ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 51
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ìbàlágà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ìbàlágà?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí ni ìbàlágà?
  • Ara ẹ máa yí pa dà
  • Ìmọ̀lára àti ìṣesí ẹ máa yí pa dà
  • Ohun tó o lè ṣe
  • Bó O Ṣe Lè Ran Ọmọ Rẹ Tó Ń Bàlágà Lọ́wọ́
    Jí!—2016
  • ‘Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Mi Yìí?’
    Jí!—2004
  • Kí Nìdí Tára Mi Fi Ń Yí Pa Dà?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Ìyípadà Ara
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 51
Àwọn ọ̀dọ́ yìí jọ ń wo ọ̀ọ́kán, àmọ́ ìṣesí gbogbo wọn yàtọ̀ síra

ÀWỌN Ọ̀DỌ̀ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ìbàlágà?

“Ohun tí ojú àwọn obìnrin máa ń rí tí wọ́n bá ń bàlágà kì í ṣe kékeré. Wọ́n máa ń kojú ìnira, nǹkan ìdọ̀tí tí wọ́n máa ń rí sì máa ń tojú sún wọn. Lọ́rọ̀ kan ṣá, kì í rọrùn fún wọn!”​—Oksana.

“Ìgbà míì inú mi á dùn, tó bá yá, inú mi á bà jẹ́. Mí ò mọ̀ bóyá bó ṣe ń ṣe gbogbo ọkùnrin nìyẹn, àmọ́ bó ṣe ń ṣe èmi nìyẹn.”​—Brian.

Tó o bá ń bàlágà, ó lè máa dùn mọ́ ẹ, kó sì tún máa dẹ́rù bà ẹ́! Àmọ́ báwo lo ṣe lè kojú rẹ̀?

  • Kí ni ìbàlágà?

  • Ara ẹ máa yí pa dà

  • Ìmọ̀lára àti ìṣesí ẹ máa yí pa dà

  • Ohun tó o lè ṣe

Kí ni ìbàlágà?

Ìbàlágà jẹ́ ìgbà kan ní ìgbésí ayé èèyàn téèyàn máa ń yára dàgbà di géńdé, tí ìmọ̀lára èèyàn á sì máa yí pa dà. Ìyípadà yìí máa ń lágbára, torí àwọn ẹ̀yà ara rẹ á máa yára dàgbà sí i, àwọn ohun kan á sì máa yí pa dà lára rẹ. Tó bá wá yá, wàá dẹni tó máa lè bímọ.

Àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ọmọ bíbí ló kàn o. Bó o ṣe ń bàlágà á kàn jẹ́ kó o mọ̀ pé o kì í ṣe ọmọdé mọ́ ni, ìyẹn sì lè jẹ́ kó o máa ronú ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ, tàbí kó máa bà ẹ́ nínú jẹ́ nígbà míì.

Ìbéèrè: Ọmọ ọdún wo lo rò pé ó yẹ kéèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí i bàlágà?

  • 8

  • 9

  • 10

  • 11

  • 12

  • 13

  • 14

  • 15

  • 16

Ìdáhùn: Téèyàn bá ti pé ìkankan nínú àwọn ọdún yìí, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í bàlágà.

A jẹ́ pé kò sídìí fún ẹ láti máa yọ ara ẹ lẹ́nu tó o bá ti ń sún mọ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, tó ò sì tíì máa bàlágà. Má sì jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu tó ò bá tíì pé ọmọ ọdún mẹ́wàá tó o sì ti ń bàlágà. Èèyàn ò lè pinnu ìgbà tóun máa bẹ̀rẹ̀ sí í bàlágà torí ara yàtọ̀ sára.

Àwọn ọmọ kan ń gun jangirọ́fà; ọ̀kan bojú jẹ́, ẹ̀rù ń ba èkejì, inú ọmọ kẹta sì ń dùn

Téèyàn bá ń bàlágà, bí ẹni ń gun jangirọ́fà tó ń lọ sókè sódò ló rí. Ó lè máa dùn mọ́ ẹ, kó sì tún máa dẹ́rù bà ẹ́, àmọ́ o lè kojú ẹ̀, kó o sì ṣàṣeyọrí

Ara ẹ máa yí pa dà

Téèyàn bá ti ń bàlágà, ohun tó sábà máa ń tètè kíyè sí ni pé àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ á máa yára dàgbà. Ìṣòro tó kàn wà níbẹ̀ ni pé àwọn ẹ̀yà ara ọ̀hún kì í dàgbà bákan náà, àwọn ibì kan máa ń yára dàgbà tàbí tóbi ju àwọn míì lọ. Torí náà, máà jẹ́ kó ṣàjèjì sí ẹ, bí àpẹẹrẹ, bó o ṣe ń rìn lè fẹ́ máa yí pa dà sí ti tẹ́lẹ̀ torí pé àwọn ẹ̀yà ara kan ti tóbi sí i tàbí gùn sí i. Fọkàn balẹ̀, gbogbo ẹ̀ ṣì máa wà bó ṣe yẹ kó wà.

Àwọn ohun míì tún máa yí pa dà lára ẹ bó o ṣe ń bàlágà.

Lára ọkùnrin:

  • Ẹ̀yà ìbímọ á máa tóbi sí i

  • Irun máa hù ní abíyá, abẹ́ àti ojú

  • Ohùn máa ki

  • Ara ẹ lè máa dédé dìde, kí àtọ̀ sì dà lára ẹ nígbà tó ò ń sùn lóru

Lára obìnrin:

  • Ọmú máa tóbi sí i

  • Irun máa hù ní abíyá àti abẹ́

  • Nǹkan oṣù á bẹ̀rẹ̀ sí í wá

Lára ọkùnrin àti obìnrin:

  • Ara ẹ lè fẹ́ máa rùn torí òógùn àti kòkòrò àrùn tó ń fa òórùn.

    Àbá: Tó o bá ń wẹ̀ déédéé, tó o sì ń lo lọ́fíńdà tàbí ìpara tó ń dín òórùn kù, ara ẹ ò ní máa rùn.

  • Ìrorẹ́ á máa yọ sí ẹ lára torí kòkòrò tó ń wo ibi tí òróró ti ń sun lára.

    Àbá: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìrorẹ́ kì í lọ bọ̀rọ̀, ó máa dín kù tó o bá ń fọ ojú ẹ déédéé, tó o sì ń lo ìpara ojú tó ń fọ ìdọ̀tí àti òróró.

Ìmọ̀lára àti ìṣesí ẹ máa yí pa dà

Báwọn ẹ̀yà ara ẹ ṣe ń dàgbà sí i, bó o ṣe ń ronú àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ẹ náà á máa yí pa dà. Ìṣesí rẹ tiẹ̀ lè ṣàdédé máa yí pa dà.

“Lọ́jọ́ míì, ẹkún ni màá sun, lọ́jọ́ kejì báyìí, ara mi á yá gágá. Inú lè bí mi nísìnyí o, tó bá fi máa ṣe díẹ̀, inú yàrá ni màá lọ ti ara mi mọ́, tí màá máa ronú.”​—Oksana.

Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó ń bàlágà ló máa ń bẹ̀rù tí wọ́n á sì máa ṣọ́ra ṣe, àfi bíi pé gbogbo èèyàn ló ń wò wọ́n tó sì ń ṣọ́ wọn. Èyí tó wá máa ń bọ̀rọ̀ jẹ́ fún wọn ni pé ìrísí wọn ti ń yàtọ̀, àwọn èèyàn á sì máa tètè kíyè sí i!

“Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í bàlágà, ṣe ni mo máa ń mọ̀ọ́mọ̀ wọ aṣọ tó tóbi, màá wá máa ṣe bí ẹni tó rẹ̀. Lóòótọ́, mo mọ ohun tó fà á tí ara mi fi ń yí pa dà, àmọ́ kò bá mi lára mu rárá, ó máa ń tì mí lójú nígbà míì. Torí bí ara mi ṣe rí látilẹ̀ kọ́ nìyẹn.”​—Janice.

Èyí tó ṣeé ṣe kó wá fọba lé e ni ojú tí wàá máa fi wo ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ.

“Mi kì í rò ó pé ṣe làwọn ọkùnrin ń da èèyàn láàmú mọ́. Ọ̀pọ̀ wọn tiẹ̀ ti wá ń wù mí báyìí, kéèyàn yófẹ̀ẹ́ ẹnì kan kì í kúkú ṣe nǹkan bàbàrà. Kódà, ‘ta lò ń fẹ́’ lọ̀pọ̀ èèyàn wá ń sọ kiri.’”​—Alexis.

Àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń kíyè sí i pé bí àwọn ṣe ń bàlágà, ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tàwọn lọkàn àwọn máa ń fà sí. Tó bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ ni ẹ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í pẹ́ tírú ìmọ̀lára yẹn fi máa ń pòórá.

“Ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí àwọn ọkùnrin bíi tèmi torí mo máa ń rí àwọn tó rẹwà jù mí lọ dáadáa nínú wọn. Ìgbà tí mo fi máa dàgbà díẹ̀ sí i ni mo bá tún kíyè sí i pé àwọn obìnrin lọkàn mi ń fà sí. Tọkùnrin tobìnrin lọkàn mi wá ń fà sí. Ìyẹn ti di ìtàn báyìí ṣá!”​—Alan.

Ohun tó o lè ṣe

  • Gbìyànjú láti fi ojú tó tọ́ wò ó. Ká sòótọ́, àwọn ohun kan máa yí pa dà lára ẹ bó o ṣe ń bàlágà, ojú tó o fi ń wo nǹkan àti bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí lára ẹ náà máa yí pa dà, àmọ́ ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní. Ọ̀rọ̀ tí onísáàmù náà, Dáfídì sọ tiẹ̀ lè mú kó dá ẹ lójú, ó sọ pé: “Lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu.”​—Sáàmù 139:14.

  • Má fi ara ẹ wé ti ẹlòmíì, kó o sì gbìyànjú láti máà jẹ́ kí bó o ṣe rí gbà ẹ́ lọ́kàn jù. Bíbélì sọ pé: “Ènìyàn . . . ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.”​—1 Sámúẹ́lì 16:7.

  • Máa ṣe eré ìmárale dáadáa, kó o sì máa sinmi. Tó o bá ń sùn dáadáa, o ò ní máa tètè bínú, kò ní máa rẹ̀ ẹ́ jù, o ò sì ní máa fi gbogbo ìgbà sorí kọ́.

  • Má kàn gbà pé òótọ́ ni gbogbo èrò òdì tó ń wá sí ẹ lọ́kàn.’ Rò ó dáadáa, ṣé lóòótọ́ ni gbogbo èèyàn ń ṣọ́ ẹ? Táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń sọ oríṣiríṣi nǹkan nípa ìrísí ẹ tó ń yí pa dà, ìwọ ronú nípa àǹfààní tó wà nínú bí ìrísí ẹ ṣe ń yí pa dà. Bíbélì sọ pé: “Má fi ọkàn-àyà rẹ sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn lè máa sọ.”​—Oníwàásù 7:​21.

  • Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi kó o ní ìbálòpọ̀, kọ́ bó o ṣe lè séra ró. Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa sá fún àgbèrè. . . . Ẹni tí ó bá ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.”​—1 Kọ́ríńtì 6:18.

  • Bá òbí ẹ tàbí àgbàlagbà kan tó ṣe é fọkàn tán sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Lóòótọ́ ó lè kọ́kọ́ ṣe ẹ́ bákàn láti bá wọn sọ̀rọ̀. Àmọ́ o ò ní kábàámọ̀ pé o ṣe é, torí wọ́n máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an.​—Òwe 17:17.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Kì í rọrùn téèyàn bá ń bàlágà. Àmọ́ lásìkò yẹn, wàá dàgbà sí i, bó o ṣe ń ronú àti bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹ máa dáa sí i, wàá sì tún lè sún mọ́ Ọlọ́run​—1 Sámúẹ́lì 2:26.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́