Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Kíkàwé Fáwọn Ọmọdé
LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ NÍ POLAND
Àwọn tó ṣètò ìpolongo ọlọ́dọọdún náà, “Kí Gbogbo Poland Máa Kàwé Fọ́mọ,” sọ pé: “Kíkàwé máa ń jẹ́ kéèyàn ní ìmọ̀ àti ọpọlọ pípé. . . . Ó máa ń jẹ́ ká lè rí bí ìrònú àti ìmọ̀ ẹ̀dá ṣe jinlẹ̀ tó.” Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló wá dé tí ọ̀pọ̀ èèyàn, àtàgbà àtọmọdé, ò fi fẹ́ràn ìwé kíkà tó jẹ́ pé bíi pé ipá ni wọ́n fi ń kà á ló rí?
Àwọn tó bẹ̀rẹ̀ ìpolongo yìí sọ pé: “Láti kékeré ló yẹ kó ti mọ́ni lára láti máa kàwé, kéèyàn sì nífẹ̀ẹ́ sí ìwé.” Wọ́n sọ fún àwọn òbí pé: “Tẹ́ ẹ bá fẹ́ káwọn ọmọ yín gbọ́n kí wọ́n sì rọ́wọ́ mú nílé ìwé àti nígbèésí ayé wọn, ẹ máa fi ogún ìṣẹ́jú kàwé sí wọn létí lójoojúmọ́.”
Wọ́n tún gba àwọn òbí níyànjú pé kí wọ́n máà sún ọ̀rọ̀ kíkàwé fáwọn ọmọ wọn síwájú, káká bẹ́ẹ̀ kí wọ́n “tètè bẹ̀rẹ̀ bó bá ṣe lè yá tó.” Nígbà wo ló yẹ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀? Wọ́n rọ àwọn òbí pé: “Ẹ jẹ́ ká máa kàwé sí ọmọ ọwọ́ létí, ká gbé e dání, ká jẹ́ kó rí i lójú wa pé a nífẹ̀ẹ́ òun, ká jẹ́ kí ohùn wa máa dùn mọ́ ọn. Tá a bá ń ṣe báyìí, ọmọ náà á lè rí i pé tí wọ́n bá ń kàwé fóun kò sí ìṣòro, á lè gbádùn rẹ̀ àti pé á mojú ẹni tó ń kàwé fún un. Yàtọ̀ síyẹn, á tún jẹ́ kí ọpọlọ rẹ̀ jí pépé bó ṣe ń dàgbà.”
Àwọn tó ṣètò ìpolongo náà tẹnu mọ́ ọn pé “kíkàwé fọ́mọ ti wá ṣe pàtàkì ju ti àtẹ̀yìnwá lọ báyìí,” wọ́n sì sọ àwọn àǹfààní mìíràn tó wà nínú ẹ̀. Kíkàwé sí ọmọ létí máa ń kọ́ àwọn ọmọdé béèyàn ṣe ń ronú, “ó máa ń jẹ́ kí wọ́n lóye àwọn ẹlòmíràn, kí wọ́n mọ bí ayé ṣe rí kí wọ́n sì lóye ara wọn dáadáa, . . . ó máa ń ru wọ́n lọ́kàn sókè, ó ń jẹ́ kí wọ́n lè máa fojú inú wo nǹkan, ó ń mú kí wọ́n lè ní ìmọ̀lára, ó ń kọ́ wọn láti máa mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára àti béèyàn ṣe máa ń gba ti ẹlòmíràn rò, ó ń kọ́ wọn ní ìwà ọmọlúwàbí . . . ó sì ń kọ́ wọn láti mọyì ara wọn.” Ibi táwọn aṣáájú nínú ìpolongo náà fẹnu ọ̀rọ̀ jóná sí ni pé ó dájú pé òun ni “oògùn tó lè dènà àwọn nǹkan tó lè nípa búburú . . . lórí ìrònú àti ọkàn àwọn ọmọdé.”
Béèyàn bá fẹ́ káwọn ògo wẹẹrẹ jàǹfààní dáadáa látinú ìwé kíkà, àwọn ìwé tó ń gbà wọ́n níyànjú láti sún mọ́ Ẹlẹ́dàá wọn tó wà lọ́run ló yẹ ká máa kà fún wọn. Bíbélì ni ìwé tó dáa jù lọ tá á ràn wá lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé, “láti ìgbà ọmọdé jòjòló” ni wọ́n ti kọ́ Tímótì ọ̀dọ́ ní “ìwé mímọ́.” (2 Tímótì 3:15) Àwọn òbí lè fi àwọn ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì bí Iwe Itan Bibeli Mi àti Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dìídì ṣe fáwọn ọmọ kéékèèké, kún ètò kíkàwé sí ọmọ létí.