Jọsin Ọlọrun Wo?
LÁÌDÀBÍ awọn ẹranko, awa eniyan ní agbara lati jọsin. Eyi jẹ́ apakan ohun ti a dá mọ́ wa lati ìgbà ìbí. A tun ni ero iwarere, ẹ̀rí-ọkàn lati ṣamọna wa niti ohun ti ó tọ́ ati ohun ti kò tọ́. Ni oniruuru awọn ọna gbogbo wa tẹle ẹ̀rí-ọkàn yẹn, ati ni ṣiṣe bẹẹ, ọpọlọpọ gbarale ọlọrun kan tabi awọn ọlọrun fun amọna.
Laaarin ọrundun kan tabi meji ti o ti kọja, awọn ọlọgbọn ayé ti tako wíwà Ọlọrun olodumare kan ati Ẹlẹdaa. Ni 1844, Karl Marx polongo pe isin jẹ́ “oògùn apanilọ́bọlọ̀ awọn eniyan.” Nigba ti ó yá, Charles Darwin mu àbá ero-ori efoluṣọn jade. Lẹhin naa ni iyipada tegbòtigaga ti Bolshevik dé. Ni Ila-oorun Europe ẹkọ aigbọlọrungbọ di ilana ijọba ti a faṣẹ si, a sì fi idaloju sọ ọ pe isin yoo ku pẹlu iran 1917. Ṣugbọn awọn alaigbọlọrungbọ wọnni kò lè yí ọna ti a gbà dá awọn eniyan pada. Eyi ni a mu ṣe kedere ninu imusọji isin ni Ila-oorun Europe ni akoko yii.
Bi o ti wu ki o ri, gẹgẹ bi Bibeli ti wi, ọpọlọpọ ni wọn wà “ti a npe ni ọlọrun . . . , ìbáà ṣe ni ọrun tabi ni ayé (gẹgẹ bi ọpọ ọlọrun ti wà ati ọpọ oluwa.)” (1 Kọrinti 8:5) La ọpọ sanmani já araye ti jọsin ògídímèje awọn ọlọrun. Awọn ọlọrun ọlọ́mọyọyọ, ifẹ, ogun, ati ti ọti waini ati ariya alariwo ti wà. Ninu isin Hindu nikan, awọn Ọlọrun ni iye wọn ń lọ si araadọta-ọkẹ.
Awọn ọlọrun mẹtalọkan ti gbilẹ ni Babiloni, Asiria, ati Ijibiti, ati bakan naa ni awọn ilẹ onisin Buddha. Kristẹndọmu pẹlu ní Mẹtalọkan “mímọ́” rẹ̀. Islam, ni ṣíṣá Mẹtalọkan tì, ‘ko ni ọlọrun kankan ayafi Allah.’ Siwaju sii, ani awọn wọnni ti wọn fi ero Ọlọrun olodumare kan, ti a kò lè rí ṣẹlẹya paapaa ní awọn ọlọrun tiwọn funraawọn. Fun apẹẹrẹ, ni Filipi 3:19, Bibeli sọ nipa awọn eniyan ti a ti dẹkùn mú ninu awọn ilepa ọrọ̀ alumọọni pe: ‘Ọlọrun wọn ni ikùn wọn.’
Ọpọ julọ awọn eniyan jọsin awọn ọlọrun tabi abo-ọlọrun ti ilẹ tabi awujọ ti ó ṣẹlẹ pe a bi wọn sí. Eyi gbe awọn ibeere dide. Njẹ gbogbo iru ijọsin ha ń sinni lọ si ibikan naa—bi awọn ọna ti ó lọ si ṣóńṣó ori oke kan? Tabi ọpọlọpọ awọn ọna olohun ijinlẹ ti isin ṣamọna si ìjábá—bi ipa ọna ti ó lọ si bèbè ọ̀gbun? Ọpọlọpọ awọn ọna títọ́ lati jọsin ha wà tabi kiki ọkanṣoṣo ni ó wà bi? Ọpọlọpọ awọn ọlọrun ti ó lẹtọọ si iyin ha wà tabi kiki Ọlọrun Olodumare kanṣoṣo ti ó lẹtọọ si ifọkansin ati ijọsin ayasọtọ gedegbe wa ni ó wà bi?
Ìdìde Awọn Ọlọrun Èké
Awọn ibeere ti nbẹ loke yii yẹ fun ayẹwo kínníkínní wa. Eeṣe? Nitori pe aṣẹ ti ó pẹ́ julọ ti a kọsilẹ lori isin, Bibeli, ṣapejuwe bi ọlọrun èké kan, ti ń ṣiṣẹ nipasẹ ejo kan, ti fa awọn babanla wa akọkọ sinu ipa ọna iparun. A ń niriiri abajade bibanininujẹ ti ọgbọn ipete rẹ̀ titi di oni yii. (Jẹnẹsisi 3:1-13, 16-19; Saamu 51:5) Jesu, “Ọmọ Ọlọrun,” sọ nipa ọlọrun ọlọtẹ yẹn gẹgẹ bi “alade ayé yii.” Ọ̀kan lara awọn apọsiteli Jesu pe e ni “ọlọrun ayé yii.” (Johanu 1:34; 12:31; 16:11; 2 Kọrinti 4:4) Ni Iṣipaya ori 12, ẹsẹ 9, a ṣapejuwe rẹ̀ gẹgẹ bi “ejo laelae nì, ti a npe ni Eṣu, ati Satani, ti ń tan gbogbo ayé jẹ.” Ilẹ ọba isin èké agbaye wà labẹ idari Satani.
Satani ni olori atannijẹ. (1 Timoti 2:14) Ó ń kó ifẹ abinibi ti araye lati jọsin nífà nipa ṣiṣagbatẹru ọpọlọpọ iru awọn ọlọrun ajọsinfun—ẹmi awọn babanla, oriṣa, awọn ère isin, Madonna. Ó tilẹ ṣonigbọwọ ijọsin awọn ọlọrun ti wọn jẹ́ eniyan, iru bii awọn oluṣakoso alagbara, jagunjagun aṣẹgun, ati awọn olokiki eré sinima ati eré idaraya. (Iṣe 12:21-23) Ó dara ki a ṣọra, ki a pinnu lati ṣàwárí ki a sì jọsin kiki Ọlọrun tootọ naa, ẹni ti “kò jinna si olukuluku wa” niti gidi.—Iṣe 17:27.
Nigba naa, ta ni Ọlọrun alailẹgbẹ ti a gbọdọ jọsin yii? Ni nǹkan bi 3,000 ọdun sẹhin, onisaamu Bibeli naa ṣapejuwe rẹ̀ gẹgẹ bi “Ọga-ogo Julọ . . . , Ẹni Olodumare naa . . . , Ọlọrun mi, ninu ẹni ti emi yoo nigbẹkẹle,” ó sì pe e ni orukọ rẹ̀ ti ó lokiki—“Jehofa.” (Saamu 91:1, 2, New World Translation [Gẹẹsi]) Ni iṣaaju, Mose ti sọ nipa rẹ̀ pe: “Jehofa Ọlọrun wa Jehofa kan ni.” (Deutaronomi 6:4, NW) Wolii Aisaya sì gba ọrọ Ọlọrun funraarẹ sọ ni wiwi pe: “Emi ni Jehofa. Iyẹn ni orukọ mi; ati fun ẹlomiran kankan ni emi ki yoo fun ni ogo temi funraami, yala iyin mi fun awọn ère gbígbẹ́.”—Aisaya 42:8, NW.
Jehofa Ọlọrun pete lati nu orukọ rẹ̀ mọ́ kuro ninu gbogbo ẹ̀gàn ti Satani ọlọrun èké ti fi rẹ́ ẹ. Ó ṣapejuwe bi oun yoo ṣe ṣe eyi ni ọdun 1513 B.C.E., nigba ti ó lo wolii Mose lati dá awọn eniyan Isirẹli nide kuro lọwọ inilara awọn ara Ijibiti. Ni akoko yẹn, Ọlọrun so orukọ rẹ̀ Jehofa pọ pẹlu awọn ọrọ naa: “Emi yoo jẹ́ ohun ti emi yoo jẹ́.” (Ẹkisodu 3:14, 15, NW) Oun yoo dá araarẹ lare lodisi Farao ti Ijibiti, ṣugbọn lakọọkọ ó sọ fun oluṣakoso buburu yẹn pe: “Nitori eyi paapaa ni emi ṣe mu ọ duro, lati fi agbara mi han lara rẹ; ati ki a lè rohin orukọ mi ká gbogbo ayé.”—Ekisodu 9:16.
Ipo naa jọra lonii. Gẹgẹ bii Farao igbaani, ọlọrun ayé yii, Satani, sayagbangba pe Jehofa Ọlọrun nija ó sì ń fi arekereke ba ogun jija tẹmi lọ lodi si awọn eniyan wọnni ti wọn nifẹẹ ododo ati otitọ. (Efesu 6:11, 12, 18) Lẹẹkansii, Ọlọrun ti pete lati sọ orukọ rẹ̀ di titobi ni oju atako Satani. Bi o ti wu ki o ri, ṣaaju fifi agbara rẹ̀ han nipa pipa Satani ati gbogbo awọn iṣẹ rẹ̀ run, Jehofa Ọlọrun rán awọn olujọsin rẹ̀ jade lati polongo orukọ Rẹ̀ ni gbogbo ilẹ-aye. Jijẹrii si orukọ rẹ̀ yii jẹ́ apa ṣiṣekoko ti ijọsin tootọ.
Lọna ti ó baamu, Ọlọrun funraarẹ sọ pe awọn olujọsin wọnyi yoo jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, “awọn eniyan ti mo ti dá fun araami, pe wọn nilati rohin iyin mi.” (Aisaya 43:10-12, 21, NW) Bawo ni wọn ṣe rohin iyin Jehofa? Wọn ń waasu wọn sì ń kọni nigbangba ati lati ile de ile, ni pipolongo ihinrere naa pe Ijọba Jehofa, tí Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, ń ṣakoso lelori yoo mu awọn ibukun ayeraye wá fun araye onigbọran lori ilẹ-aye yii. Nipa bayii, wọn ń jọsin Ọlọrun ‘láìdẹ́kun,’ gẹgẹ bi awọn Kristẹni tootọ ni ọgọrun-un ọdun kìn-ín-ní ti ṣe. (Iṣe 5:42; 20:20, 21) Wọn ha ti gbadun ibukun atọrunwa ninu eyi bi? Awọn oju-ewe ti o tẹle e yoo dahun.