ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/06 ojú ìwé 13
  • Ṣó Tún Lè Ṣẹlẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣó Tún Lè Ṣẹlẹ̀?
  • Jí!—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Tíì Burú Jù Lọ Látọjọ́ Táláyé Ti Dáyé
    Jí!—2006
  • Àrùn Gágá Ibi Tó Yé Wa Dé Báyìí
    Jí!—2006
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn Ibi Tó Máa Já Sí
    Jí!—2006
  • Ẹni Tó Wà Nídìí Ogun àti Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Jí!—2006
g 1/06 ojú ìwé 13

Ṣó Tún Lè Ṣẹlẹ̀?

BÁ A bá bojú wẹ̀yìn wo báyé ṣe rí nígbà tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, ó lè dà bí ìgbà àtijọ́ àmọ́ ó ní ọ̀nà tó gbà fani mọ́ra. Bí àpẹẹrẹ, àkókò yẹn ni wọ́n máa ń fi ẹṣin fa kẹ̀kẹ́ nílẹ̀ Yúróòpù àti Amẹ́ríkà, wọ́n máa ń dé fìlà gogoro, wọ́n sì máa ń wọ kaba gígùn tó ń gbá riyẹriyẹ. Síbẹ̀, ìgbà ìpayà ló tún jẹ́, táwọn èèyàn ń kú pọ̀ọ́pọ̀ọ́ káàkiri ayé. Kí ló fà á?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iná ogun ń jó nígbà yẹn, kì í ṣòun ló fà á. Àní sẹ́, àjàkálẹ̀ àrùn tó yàtọ̀ gbáà là ń sọ̀rọ̀ ẹ̀, èyí tí wọ́n sọ pé ó tíì pààyàn nípakúpa jù lọ látijọ́ táláyé ti dáyé, ìyẹn ni àrùn gágá, tó jà lọ́dún 1918 sí ọdún 1919.

Àwọn tí àrùn náà pa pọ̀ lọ bẹẹrẹbẹ, nítorí pé wọn ò rí ìtọ́jú tó dáa, kò sì sóògùn tó gbọ́ àìsàn ọ̀hún. Bí eré bí àwàdà, àrùn náà ti dá ẹ̀mí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọ̀dọ́ légbodò. Kí wọ́n tó sin òkú kan tán, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ òkú míì á ti wà nílẹ̀. Láwọn ibì kan sì rèé, àrùn náà run odindi ìlú àti abúlé pátá.

Èyí tí gbogbo ohun tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí wáyé ti lé lọ́dún márùndínláàádọ́rùn-ún báyìí. Ǹjẹ́ a mọ ohun tó fa àrùn náà? Ṣé irú àjálù bẹ́ẹ̀ tún lè ṣẹlẹ̀? Bó bá sì ṣẹlẹ̀, ǹjẹ́ a lè gba ara wa lọ́wọ́ ẹ̀?

Apá kan tún wà tó fani mọ́ra nínú ọ̀rọ̀ tá à ń jíròrò yìí. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ó ti pẹ́ tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn àjàkálẹ̀ àrùn tó ń gbèèràn lákòókò wa yìí? (Lúùkù 21:11; Ìṣípayá 6:8) Ṣé àrùn gágá wà lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ? Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a óò jíròrò ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè míì.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Wọ́n fẹ́ sìnkú àwọn tí àrùn gágá pa nílùú Philadelphia, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

[Credit Line]

Ibi Ìkówèésí ní ilé ẹ̀kọ́ àwọn oníṣègùn, ìyẹn College of Physicians tó wà nílùú Philadelphia

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́