Níbo Ni Ìwọ Ti Lè Rí Ìtọ́sọ́nà Tí Ó Ṣeé Gbáralé?
“OLUWA! èmi mọ̀ pé, ọ̀nà ènìyàn kò sí ní ipa araarẹ̀: kò sí ní ipá ènìyàn tí ń rìn, láti tọ́ ìṣísẹ̀ rẹ̀. Oluwa kìlọ̀ fún mi.”—Jeremiah 10:23‚ 24.
Jeremiah òǹkọ̀wé Bibeli náà kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ní nǹkan bí ọ̀rúndún 25 sẹ́yìn. Ipò amúnikẹ́dùn tí aráyé wà lẹ́yìn ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ti fífi ìtọ́sọ́nà ènìyàn sílò jẹ́rìí sí ìjótìítọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn lọ́nà tí kò ṣeé jáníkoro. Ṣùgbọ́n ìwọ lè béèrè pé, ‘Níbo ni a ti lè rí ìtọ́sọ́nà tí ó ṣeé gbáralé?’
Ẹsẹ ìwé mímọ́ tí a fàyọ lókè yìí tọ́kasí orísun ìtọ́sọ́nà àti ìdarí tí ó ṣeé fọkàntẹ̀ tí ó galọ́lá ju ti ènìyàn lọ—Ẹlẹ́dàá ènìyàn, Jehofa Ọlọrun. Dájúdájú kò sí ẹnikẹ́ni tí ó mọ ànímọ́ ènìyàn àti àìní rẹ̀ ju Ẹlẹ́dàá wa lọ. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ọlọrun ha nífẹ̀ẹ́ sí pípèsè irú ìtọ́sọ́nà ati ìdarí bẹ́ẹ̀ fún wa bí? Báwo ni òun ṣe ṣe é? Ó ha gbéṣẹ́ ní àkókò wa bí?
A Ṣẹ̀dá Wa Láti Gba Ìtọ́sọ́nà Àtọ̀runwá
A mọ̀ dáradára pé ìyàtọ̀ pàtàkì kan tí ó mú kí ènìyàn yàtọ̀ sí ẹranko sinmi lórí ìgbékalẹ̀, agbára, àti ìṣiṣẹ́ ọpọlọ ènìyàn. Nínú ẹranko, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìṣiṣẹ́ ọpọlọ wọn ni a ti ṣètò rẹ̀ sílẹ̀ nínú ohun tí a wá ń pè ní ọgbọ́n àdánidá. Èyí kò rí bẹ́ẹ̀ níti ènìyàn.—Owe 30:24-28.
Láìdàbí ọpọlọ àwọn ẹranko, apá tí ó pọ̀ jù lára ọpọlọ ènìyàn ni kò ní irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a ti lànà rẹ̀ sílẹ̀. Ọlọrun fi òmìnira ìfẹ́-inú jíǹkí ènìyàn ní mímú kí ó ṣeéṣe fún wọn láti ṣe ìpinnu tí ó lọ́gbọ́n nínú àti láti fi àwọn ànímọ́ gígalọ́lá bí ìfẹ́, ìwà-ọ̀làwọ́, àìmọtara-ẹni-nìkan, ìdájọ́-òdodo, àti ọgbọ́n hàn.
Ó ha bá ọgbọ́n mu láti ronú pé Ọlọrun yóò dá ènìyàn pẹ̀lú irú agbára èrò-orí bẹ́ẹ̀ láìpèsè irú ìtọ́sọ́nà kan lórí bí a ṣe lè lò ó lọ́nà tí ó dára jùlọ bí? Ọlọrun pèsè ìtọ́sọ́nà tí ó ṣe tààràtà fún àwọn ènìyàn àkọ́kọ́. (Genesisi 2:15-17, 19; 3:8, 9) Kódà lẹ́yìn tí ènìyàn ti ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀, Jehofa ti ń bá a lọ láti tọ́ àwọn olùṣòtítọ́ ọkùnrin àti obìnrin sọ́nà, lọ́nà tí ó ṣe kedere jùlọ, nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ òun tìkáraarẹ̀ tí a mísí, Bibeli. (Orin Dafidi 119:105) Èyí ti mú kí ó ṣeéṣe fún ènìyàn láti fi pẹ̀lú àṣeyọrí kojú àwọn ìṣòro ìgbésí-ayé ojoojúmọ́ bí wọ́n ti ń fi ọgbọ́n lo òmìnira ìfẹ́-inú wọn.
Níní Tí Bibeli Ní Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Àtọ̀runwá
Kí ni ó mú kí Bibeli jẹ́ orísun ìtọ́sọ́nà tí ó ṣeé gbáralé? Ìdí kan ni pé, ó pèsè ìsọfúnni tí ó jẹ́ pé Ẹlẹ́dàá nìkanṣoṣo ni ó lè pèsè rẹ̀. Ó ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìtàn àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí-ayé ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ, ó pèsè ìtàn bí a ti ṣe múra ilẹ̀-ayé sílẹ̀ ní ìpele ìpele títí tí ó fi di ibi tí ó bójúmu fún ẹ̀dá-ènìyàn láti gbé. (Genesisi, orí 1, 2) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kọ èyí sínú Bibeli ní nǹkan tí ó ju 3,000 ọdún sẹ́yìn, ó wà ní ìbámu pẹ̀lú èrò ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ òde-òní.
Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí aráyé ní gbogbogbòò tó gbà pé ilẹ̀-ayé rí róbótó ni Bibeli ti sọ pé: “[Ọlọrun] ni ó na ìhà àríwá ọ̀run ní ibi òfuurufú, ó sì fi ayé rọ̀ ní ojú òfo.” (Jobu 26:7) Síwájú síi, Bibeli ṣí i payá pé “oun ni ẹni tí ó jókòó lórí òbírí ayé, gbogbo àwọn tí ń gbé ibẹ̀ sì dàbí ẹlẹ́ǹgà.” (Isaiah 40:22) Ọlọrun, Ẹlẹ́dàá, nìkanṣoṣo, ni ó ti lè pèsè kúlẹ̀kúlẹ̀ yìí.
Agbára láti rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú kìí ṣe ẹ̀bùn kan tí a fifún ènìyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ẹlẹ́dàá ń lo àwọn ojú-ìwé Bibeli láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́-iwájú. Ọlọrun mísí wòlíì Isaiah láti kọ nípa Òun pé: “Èmi ni Ọlọrun, kò sì sí ẹlòmíràn, èmi ni Ọlọrun, kò sì sí ẹni tí ó dàbí èmi. Ẹni tí ń sọ òpin láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ wá, àti nǹkan tí kò tíì ṣe láti ìgbàanì wá.”—Isaiah 46:9, 10.
Bibeli ti fi ẹ̀rí hàn kedere pé òun lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa òpin láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ìpépérépéré tí ó yanilẹ́nu. Fún àpẹẹrẹ, ó sọtẹ́lẹ̀ nípa ìdìde, ìṣubú, àti ìṣesí àwọn agbára ayé ṣíṣepàtàkì lákòókò ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ìtàn ènìyàn. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pípẹtẹrí wọ̀nyí ni a kọ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú ìmúṣẹ wọn, nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó jẹ́ ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú. Bibeli tipa báyìí sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ òde-òní, àti àbájáde wọn ìkẹyìn lọ́nà pípé pérépéré. Bibeli tún jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ nítorí pé ó sọ ọ̀nà láti làájá nígbà ìparun àwọn ìjọba aláìpé àtọwọ́dá ènìyàn ní Armageddoni, “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọrun Olódùmarè.” Ìjọba Ọlọrun ní ọwọ́ Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi, yóò ṣe àṣeparí iṣẹ́ ńlá yẹn.—Ìfihàn 16:14, 16; 17:9-18; Danieli, orí 2, 8.
Ó Ṣàǹfààní Ní Gbogbo Ìgbà—Kìí Panilára Rárá
Ọgbọ́n ènìyàn lásánlàsàn jẹ́ aláìpé; nítìtorí èyí, ìmọ̀ràn ènìyàn kìí fi ìgbà gbogbo ṣàǹfààní, àní bí a bá tilẹ̀ fifúnni pẹ̀lú ète rere. Èyí kò rí bẹ́ẹ̀ níti ìmọ̀ràn Bibeli. Ọlọrun fúnraarẹ̀ sọ pé: “Èmi ni Oluwa . . . tí ó . . . tọ́ ọ ní ọ̀nà tí ìwọ ìbá máa lọ. Ìbáṣepé ìwọ fi etí sí òfin mi! nígbà náà ni àlàáfíà rẹ ìbá dàbí odò, àti òdodo rẹ bí ìgbì-omi òkun.”—Isaiah 48:17, 18.
Ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbé àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì kalẹ̀ kí á sì rọ̀ mọ́ àwọn ohun iyebíye gígalọ́lá nínú ìgbésí-ayé. Nígbà tí ẹgbẹ́ àwùjọ òde-òní gbé ìtẹnumọ́ karí àṣeyọrí àti góńgó ti ara, Bibeli tẹnumọ́ bí ó ṣe níyelórí tó fún wa láti máṣe “wo ohun tí a ń rí, bíkòṣe ohun tí a kò rí: nítorí ohun tí a ń rí ni ti ìgbà ìsinsìnyí; ṣùgbọ́n ohun tí a kò rí ni ti ayérayé.” (2 Korinti 4:18) Ní ọ̀nà yìí a ń fún wa ní ìṣírí láti ní àwọn góńgó tí ó dára jùlọ nínú ìgbésí-ayé, ìyẹn ni, àwọn góńgó tẹ̀mí ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun, èyí tí góńgó ìpẹ̀kun rẹ̀ jẹ́ ìwàláàyè nínú ètò-titun òdodo.
Bí Kristian náà ti ń tiraka láti lé àwọn góńgó tí ó níyì wọ̀nyí bá, ìmọ̀ràn Bibeli ń ràn án lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí-ayé tí ó dára jùlọ tí ó ṣeéṣe nínú ètò búburú àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Ọgbọ́n ènìyàn òde-òní ń tẹ̀ síhà fífún èrò ká ṣiṣẹ́ kékeré kí a rí èrè púpọ̀ ní ìṣírí. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Bibeli sọ fún wa pé “ẹni tí ó bá dẹ ọwọ́ a di tálákà; ṣùgbọ́n ọwọ́ àwọn aláápọn ni ń mú ọlà wá.” Aposteli Paulu kọ̀wé sí àwọn Kristian tí wọ́n jẹ́ Heberu pé: “Àwa gbàgbọ́ pé àwa ní ẹ̀rí-ọkàn rere, a sì ń fẹ́ láti máa wà lódodo nínú ohun gbogbo.”—Owe 10:4; Heberu 13:18.
Bibeli tún fúnni ní ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ lórí ìṣètò ìdílé. Ó fìdí ipa tí ọkọ àti aya ń kó nínú ìṣètò ìgbéyàwó múlẹ̀ ní pàtó, àti ọ̀nà tí ó tọ́ láti gbà tọ́ àwọn ọmọ kí a sì kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ó sọ pé: “Ó tọ́ kí àwọn ọkùnrin kí ó máa fẹ́ràn àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn tìkáraawọn. . . . kí aya kí ó sì bẹ̀rù ọkọ rẹ̀. Ẹyin ọmọ, ẹ máa gbọ́ ti àwọn òbí yin . . . Ẹ̀yin baba, ẹ máṣe mú àwọn ọmọ yín bínú: ṣùgbọ́n ẹ máa tọ́ wọn ninu ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ Oluwa.” Títẹ̀lé ìmọ̀ràn gígalọ́lá ti Ẹlẹ́dàá ń fikún ìdúró déédéé àti ayọ̀ ìdílé lọ́pọ̀lọpọ̀.—Efesu 5:21–6:4.
Ọjọ́-Ọ̀la Aláìléwu fún Àwọn Wọnnì tí Wọ́n Tẹ̀lé Ìtọ́sọ́nà Ọlọrun
Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí a kọ sílẹ̀ tọ́kasí ojútùú tí Ọlọrun ní fún gbogbo ìṣòro aráyé. Láìpẹ́ láìjìnnà Jehofa Ọlọrun yóò mú ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí kúrò, pẹ̀lú gbogbo ìrora, àìṣèdájọ́-òdodo àti ìjìyà, yóò sì fi ètò titun òdodo rẹ̀ rọ́pò rẹ̀. Bibeli ṣàpèjúwe èyí ní 2 Peteru 3:7-10, ní fífikún un ní ẹsẹ 13 pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, àwa ń retí àwọn ọ̀run titun àti ayé titun, nínú èyí tí òdodo ń gbé.” Èyí papọ̀ jẹ́ ìhìnrere tí ó dára jùlọ tí a lè fifún ìdílé ẹ̀dá-ènìyàn. Òun gan-an ni ìhìn-iṣẹ́ tí Bibeli gbékalẹ̀ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sì ń wàásù rẹ̀ ní èyí tí ó ju 200 ilẹ̀ àti erékùṣù òkun.
Nígbà tí ìfẹ́-inú Ọlọrun bá di ṣíṣe ní gbogbo ilẹ̀-ayé, gbogbo ìdílé ẹ̀dá-ènìyàn pátápátá ni yóò jàǹfààní nípa títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà pípegedé ti Ẹlẹ́dàá rẹ̀, Jehofa. Kì yóò sí ìṣòro òṣì, ìwà-ọ̀daràn, àti oògùn mọ́. Aráyé kì yóò jìyà lọ́wọ́ àìsàn, ọjọ́ ogbó, àti ikú mọ́. Ìdílé ẹ̀dá-ènìyàn ni a óò gbéga sípò ìjẹ́pípé tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ní ṣáájú kí wọ́n tó ṣọ̀tẹ̀ sí ìtọ́sọ́nà Ọlọrun.
Ẹ wo bí ìwé tí ó kẹ́yìn nínú Bibeli ṣe ṣàkópọ̀ ipò aláyọ̀ tí àwọn wọnnì tí wọ́n fọkàntán ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá yóò gbádùn! Ìfihàn 21:4, 5 sọ pé: “Ọlọrun yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn; kì yóò sì sí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ìrora mọ́: nítorí pé ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” Ẹlẹ́dàá wa mú ìyẹn dánilójú, ní wíwí pé: “Kíyèsí i, mo sọ ohun gbogbo di ọ̀tun.” Ó fikún un pé: “Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí òdodo àti òtítọ́ ni wọ́n.”
Bí a óò bá gba àwọn ìbùkún wọ̀nyí, kí ni ohun tí Ọlọrun ń retí lọ́dọ̀ wa? Aposteli Paulu ṣàlàyé pé ìfẹ́-inú Ọlọrun ni pé “kí gbogbo ènìyàn ní ìgbàlà kí wọ́n sì wá sínú ìmọ̀ òtítọ́.” (1 Timoteu 2:4) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà késí ọ láti jèrè ìmọ̀ pípéye ti òtítọ́ náà nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ó jinlẹ̀. Nípa fífi taápọntaápọn kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́ àtọ̀runwá, ìwọ lè tipasẹ̀ ìrírí ríi pé ọgbọ́n àtọ̀runwá nìkanṣoṣo ni ìtọ́sọ́nà tí ó ṣeé gbáralé ní àwọn àkókò eléwu wọ̀nyí. Ìjẹ́kánjúkánjú àwọn àkókò mú kí ó túbọ̀ ṣe pàtàkì ju ti ìgbàkigbà rí lọ lati tẹ̀lé e!