ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/06 ojú ìwé 22-23
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ Kí Bíbélì Máa Tọ́ Wa Sọ́nà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ Kí Bíbélì Máa Tọ́ Wa Sọ́nà?
  • Jí!—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwé Òtítọ́
  • Ó Péye Ó sì Wúlò
  • Níbo Ni Ìwọ Ti Lè Rí Ìtọ́sọ́nà Tí Ó Ṣeé Gbáralé?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ohun tó wà nínú ìwé yìí: Ṣé Bíbélì Lè Mú Káyé Ẹ Dáa Sí I?
    Jí!—2019
  • Jẹ́ Kí Ọlọ́run Máa Ṣamọ̀nà Rẹ Nínú Ohun Gbogbo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìwé Náà Tí Ó Ṣí Ìmọ̀ Ọlọrun Payá
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
Àwọn Míì
Jí!—2006
g 1/06 ojú ìwé 22-23

Ojú Ìwòye Bíbélì

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ Kí Bíbélì Máa Tọ́ Wa Sọ́nà?

“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́.”—2 Tímótì 3:16.

KÍ LO máa ń jẹ́ kó tọ́ ọ sọ́nà nínú ìgbésí ayé rẹ? Lójúmọ́ tó mọ́ lónìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé lórí gbogbo ọ̀ràn la ti lè rí ẹgbàágbèje àmọ̀ràn táwọn èèyàn kọ sílẹ̀. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tí wọ́n kọ sínú Bíbélì látọdọ́mọdún máa darí àwọn.

Ṣùgbọ́n, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn ló ka Bíbélì sí ìwé kan tí ò fi bẹ́ẹ̀ wúlò, pàápàá láyé tí ètò ìbánisọ̀rọ̀ àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tí gbàlú kan yìí. Àwọn ọ̀mọ̀wé àtàwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan táyé ń wárí fún sọ pé Bíbélì ò bágbà mu mọ́. Ṣóòótọ́ ni wọ́n sọ? Bá a bá fojú ọ̀pọ̀ ibi tá a ti lè rí àmọ̀ràn gbà, èyí tó gbòde kan lóde òní wò ó, kí nìdí tẹ́nikẹ́ni tún fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Bíbélì darí òun?

Ìwé Òtítọ́

Ìgbà kan wà tí Jésù Kristi ń sinmi lẹ́bàá kànga, tó sì ń bá obìnrin ará Samáríà kan fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀. Ó sọ fún obìnrin náà pé: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí, àwọn tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) Ìjíròrò yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ìjọsìn kan wà tí Ọlọ́run fọwọ́ sí. Kí ìjọsìn wa tó lè bá òtítọ́ mu, ó gbọ́dọ̀ bá ohun tí Ọlọ́run sọ nípa òun fúnra rẹ̀ nínú Bíbélì mu. Òtítọ́ ló wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Jòhánù 17:17.

Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìsìn ló wà tí wọ́n ń sọ pé àwọn gba Bíbélì gbọ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó dà bíi pé ẹ̀kọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni kálukú wọn fi ń kọ́ àwọn èèyàn. Àbájáde rẹ̀ ni pé, wọ́n lọ́jú ojúlówó ẹ̀kọ́ tó wà nínú Bíbélì pọ̀. Ṣé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù ni àbí òun gan-an ni Ọlọ́run? Ṣé èèyàn tún máa ń wà láàyè bó bá ti kú àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ṣé lóòótọ́ ni hẹ́ẹ̀lì jẹ́ ibi tí wọ́n ti ń dá àwọn èèyàn lóró lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kú? Ṣé ẹni gidi ni Sátánì? Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ Kristẹni? Ǹjẹ́ àwọn nǹkan tá à ń ṣe àtohun tá a máa ń ronú lé lórí kan Ọlọ́run? Ṣó tọ́ káwọn tí ò tíì ṣègbéyàwó máa bá ara wọn lò pọ̀ torí pé wọ́n ní ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn síra wọn? Ṣó burú kéèyàn máa mutí líle?a Onírúurú ẹ̀sìn ló ń pariwo pé àwọn ń fi ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn ọ̀ràn yìí kọ́ni. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ìgbà lohun táwọn ẹ̀sìn wọ̀nyí fi ń kọ́ni máa ń takora. Gbogbo ọ̀rọ̀ wọn ò ṣáà lè jóòótọ́.—Mátíù 7:21-23.

Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí yìí, báwo lèèyàn ṣe lè mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ nítòótọ́ àti irú ìjọsìn tó fọwọ́ sí? Ká ní iṣẹ́ abẹ ló lè gbà ọ́ lọ́wọ́ àìlera kan tó ń bá ẹ fínra. Kí lò bá ṣe? Bó bá ṣeé ṣe, wàá wá bó o ṣe máa wá oníṣẹ́ abẹ tó o mọ̀ pé ó mọṣẹ́ yẹn dunjú lọ. Wàá fẹ́ mọ̀ bóyá ó tóótun, bóyá ó ní ìrírí tó pọ̀ tó, wàá fẹ́ wá a lọ sílé, wàá sì fẹ́ kẹ́ ẹ fèrò wérò. Lákòótán, tó o bá ti rí ẹ̀rí tó mú kó dá ọ lójú pé òun ló mọṣẹ́ jù, wàá lè gbọ́kàn lé e, wàá sì jẹ́ kó ṣiṣẹ́ abẹ ọ̀hún fún ọ. Èrò àwọn míì lè yàtọ̀. Ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ tó o ní nínú oníṣẹ́ abẹ yẹn á túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀.

Bákan náà, bó o bá fi òótọ́ inú gbé àwọn ẹ̀rí tó wà lọ́wọ́ yẹ̀ wò fínnífínní, wàá túbọ̀ lè gba Ọlọ́run àti Bíbélì gbọ́. (Òwe 2:1-4) Bó o bá ń wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè nípa irú ìjọsìn tí Ọlọ́run fọwọ́ sí, o mọ ibi tó o lè lọ. O lè fọwọ́ mú àwọn ẹ̀kọ́ àti èrò èèyàn tó lọ́jú pọ̀ tàbí kẹ̀, kó o fọwọ́ mú ohun tí Bíbélì sọ.

Ó Péye Ó sì Wúlò

Bó o bá fara balẹ̀ yẹ Bíbélì wo dáadáa, wàá rí ẹ̀rí tó pọ̀ tó pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí ó sì ṣàǹfààní.”b (2 Tímótì 3:16, 17) Bí àpẹẹrẹ, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó kún rẹ́rẹ́ ló wà nínú Bíbélì. Ìtàn sì ti jẹ́ ká rí bó ṣe ń nímùúṣẹ. (Aísáyà 13:19, 20; Dáníẹ́lì 8:3-8, 20-22; Míkà 5:2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé sáyẹ́ǹsì síbẹ̀ àwọn ìwádìí sáyẹ́ǹsì ṣe rẹ́gí pẹ̀lú rẹ̀. Ní nǹkan bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú káwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó o ṣe àwọn àwárí wọn ló ti sọ òtítọ́ tó wà nípa àwọn ìṣẹ̀dá àti ìlera.—Léfítíkù 11:27, 28, 32, 33; Aísáyà 40:22.

Síwájú sí i, Bíbélì máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Bó o bá wonú Bíbélì wàá rí àìmọye àmọ̀ràn tó wúlò lórí ìgbésí ayé ìdílé, lórí ìlera tara àti ẹ̀dùn ọkàn, lórí òwò àtàwọn ọ̀ràn ìgbésí ayé mìíràn. Òwe 2:6, 7 sọ pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n; láti ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá. Òun yóò sì to ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ jọ fún àwọn adúróṣánṣán.” Nítorí náà, bó o bá ń jẹ́ kí Bíbélì máa darí rẹ, wàá lè kọ́ agbára ìwòye rẹ “láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—Hébérù 5:14.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ohun tí Ọlọ́run tìtorí rẹ̀ dá wa. (Jòhánù 17:3; Ìṣe 17:26, 27) Ó ṣàlàyé ìtumọ̀ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé. (Mátíù 24:3, 7, 8, 14; 2 Tímótì 3:1-5) Ọlọ́run fi hàn wá nínú rẹ̀ bí òun ṣe máa mú ìwà búburú kúrò lórí ilẹ̀ ayé tí aráyé á lè gbádùn ìlera pípé tí wọ́n á sì lè máa wà láàyè nìṣó.—Aísáyà 33:24; Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 21:3, 4.

Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti rí àrídájú pé Bíbélì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé àti pé kì í bà á tì tó bá dọ̀ràn ọgbọ́n tó wúlò. Àwọn òǹṣèwé Jí! ń rọ̀ ọ́ láti máa ka ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ yìí, èyí tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ojú Ìwòye Bíbélì,” tí yóò máa jáde déédéé nínú ìwé ìròyìn yìí. Bó o bá ń kà á, wàá lè rí àlàyé síwájú sí i tó ń fi hàn pé Bíbélì ló dáa jù lọ kó máa tọ́ ọ sọ́nà nínú ìgbésí ayé rẹ.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “Ojú Ìwòye Bíbélì”—tó jẹ́ kókó tó máa ń jáde déédéé nínú Jí! á máa jíròrò àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn míì lọ́jọ́ iwájú.

b Kó bàa lè dá ọ lójú pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run mí sí Bíbélì, wo ìwé The Bible—God’s Word or Man’s? tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀.

ǸJẸ́ Ó TI ṢE Ọ́ RÍ BÍI KÓ O BÉÈRÈ PÉ?

◼ Irú ìjọsìn wo ni Ọlọ́run fẹ́?—Jòhánù 4:24.

◼ Kí lo gbọ́dọ̀ ṣe kí ọgbọ́n Ọlọ́run lè ṣe ọ́ láǹfààní?—Òwe 2:1-4.

◼ Ọ̀nà wo ni Bíbélì gbà jẹ́ ìwé tó ń fúnni ní ìtọ́sọ́nà tó wúlò?—Hébérù 5:14.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́