èyíkéyìí wà lára àwọn àgbà ọlọ́jọ́ orí tí wọ́n á fẹ́ kó o bẹ àwọn wò? Ṣé o lè bá wọn ṣe àwọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, pàápàá jù lọ bí wọ́n bá nílò ìrànlọ́wọ́? Bíbélì gba gbogbo èèyàn, àtàgbà àtèwe, níyànjú pé kí wọ́n “gbòòrò síwájú” nínú ìfẹ́ni wọn fáwọn ẹlòmíràn. (2 Kọ́ríńtì 6:11-13) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àǹfààní púpọ̀ jaburata.
Ọ̀kan péré ni ẹsẹ Bíbélì tá a fà yọ lókè yìí jẹ́ lára àwọn ìlànà rẹpẹtẹ tó ti ran àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro ìgbà ìbàlágà. Bó o ti ń ka àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, ṣàyẹ̀wò bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ṣe ìgbésí ayé rẹ ní rere bó o ti ń bàlágà.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí nǹkan oṣù bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ó lè máa wáyé lemọ́lemọ́ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ lóṣù, ó sì lè fo oṣù míì dá láìwáyé. Bó ṣe ń dà lára tó náà tún máa ń yàtọ̀ síra. Má ṣe jẹ́ kí èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí bà ọ́ lẹ́rù. Àmọ́ ṣá, bí nǹkan oṣù bá ń wáyé gátagàta fún odidi ọdún kan tàbí méjì, ara ń kìlọ̀ fún ọ pé kó o lọ rí dókítà nìyẹn.
b Bí ìṣòro dídá wà náà bá ga ọ́ lára jù tàbí tó o bá ń ronú àtipa ara ẹ, á dáa kó o tètè wá ìrànwọ́. Má ṣe jáfara, fọ̀rọ̀ lọ àwọn òbí ẹ tàbí ẹnì kan tó o lè finú hàn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn Òbí Lè Ṣàṣìṣe
“Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo lérò pé àwọn òbí mi ò lè ṣàṣìṣe. Nígbà tí mo di ọ̀dọ́langba, mo kàn ṣáà wá rí i pé ó níbi táwọn náà kù díẹ̀ káàtó sí. Ohun tí mò ń sọ ni pé mo wá mọ̀ pé àwọn òbí mi kì í ṣe ẹni tí ò lè ṣàṣìṣe, ìyẹn sì mú kí ominú máa kọ mí. Láìròtẹ́lẹ̀, ohun tí mo mọ̀ yìí mú kí n máa ṣiyèméjì nípa èrò wọn àti ìpinnu wọn. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí àwọn ipò líle koko tí mo là kọjá ti kọ́ mi lọ́gbọ́n, mo ti dẹni tó bọ̀wọ̀ fún wọn ní kíkún. Ó dájú pé wọn kì í ṣe ẹni tí ò lè ṣàṣìṣe, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ wọn sábà máa ń tọ̀nà. Bí ọ̀rọ̀ wọn ò bá tiẹ̀ tọ̀nà, àwọn ló bí mi lọ́mọ. Ọ̀rọ̀ wa túbọ̀ ń wọ̀ sí i, èyí tí mo rò pó jẹ́ ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn.”—Teresa, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló ti di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn àgbàlagbà