Ohun Tó O Bá Ṣe Láá Pinnu Bọ́jọ́ Ọ̀la Ẹ Ṣe Máa Rí
Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ (3,500) ọdún sẹ́yìn, Jèhófà Ọlọ́run sọ ohun táwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ máa ṣe tí wọ́n bá fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la wọn dáa. Ó ní: “Mo ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, ìbùkún àti ègún; yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè, ìwọ àti àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ.”—Diutarónómì 30:19.
Àwọn èèyàn yẹn gbọ́dọ̀ pinnu láti ṣe ohun tó tọ́ tí wọ́n bá fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la wọn dáa. Àwa náà ní láti ṣe ohun kan náà lónìí. Bíbélì sọ ohun tá a lè ṣe tá a bá fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la wa dáa. Ó sọ pé ká ‘nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run wa, ká sì máa fetí sí ohùn rẹ̀.’—Diutarónómì 30:20.
BÁWO LA ṢE LÈ NÍFẸ̀Ẹ́ JÈHÓFÀ KÁ SÌ MÁA FETÍ SÍ OHÙN RẸ̀?
MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ: Kó o tó lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, o ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ látinú Bíbélì. Bó o bá ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni wàá máa rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ, wàá sì gbà pé ohun tó dáa jù lọ ló fẹ́ fún ẹ. Ó fẹ́ kó o máa gbàdúrà sí òun ‘torí ó ń bójú tó ẹ.’ (1 Pétérù 5:7) Kódà, Bíbélì jẹ́ ká rí i pé tó o bá gbìyànjú láti sún mọ́ ọn, ó máa ‘sún mọ́ ẹ.’—Jémíìsì 4:8.
MÁA FI OHUN TÓ Ò Ń KỌ́ SÍLÒ: O máa fi hàn pé ò ń fetí sí Ọlọ́run tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n rẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, “ọ̀nà rẹ máa yọrí sí rere, . . . wàá sì máa hùwà ọgbọ́n.”—Jóṣúà 1:8.
a Ní báyìí, ó wà ní èdè méje. Lára àwọn èdè náà ni Gẹ̀ẹ́sì, Mandarin Chinese àti Cantonese Chinese.