ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/06 ojú ìwé 14-16
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Tíì Burú Jù Lọ Látọjọ́ Táláyé Ti Dáyé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Tíì Burú Jù Lọ Látọjọ́ Táláyé Ti Dáyé
  • Jí!—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀
  • Ìgbà Tí Ṣòkòtò Ṣòdí Àwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì
  • Àrùn Gágá Ibi Tó Yé Wa Dé Báyìí
    Jí!—2006
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn Ibi Tó Máa Já Sí
    Jí!—2006
  • Ṣó Tún Lè Ṣẹlẹ̀?
    Jí!—2006
  • Ẹni Tó Wà Nídìí Ogun àti Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Jí!—2006
g 1/06 ojú ìwé 14-16

Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Tíì Burú Jù Lọ Látọjọ́ Táláyé Ti Dáyé

OGUN Àgbáyé Kìíní ṣì ń jà lọ́wọ́ ní oṣù October, ọdún 1918. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ogun náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí, àwọn èèyàn ò tíì ṣíwọ́ láti máa ṣe lámèyítọ́ ohun táwọn oníròyìn ń gbé jáde. Nítorí náà, orílẹ̀-èdè Sípéènì tí kò lọ́wọ́ sógun ló ráàyè láti máa gbé ìròyìn jáde pé ńṣe làwọn aráàlú níbi gbogbo ń ṣàìsàn tí wọ́n sì ń kú lọ bí ilẹ̀ bí ẹní. Ìyẹn ló sì fà á tí Sípéènì fi wà lára orúkọ tí wọ́n ń pe àìsàn tó ń pàwọn èèyàn náà lédè Gẹ̀ẹ́sì títí dòní olónìí, ìyẹn Spanish flu tàbí àrùn gágá ilẹ̀ Sípéènì.

Oṣù kẹta, ọdún 1918 ni àrùn àjàkáyé náà bẹ̀rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wá fìn-ín ìdí kókò àrùn náà gbà pé ìpínlẹ̀ Kansas, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn náà làwọn sójà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà dé wá kó o ran àwọn ará ilẹ̀ Faransé. Lẹ́yìn tí iye àwọn tí àrùn gágá ń pa ṣàdédé ròkè lóṣù July, lọ́dún 1918, ṣe ló wà dà bíi pé ibi tí kútákútá ẹ̀ mọ sí náà nìyẹn. Àwọn dókítà ò mọ̀ nígbà yẹn pé ṣe ni àrùn tó ń jà kárí ayé náà lọ túnra mú kó lè gbẹ̀mí púpọ̀ sí i.

Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní parí ní November 11, ọdún 1918, ṣe ni ìdùnnú ṣubú layọ̀ fáráyé. Àfi bí àjàkálẹ̀ àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí yẹn ṣe tún gbé ìṣe ẹ̀ dé, tó sì ń jà ràn-ìn káàkiri àgbáyé. Apanimáyọdà ni, jákèjádò ayé sì làwọn ìwé ìròyìn ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Ìwọ̀nba kéréje lára àwọn tó wà láàyè nígbà yẹn ni ò rí fìrífìrí àrùn náà, àmọ́ gbogbo wọn ló kó jìnnìjìnnì bá. Ẹnì kan tó mọwá mẹ̀yìn àrùn gágá ṣàlàyé pé: “Ó lé lọ́dún mẹ́wàá tí ọdún táwọn ará Amẹ́ríkà ń lò láyé fi dín kù lọ́dún 1918.” Kí ni àjàkálẹ̀ àrùn yìí fi yàtọ̀ sáwọn àjàkálẹ̀ àrùn yòókù?

Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀

Èyí tó muni lómi jù lọ lára ohun tí àrùn yìí fi yàtọ̀ sáwọn àjàkálẹ̀ àrùn míì ni bó ṣe máa ń ṣàdédé bẹ̀rẹ̀. Báwo ló ṣe máa ń yara pààyàn tó? Nínú ìwé kan tí òǹkọ̀wé John M. Barry ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ tó pe àkọlé rẹ̀ ní The Great Influenza, èyí tó dá lórí ohun tẹ́nì kan sọ nípa bí àrùn gágá ṣe máa ń ṣàdédé bẹ̀rẹ̀, ó ní: “Nílùú Rio de Janeiro, ọkùnrin kan tí ohùn ẹ̀ já gaara ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Ciro Viera Da Cunha, akẹ́kọ̀ọ́ ìṣègùn kan tó fẹ́ wọ ọkọ̀ ilẹ̀, ṣàdédé ni ọkùnrin náà ṣubú lulẹ̀, tó sì kú; ní ìlú Cape Town, lórílẹ̀-èdè South Africa, Charles Lewis wọ ọkọ̀ ilẹ̀ láti rìnrìn-àjò kìlómítà márùn-ún lọ sílé, àfi bí ọmọ ẹ̀yìn ọkọ̀ náà ṣe ṣubú lulẹ̀ tó sì kú. Láàárín bíi kìlómítà márùn-ún tó kù kó délé, èèyàn mẹ́fà, tó fi mọ́ awakọ̀, ló tún kú nínú ọkọ̀ ilẹ̀ náà.” Àrùn gágá ló sì pa gbogbo wọn.

Pabanbarì míì nípa àrùn ọ̀hún ni ti bó ṣe máa ń dá ẹ̀rù bani, ìyẹn kéèyàn máa bẹ̀rù pé òun ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ò tíì lè sọ nǹkan tó ń fa àrùn náà, wọn ò sì tíì mọ báwo gan-an ló ṣe ń tàn káàkiri. Wọ́n ṣe àwọn ohun tí wọ́n rò pé ó lè dáàbò bo àwọn aráàlú: wọ́n dá àwọn ọkọ̀ tó ń bọ̀ wá gúnlẹ̀ sí èbúté dúró; wọ́n ti àwọn ilé sinimá, ṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn ilé míì tó wà fún ìlò àwọn aráàlú. Bí àpẹẹrẹ, ní ìlú San Francisco tó wà ní ìpínlẹ̀ California lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn aláṣẹ sọ fún gbogbo aráàlú pé kí wọ́n máa fi nǹkan bo imú àti ẹnu. Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí nígboro tí kò fi nǹkan bomú á sanwó ìtanràn tàbí kí wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n. Ṣùgbọ́n ó dà bí ẹni pé pàbó náà ni gbogbo ẹ̀ ń já sí. Gbogbo ọgbọ́n tí wọ́n ń dá ò ká ohun tó wà nílẹ̀, ó sì ti pẹ́ wọn jù kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀.

Ẹ̀rù tún ń ba àwọn èèyàn nítorí ìpakúpa tí àrùn gágá ń pa àwọn èèyàn. Kò tíì sẹ́ni tó lè sọ ìdí tó fi jẹ́ pé nígbà tí àrùn tó jà kárí ayé náà bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún 1919, kò fi bẹ́ẹ̀ pa àwọn àgbàlagbà; àwọn ọ̀dọ́ ló ń kọlù tó sì ń pa wọ́n ní rèwerèwe. Àwọn tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ogún ọdún sí ogójì ọdún ló pa jù lọ.

Láfikún sí ìyẹn, àjàkálẹ̀ àrùn tó kárí ayé ni. Ó dé àwọn erékùṣù tó wà láwọn ilẹ̀ olóoru pàápàá. Ọkọ̀ ojú omi ló tan àrùn gágá dé erékùṣù Western Samoa (tó ń jẹ́ Samoa báyìí), ní November 7, ọdún 1918, láàárín oṣù méjì péré tó sì débẹ̀, nǹkan bí egbèjìdínlógójì ó lé ọgọ́ta [7,660] èèyàn ló ti kú lára àwọn ẹgbàá mọ́kàndínlógún àti èjìlélọ́ọ̀ọ́dúnrún èèyàn [38,302] tó ń gbébẹ̀. Gbogbo orílẹ̀-èdè ńláńlá tó wà láyé làrùn náà bá fínra!

A ò sì tún ní gbàgbé báwọn èèyàn tí àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí náà ń pa ṣe pọ̀ yamùrá. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà tí àrùn náà kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ló ti kọ lu ìlú Philadelphia ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ọṣẹ́ tó sì ṣe níbẹ̀ ò ṣeé fẹnu sọ. Nígbà tí oṣù October fi máa dé ìdajì lọ́dún 1918, ọ̀dá pósí ti ń hàn wọ́n léèmọ̀. Òpìtàn Alfred W. Crosby sọ pé: “Ẹnì kan tó ń kan pósí tà sọ pé bóun bá ní pósí tó tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún, òun lè tà wọ́n tán láàárín wákàtí méjì. Ìgbà míì tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé àwọn òkú tó wà níbi tí wọ́n ń gbé òkú sí pọ̀ ju pósí tó wà nílẹ̀ lọ nígbà mẹ́wàá.”

Láàárín àkókò díẹ̀ tí àrùn gágá bẹ̀rẹ̀, ó ti yára pa èèyàn tó pọ̀ ju iye tí àrùn àjàkáyé èyíkéyìí mìíràn tó fara jọ ọ́ tíì pa lọ látijọ́ táláyé ti dáyé. Iye èèyàn tí wọ́n sábà máa ń fojú bù tẹ́lẹ̀ pé ó pa kárí ayé jẹ́ mílíọ̀nù mọ́kànlélógún, àmọ́ àwọn ògbógi kan ti wá ń sọ pé iye yẹn ti kéré jù. Ní báyìí, àwọn kan tó mọ̀ nípa bí àrùn ṣe ń jà tiẹ̀ ń sọ pé á tó àádọ́ta mílíọ̀nù èèyàn tó pa, tàbí kó tiẹ̀ tó ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù! Òǹkọ̀wé Barry tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Iye èèyàn tí àrùn gágá pa lọ́dún kan pọ̀ ju iye èèyàn tí àrùn adápàádúdú ti Sànmánì Ìgbà Ọ̀làjú pa ní ọ̀rúndún kan, èèyàn tó sì pa lọ́sẹ̀ mẹ́rìnlélógún pọ̀ ju èèyàn tí àrùn éèdì pa lọ́dún mẹ́rìnlélógún.”

Pabanbarì ibẹ̀ wá ni pé iye àwọn ará Amẹ́ríkà tí àrùn gágá pa ní nǹkan bí ọdún kan pọ̀ ju àròpọ̀ àwọn ará Amẹ́ríkà tí Ogun Àgbáyé méjèèjì pa lọ. Òǹkọ̀wé Gina Kolata ṣàlàyé pé: “Bí àrùn yẹn bá padà jà lóde òní, pẹ̀lú iye àwọn tó wà nílẹ̀ Amẹ́ríkà nísinsìnyí, iye tó máa pa lára wọn á tó mílíọ̀nù kan ààbọ̀. Ìyẹn á sì ju iye èèyàn tí àrùn àyà, àrùn jẹjẹrẹ, rọpárọsẹ̀, àrùn ẹ̀dọ̀fóró tó le gan-an, àrùn éèdì àti àrùn ọdẹ orí tó máa ń bá ọjọ́ ogbó rìn ń pa lọ́dún.”

Ká sọ ọ́ ní ṣókí, àrùn gágá ni àrùn àjàkáyé tó ṣọṣẹ́ tó tíì pọ̀ jù lọ látijọ́ táláyé ti dáyé. Ìrànlọ́wọ́ wo ni sáyẹ́ǹsì ti wá rí ṣe o?

Ìgbà Tí Ṣòkòtò Ṣòdí Àwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì

Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní fi máa bẹ̀rẹ̀ ló ti dà bí ẹni pé àwọn onímọ̀ ìṣègùn ti ń ṣe gudugudu méje nípa kíki àìsàn wọ̀. Kódà, nígbà tí ogun ṣì ń lọ lọ́wọ́, àwọn dókítà ń fi àṣeyọrí tí wọ́n ti ṣe láti dín àwọn àrùn tí ń ràn kù yangàn. Nígbà yẹn, ìwé ìròyìn The Ladies Home Journal kéde pé àwọn ará Amẹ́ríkà ò nílò yàrá tí wọ́n á máa tẹ́ òkú sí kí wọ́n tó sin ín mọ́, káwọn fúnra wọn máa gbébẹ̀ ló kù. Ó dámọ̀ràn pé látìgbà yẹn lọ yàrá àwọn alààyè ni kí wọ́n máa pe irú àwọn yàrá bẹ́ẹ̀. Àfi bí àrùn gágá ṣe wọlé dé, tí ṣòkòtò sì ṣòdí àwọn onímọ̀ ìṣègùn.

Ọ̀gbẹ́ni Crosby kọ̀wé pé: “Gbogbo àwọn oníṣègùn tó wà lọ́dún 1918 ni wọ́n ni ẹ̀bi kíkùnà tí ìmọ̀ ìṣègùn kùnà jù lọ ní ọ̀rúndún ogún. Àmọ́, tá a bá wá fojú iye gbogbo àwọn tó kú wò ó, ìmọ̀ ìṣègùn ò tíì kùnà tó bẹ́ẹ̀ rí látọjọ́ táláyé ti dáyé.” Kó má wàá lọ jẹ́ pé àwọn oníṣègùn nìkan la di ẹ̀bi ọ̀ràn ọ̀hún rù, Barry ṣàlàyé pé: “Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ò ṣàì mọ bí ewú náà ṣe máa pọ̀ tó, wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè tọ́jú òtútù àyà tí kòkòrò bakitéríà fà, wọ́n sì gbé àwọn àbá tí ì bá ti ran ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará Amẹ́ríkà lọ́wọ́ kalẹ̀. Àmọ́, ṣe làwọn olóṣèlú fetí palàbà gbogbo àbá wọn.”

Wàyí o, ní nǹkan bí ọdún márùndínláàádọ́rùn-ún lẹ́yìn náà, kí ni wọ́n ti mọ̀ nípa àrùn burúkú tó ń jà kárí ayé yìí? Kí ló fà á? Ṣó lè padà wá? Ṣé apá á ká a bó bá padà wá? Kàyéfì ni díẹ̀ lára àwọn ìdáhùn sí ìbéèrè yìí máa jẹ́ fún ọ.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 16]

Àwọn tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ogún ọdún sí ogójì ọdún ni àrùn gágá pa jù lọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Yàrá ilé ẹ̀kọ́ kan rèé lọ́dún 1919. Ó wà ní ìlú Canon City, ní ìpínlẹ̀ Colorado, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

[Credit Line]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Colorado Historical Society, 10026787

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14, 15]

Ọlọ́pàá

[Credit Line]

Fọ́tò tí Topical Press Agency/Getty Images yà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àwọn tó ń gbá bọ́ọ̀lù àfọ̀págbá tí wọ́n fi nǹkan bo imú

[Credit Line]

© Underwood & Underwood/CORBIS

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́