Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Pinnu Ohun Tí Wàá Ṣe
Ìlànà tá a bá yàn láti tẹ̀ lé ló máa pinnu bóyá a máa láyọ̀ àbí a ò ní láyọ̀. Jèhófà náà mọ̀ bẹ́ẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi ń rọ̀ wá pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òun.
Jèhófà fẹ́ ká láyọ̀ kí ọkàn wa sì balẹ̀.
“Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tó ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tó ń jẹ́ kí o mọ ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn. Ká ní o fetí sí àwọn àṣẹ mi ni! Àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.”—Àìsáyà 48:17, 18.
Torí pé Ọlọ́run ló dá wa, ó mọ ohun tó máa jẹ́ káyé wa dáa. Ó ní ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn òun, torí wọ́n máa ṣe wá láǹfààní. Tá a bá ń pa òfin Ọlọ́run mọ́, a ò ní máa bẹ̀rù bóyá ohun tá a ṣe dáa àbí kò dáa. Gbogbo ìgbà làá máa ṣe ohun tó dáa, torí náà inú wa á máa dùn, ọkàn wa á sì balẹ̀.
Jèhófà ò retí pé ká ṣe ohun tó kọjá agbára wa.
“Àṣẹ tí mò ń pa fún ọ lónìí yìí kò nira jù fún ọ, kì í sì í ṣe ohun tí kò sí lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ.”—Diutarónómì 30:11.
Tá a bá fẹ́ máa tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà, ó lè gba pé ká yí ìwà àti ìrònú wa pa dà. Àmọ́, Jèhófà ò retí pé ká ṣe ohun tó ju agbára wa lọ. Ó ṣe tán, òun ni Ẹlẹ́dàá wa, ó sì mọ ohun tí agbára wa gbé. Bá a bá ṣe ń mọ Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ làá máa rí i pé “àwọn àṣẹ rẹ̀ kò nira.”—1 Jòhánù 5:3.
Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ran àwọn tó bá ń tẹ̀ lé ìlànà òun lọ́wọ́.
“Èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tó ń sọ fún ọ pé, ‘Má bẹ̀rù. Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.’”—Àìsáyà 41:13.
A lè ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, torí ó dájú pé ó máa ràn wá lọ́wọ́. Ó lè lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́, kó lè fún wa níṣìírí, ká sì lè ní ìrètí.
Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló ti rí i pé nígbà tí wọ́n ń ṣe ohun tí Bíbélì sọ, ńṣe layé wọn ń dáa sí i. Ìwọ náà máa rí ọ̀pọ̀ àǹfààní tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ sí i, kó o lè mọ àwọn ìmọ̀ràn àtàtà tó wà nínú Bíbélì. O lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì látinú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ìwé yìí wà lórí jw.org, ọ̀fẹ́ lo sì máa wà á jáde. Àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé náà rèé:
Ṣé Bíbélì Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́?
Bíbélì Sọ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Gbára Lé Bíbélì?
Tó o bá fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wàá rí i pé ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ṣì wúlò gan-an, ó sì “ṣeé gbára lé ní gbogbo ìgbà, ní báyìí àti títí láé.” (Sáàmù 111:8) Ohun tó dáa jù tá a lè ṣe ni pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, torí ìyẹn ló máa jẹ́ káyé wa dáa. Àmọ́, Ọlọ́run ò ní fipá mú wa pé ká tẹ̀ lé ìlànà òun. (Diutarónómì 30:19, 20; Jóṣúà 24:15) Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa yàn bóyá òun máa ṣe bẹ́ẹ̀ àbí òun ò ní ṣe bẹ́ẹ̀.