Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù Fún Ìyá Kan Lẹ́tọ̀ọ́ Ẹ̀
Látọwọ́ òǹkọ̀wé Jí! nílẹ̀ Faransé
NÍ December 16, ọdún 2003, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù èyí tó wà nílùú Strasbourg, lórílẹ̀-èdè Faransé dá àwọn ilé ẹjọ́ tó wà lórílẹ̀-èdè Faransé lẹ́bi lórí pé wọ́n fẹ̀tọ́ Séraphine Palau-Martínez, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dù ú, nítorí ẹ̀sìn rẹ̀.
Ní ọdún 1996, ilé ẹjọ́ gbà kí Séraphine jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ fọ́kọ rẹ̀ tó ti pa á tì láti bí ọdún méjì. Wọ́n fún un láṣẹ láti kó àwọn ọmọ wọn méjèèjì tira. Ṣùgbọ́n lọ́dún 1997, nígbà tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ táwọn ọmọ yìí ti ń gbé pẹ̀lú ìyá wọn, wọ́n lọ bá bàbá wọn ṣeré, kò sì kó wọn lọ sọ́dọ̀ ìyá wọn mọ́. Séraphine sọ pé: “Nígbà tí mo lọ sí ilé ìwé wọn láti kó wọn wálé, ọ̀gá ilé ìwé wọn pé ọlọ́pàá sí mi. Ńṣe ni ọlọ́pàá ń ṣọ́ mi nígbà tí mo wà pẹ̀lú àwọn ọmọ mi kí n má bàa bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn mi. Wọ́n wá ń wò mí bí ọ̀daràn. Wọ́n ní tí n bá fẹ́ mú wọn lọ sílé, àfi kí n tọwọ́ bọ̀wé pé mi ò ní bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run tàbí Bíbélì, mi ò sì ní mú wọn lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni.”
Séraphine gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́. Àmọ́ lọ́dún 1998, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti Ìlú Nîmes dájọ́ pé bàbá ni kó kó àwọn ọmọ sọ́dọ̀. Láti sọ ìdí tó fi ṣèpinnu náà, ilé ẹjọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀jò èébú lé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí nípa bíbẹnu àtẹ́ lu ọ̀nà tó gbà gbọ́ pé wọ́n gbà ń kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tí Séraphine rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Ó dùn mí gan-an ni pé wọ́n fẹ̀sùn kàn mí pé ńṣe ni mò ń dorí àwọn ọmọ mi rú, nígbà tó sì jẹ́ pé gbogbo ohun tí mò ń gbìyànjú àtiṣe ni ohun tí mo rò pé ó dáa jù lọ fún wọn, ìyẹn ni pé kí n tọ́ wọn dàgbà bíi Kristẹni.”
Nígbà tí ilé ẹjọ́ gíga jù lọ nílẹ̀ Faransé fara mọ́ ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn yìí, Séraphine pinnu pé òun á gbé ẹjọ́ náà lọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù. Ilé ẹjọ́ náà sọ nínú ìdájọ́ rẹ̀, níbi tí èrò àwọn adájọ́ mẹ́fà nínú méje tó wà níbẹ̀ ti jọra, pé “Ilé Ẹjọ́ yìí kò ṣiyèméjì pé ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn [ilẹ̀ Faransé] ṣojúsàájú nínú ìdájọ́ rẹ̀ lórí ojú tó fi wo ọ̀ràn àwọn òbí méjèèjì nítorí ẹ̀sìn olùpẹ̀jọ́. . . . Ìwà kẹ́lẹ́sìnmẹ̀sìn nìyẹn.” Ilé ẹjọ́ náà rí i pé ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Faransé kò gbé ìdájọ́ rẹ̀ karí bóyá Séraphine lè dá àwọn ọmọ rẹ̀ bójú tó tàbí kò lè dá bójú tó wọn, nítorí pé kò sẹ́ni tó jiyàn lórí ìyẹn. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò gbé ìdájọ́ rẹ̀ karí ẹ̀rí kankan, orí ohun tó gbé ìdájọ́ rẹ̀ lé ni “gbogbo ohun tó kàn rò nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Nítorí ìwà kẹ́lẹ́sìnmẹ̀sìn tí wọ́n hù sí Séraphine àti bí wọ́n ṣe fàwọn ẹ̀tọ́ ẹ̀ dù ú, Ilé Ẹjọ́ náà pàṣẹ pé kí ilẹ̀ Faransé fún Séraphine lówó gbà-máà-bínú kó sì tún sanwó tó fi pẹjọ́ padà fún un.
Ìpinnu Ilé Ẹjọ́ yìí jọ èyí tó ṣe lóṣù June ọdún 1993, lórí ẹjọ́ kan tó fara jọ èyí nígbà tí Ilé Ẹjọ́ náà dájọ́ pé orílẹ̀-èdè Austria hùwà kẹ́lẹ́sìnmẹ̀sìn sí Ingrid Hoffmann, obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan, nítorí ẹ̀sìn rẹ̀.a Ìwé ilẹ̀ Faransé náà tó máa ń ṣàyẹ̀wò ohun tó ń lọ nílé ẹjọ́, La Semaine juridique sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìdájọ́ yìí ṣe fìdí ẹ̀ múlẹ̀, a ò lè gbé ìpinnu nípa àṣẹ òbí lórí ọmọ karí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.” Agbẹjọ́rò Séraphine sọ pé: “Ìpinnu yìí ṣe pàtàkì gan-an ni, nítorí pé wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ la máa ń tọ́ka sáwọn ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ yìí bá ṣe láti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé kò yẹ́ kí ẹnikẹ́ni yí ẹjọ́ àwọn òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà po.”
Nígbà tí wọ́n bi Séraphine, tó ń gbé nílẹ̀ Sípéènì báyìí, nípa bó ṣe rí ìdájọ́ yẹn sí, ó dáhùn pé: “Inú mi dùn ara sì tù mí. Kíkó tí wọ́n kó àwọn ọmọ mi kúrò lọ́dọ̀ mi nítorí ẹ̀sìn mi tí mi ò sì fojú kàn wọ́n fọ́dún márùn-ún nira fún mi gan-an, ṣùgbọ́n Jèhófà ò fi mí sílẹ̀. Mo gbà gbọ́ pé ìdájọ́ yìí á ran àwọn mìíràn tí wọ́n bá níṣòro bíi tèmi yìí lọ́wọ́.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “A Dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Láre Ninu Ìjà Ẹ̀tọ́-Abójútó Ọmọ” tó wà nínú Jí! October 8, 1993, ojú ìwé 15.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Séraphine