ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp24 No. 1 ojú ìwé 6-9
  • Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Bíbélì Ni Afinimọ̀nà Tó Dájú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Bíbélì Ni Afinimọ̀nà Tó Dájú
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2024
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A NÍLÒ ÌTỌ́SỌ́NÀ ỌLỌ́RUN
  • BÍBÉLÌ JẸ́ KÁ MỌ OHUN TÍ ỌLỌ́RUN FẸ́ KÁ MÁA ṢE
  • Ṣé A Ṣì Lè Gbára Lé Àwọn Ìlànà Bíbélì Lórí Ohun Tó Tọ́ àti Ohun Tí Kò Tọ́?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ohun Míì Tó Máa Ran Ìdílé Lọ́wọ́
    Jí!—2018
  • Amọ̀nà Tó Ṣeé Gbára Lé Nípa Bí Ọjọ́ Ọ̀la Wa Ṣe Máa Dáa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2021
  • Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Pinnu Ohun Tí Wàá Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2024
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2024
wp24 No. 1 ojú ìwé 6-9

Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Bíbélì Ni Afinimọ̀nà Tó Dájú

Tó bá jẹ́ pé bí nǹkan ṣe ń rí lára wa tàbí ohun táwọn èèyàn ń sọ la fi ń mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, ó ṣeé ṣe ká má ṣe ohun tó tọ́. Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀, ó sì tún fún wa ní ìmọ̀ràn tó ṣeé gbára lé, tó máa jẹ́ ká gbádùn ayé wa, kí ọkàn wa sì balẹ̀.

A NÍLÒ ÌTỌ́SỌ́NÀ ỌLỌ́RUN

Nínú Bíbélì, Jèhófàa Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá fẹ́ ṣàṣeyọrí, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kóun máa darí wa. (Jeremáyà 10:23) Ìdí nìyẹn tó fi fún wa láwọn ìlànà tó yẹ ká máa tẹ̀ lé. Ó nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an, kò fẹ́ ká ṣe ohun tó máa kó bá wa, kò sì fẹ́ ká jìyà ká tó gbọ́n. (Diutarónómì 5:29; 1 Jòhánù 4:8) Yàtọ̀ síyẹn, torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, ó ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ tó pọ̀ tó láti fún wa ní ìmọ̀ràn tó máa ṣe wá láǹfààní jù lọ. (Sáàmù 100:3; 104:24) Síbẹ̀, kì í fipá mú wa láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀.

Jèhófà fún Ádámù àti Éfà, ìyẹn ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ ní gbogbo ohun tí wọ́n nílò kí wọ́n lè máa láyọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28, 29; 2:8, 15) Ó sọ àwọn nǹkan tó yẹ kí wọ́n ṣe àtàwọn nǹkan tí kò yẹ kí wọ́n ṣe, àwọn nǹkan náà ò sì nira. Àmọ́, ó fún wọn láǹfààní láti yàn bóyá wọ́n máa ṣe ohun tóun sọ àbí wọn ò ní ṣe é. (Jẹ́nẹ́sísì 2:9, 16, 17) Ó dunni pé ohun tó wu Ádámù àti Éfà ni wọ́n ṣe dípò kí wọ́n ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ. (Jẹ́nẹ́sísì 3:6) Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Ṣáwọn èèyàn ń láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń ṣe ohun tí wọ́n gbà pé ó dáa? Rárá o. Ohun tójú àwa èèyàn ti rí fi hàn pé tá ò bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run, ọkàn wa ò ní balẹ̀, a ò sì ní láyọ̀.—Oníwàásù 8:9.

Gbogbo èèyàn ni ìmọ̀ràn inú Bíbélì wúlò fún, tá a bá ń tẹ̀ lé e, àá máa ṣe ohun tó dáa, a ò sì ní kó ara wa sí ìṣòro. (2 Tímótì 3:16, 17; wo àpótí náà “Gbogbo Èèyàn Ni Bíbélì Wúlò Fún.”) Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ìmọ̀ràn náà.

Kẹ́kọ̀ọ́ sí i, kó o lè mọ ìdí tá a fi gbà pé “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ni Bíbélì lóòótọ́.—1 Tẹsalóníkà 2:13. Lọ sí jw.org, kó o sì wo fídíò náà Ta Ni Òǹṣèwé Bíbélì?

GBOGBO ÈÈYÀN NI BÍBÉLÌ WÚLÒ FÚN

Torí pé ọlọ́gbọ́n ni Ẹlẹ́dàá wa, tó sì nífẹ̀ẹ́ wa, ó rí i dájú pé àwọn ìmọ̀ràn tó fẹ́ ká máa tẹ̀ lé wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo èèyàn. Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan díẹ̀ nípa Bíbélì:

Àwọn èèyàn láti onírúurú orílẹ̀-èdè ń ka Bíbélì. Àwọn oríṣi Bíbélì àtèyí tó wà lórí ẹ̀rọ wà nísàlẹ̀ wọn.
  • 3,500+ Èyí ni iye èdè tí wọ́n ti túmọ̀ Bíbélì sí lódindi tàbí lápá kan. Kò sí ìwé míì tí wọ́n túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ láyé.

  • 5,000,000,000+ Èyí ni iye Bíbélì tí wọ́n ti tẹ̀ jáde, kò sí ìwé míì láyé tí iye ẹ̀ pọ̀ tóyẹn.

Bíbélì ò gbé àwọ̀, orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà tàbí àṣà kan ga ju òmíì lọ. Ó ṣe kedere pé gbogbo èèyàn ni Bíbélì wà fún.

Lọ sí jw.org, wàá rí Bíbélì kà níbẹ̀ ní èdè tó ju 250 lọ

Ọkùnrin kan ń ka Bíbélì, ó sì ń fọwọ́ kàn án bó ṣe ń kà á.

ÌDÍ TÁWỌN KAN FI GBÀ PÉ BÍBÉLÌ Ò LÈ RAN ÀWỌN LỌ́WỌ́

Àwọn kan gbà pé ìmọ̀ràn Bíbélì ò lè ṣe àwọn láǹfààní. Díẹ̀ lára ohun tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń sọ rèé.

Ohun Táwọn Kan Sọ: “Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ta kora.”

Òótọ́ Ọ̀rọ̀: Ó lè dà bíi pé àwọn apá ibì kan wà nínú Bíbélì tó ta kora wọn lóòótọ́. Àmọ́, téèyàn bá fara balẹ̀ wo ohun tí wọ́n ń sọ bọ̀ àtohun tí wọ́n sọ tẹ̀ lé e, ohun tí ìtàn sọ, àṣà àwọn èèyàn láyé ìgbà yẹn, èrò ẹni tó kọ ọ̀rọ̀ náà àtàwọn nǹkan míì, èèyàn á rí i pé Bíbélì ò ta kora rárá.

Kó o lè rí àpẹẹrẹ irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, lọ sí jw.org, kó o sì ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Bíbélì Ta Kora?”

Ohun Táwọn Kan Sọ: “Oríṣiríṣi ìwà burúkú là ń bá lọ́wọ́ àwọn tó sọ pé àwọn ń ka Bíbélì, torí náà kò lè jẹ́ ìwé gidi kan tọ́rọ̀ inú ẹ̀ ṣeé tẹ̀ lé.”

Òótọ́ Ọ̀rọ̀: Táwọn kan tó ń ka Bíbélì bá ń hùwà burúkú, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ò dáa. Àwọn èèyàn yẹn ni ò fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò. Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ìwà àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àtàwọn míì kò ní bá ohun tí wọ́n ń kọ́ nínú Bíbélì mu. Kódà, Bíbélì tún sọ pé àwọn kan á máa “sọ̀rọ̀ àbùkù sí” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—2 Pétérù 2:1, 2.

Tó o bá fẹ́ rí àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ò tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ, lọ sí jw.org, kó o sì ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Ẹ̀sìn Ti Wá Di Òwò Tó Ń Mówó Rẹpẹtẹ Wọlé?”

Ohun Táwọn Kan Sọ: “Àwọn tó ń tẹ̀ lé ohun tó wà nínú Bíbélì kì í bọ̀wọ̀ fáwọn tí kò bá ti fara mọ́ èrò wọn.”

Òótọ́ Ọ̀rọ̀: Bíbélì kọ́ wa pé ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún gbogbo èèyàn. Bíbélì ò fàyè gbà á pé . . .

  • kéèyàn máa wo ara ẹ̀ bíi pé òun dáa ju àwọn tó kù lọ.—Fílípì 2:3.

  • kéèyàn máa fàbùkù kan àwọn tó ní èrò tó yàtọ̀ sí tiẹ̀.—1 Pétérù 2:17.

  • kéèyàn máa fipá mú àwọn èèyàn láti fara mọ́ ohun tó gbà gbọ́.—Mátíù 10:14.

Bíbélì jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, gbogbo ìgbà ló máa ń ṣoore fáwọn èèyàn, ó sì fẹ́ káwa náà máa ṣe bẹ́ẹ̀.—Róòmù 9:14.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, lọ sí jw.org, kó o sì ka àpilẹ̀kọ náà “Bíbélì Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Ká Lè Máa Bọ̀wọ̀ fún Èrò Àwọn Míì.”

BÍBÉLÌ JẸ́ KÁ MỌ OHUN TÍ ỌLỌ́RUN FẸ́ KÁ MÁA ṢE

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe bá àwọn èèyàn lò látìbẹ̀rẹ̀. Ohun tó wà nínú ẹ̀ jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run kà sí ohun tó dáa àti ohun tí kò dáa, ohun tó lè ṣe wá láǹfààní àti ohun tó lè kó bá wa. (Sáàmù 19:7, 11) Kò sígbà táwọn ìlànà inú ẹ̀ kì í ṣeni láǹfààní, tá a bá sì ń tẹ̀ lé e, á jẹ́ ká máa ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu nígbà gbogbo.

Bí àpẹẹrẹ, wo ìmọ̀ràn tó wà nínú Òwe 13:20, tó sọ pé: “Ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, àmọ́ ẹni tó ń bá òmùgọ̀ da nǹkan pọ̀ yóò rí láburú.” Bí ìmọ̀ràn yẹn ṣe wúlò nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣì ṣe wúlò lásìkò wa yìí. Àwọn ìmọ̀ràn àtàtà bí irú èyí pọ̀ gan-an nínú Bíbélì.—Wo àpótí náà “Ìmọ̀ràn Inú Bíbélì Ṣì Wúlò.”

Àmọ́, o lè máa rò ó pé ‘Ẹ̀rí wo ló wà pé àwọn ìlànà Bíbélì ṣì wúlò lóde òní?’ Àpilẹ̀kọ tó kàn máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ìlànà Bíbélì ti ṣe láǹfààní.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.

ÌMỌ̀RÀN INÚ BÍBÉLÌ ṢÌ WÚLÒ

Òótọ́ ni pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn ni wọ́n parí kíkọ Bíbélì, síbẹ̀ ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ṣì wúlò títí di báyìí. Ó ṣe tán, ohun táwọn èèyàn kà sí pàtàkì ò tíì yí pa dà. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo èèyàn ló fẹ́ láyọ̀, tí wọ́n sì fẹ́ kọ́kàn wọn balẹ̀. (Oníwàásù 1:9) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti kọ Bíbélì, tá a bá ń fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú ẹ̀ sílò, a máa láyọ̀, ọkàn wa sì máa balẹ̀.

Jíjẹ́ Olóòótọ́

  • Ó “wù wá láti jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.”—Hébérù 13:18.

  • “Kí ẹni tó ń jalè má jalè mọ́; kàkà bẹ́ẹ̀, kó máa ṣiṣẹ́ kára.”—Éfésù 4:28.

Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Ṣe Sáwọn Èèyàn

  • “Kí kálukú máa wá ire ti ẹlòmíì, kì í ṣe ti ara rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 10:24.

  • “Ẹ máa fara dà á fún ara yín, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà.”—Kólósè 3:13.

Tá A Bá Fẹ́ Ṣèpinnu

  • “Aláìmọ̀kan máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́, àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.”—Òwe 14:15.

  • “Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pa mọ́, àmọ́ aláìmọ̀kan kọrí síbẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.”—Òwe 22:3.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́