ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/06 ojú ìwé 26-27
  • Ṣé Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Ló Wà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Ló Wà?
  • Jí!—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Èèyàn Wulẹ̀ Ń Méfò Pé Wọ́n Wà Ni
  • Jésù, Àwọn Áńgẹ́lì àti Èṣù
  • Jọsin Ọlọrun Wo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ṣé Ọ̀kan Náà Ni Gbogbo Ìsìn? Ǹjẹ́ Gbogbo Rẹ̀ Ni Ọlọrun Tẹ́wọ́ Gbà?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ojú Tí Àwọn Kristẹni Ọ̀rúndún Kìíní Fi Wo Òrìṣà Àwọn Ará Róòmù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ẹ Padà Sínú Ìjọsìn Jèhófà
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
Àwọn Míì
Jí!—2006
g 4/06 ojú ìwé 26-27

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣé Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Ló Wà?

MÓLÉKÌ, Áṣítórétì, Báálì, Dágónì, Méródákì, Súúsì, Hẹ́mísì àti Átẹ́mísì jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ọlọ́run àti abo-ọlọ́run tí Bíbélì dárúkọ. (Léfítíkù 18:21; Onídàájọ́ 2:13; 16:23; Jeremáyà 50:2; Ìṣe 14:12; 19:24) Àmọ́, Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Ìwé Mímọ́ pè ní Ọlọ́run Olódùmarè. Orin ìṣẹ́gun kan tí Mósè ṣíwájú àwọn èèyàn náà láti kọ lọ báyìí pé: “Jèhófà, ta ní dà bí rẹ láàárín àwọn ọlọ́run?”—Ẹ́kísódù 15:11.

Ó ṣe kedere pé Bíbélì gbé Jèhófà ga ju gbogbo àwọn ọlọ́run mìíràn lọ. Bá a bá tiẹ̀ ní ká dà á sílẹ̀ ká tún un ṣà, kí niṣẹ́ àwọn ọlọ́run kéékèèké wọ̀nyẹn? Ṣé lóòótọ́ làwọn ọlọ́run tá a mẹ́nu bà lókè yìí àti àìmọye ọlọ́run mìíràn táwọn èèyàn ti ń jọ́sìn látìgbà láéláé jẹ́ irúnmọlẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè ń rán níṣẹ́ sí aráyé?

Àwọn Èèyàn Wulẹ̀ Ń Méfò Pé Wọ́n Wà Ni

Jèhófà ni Bíbélì pe orúkọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo tó wà. (Sáàmù 83:18; Jòhánù 17:3) Wòlíì Aísáyà ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ, pé: “Ṣáájú mi, kò sí Ọlọ́run kankan tí a ṣẹ̀dá, àti lẹ́yìn mi, kò sí ìkankan tí ó ṣì wà nìṣó. Èmi—èmi ni Jèhófà, yàtọ̀ sí mi, kò sí olùgbàlà kankan.”—Aísáyà 43:10, 11.

Kì í ṣe pé àwọn ọlọ́run yòókù ò lè dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jèhófà nìkan ni o. Ká ṣáà sọ pé wọn ò sí rárá, àwọn èèyàn wulẹ̀ ń méfò pé wọ́n wà ni. Bíbélì pe àwọn ọlọ́run yẹn ní “àwọn àmújáde láti ọwọ́ ènìyàn . . . , èyí tí kò lè ríran tàbí kí ó gbọ́ràn tàbí kí ó jẹun tàbí kí ó gbóòórùn.” (Diutarónómì 4:28) Bíbélì fi kọ́ni lọ́nà tó ṣe kedere pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo tó wà.

Kò wá yẹ kó yà wá lẹ́nu pé Ìwé Mímọ́ kìlọ̀ fún wa gbọnmọ gbọnmọ pé a ò gbọ́dọ̀ sin òrìṣà èyíkéyìí àfi Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, èyí àkọ́kọ́ nínú Òfin Mẹ́wàá tí Mósè gbà ki orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nílọ̀ pé, wọn ò gbọ́dọ̀ sin ọlọ́run mìíràn. (Ẹ́kísódù 20:3) Torí kí ni?

Lákọ̀ọ́kọ́, àbùkù gbáà ló jẹ́ sí Ẹlẹ́dàá pé kéèyàn máa júbà ohun tí kò sí tí wọ́n sì ń pè ní ọlọ́run. Bíbélì ṣàpèjúwe àwọn tó ń sin irú àwọn ọlọ́run irọ́ wọ̀nyẹn gẹ́gẹ́ bí “àwọn tí wọ́n fi irọ́ ṣe pàṣípààrọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run, tí wọ́n ń júbà, tí wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún ìṣẹ̀dá dípò Ẹni tí ó ṣẹ̀dá.” (Róòmù 1:25) Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àwọn ohun táwọn èèyàn kà sí ọlọ́run yìí ló jẹ́ òrìṣà tí wọ́n fi irin tàbí igi ṣe, ìyẹn àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá. Ọ̀pọ̀ àwọn irúnmọlẹ̀ làwọn èèyàn so pọ̀ mọ́ ohun tí Ọlọ́run dá, bí àrá, òkun àti ẹ̀fúùfù. Nítorí náà, ó hàn gbangba pé jíjọ́sìn àwọn ère tí wọ́n ń pè ní ọlọ́run yẹn tàbí jíjúbà wọn jẹ́ ìwà àìlọ́wọ̀ tó burú jáì sí Ọlọ́run Olódùmarè.

Lójú Ẹlẹ́dàá, ohun ìríra làwọn ọlọ́run èké àtàwọn ère wọn. Kẹ́ ẹ sì má wò ó o, àwọn tó ṣe àwọn ọlọ́run èké yẹn ni Ọlọ́run dìídì gbá lọ́rọ̀. Láìfi ọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ó ní: “Fàdákà àti wúrà ni òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè, iṣẹ́ ọwọ́ ará ayé. Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ nǹkan kan; wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò lè rí nǹkan kan; wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò lè fi etí sí nǹkan kan. Pẹ̀lúpẹ̀lù, kò sí ẹ̀mí kankan ní ẹnu wọn. Àwọn tí ń ṣe wọ́n yóò dà bí àwọn gan-an, gbogbo ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé wọn.”—Sáàmù 135:15-18.

Ìdí mìíràn tún wà tí Bíbélì fi kìlọ̀ fún wa gbọnmọ gbọnmọ pé ká má ṣe jọ́sìn ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun, àfi Jèhófà Ọlọ́run. Èèyàn á wulẹ̀ fi àkókò àti ìsapá téèyàn bá lò níbi irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀ ṣòfò ni. Wòlíì Aísáyà sọ ojú abẹ níkòó pé: “Ta ni ó ti ṣẹ̀dá ọlọ́run kan tàbí tí ó mọ ère dídà lásán-làsàn? Ó jẹ́ èyí tí kò ṣàǹfààní rárá.” (Aísáyà 44:10) Bíbélì tún sọ pé “gbogbo ọlọ́run àwọn ènìyàn jẹ́ àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí.” (Sáàmù 96:5) Aláìsí làwọn ọlọ́run èké, òfo ló wà nídìí jíjọ́sìn wọn, ẹni tó bá sì ń sìn wọ́n á jogún òfo.

Jésù, Àwọn Áńgẹ́lì àti Èṣù

Ìwé Mímọ́ máa ń pe àwọn èèyàn ní ọlọ́run lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, ìwàdíì tá a fara balẹ̀ ṣe jẹ́ kó ṣe kedere pé ọ̀rọ̀ náà, “ọlọ́run” nírú àwọn ipò yìí kò ka ẹni náà sí irúnmọlẹ̀ kan téèyàn gbọ́dọ̀ máa bọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ lo ọ̀rọ̀ náà “ọlọ́run” láti fi ṣàpèjúwe ẹni tó lágbára tàbí ẹni ẹ̀mí bíi ti Ọlọ́run tàbí tó ń ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọpọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run Olódùmarè.

Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹsẹ Bíbélì kan pe Jésù Kristi ní ọlọ́run. (Aísáyà 9:6, 7; Jòhánù 1:1, 18) Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ó yẹ ká máa jọ́sìn Jésù? Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.” (Lúùkù 4:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ní agbára tó sì jẹ́ ẹni ẹ̀mí bí Ọlọ́run, ó ṣe kedere pé Bíbélì ò sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wa bí ẹni tó yẹ ká máa jọ́sìn.

Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì jẹ́ “àwọn ẹni bí Ọlọ́run.” (Sáàmù 8:5; Hébérù 2:7) Síbẹ̀, kò síbi tí Ìwé Mímọ́ ti gba àwọn èèyàn níyànjú pé kí wọ́n máa jọ́sìn àwọn áńgẹ́lì. Ó tiẹ̀ dójú ẹ̀ lákòókò kan tí ọlá ńlá áńgẹ́lì kan mú àpọ́sítélì Jòhánù tó jẹ́ arúgbó débi tó fi wólẹ̀ láti jọ́sìn áńgẹ́lì náà. Àmọ́ ohun tí áńgẹ́lì náà sọ ni pé: “Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀! . . . Jọ́sìn Ọlọ́run.”—Ìṣípayá 19:10.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe Èṣù ní “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (2 Kọ́ríńtì 4:4) Èṣù gẹ́gẹ́ bí “olùṣàkoso ayé yìí,” ti mú káwọn èèyàn máa jọ́sìn àìmọye ọlọ́run èké. (Jòhánù 12:31) Ìyẹn ló ṣe jẹ́ pé gbogbo báwọn èèyàn ṣe ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run àfọwọ́ṣe wọ̀nyẹn, Sátánì ni wọ́n ń jọ́sìn. Sátánì sì rèé, kì í ṣe ọlọ́run tó yẹ ká máa jọ́sìn. Fúnra rẹ̀ ló sọ ara ẹ̀ di olùṣàkóso, afagídí-gbapò. Bó pẹ́ bó yá, òun alára àti gbogbo onírúurú ẹ̀sìn èkè rẹ̀ ló máa di àwáàrí. Nígbà tíyẹn bá ṣẹlẹ̀, gbogbo èèyàn kódà gbogbo ìṣẹ̀dá ló máa gba Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run alààyè tòótọ́ kan ṣoṣo.—Jeremáyà 10:10.

ǸJẸ́ Ó TI ṢE Ọ́ RÍ BÍI KÓ O BÉÈRÈ PÉ?

◼ Kí ni ohun tí Bíbélì fi kọ́ wa nípa jíjọ́sìn òrìṣà?—Sáàmù 135:15-18.

◼ Ṣó yẹ ká máa jọ́sìn Jésù àtàwọn áńgẹ́lì bí ọlọ́run?—Lúùkù 4:8.

◼ Ta ni Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà?—Jòhánù 17:3.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]

Àwọn ère látọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tun: Màríà, orílẹ̀-èdè Ítálì; Maya, ọlọ́run àgbàdo, orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò àti Àárín Gbùngbùn Amẹ́ríkà; Áṣítórétì, ilẹ̀ Kénáánì; ère àkúnlẹ̀bọ, orílẹ̀-èdè Sierra Leone; Búdà, ilẹ̀ Japan; Chicomecóatl, Aztec, orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò; àwòdì Horus, ilẹ̀ Íjíbítì; Súúsì, ilẹ̀ Gíríìsì

[Credit Line]

Ọlọ́run àgbàdo, àwòdì Horus, àti Súúsì: Àwọn aláṣẹ ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí British Museum ló jẹ́ ká yà wọ́n ní fọ́tò

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́