ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp21 No. 3 ojú ìwé 12-14
  • Amọ̀nà Tó Ṣeé Gbára Lé Nípa Bí Ọjọ́ Ọ̀la Wa Ṣe Máa Dáa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Amọ̀nà Tó Ṣeé Gbára Lé Nípa Bí Ọjọ́ Ọ̀la Wa Ṣe Máa Dáa
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2021
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • AMỌ̀NÀ TÍ KÒ LẸ́GBẸ́
  • Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Jí!—2017
  • Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Tínú Ọlọ́run Dùn Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Bíbélì Ni Afinimọ̀nà Tó Dájú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2024
  • Níbo Ni Ìwọ Ti Lè Rí Ìtọ́sọ́nà Tí Ó Ṣeé Gbáralé?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2021
wp21 No. 3 ojú ìwé 12-14
Ọkùnrin kan ń ka Bíbélì.

Amọ̀nà Tó Ṣeé Gbára Lé Nípa Bí Ọjọ́ Ọ̀la Wa Ṣe Máa Dáa

Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a ti sọ̀rọ̀ nípa ohun táwọn èèyàn máa ń ṣe kí ọjọ́ ọ̀la wọn lè dáa. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n gbà gbọ́ nínú àyànmọ́, wọ́n máa ń kàwé dáadáa, wọ́n máa ń lé bí wọ́n ṣe máa dolówó rẹpẹtẹ, wọ́n sì máa ń hùwà rere. Àmọ́, ohun tó ṣẹlẹ̀ sọ́pọ̀ èèyàn ti jẹ́ ká rí i pé tẹ́nì kan bá gbà pé àwọn nǹkan yìí ló máa jẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la òun dáa, ṣe lọ̀rọ̀ ẹni náà máa dà bíi tẹnì kan tó fẹ́ lọ síbì tí ò dé rí tó wá lọ ń béèrè ọ̀nà lọ́wọ́ ẹni tí kò mọ̀nà. Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé kò sẹ́ni tó lè fún wa nímọ̀ràn tó lè fi wá lọ́kàn balẹ̀, táá sì jẹ́ ká gbà pé ọjọ́ ọ̀la wa máa dáa? Rárá o!

AMỌ̀NÀ TÍ KÒ LẸ́GBẸ́

Tá a bá fẹ́ ṣèpinnu, a sábà máa ń fẹ́ gbàmọ̀ràn látọ̀dọ̀ ẹni tó dàgbà tó sì tún gbọ́n jù wá lọ. Lọ́nà kan náà, a lè rí ìmọ̀ràn tó ṣeé gbára lé nípa bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí látọ̀dọ̀ ẹnì kan tó dàgbà jù wá lọ fíìfíì, tó sì tún gbọ́n jù wá lọ. Ìmọ̀ràn ẹni náà wà nínú ìwé kan tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tà ààbọ̀ (3,500) ọdún sẹ́yìn. Bíbélì lorúkọ ìwé náà.

Kí nìdí tó fi yẹ kó o gbára lé Bíbélì? Ìdí ni pé ọ̀dọ̀ ẹni tó dàgbà jù lọ tó sì gbọ́n jù lọ ni àwọn nǹkan tó wà nínú ẹ̀ ti wá. Òun ni “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,” ó sì wà “láti ayérayé dé ayérayé.” (Dáníẹ́lì 7:9; Sáàmù 90:2) Bákan náà, òun ni “Ẹlẹ́dàá ọ̀run, Ọlọ́run tòótọ́, ẹni tó dá ayé.” (Àìsáyà 45:18) Ó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ òun.​—Sáàmù 83:18.

Torí pé ọ̀dọ̀ ẹni tó dá gbogbo èèyàn ni Bíbélì ti wá, gbogbo èèyàn ló lè jàǹfààní látinú ohun tó wà nínú rẹ̀. Kò sígbà táwọn ìmọ̀ràn inú ẹ̀ ò wúlò, ó sì ti ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní níbi gbogbo láyé. Nínú gbogbo ìwé tó wà láyé, Bíbélì ni ìwé tó dé ibi tó pọ̀ jù lọ, òun ló sì wà ní èdè tó pọ̀ jù lọ.a Torí náà, ó rọrùn fún gbogbo èèyàn láti kà, ó sì ń ṣe gbogbo àwọn tó ń kà á láǹfààní. Ìyẹn sì bá ohun tí Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ mu pé:

“Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àmọ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.”​—ÌṢE 10:34, 35.

Bó ṣe jẹ́ pé àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn máa ń tọ́ wọn sọ́nà, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà Bàbá wa ọ̀run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa, tó sì fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kó lè máa tọ́ wa sọ́nà. (2 Tímótì 3:16) A lè gbára lè Bíbélì, ó ṣe tán Jèhófà tó fún wa ní Bíbélì ni Ẹlẹ́dàá wa, ó sì mọ ohun tá a lè ṣe káyé wa lè ládùn kó sì lóyin.

AMỌ̀NÀ TÓ ṢEÉ GBÁRA LÉ

Àwòrán: 1. Ọkùnrin kan wà nínú ọkọ̀ ojú irin, ó sì ń ka Bíbélì lórí fóònù rẹ̀. 2. Ọkùnrin náà mú fóònù ẹ̀ dání, Bíbélì tó ń kà sì wà lójú fóònù náà.

Kí nìdí tá a fi lè gbára lé ohun tí Bíbélì bá sọ nípa bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí? Ìdí ni pé láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn ló ti sọ àwọn nǹkan táá máa ṣẹlẹ̀ lóde òní àti irú ìwà táwọn èèyàn á máa hù, gbogbo ohun tó sọ ló sì ti ń ṣẹlẹ̀ báyìí.

ÀWỌN NǸKAN TÁÁ MÁA ṢẸLẸ̀

“Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba. Ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára máa wáyé, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn sì máa wà láti ibì kan dé ibòmíì.”​—LÚÙKÙ 21:10, 11.

ÌWÀ TÁWỌN ÈÈYÀN Á MÁA HÙ

“Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yóò jẹ́ àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira. Torí àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan, wọ́n á nífẹ̀ẹ́ owó, wọ́n á jẹ́ afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìmoore, aláìṣòótọ́, ẹni tí kò ní ìfẹ́ àdámọ́ni, kìígbọ́-kìígbà, abanijẹ́, ẹni tí kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu, ẹni tó burú gan-an, ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ ohun rere, ọ̀dàlẹ̀, alágídí, ajọra-ẹni-lójú, wọ́n á fẹ́ràn ìgbádùn dípò Ọlọ́run.”​—2 TÍMÓTÌ 3:1-4.

Ní báyìí tó o ti mọ̀ pé Bíbélì ti sọ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lásìkò wa yìí látọjọ́ tó ti pẹ́, kí lèrò ẹ? Ó dájú pé wàá gbà pé òótọ́ lohun tí Leung tó ń gbé ní Hong Kong sọ pé: “Ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti kọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. Kò sí bí èèyàn lásán-làsàn ṣe lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí kó sì rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Ó ní láti jẹ́ pé ọ̀dọ̀ ẹnì kan tí ìmọ̀ ẹ̀ ò lẹ́gbẹ́ ni Bíbélì ti wá.”

Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì ló ti ṣẹ.b Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì lóòótọ́. Jèhófà fúnra ẹ̀ sọ pé: “Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹni tó dà bí èmi. Láti ìbẹ̀rẹ̀, mò ń sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀.” (Àìsáyà 46:9, 10) Torí náà, a lè gbára lé ohun tí Bíbélì bá sọ nípa bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí.

AMỌ̀NÀ TÁÁ ṢE Ẹ́ LÁǸFÀÀNÍ NÍ BÁYÌÍ ÀTI TÍTÍ LÁÉ

Bàbá àti ìyá kan di ọwọ́ àwọn ọmọ wọn mú, inú wọn sì ń dùn bí wọ́n ṣe ń rìn kọjá lórí pápá kan.

O máa rí àǹfààní tó pọ̀ gan-an tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀.

ÌMỌ̀RÀN TÓ ṢEÉ GBÁRA LÉ NÍPA OWÓ ÀTI IṢẸ́

“Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílé ohun tó jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.”​—ONÍWÀÁSÙ 4:6.

ÌMỌ̀RÀN NÍPA BÍ ÌDÍLÉ ṢE LÈ LÁYỌ̀

“Kí kálukú yín nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; bákan náà, kí aya ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”​—ÉFÉSÙ 5:33.

ÌMỌ̀RÀN NÍPA BÓ ṢE YẸ KÁ MÁA ṢE SÁWỌN ÈÈYÀN

“Fi ìbínú sílẹ̀, kí o sì pa ìrunú tì; má ṣe bínú kí o wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ibi.” ​—SÁÀMÙ 37:8.

Tó o bá ń ṣe ohun tí Bíbélì sọ, wàá rí ọ̀pọ̀ àǹfààní ní báyìí, ọjọ́ ọ̀la rẹ á sì dáa. Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan rere tí Ọlọ́run ṣèlérí pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Díẹ̀ lára wọn rèé:

ÀLÀÁFÍÀ MÁA WÀ NÍBI GBOGBO

“Inú wọn yóò . . . máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”​—SÁÀMÙ 37:11.

GBOGBO ÈÈYÀN Á RÍLÉ GBÉ, WỌ́N Á SÌ RÍ OÚNJẸ TÓ WÙ WỌ́N JẸ

“Wọ́n á kọ́ ilé, wọ́n sì máa gbé inú wọn, wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, wọ́n sì máa jẹ èso wọn.”​—ÀÌSÁYÀ 65:21.

KÒ NÍ SÍ ÀÌSÀN TÀBÍ IKÚ MỌ́

“Ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.”​—ÌFIHÀN 21:4.

Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ gbádùn àwọn nǹkan yìí? Wàá rí ìdáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

a Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i nípa bí wọ́n ṣe ń túmọ̀ Bíbélì àti bó ṣe ń dọ́wọ́ àwọn èèyàn, lọ sórí ìkànnì www.jw.org, wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÌTÀN ÀTI BÍBÉLÌ.

b Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, wo orí 9 nínú ìwé The Bible​—God’s Word or Man’s? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí, ó sì wà lórí ìkànnì www.jw.org. Lọ sí abẹ́ OHUN TÁ A NÍ > ÌWÉ ŃLÁ ÀTI ÌWÉ PẸLẸBẸ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́