ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Kí Ni Mo Lè Ṣe Kí N Lè Máa Sùn Dáadáa?
Tó o bá ń jó àjórẹ̀yìn nínú iṣẹ́ iléèwé ẹ̀, o lè ronú pé ó yẹ kó o túbọ̀ fojú sí ẹ̀kọ́ ẹ dáadáa. Tó bá sì jẹ́ pé o ò ṣe dáadáa mọ́ nínú eré ìdárayá, o lè ronú pé ó yẹ kó o túbọ̀ máa ṣe ìdánrawò dáadáa. Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àìsùn dáadáa ló fa ìṣòro ẹ. Jẹ́ ká wo ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀.
Ìdí tó fi yẹ kó o máa sùn dáadáa?
Àwọn tó ń ṣèwádìí sọ pé wákàtí mẹ́jọ sí mẹ́wàá ló yẹ káwọn ọ̀dọ́ fi máa sùn lálaalẹ́. Kí nìdí tíyẹn fi ṣe pàtàkì?
Oorun máa ń jẹ́ kí ọpọlọ jí pépé. Àwọn kan sọ pé “oorun ni oúnjẹ ọpọlọ.” Tó o bá sùn dáadáa, ó lè jẹ́ kí ọpọlọ ẹ̀ túbọ̀ jí sí iṣẹ́ iléèwé ẹ̀, kó o sì túbọ̀ máa ṣe dáadáa nínú eré ìdárayá. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa jẹ́ kó o lè ronú dáadáa tó o bá fẹ́ yanjú ìṣòro.
Oorun máa ń jẹ́ kára tuni, kí inú èèyàn sì dùn. Téèyàn ò bá sùn dáadáa, ó lè máa kanra, kí inú ẹ̀ má dùn tàbí kó rẹ̀wẹ̀sì. Yàtọ̀ síyẹn, ó lè ṣòro fún un láti bá àwọn míì ṣọ̀rẹ́.
Oorun máa ń jẹ́ kéèyàn lè wakọ̀ dáadáa. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé àwọn awakọ̀ tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́rìndínlógún (16) sí mẹ́rìnlélógún (24) sábà máa ń tòògbé lásìkò tí wọ́n ní ìjàǹbá ọkọ̀. Àmọ́ ọ̀rọ̀ kì í rí bẹ́ẹ̀ láàárín àwọn awakọ̀ tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ogójì (40) ọdún sí mọ́kàndínlọ́gọ́ta (59).
Oorun máa ń jẹ́ kéèyàn ní ìlera tó dáa. Bí àpẹẹrẹ, àsìkò yẹn lara máa ń tún àwọn sẹ́ẹ̀lì ṣe, títí kan ẹran ara àti iṣan tí ẹ̀jẹ̀ ń gbà kọjá. Téèyàn bá sùn dáadáa, kò ní jẹ́ kéèyàn tètè ní àìsàn bí ìtọ̀ ṣúgà àti rọpárọsẹ̀, kò sì ní jẹ́ kéèyàn sanra jọ̀kọ̀tọ̀.
Bó ṣe jẹ́ pé èèyàn gbọ́dọ̀ ki fóònù bọ iná kó tó lè ṣiṣẹ́ dáadáa, ó ṣe pàtàkì kíwọ náà máa sùn dáadáa kára ẹ lè jí pépé
Kí ni kì í jẹ́ kó o rí oorun sùn?
Pẹ̀lú gbogbo àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa sùn dáadáa, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni kì í rí oorun sùn tàbí kí wọ́n má sùn tó. Bí àpẹẹrẹ, Elaine tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) sọ pé:
“Olùkọ́ wa bi wá pé aago mélòó la máa ń lọ sùn. Ọ̀pọ̀ sọ pé aago méjì òru. Àwọn míì sọ pé aago márùn-ún ìdájí. Ọmọ kan ṣoṣo péré ló sọ pé aago mẹ́sàn-án ààbọ̀ lòun máa ń sùn.”
Àwọn nǹkan wo ló lè mú kó ṣòro fún ẹ láti máa sùn dáadáa?
Bó o ṣe ń gbé ìgbésí ayé rẹ. “Ó rọrùn gan-an láti máa fàkókò ṣòfò kéèyàn sì pẹ́ kó tó sùn, pàápàá lọ́jọ́ téèyàn bá jáde pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀.”—Pamela.
Ojúṣe. “Àtisùn kì í ṣe ìṣòro mi rárá, àmọ́ tí mo bá wo adúrú nǹkan tó wà nílẹ̀ láti ṣe, oorun máa fò lọ ni.”—Ana.
Ẹ̀rọ ìgbàlódé. “Fóònù mi ni kì í jẹ́ kí n sùn. Ó máa ń ṣòro fún mi láti gbé e sílẹ̀ ti ń bá ti wà lórí bẹ́ẹ̀dì.”—Anisa.
Kí lo lè ṣe tí wàá fi máa sùn dáadáa?
Mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn máa sùn dáadáa. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílé ohun tó jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.” (Oníwàásù 4:6) Oorun ṣe pàtàkì, kì í ṣọ̀rọ̀ pé bóyá ó wuni tàbí kò wuni. Téèyàn ò bá sùn dáadáa, iṣẹ́ rẹ̀ á máa falẹ̀, kódà kó ní gbádùn ìgbésí ayé ẹ̀!
Mọ ohun pàtó tí kì í jẹ́ kó o sùn dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, ṣé o máa ń pẹ́ níta pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ? Ṣé kì í ṣe pé iṣẹ́ tó wà lọ́rùn ẹ ti pọ̀ jù? Ṣé fóònù rẹ ló máa ń jẹ́ kó o pẹ́ sùn àbí òun ló ń jẹ́ kó o tètè jí?
Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ó máa ń gba ìsapá gan-an kó o tó lè borí ohun tí kì í jẹ́ kó o sùn dáadáa, àmọ́ àǹfààní tí wàá rí ju iṣẹ́ rẹ̀ lọ. Òwe 21:5 sọ pé: “Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere.”
Fi sọ́kàn pé, ohun tó ṣiṣẹ́ fẹ́nì kan lè má ṣiṣẹ́ fún ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan sọ pé táwọn bá rẹjú díẹ̀ lọ́sàn-án, ó máa ń jẹ́ káwọn lè sùn dáadáa lálẹ́. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ fáwọn míì. Torí náà, mọ ohun tó máa bá ẹ lára mu. Àwọn àbá tó wà nísàlẹ̀ yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́:
Jẹ́ kára tù ẹ́ dáadáa kó o tó lọ sùn. Tó o bá ti rọra na ẹ̀yìn sílẹ̀ ṣáájú àkókò tó máa sùn, á jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti tètè sùn.
“Ó dáa kó o parí iṣẹ́ èyíkéyìí tó o bá ní lásìkò, ìyẹn ò ní jẹ́ kó o máa ronú nípa iṣẹ́ náà tó o bá fẹ́ sùn.”—Maria.
Ṣètò ara ẹ dáadáa. Dípò kó jẹ́ pé àwọn nǹkan tó o bá fẹ́ ṣe ló máa pinnu ìgbà tó o máa sùn, ṣètò ara ẹ lọ́nà tí wàá fi lè sùn lásìkò tó yẹ.
“Mo mọ̀ pé wákàtí mẹ́jọ ló yẹ kí n fi sùn lálẹ́. Torí náà, tí mo bá ti mọ̀ pé ohun kan wà tó máa gba pé kí n tètè jí lọ́jọ́ kejì, mo máa ń tètè sùn kí n lè rí i dájú pé mo sun oorun wákàtí mẹ́jọ.”—Vincent.
Ní àkókò pàtó tí wàá máa sùn. Tó o bá ti ní àkókò pàtó tó o máa ń lọ sùn, tó bá yá, á mọ́ ẹ lára. Àwọn tó ń ṣèwádìí sọ pé ó dáa kéèyàn ní àkókò pàtó táá lọ sùn àti àkókò pàtó tó máa dìde lójoojúmọ́. O ò ṣe gbìyànjú ẹ̀ fún oṣù kan, ó ṣeé ṣe kó o rí ìyàtọ̀ nínú ìlera ẹ.
“Tó o bá ń sùn lákòókò kan náà lálaalẹ́, wàá rí i pé ará máa tù ẹ́ lọ́jọ́ kejì. Èyí á jẹ́ kó o túbọ̀ jáfáfá nínú ohunkóhun tó o bá dáwọ́ lé.”—Jared.
Sapá láti wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Bíbélì sọ pé kò yẹ ká máa “ṣe àṣejù” nínú ohunkóhun tá a bá ń ṣe, èyí sì kan ohun tá à ń ṣe lásìkò ọwọ́dilẹ̀.—1 Tímótì 3:2, 11.
“Mo ti dín àkókò tí mo máa ń lò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ lọ́wọ́ alẹ́ kù. Tí mi ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, nǹkan kan ló máa jìyà ẹ̀, oorun mi ló sì sábà máa ń jẹ́!”—Rebecca.
Jẹ́ kí fóònù rẹ náà sinmi! Ó kéré tán, wákàtí kan ṣáájú kó o tó sùn ni ko o ti gbé fóònù rẹ sílẹ̀, má ṣe lọ sórí íńtánẹ́ẹ̀tì, má sì máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́. Kódà, àwọn olùṣèwádìí kìlọ̀ pé iná fóònù tàbí ti tẹlifíṣọ̀n lè mú kó ṣòro láti rí oorun sùn.
“Àwọn èèyàn máa ń ronú pé gbogbo ìgbà ló yẹ káwọn lè kàn sí ẹ. Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé kó o tó lè sinmi dáadáa, ó gbọ́dọ̀ gbé fóònù ẹ sílẹ̀.”—Julissa.