ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/06 ojú ìwé 20-21
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn Ibi Tó Máa Já Sí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àjàkálẹ̀ Àrùn Ibi Tó Máa Já Sí
  • Jí!—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Nípa Àjàkálẹ̀ Àrùn
  • Ewu Ṣì Ń Rọ̀ Dẹ̀dẹ̀
  • Ṣé Ọjọ́ Iwájú Á Burú Ni àbí Ó Máa Dára?
  • Àrùn Gágá Ibi Tó Yé Wa Dé Báyìí
    Jí!—2006
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Tíì Burú Jù Lọ Látọjọ́ Táláyé Ti Dáyé
    Jí!—2006
  • Ayé Kan Níbi Tí Kò Ti Ní Sí Àrùn
    Jí!—2004
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn—Àmì Òpin Ayé Ni Bí?
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—2006
g 1/06 ojú ìwé 20-21

Àjàkálẹ̀ Àrùn Ibi Tó Máa Já Sí

DÍẸ̀ lára àwọn tí ìwádìí wọn dá lórí àrùn gágá tó jà káàkiri ayé lọ́dún 1918 sí ọdún 1919 kì í yé rántí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé tí Gina Kolata kọ lórí àrùn gágá, èyí tó pè ní Flu—The Story of the Great Influenza Pandemic of 1918 and the Search for the Virus that Caused It, ó sọ pé: “Wọ́n pe àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí ọdún 1918 ní àrùn gágá, ṣùgbọ́n kò tíì sí àrùn gágá tó jọ irú ẹ̀ rí. Ṣe ló dà bíi pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló ń ní ìmúṣẹ.”

Ṣé lóòótọ́ ni Bíbélì sọ ohunkóhun tó jẹ mọ́ àjálù tó bá aráyé yìí? Dájúdájú, ó sọ bẹ́ẹ̀.

Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Nípa Àjàkálẹ̀ Àrùn

Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi ní kó fún àwọn ní àmì “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 24:3) Jésù dá wọn lóhùn pé: “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba; ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà yóò sì wà, àti àwọn àjàkálẹ̀ àrùn . . . láti ibì kan dé ibòmíràn.” (Lúùkù 21:7, 10, 11) Bíbélì tún sọ tẹ́lẹ̀ pé lákòókò òpin, “ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani” yóò wà.—Ìṣípayá 6:8.

Àrùn gágá tó jà kárí ayé bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ogun Ńlá tá a wá mọ̀ sí Ogun Àgbáyé Kìíní (tó jà lọ́dún 1914 sí ọdún 1918), ń parí lọ. Ìgbà yẹn náà làwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” bẹ̀rẹ̀ sì ní ìmúṣẹ. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí mẹ́nu kan àìtó oúnjẹ tí yóò légbá kan, ilẹ̀ ríri tó kàmàmà, ìwà àìlófin tí yóò máa pọ̀ sí i, àti báwọn èèyàn á ṣe máa tàpá sí ìlànà tí ìwà ọmọlúwàbí á sì di ohun tó ṣọ̀wọ́n. Kò sí iyèméjì pé gbogbo wa là ń rí i báwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé lónìí.—Mátíù 24:3-14; 2 Tímótì 3:1-5.

Ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú “àwọn àjàkálẹ̀ àrùn” àti “ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani” ti yọrí sí ìbẹ̀rù tó kọjá sísọ, òṣì àti ikú. Bí ìwé ìròyìn Microbes and Infection sì ṣe sọ, “kò sí ìdí tá a ò fi ní máa retí pé kí àrùn míì tó máa já kárí ayé tún ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó dà bí ẹni pé kò sí bó ṣe lè jẹ́ tírú ẹ̀ ò fi ní ṣẹlẹ̀.”

Ewu Ṣì Ń Rọ̀ Dẹ̀dẹ̀

Ìwé ìròyìn náà, Emerging Infectious Diseases, ti oṣù April ọdún 2005 sọ pé: “Àwọn tí kò sọ̀rètí nù lórí ọ̀ràn náà ti kọ́kọ́ ń ronú pé ó yẹ kí apá ti ká ewu èyíkéyìí tí àìsàn tí ń gbèèràn náà fi ń wu àwọn èèyàn.” Àmọ́, ìwé ìròyìn náà wá fi kún un pé “àwọn àrùn tí ń gbèèràn ò tíì yé yọjú.” Ìwé ìròyìn Nature ti July 8, 2004, sọ ohun tó jẹ́ àbájáde èyí pé: “Wọ́n ti fojú díwọ̀n rẹ̀ pé èèyàn bíi mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún . . . tó ń kú lọ́dọọdún ni ikú wọn ò ṣẹ̀yìn àwọn àrùn tí ń gbèèràn.”

Ìwé ìròyìn Nature ṣàlàyé pé: “Ìgbà tí àrùn éèdì dé lojú àwọn èèyàn tó là sí i pé kò sí ọgbọ́n téèyàn lè dá kí àrùn tí ń gbèèràn má padà ṣẹlẹ̀ tàbí kó má pitú ọwọ́ ẹ̀.” Àjọ UNAIDS, ètò tí ìparapọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àtàwọn àjọ míì pawọ́ pọ̀ ṣe lórí àrùn éèdì ròyìn pé: “Wọ́n fojú bù ú pé láàárín ọdún 2000 àti ọdún 2020, láwọn orílẹ̀-èdè márùndínláàádọ́ta tí àrùn náà kọ lù jù lọ, mílíọ̀nù méjìdínláàádọ́rin èèyàn ni àrùn éèdì máa pa láìtọ́jọ́.”

Láti ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sẹ́yìn, àrùn éèdì ti di lùkúlùkú tí ń dá ẹ̀mí àwọn èèyàn légbodò, ó sì ti pa èèyàn tó lé ní ogún mílíọ̀nù. Àmọ́ láàárín ọdún kan ó lé díẹ̀ péré ni àrùn gágá fi ṣọṣẹ́ tó sì pa gbogbo àwọn tó pa. Ní báyìí, nítorí ìkìlọ̀ tó ń dún gbọnmọgbọnmọ, ó ti wá dà bíi pé tipẹ́tipẹ́ ló ti yẹ kí irú àrùn gágá míì tó burú jọjọ táráyé ò retí ti jà.

Ní May 19, 2005, ètò ìròyìn kan tó ń tani lólobó nípa ohun tó bá ṣẹlẹ̀, ìyẹn Reuters Alert Net, ṣèkìlọ̀ pé irú àwọn fáírọ́ọ̀sì àrùn gágá míì á ṣì máa fara hàn nìṣó, ó sì tún fi kún un pé ìwọ̀nyí “á wulẹ̀ jẹ́ kí ewu àrùn tó ń jà kárí ayé náà túbọ̀ máa pọ̀ sí i ni.” Ìwé ìròyìn The Wall Street Journal ti May 18, 2005 sọ pé: “Fáírọ́ọ̀sì àrùn gágá tó ń kéèràn ran àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ nílẹ̀ Éṣíà ní báyìí ni wọ́n mọ̀ sí H5N1, ọjà tí wọ́n ti ń ta àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ lórílẹ̀-èdè Hong Kong ni wọ́n sì ti kọ́kọ́ rí i lọ́dún 1997. Ó rorò bí ataare, nínú ẹ̀dá alààyè márùn-ún tó bá fọwọ́ bá, á pa tó mẹ́rin.” Ìròyìn tiẹ̀ sọ pé fáírọ́ọ̀sì náà lè ran àwọn èèyàn tó bá sún mọ́ ẹranko tó ní in lára.

Ṣé Ọjọ́ Iwájú Á Burú Ni àbí Ó Máa Dára?

Ọwọ́ wa lè máà tètè tẹ ọjọ́ iwájú rere tá à ń wọ̀nà fún. Nígbà tí Jésù Kristi sọ̀rọ̀ nípa àjàkálẹ̀ àrùn ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ó jẹ́ kó ṣe kedere pé ìdí wà láti ṣàníyàn nípa bí nǹkan ṣe máa rí. Àmọ́ ṣá, Bíbélì tún mú ká nírètí. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run ṣèlérí fún Nóà àti ìdílé rẹ̀ ṣáájú Ìkún Omi tó kárí ayé. Ó kọ́kọ́ kìlọ̀ fún Nóà nípa ìparun tó ń bọ̀, lẹ́yìn náà ló wá fún un ní ìtọ́ni pé kó kan ọkọ̀ áàkì, nínú èyí tí Ọlọ́run máa fi òun àtàwọn míì pa mọ́ sí. (Jẹ́nẹ́sísì 6:13, 14; 7:1) Àpọ́sítélì Pétérù ṣàlàyé pé “sùúrù Ọlọ́run ń dúró ní àwọn ọjọ́ Nóà, nígbà tí a ń kan ọkọ̀ áàkì lọ́wọ́,” nígbà tí ó sì kan ọkọ̀ áàkì náà tán, àwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà la “gbé . . . la omi já láìséwu.”—1 Pétérù 3:20.

Jésù Kristi, tó sọ ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ipò ayé tá à ń rí lónìí, ṣí i payá pé bí ọjọ́ Nóà ni àkókò tá à ń gbé yìí rí. Àwọn tó gbọ́kàn lé Ọlọ́run bí Nóà ti ṣe ní ìrètí àtila ìparun ńláǹlà kan já. (Lúùkù 17:26, 27) Jòhánù, àpọ́sítélì Jésù, kọ̀wé pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:17.

Nígbà yẹn, òpin á ti dé bá ètò ayé ìsinsìnyí. Irú ìgbésí ayé wo làwọn tó bá là á já á máa gbádùn? Ọlọ́run mú kí àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran ipò ológo tí yóò wà lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run, ó sọ pé: “[Ọlọ́run] yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.

Kò sí ìdí fún ọ láti rò pé ọjọ́ iwájú rẹ ò ní dáa. Bó o bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tó o sì gbẹ́kẹ̀ lé e, ọjọ́ ọ̀la tó dára ló máa jẹ́ tìẹ. Ìlérí tó dájú tí Ọlọ́run ṣe ni pé nínú ayé tuntun, àwọn òkú á jíǹde. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Àjàkálẹ̀ àrùn á sì ti kásẹ̀ ńlẹ̀ títí láé fáàbàdà. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan tó máa nímùúṣẹ nínú ayé tuntun, Bíbélì ṣèlérí pé: “Kò [ní] sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Bíbélì ṣèlérí ayé tuntun nínú èyí tí “kò [ní] sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́