Àrùn Gágá Ibi Tó Yé Wa Dé Báyìí
ỌDÚN 1997 lọdún tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan jókòó sí abúlé kékeré kan báyìí tó ń jẹ́ Brevig, níbi táwọn Eskimo ń gbé ní Seward tí omi fẹ́rẹ̀ẹ́ yí po, ní ìpínlẹ̀ Alaska. Kò sí igi ni àgbègbè náà, yìnyín sì bo ojú ilẹ̀. Òkú ọ̀dọ́mọbìnrin kan tí Dókítà kan àtàwọn Eskimo mẹ́rin tí wọ́n ń ràn án lọ́wọ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ hú jáde látinú ilẹ̀ yìnyín wà níwájú ẹ̀. Òkú ọ̀kan lára àwọn tí àrùn gágá pa lọ́dún 1918 ni, látìgbà náà ló sì ti di gbagidi síbi tí wọ́n sin ín sí níbẹ̀.
Àǹfààní wo ló wà nínú ṣíṣe àyẹ̀wò òkú obìnrin náà báyìí? Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nírètí pé kòkòrò àrùn gágá náà ṣì máa wà nínú ẹ̀dọ̀fóró rẹ̀ àti pé táwọn bá lo ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ láti fi ṣàyẹ̀wò apilẹ̀ àbùdá rẹ̀, ó ṣeé ṣe káwọn wá kòkòrò àrùn náà rí káwọn sì fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀. Kí nìdí tírú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ fi lè wúlò? Ká tó lè dáhùn ìbéèrè yìí, a gbọ́dọ̀ lóye díẹ̀ sí i nípa báwọn fáírọ́ọ̀sì tó ń fa àrùn ṣe ń ṣọṣẹ́ àtohun tó mú kí wọ́n léwu gan-an.
Fáírọ́ọ̀sì Tó Lè Gbẹ̀mí Èèyàn
Lóde òní, a ti wá mọ̀ pé fáírọ́ọ̀sì kan báyìí ló ń fa àrùn gágá àti pé ó lè bá èémí jáde lára, kó sì ràn látọ̀dọ̀ ẹnì kan dé ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn, bíi nígbà tí ẹni tó wà lára rẹ̀ bá wúkọ́, tó bá sín tàbí tó bá ń sọ̀rọ̀. Ó wà káàkiri orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé tó fi dé àwọn ilẹ̀ olóoru, níbi tó ti lè jà kolẹ̀ ọdún. Ní Àríwá Ìlàjì ayé, àrùn gágá sábà máa ń jà láti oṣù November títí di oṣù March ọdún tó tẹ̀ lé e; ó sì máa ń jà láti oṣù April títí di oṣù September, ní Gúúsù Ìlàjì ayé.
Oríṣi fáírọ́ọ̀sì àrùn gágá kan tó wà ní ìpele A (type A), lèyí tó léwu jù lọ, ó sì kéré jọjọ bá a bá fi wé ọ̀pọ̀ fáírọ́ọ̀sì mìíràn. Ó máa ń rí róbótó, àwọn nǹkan bíi fọ́nrán iṣan sì wà lójú ẹ̀. Bí fáírọ́ọ̀sì yìí bá ti fara kan ọ̀kan lára ohun tín-tìn-tín tó wà nínú ara báyìí, ńṣe lá máa yára sọ ara ẹ̀ di púpọ̀ débi pé lọ́pọ̀ ìgbà, láàárín wákàtí bíi mẹ́wàá, irú ẹ̀ míì táá ti wà nínú ara á ti tó ọ̀kẹ́ márùn-ún sí àádọ́ta ọ̀kẹ́.
Ohun kan tó ń bani lẹ́rù lára fáírọ́ọ̀sì yìí ni bó ti ṣe máa ń tètè sọ ara ẹ̀ di púpọ̀. Nítorí pé fáírọ́ọ̀sì náà tètè máa ń pọ̀ sí i (lọ́nà tó yára gan-an ju ti kòkòrò àrùn éèdì), ọ̀pọ̀ irú míì tó máa ń mú jáde kì í rí bákan náà. Àwọn kan máa ń yàtọ̀ débi pé ọwọ́ àwọn ohun tó ń dènà àrùn nínú ara kì í tẹ̀ wọ́n. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé lọ́dọọdún là ń rí ọlọ́kan-ò-jọ̀kan fáírọ́ọ̀sì àrùn gágá tó jẹ́ èèwọ̀ ara tó sì ń dá àwọn adènà àrùn inú ara lágara. Bí fáírọ́ọ̀sì tó jẹ́ èèwọ̀ ara yìí bá tètè ń pọ̀ sí i bó ti máa ń ṣe gan-an, a jẹ́ pé apá ohun tó ń dènà àrùn inú ara ò ní ká a nìyẹn, bó bá sì rí bẹ́ẹ̀, ó di kí àrùn náà máa jà káàkiri.
Kò mọ síbẹ̀ yẹn, fáírọ́ọ̀sì àrùn gágá tún máa ń ran àwọn ẹranko, ìṣòro gbáà sì nìyẹn jẹ́ fáwa èèyàn. Wọ́n máa ń sọ pé àwọn fáírọ́ọ̀sì tó ń bá àwọn òròmọdìyẹ àti pẹ́pẹ́yẹ jà lè fi ara ẹlẹ́dẹ̀ ṣe ilé. Bákan náà, àwọn fáírọ́ọ̀sì míì tó máa ń bá àwọn èèyàn jà tún lè fi ara ẹlẹ́dẹ̀ ṣe ilé pẹ̀lú.
Nítorí náà, bí ẹlẹ́dẹ̀ kan bá ní oríṣi fáírọ́ọ̀sì méjèèjì lára, ìyẹn irú èyí tó máa ń báwọn ẹranko jà àti irú èyí tó máa ń báwọn èèyàn jà, apilẹ̀ àbùdá oríṣi méjèèjì lè dà pọ̀. Àbájáde rẹ̀ sì ni pé irú fáírọ́ọ̀sì àrùn gágá míì lè tibẹ̀ jáde, èyí tí ara èèyàn ò ní lè gbógun tì. Àwọn kan gbà gbọ́ pé láwọn ibi táwọn èèyàn bá ti ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ ẹlẹ́ran ọ̀sìn bíi ká sin adìyẹ àti ẹlẹ́dẹ̀, tí ilé táwọn èèyàn ń gbé sì sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí, bó ṣe sábà máa ń rí nílẹ̀ Éṣíà, ó ṣeé ṣe káwọn oríṣi fáírọ́ọ̀sì àrùn gágá míì tibẹ̀ bẹ̀rẹ̀.
Kí Nìdí Tó Fi Tètè Máa Ń Tàn Kálẹ̀ Bẹ́ẹ̀?
Ìbéèrè tó wá jẹyọ ni pé, Kí ló fà á tí kòkòrò fáírọ́ọ̀sì tó fa àrùn gágá lọ́dún 1918 sí ọdún 1919 fi di otútù àyà tó pa àwọn èwe nípakúpa? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí èyíkéyìí tó ṣì wà láàyè lára àwọn fáírọ́ọ̀sì tìgbà yẹn, ó ti pẹ́ táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti ń ronú pé báwọn bá lè rí àpẹẹrẹ irú rẹ̀ kan tó dì gbagidi, á lè ṣeé ṣe fáwọn láti yọ apilẹ̀ àbùdá rẹ̀ sọ́tọ̀ gédégbé káwọn sì ṣàwárí ohun tó mú kó máa ṣekú pani bẹ́ẹ̀. Dájúdájú, wọ́n ti ṣàṣeyọrí dé ìwọ̀n tó láàlà.
Ọpẹ́lọpẹ́ irú rẹ̀ kan tí yìnyín mú kó dì gbagidi, èyí tí wọ́n rí ní ìpínlẹ̀ Alaska gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Ẹgbẹ́ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan ti dá èyí tó pọ̀ jù lára apilẹ̀ àbùdá fáírọ́ọ̀sì àrùn gágá tọdún 1918 sí ọdún 1919 mọ̀, wọ́n sì ti lóye àwọn nǹkan tó para pọ̀ di apilẹ̀ àbùdá àwọn fáírọ́ọ̀sì. Àmọ́ ṣá o, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ò tíì lè sọ ohun tó mú káwọn fáírọ́ọ̀sì náà pa àwọn èèyàn tóyẹn. Ohun kan tó ṣì dá wọn lójú ni pé fáírọ́ọ̀sì àrùn gágá yìí jọ irú fáírọ́ọ̀sì tó máa ń fa àrùn sára àwọn ẹlẹ́dẹ̀ àtàwọn ẹ̀dá abìyẹ́.
Ṣó Tún Lè Padà Wá?
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn ògbógi sọ, ọ̀rọ̀ ti kọjá bóyá irú fáírọ́ọ̀sì tó léwu jọjọ bẹ́ẹ̀ á padà wá, ohun tó kù báyìí ni pé ìgbà wo ló máa padà wá àti pé báwo ló ṣe máa padà wá. Kódà, àwọn kan tiẹ̀ ń retí pé kí àrùn gágá tuntun, tó pọ̀ gan-an máa wáyé ní nǹkan bí ọdún mọ́kànlá mọ́kànlá, kí èyí tó tún wá gbẹ̀kan jù bẹ́ẹ̀ lọ máa wáyé bóyá lẹ́ẹ̀kan ní ọgbọ̀n ọdún. Bá a bá fojú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí wò ó, a jẹ́ pé ṣe ni káráyé máa múra sílẹ̀ de àrùn àjàkáyé míì láìpẹ́ láìjìnnà.
Ìwé ìròyìn ìṣègùn náà, Vaccine sọ lọ́dún 2003 pé: “Ó ti tó ọdún márùndínlógójì báyìí tí àrùn gágá ti jà kárí ayé kẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àkókò tó dájú jù lọ, tó wà lákọọ́lẹ̀ pé ó máa ń gba àrùn àjàkáyé náà kó tó jà jẹ́ ọdún mọ́kàndínlógójì.” Àpilẹ̀kọ náà ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Fáírọ́ọ̀sì tó máa ń jà káàkiri ayé yìí lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ọṣẹ́ láti orílẹ̀-èdè Ṣáínà tàbí orílẹ̀-èdè kan tó sún mọ́bẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ irú èyí tó máa ń fa àrùn sára àwọn ẹranko tó sì lágbára láti dà pọ̀ mọ́ ẹ̀yà fáírọ́ọ̀sì míì láti mú irú èyí tó máa rorò gan-an jáde.”
Àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn Vaccine sọ tẹ́lẹ̀ nípa fáírọ́ọ̀sì náà pé: “Wéré bí ọgán ló máa ràn dé orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé. Á sì máa ràn ní àràntúnràn. Bíi pápá tó ń jó nígbà ọyẹ́ lá ṣe máa ran tọmọdé tàgbà, ó sì máa ṣàkóbá fún ìgbòkègbodò ẹ̀dá àti ètò ìṣúnná owó káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè. Àwọn èèyàn tó máa kú á pọ̀ gan-an láìka ọjọ́ orí wọn sí. Kò sì dájú pé apá àwọn elétò ìlera máa ká a láti fún àwọn èèyàn ní ìtọ́jú bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ àní lọ́pọ̀ jù lọ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti rí towó ṣe pàápàá.”
Báwo gan-an lọ̀ràn ọ̀hún á ṣe kó ìdágìrì báni tó? Ẹni tó kọ ìwé The Great Influenza, ọ̀gbẹ́ni John M. Barry, sọ èrò tiẹ̀ nípa ọ̀ràn náà pé: “Lójú gbogbo olóṣèlú ayé, ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ni akópayàbáni tó ní ohun ìjà runlérùnnà jẹ́. Bó ṣe yẹ kí ọ̀rọ̀ àrùn gágá tuntun tó máa jà kárí ayé rí lójú wa náà nìyẹn.”
Àwọn Nǹkan Wo Ni Wọ́n Lè Fi Wo Àrùn Náà?
O lè béèrè pé, ‘Ṣé kò tíì sí egbòogi tó lè wo àrùn náà ni?’ Apá méjì ni ìdáhùn ìbéèrè náà pín sí. Bí fáírọ́ọ̀sì àrùn gágá bá ti dọ́gbẹ́ sínú ara, ọgbẹ́ náà tún lè ṣokùnfà bakitéríà tó ń fa otútù àyà. Àwọn agbóguntàrùn tó wà nínú ara lè dín ọṣẹ́ tí irú ọgbẹ́ bẹ́ẹ̀ lè ṣe kù, àwọn oògùn kan sì wà tí wọ́n lágbára láti pa irú àwọn fáírọ́ọ̀sì àrùn gágá kan báyìí. Àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára wà tó lè ṣèrànwọ́ láti gbógun ti fáírọ́ọ̀sì àrùn gágá bá a bá mọ irú èyí tí agbára abẹ́rẹ́ náà ká, tá a sì tètè jẹ́ kí irú abẹ́rẹ́ bẹ́ẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Èyí tó jẹ́ rere nínú ìròyìn náà nìyẹn. Èyí tó jẹ́ ibi nínú ẹ̀ wá ń kọ́ o?
Ọ̀rọ̀ pé à ń fi abẹ́rẹ́ àjẹsára wo àrùn gágá ò láyọ̀lé. Awuyewuye ṣì wà lórí àrùn gágá tó pàwọn ẹlẹ́dẹ̀ lọ́dún 1976 àti ìṣòro àìròtẹ́lẹ̀ tí abẹ́rẹ́ àjẹsára mú wá àti bí abẹ́rẹ́ àjẹsára tí wọ́n ṣe nítorí àrùn gágá lọ́dún 2004 ò ṣe pọ̀ tó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìṣègùn ti ṣàṣeyọrí débi tó lámì látìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní, síbẹ̀ àwọn dókítà ò tíì mọ ohun tó lè wo àrùn gágá tápá kì í ká bọ̀rọ̀.
Wàyí o, ìbéèrè kan wà tí ń gbéni lọ́kàn sókè, ìyẹn ni pé: Ṣé ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1918 sí ọdún 1919 ṣì tún lè ṣẹlẹ̀? Ohun tí ìwé ìròyìn kan látọ̀dọ̀ àjọ tó ń rí sí ìwádìí nípa ìṣègùn, ìyẹn London’s National Institute for Medical Research, sọ rèé: “Lóde tòní, àwọn nǹkan ò ṣaláì máa rí bí wọ́n ṣe rí lọ́dún 1918: ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn ló ń rìnrìn-àjò nítorí ìtẹ̀síwájú tó ti bá ètò ìrìnnà, àìmọye ibi tógun ti ń jà tí wọn ò róúnjẹ jẹ kánú tí àyíká wọn sì dọ̀tí ló wà, iye èèyàn tó ń gbé láyé ti di bílíọ̀nù mẹ́fà ààbọ̀ èyí tó sì pọ̀ jù lára iye yìí ló ń gbé nílùú, nínú àwọn ilé hẹ́gẹhẹ̀gẹ tí wọ́n kọ́ sáàárín ìdọ̀tí nítòsí ibi tí wọ́n ń ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ sí.”
Ògbógi kan tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà wá parí ọ̀rọ̀ náà pé: “Ká sọ ọ́ ní ṣókí, ọdọọdún la túbọ̀ ń sún mọ́ àrùn àjàkáyé.” Ṣé gbogbo èyí wá túmọ̀ sí pé kò sí ìrètí kankan fún wa lọ́jọ́ iwájú ni? Ó tì o!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Oríṣi fáírọ́ọ̀sì àrùn gágá míì lè bẹ̀rẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ ẹlẹ́ran ọ̀sìn
[Credit Line]
Àwòrán tí BAY ISMOYO/AFP/Getty Images yà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]
Fáírọ́ọ̀sì àrùn gágá tó wà ní ìpele A
[Credit Line]
© Science Source/ Photo Researchers, Inc
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Àwọn tó ń ṣèwádìí ti ṣàyẹ̀wò fáírọ́ọ̀sì tó fa àrùn gágá lọ́dún 1918 sí ọdún 1919
[Credit Line]
© TOUHIG SION/CORBIS SYGMA