ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 8/8 ojú ìwé 26-27
  • Ṣé Lóòótọ́ Ni Ọlọ́run Bìkítà Nípa Àwọn Ọmọdé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Lóòótọ́ Ni Ọlọ́run Bìkítà Nípa Àwọn Ọmọdé?
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọ́run Dẹ́bi Fáwọn Tó Ń Hùwà Ìkà Sáwọn Ọmọdé
  • Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ọmọdé
  • Ìrètí Tó Wà Fáwọn Ọmọdé
  • Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Láti Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Bá A Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Nínú Ilé
    Jí!—1993
  • Ẹ Máa Wáyè Gbọ́ Tàwọn Ọmọ
    Jí!—2005
  • Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Jẹ́ Aláyọ̀?—Apá Kejì
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 8/8 ojú ìwé 26-27

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣé Lóòótọ́ Ni Ọlọ́run Bìkítà Nípa Àwọn Ọmọdé?

LỌ́DỌỌDÚN, ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọdé ni wọ́n ń kó nífà, ni wọ́n ń hùwà ìkà sí, tí wọ́n sì ń ṣe bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú. Ńṣe ni wọ́n ń kó ọ̀pọ̀ lára wọn ṣiṣẹ́ bí ẹrú lábẹ́ àwọn ipò tó léwu. Wọ́n jí àwọn míì gbé sá lọ wọ́n sì fipá sọ wọ́n di sójà tàbí ọ̀dọ́mọdé aṣẹ́wó. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé ò nígbọ̀ọ́kànlé nínú àwọn àgbàlagbà mọ́ nítorí pé a rí lára àwọn ìbátan tó sún mọ́ wọn tó ti bá wọn lò pọ̀ rí tí wọ́n sì hu àwọn ìwà àìdáa míì tó burú jáì sí wọn.

A lè wá rí ìdí tí ìṣòro táwọn ọmọdé ń dojú kọ fi ń da àwọn olóòótọ́ ọkàn, tí wọ́n bìkítà láàmú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan gbà pé ìwà ojúkòkòrò ẹ̀dá àti ìwà ìbàjẹ́ ni olórí ohun tó ń fa irú ìwàkiwà bẹ́ẹ̀, ó ṣì lè ṣòro fáwọn kan láti gbà pé Ọlọ́run ìfẹ́ á gba irú ìwà àìṣòdodo bẹ́ẹ̀ láyè. Wọ́n lè ronú pé Ọlọ́run ti pa àwọn ọmọ wọ̀nyí tì àti pé bóyá kò bìkítà nípa wọn nítòótọ́. Ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí? Ǹjẹ́ ìròyìn tó ń bani nínú jẹ́ náà pé wọ́n ń kó àwọn ọmọdé nífà tí wọ́n sì sábà máa ń hùwà ìkà sí wọn fi hàn pé Ọlọ́run ò bìkítà nípa wọn? Kí ni Bíbélì sọ?

Ọlọ́run Dẹ́bi Fáwọn Tó Ń Hùwà Ìkà Sáwọn Ọmọdé

Kì í ṣe ète Jèhófà Ọlọ́run pé káwọn àgbà tí ò lójú àánú máa kó àwọn ọmọdé nífà. Ọ̀kan lára àbájáde búburú jù lọ tó tẹ̀yìn ìwà ọ̀tẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn nínú ọgbà Édẹ́nì wá ni híhùwà ìkà sáwọn ọmọdé. Kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ láti tẹrí ba fún ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ló fa kí ẹ̀dá ènìyàn máa fìwà òǹrorò kó ẹ̀dá ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nífà.—Jẹ́nẹ́sísì 3:11-13, 16; Oníwàásù 8:9.

Ọlọ́run kórìíra àwọn tó bá ń kó àwọn aláìlera àtàwọn tí ò lè gbèjà ara wọn nífà. Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ìgbàanì tí wọn ò sin Jèhófà fi àwọn ọmọ wọn rúbọ, ṣùgbọ́n Jèhófà sọ pé èyí jẹ́ ‘ohun tí òun kò pa láṣẹ tí kò sì wá sínú ọkàn-àyà òun.’ (Jeremáyà 7:31) Ọlọ́run kìlọ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀ ìgbàanì pé: “Bí o bá ṣẹ́ [ọmọdékùnrin aláìníbaba] níṣẹ̀ẹ́ pẹ́nrẹ́n, tí ó sì ké jáde sí mi pẹ́nrẹ́n, èmi yóò gbọ́ igbe ẹkún rẹ̀ láìkùnà; ìbínú mi yóò sì ru ní ti gidi.”—Ẹ́kísódù 22:22-24.

Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ọmọdé

Nínú àwọn ìtọ́ni ọlọgbọ́n tí Ọlọ́run fún àwọn òbí, ó ṣe kedere pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọdé. Àwọn ọmọ tí wọ́n bá tọ́ dàgbà nínú ilé tí àlàáfíà ti jọba, sábà máa ń níwà àgbà, wọ́n sì máa ń di ẹni tó lè bẹ́gbẹ́ òun ọ̀gbà pé. Ìdí nìyẹn tí Ẹlẹ́dàá wa fi dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀, èyí jẹ́ ètò wíwà títí nínú èyí tí ‘ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ tí yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.’ (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Nínú Bíbélì, inú ìdè ìgbéyàwó nìkan ni Ọlọ́run ti fàṣẹ sí ìbálòpọ̀ kí ọmọ tó bá tipasẹ̀ irú ìbálòpọ̀ bẹ́ẹ̀ wá lè rẹ́ni bójú tó o lábẹ́ ipò tó fara rọ.—Hébérù 13:4.

Ìwé Mímọ́ tún tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé káwọn òbí máa tọ́ ọmọ wọn. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà; èso ikùn jẹ́ èrè. Bí àwọn ọfà ní ọwọ́ alágbára ńlá, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ìgbà èwe rí.” (Sáàmù 127:3, 4) Àwọn ọmọ jẹ́ ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó sì fẹ́ kí wọ́n dàgbà. Ọlọ́run gba àwọn òbí níyànjú láti fún àwọn ọmọ wọn ní ìtọ́sọ́nà tó dáa nínú ìgbésí ayé, bíi ti tafàtafà tó kọ́kọ́ máa ń fojú sun ibi tó fẹ́ tafà sí kó tó ta á. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn nítọ̀ọ́ni pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.”—Éfésù 6:4.

Ọ̀nà mìíràn tí Jèhófà ti gbà fi ìfẹ́ tó ní sáwọn ọmọ hàn ni nípa kíkọ́ àwọn òbí ní ọ̀nà tí wọ́n lè gbà dáàbò bo àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ àwọn tó ń kó wọn nífà. Ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì, Ọlọ́run pàṣẹ fún “àwọn ọmọ kéékèèké” pàápàá pé kí wọ́n tẹ́tí sí Òfin, èyí tó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ ìwà ìbálòpọ̀ tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́. (Diutarónómì 31:12; Léfítíkù 18:6-24) Ọlọ́run fẹ́ káwọn òbí sa gbogbo ipá wọn láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ kó wọn nífà tàbí tó bá fẹ́ hùwà ìkà sí wọn.

Ìrètí Tó Wà Fáwọn Ọmọdé

Jésù Kristi fi àpẹẹrẹ ìfẹ́ wíwà títí tí Jèhófà ní sáwọn ọmọdé lélẹ̀, nítorí pé ó fara wé Bàbá rẹ̀ lọ́nà pípé nípa lílo irú ànímọ́ tó ní. (Jòhánù 5:19) Nígbà táwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kan rò pé ńṣe làwọn ń ran Jésù lọ́wọ́ nípa líle àwọn òbí padà kí wọ́n má bàa gbé àwọn ọmọ wọn kékeré wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ìwà tí wọ́n hù yìí bí Jésù nínú, ó sì tún ojú ìwòye wọn ṣe. Ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi.” Lẹ́yìn èyí ló wá “gbé àwọn ọmọ náà sí apá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún wọn.” (Máàkù 10:13-16) Àwọn ọmọdé ṣe pàtàkì lójú Jèhófà Ọlọ́run àti lójú Ọmọ rẹ̀.

Kódà, Ọlọ́run máa tó tipasẹ̀ Jésù Kristi, Ọba tó yàn sípò, wá ìtura fáwọn ọmọdé tí wọ́n ń jẹ níyà. Àwọn tó ń fìwọra mú àwọn ọmọdé sìn àtàwọn tó ń hùwà ìkà sí wọn nítorí pé wọn ò láàánú, ni a óò pa run títí láé. (Sáàmù 37:10, 11) Ní ti àwọn ọlọ́kàn tútú tí wọ́n ń wá Jèhófà, Bíbélì sọ pé: “Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.

Kó tó dìgbà yẹn, Ọlọ́run ń fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn ní báyìí sí gbogbo àwọn tí wọ́n ń kó nífà tí wọ́n sì ń hùwà ìkà sí nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tẹ̀mi àti nípa mímù kí wọ́n rí ìtùnú. Ó ṣèlérí pé: “Èyí tí ó sọnù ni èmi yóò wá kiri, èyí tí a lé lọ ni èmi yóò sì mú padà bọ̀, èyí tí ó fara pa ni èmi yóò sì fi ọ̀já wé, èyí tí ń ṣòjòjò ni èmi yóò sì fún lókun.” (Ìsíkíẹ́lì 34:16) Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́, àti ìjọ Kristẹni, Jèhófà ń tu àwọn ọmọdé tí a tẹ̀ lórí ba tí a sì sọ dìdàkudà nínú. Ohun ayọ̀ gbáà ló jẹ́ láti mọ̀ pé bí ‘Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ṣe ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa,’ nísinsìnyí náà ló máa ṣe lọ́jọ́ iwájú.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]

© Mikkel Ostergaard /Panos Pictures

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́