ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g16 No. 2 ojú ìwé 8-9
  • Bó O Ṣe Lè Ran Ọmọ Rẹ Tó Ń Bàlágà Lọ́wọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bó O Ṣe Lè Ran Ọmọ Rẹ Tó Ń Bàlágà Lọ́wọ́
  • Jí!—2016
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO
  • OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀
  • OHUN TÓ O LÈ ṢE
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ìbàlágà?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • ‘Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Mi Yìí?’
    Jí!—2004
  • Kí Nìdí Tára Mi Fi Ń Yí Pa Dà?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Bá A Ṣe Lè Máa Bá Àwọn Ọmọ Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Ń Bàlágà Sọ̀rọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Jí!—2016
g16 No. 2 ojú ìwé 8-9
Bàbá kan ń bá ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Bó O Ṣe Lè Ran Ọmọ Rẹ Tó Ń Bàlágà Lọ́wọ́

Bàbá kan àti ọmọ rẹ̀ ń wo àmì tó sọ̀rọ̀ nípa bí ọmọ ṣe ń bọ́ sí ipò àgbà

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Ọjọ́ náà rèé bí àná, tó o gbé ọmọ rẹ jòjòló lọ́wọ́. Ọmọ náà sì ti ń dàgbà. Òótọ́ ni pé ó ṣì kéré, àmọ́ ní báyìí, ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bàlágà.

Lásìkò tí ọmọ bá ń bàlágà, nǹkan máa ń tojú sú u, torí pé àsìkò yẹn ni ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ máa bẹ̀rẹ̀ sí í tóbi. Báwo lo ṣe lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ nírú àsìkò yìí?

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Àsìkò tí ọmọ máa ń bàlágà. Ọmọ lè bẹ̀rẹ̀ sí í bàlágà láti nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́jọ, àwọn ọmọ míì sì lè tó ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] kí wọ́n tó bàlágà. Ìwé Letting Go With Love and Confidence sọ pé: “Àkókò tí àwọn ọmọ máa ń bàlágà máa ń yàtọ̀ síra.”

Ojú máa ń ti ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà. Àwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà máa ń ronú lórí ojú tí àwọn èèyàn fi ń wò wọ́n. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Jareda sọ pé: “Mo máa ń kíyè sí ìrísí mi gan-an mo sì máa ń ṣọ́ra ṣe. Tí mo bá wà láàárín àwọn èèyàn, ó máa ń ṣe mí bíi pé ńṣe ni mo dá yàtọ̀ láàárín wọn.” Ìtìjú wọn tún máa ń pọ̀ sí i tí ifo tàbí irorẹ́ bá yọ sí wọn lójú. Kellie, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sọ pé: “Ó ń ṣe mí bíi pé ojú mi ti fẹ́ bà jẹ́. Mo rántí pé mo máa ń sunkún, mo sì máa ń pe ara mi ní ọ̀bọ.”

Àwọn tó bá tètè bàlágà máa ń kan ìṣòro. Pàápàá àwọn ọmọbìnrin. Wọ́n lè máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ tí wọ́n bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í gúnyàn. Ìwé kan tó ń jẹ́ A Parent’s Guide to the Teen Years sọ pé: “Èyí lè mú kí wọ́n wà nínú ewu torí pé ojú àwọn ọkùnrin oníṣekúṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí í wà lára wọn.”

Ti pé ọmọ bàlágà kò túmọ̀ sí pé ó ti gbọ́n. Òwe 22:15 sọ pé: “Ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí.” Ti pé ọmọ kan bàlágà kò túmọ̀ sí pé ó ti gbọ́n. Ìwé You and Your Adolescent sọ pé, ìrísí ọmọ kan lè jọ ti ẹni tó ti dàgbà, àmọ́ “ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ó máa lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání tàbí kó hùwà ọgbọ́n. Bákan náà, ìyẹn ò sọ pé ó máa lè kó ara rẹ̀ ní ìjánu tàbí kó hùwà àgbà láwọn ọ̀nà míì.”

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Kí ọmọ rẹ tó bàlágà ni kó o ti ṣàlàyé fún un. Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ àwọn àmì tó máa rí tó bá ti ń bàlágà. Sọ nípa àwọn àyípadà tó máa ń wáyé lójijì tó sì lè mú kí nǹkan tojú sú u. Bí àpẹẹrẹ, sọ fún ọmọbìnrin rẹ nípa ṣíṣe nǹkan oṣù, kó o sì sọ fún ọmọkùnrin rẹ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan á máa da àtọ̀ tó bá sùn. Èyí yàtọ̀ sí àwọn àyípadà míì tó máa ń ṣẹlẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Tó o bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìyípadà yìí, má ṣe sọ ọ́ bíi pé nǹkan burúkú ló ń ṣẹlẹ̀ sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o jẹ́ kó mọ̀ pé àwọn ìyípadà yẹn máa jẹ́ kó kúrò lọ́mọdé.—Ìlànà Bíbélì: Sáàmù 139:14.

Má ṣe pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ John sọ pé: “Ńṣe làwọn òbí mi ń pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ nígbà tí wọ́n ń ṣàlàyé àwọn ìyípadà náà fún mi. Ì bá dáa ká ní wọ́n sojú abẹ níkòó.” Irú èrò yìí ni ọ̀dọ́bìnrin ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún [17] tórúkọ rẹ ń jẹ́ Alana náà ní. Ó sọ pé: “Màmá mi ṣàlàyé àwọn àyípadà tó dé bá ara mi, àmọ́ ì bá dáa ká ní wọ́n tún ṣàlàyé bí mo ṣe lè kojú àwọn àyípadà náà.” Kí ni èyí kọ́ wa? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà kì í rọrùn láti sọ, ohun tó dáa jù ni pé kó o ṣàlàyé gbogbo ohun tó jẹ mọ́ bíbàlágà fún ọmọ rẹ.—Ìlànà Bíbélì: Ìṣe 20:20.

Béèrè ìbéèrè tó máa jẹ́ kí ọmọ rẹ sọ tọkàn rẹ̀. Kí ọmọ rẹ lè sọ tinú ẹ̀, o lè sọ ohun tójú àwọn míì rí nígbà tí wọ́n ń bàlágà. Bí àpẹẹrẹ, o lè bi ọmọbìnrin rẹ pé, “Ṣé ẹnikẹ́ni ní kíláàsì rẹ ti ń sọ̀rọ̀ nípa ṣíṣe nǹkan oṣù?” “Ṣé wọ́n máa ń fi ọmọbìnrin tó bá tètè bàlágà ṣe yẹ̀yẹ́?” O lè bi ọmọkùnrin rẹ pé, “Ṣé wọ́n máa ń fi àwọn tí kò bá tètè bàlágà ṣe yẹ̀yẹ́?” Táwọn ọmọ bá ń sọ ohun tójú àwọn míì ń rí nígbà tí wọ́n bàlágà, ó máa rọrùn fún wọn láti sọ bí àwọn àyípadà náà ṣe rí lára wọn àti ohun tójú wọn ń rí. Nígbà tí wọ́n bá ń sọ tinú wọn, tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.”—Jákọ́bù 1:19.

Ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè ní “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú.” (Òwe 3:21) Kì í ṣe àwọn àyípadà ara nìkan ló ń fi hàn pé ọmọ kan ń bàlágà. Àsìkò yìí làwọn ọmọ máa ń kọ́ ọgbọ́n tó máa jẹ́ kí wọ́n lè máa ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání tí wọ́n bá dàgbà. Lo àsìkò yìí láti kọ́ ọmọ rẹ ní ìwà rere.—Ìlànà Bíbélì: Hébérù 5:14.

Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ kì í fẹ́ sọ fáwọn òbí wọn nípa àwọn ìyípadà tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn bí wọ́n ṣe ń bàlágà, àmọ́ má ṣe jẹ́ kí èyí mú ẹ rẹ̀wẹ̀sì. Ìwé kan tó ń jẹ́ You and Your Adolescent sọ pé: “Àwọn ọmọ tó máa ń tijú tàbí tí kì í fẹ́ sọ̀rọ̀ lè máa há gbogbo ohun tí ò ń sọ sórí.”

a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.

FI ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ YÌÍ SỌ́KÀN

  • “Lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu.”​—Sáàmù 139:14.

  • ‘Èmi kò fà sẹ́yìn kúrò nínú sísọ èyíkéyìí lára àwọn ohun tí ó lérè nínú fún yín.’​—Ìṣe 20:20.

  • “Àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú . . . kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”​—Hébérù 5:14.

“Àwọn òbí mi ràn mí lọ́wọ́ gan-an nígbà tí mò ń bàlágà, pàápàá jù lọ màmá mi. Wọ́n fara balẹ̀ ṣàlàyé bó ṣe máa rí fún mi dáadáa. Èyí jẹ́ kí n gbara dì fún ohun tó ń bọ̀, torí náà àwọn ìyípadà yẹn kò bá mi lójijì. Màmá mi tún máa ń mú kí ara tù mí tí mo bá ń bá wọn sọ̀rọ̀. Àwọn òbí mi mú kó rọrùn fún mi láti kojú àsìkò náà.”—Marie, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16].

“Àwọn òbí mi kò dá mi dá àsìkò náà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí mi fọ̀wọ̀ mi wọ̀ mí torí wọ́n mọ̀ pé gbogbo ìyípadà yẹn ń kó ìtìjú bá mi. Bí wọ́n ṣe pa ọ̀rọ̀ náà mọ́ láṣìírí tún jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀. Wọ́n sì ti ṣàlàyé àwọn àyípadà tí màá rí ṣáájú kí n tó bẹ̀rẹ̀ sí í rí wọn.”—Joan, ọmọ ọdún méjìdínlógún [18].

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́