ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 9/8 ojú ìwé 27
  • “Ìgbà Wo Lo Máa Ráyè Ka Gbogbo Èyí Tán?”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ìgbà Wo Lo Máa Ráyè Ka Gbogbo Èyí Tán?”
  • Jí!—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Sí Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—2006
  • Bíbélì Ni Yóò Túbọ̀ Máa Tẹnu Mọ́!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Wo Àwọn Ojú Ìwé Tó Kẹ́yìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Máa Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Tó O Bá Ń Wàásù
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 9/8 ojú ìwé 27

“Ìgbà Wo Lo Máa Ráyè Ka Gbogbo Èyí Tán?”

Lóṣù July ọdún 2001, ọkùnrin kan láti ìlú Khabarovsk ní ẹkùn Ìlà Oòrùn Rọ́ṣíà rí ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn Jí! mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n tí wọ́n tò sí ilé ìkàwé kan ní ìlú náà. Ó yá àwọn ìwé ìròyìn yìí lọ sílé, nígbà tí ọjọ́ tó kọ sílẹ̀ pé òun máa dá wọn padà sì pé, ìyẹn ní oṣù August, kò fẹ́ kó wọn sílẹ̀ mọ́. Nítorí náà, ó tún forúkọ sílẹ̀ láti yá wọn títí di oṣù September. Àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí wù ú gan-an débi pé ó tún yá wọn lẹ́ẹ̀kan sí i títí di oṣù November, lọ́tẹ̀ yìí àwọn ìtẹ̀jáde tuntun mẹ́fà mìíràn ti kún wọn.

Kó tó di àkókò náà, ọkùnrin yìí kì í fẹ́ ka àwọn ìwé tó bá dá lórí ọ̀ràn ẹ̀sìn. Kí ló wá dé tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í ka Jí!? Ó sọ pé: “Nítorí pé ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tí wọ́n máa ń kọ sínú ìwé ìròyìn náà dá lórí àwọn ìṣòro tó ń jẹ àwọn èèyàn lọ́kàn, kò sì sẹ́ni tí wọn ò kàn.”

Ọkùnrin náà fi kún un pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń kọ àwọn àpilẹ̀kọ tó yè kooro, tó máa ń gbé ọkàn èèyàn lọ sáwọn ìlú àtàwọn orílẹ̀-èdè ayé òde òní, ó tún máa ń jíròrò àṣà àwọn onírúurú èèyàn.” Àwọn àpilẹ̀kọ tó tún máa ń gbádùn mọ́ ọn làwọn tó bá sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ti ṣàṣeyọrí nínú ìgbésí ayé, àwọn tí wọ́n di ìgbàgbọ́ wọn mú tí wọ́n sì ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti forí tì í nígbà tí láburú àti àjálù dé bá wọn. Ipò wo ló wá to ìwé ìròyìn yìí sí o? Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, “a lè fi ìdánilójú sọ ọ́ pé kò sí ìwé ìròyìn mìíràn tá a lè fi wé Jí! nínú àwọn ìwé ìròyìn tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, ìmọ̀ nípa àgbáálá ayé àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀, àti àṣà àwọn èèyàn káàkiri àgbáyé!”

Ọkùnrin náà sọ pé òun fẹ́ àwọn ìwé ìròyìn Jí! lédè Rọ́ṣíà tí wọ́n ti tẹ̀ jáde láti ọdún 1995 títí di àkókò yìí. Kì í ṣe ìwé ìròyìn Jí nìkan ló béèrè, ó tún lóun fẹ́ oríṣiríṣi àwọn ìwé àti ìwé pẹlẹbẹ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ̀ jáde. Nínú lẹ́tà tó kọ, ó sọ pé: “Ẹ lè béèrè pé, ‘Ìgbà wo lo máa ráyè ka gbogbo èyí tán?’” Ó dáhùn ìbéèrè ara ẹ̀ nípa sísọ pé òun máa ń ráyè ka àwọn ìwé tó ń ṣàǹfààní fún èèyàn nítorí pé òun kì í lo àkókò tó pọ̀ nídìí tẹlifíṣọ̀n àti lórí wíwá nǹkan tí ò sọnù kiri orí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

Ìwé ìròyìn Jí! kún fún àwọn ìsọfúnni tó gbámúṣé nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ ó sì fi báwọn ìṣòro ìsinsìnyí yóò ṣe yanjú hàn wá. O ò ṣe sọ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n máa fún ọ ní àwọn ìtẹ̀jáde Jí! bó bá ṣe ń jáde lóṣooṣù?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Lílóye Àwọn Tí Ìṣesí Wọn Ṣàdédé Ń Yí Padà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ Ogun Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé—Ṣóòótọ́ Ni?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 27]

Bọ́ǹbù tó bú gbàù: Fọ́tò U.S. Department of Energy

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́