Ṣé Ọ̀kan Náà Ni Gbogbo Ìsìn? Ǹjẹ́ Gbogbo Rẹ̀ Ni Ọlọrun Tẹ́wọ́ Gbà?
Ohun tí Bíbélì sọ
Rárá, gbogbo ìsìn kì í ṣe ọ̀kan náà. Nínú Bíbélì, a rí àpẹẹrẹ àwọn ìsìn tí inú Ọlọ́run kò dùn sí. Apá méjì sì ni àwọn ìsìn yìí pín sí.
Apá kìíní: Àwọn tó ń jọ́sìn ọlọ́run èké
Bíbélì lo àwọn ọ̀rọ̀ bí “èémí àmíjáde lásán,” “asán,” àti “àwọn nǹkan tí kò ní àǹfààní” láti fi ṣàpèjúwe ìjọsìn ọlọ́run èké. (Jeremáyà 10:3-5; 16:19, 20) Jèhófàa Ọlọ́run pàṣẹ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní àwọn ọlọ́run èyíkéyìí mìíràn níṣojú mi.” (Ẹ́kísódù 20:3, 23; 23:24) ‘Ìbínú Jèhófà ru’ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn àwọn ọlọ́run mìíràn.—Númérì 25:3; Léfítíkù 20:2; Àwọn Onídàájọ́ 2:13, 14.
Ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìjọsìn ‘àwọn tí wọ́n ń pè ní ọlọ́run’ kò tíì yí pa dà. (1 Kọ́ríńtì 8:5, 6; Gálátíà 4:8) Ó pàṣẹ fún àwọn tó fẹ́ jọ́sìn rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn tó ń ṣe ìsìn èké, ó ní: “Ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀.” (2 Kọ́ríńtì 6:14-17) Tó bá jẹ́ pé ọ̀kan náà ni gbogbo ìsìn, tí Ọlọ́run sì tẹ́wọ́ gbà gbogbo wọn, kí wá nìdí tí Ọlọ́run fi pa irú àṣẹ yìí?
Apá kejì: Àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ lọ́nà tí kò tẹ́wọ́ gbà
Nígbà míì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń tẹ̀ lé àṣà àwọn tó ń ṣe ìsìn èké tí wọ́n bá ń jọ́sìn Ọlọ́run, ṣùgbọ́n Jèhófà kò nífẹ̀ẹ́ sí bí wọ́n ṣe fẹ́ máa da ìsìn tòótọ́ pọ̀ mọ́ ìsìn èké. (Ẹ́kísódù 32:8; Diutarónómì 12:2-4) Jésù bẹnu àtẹ́ lu àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà ayé rẹ̀ torí ọ̀nà tí wọ́n gbà jọ́sìn Ọlọ́run; wọ́n máa ń ṣe bí ẹni pé ọ̀nà tó tọ́ ni wọ́n ń gbà jọ́sìn Ọlọ́run, síbẹ̀ “wọ́n ṣàìka àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ nínú Òfin sí, èyíinì ni, ìdájọ́ òdodo àti àánú àti ìṣòtítọ́.”—Mátíù 23:23.
Bákan náà lóde òní, ìsìn tó ń fi òtítọ́ kọ́ni nìkan ló máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ Ọlọ́run. Inú Bíbélì sì ni òtítọ́ yìí wà. (Jòhánù 4:24; 17:17; 2 Tímótì 3:16, 17) Ẹ̀sìn tó ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ tó ta ko Bíbélì kì í jẹ́ káwọn èèyàn fẹ́ mọ Ọlọ́run. Àwọn ẹ̀kọ́ bíi Mẹ́talọ́kan, àìleèkú ọkàn àti ìdálóró ayérayé táwọn èèyàn rò pé ó wà nínú Bíbélì jẹ́ ara àwọn ẹ̀kọ́ èké tó wà látọ̀dọ̀ àwọn tó ń jọ́sìn ọlọ́run èké. Ẹ̀sìn tí kò wúlò tàbí tó jẹ́ ‘asán’ ni ìsìn tó ń fi irú àwọn ẹ̀kọ́ yìí kọ́ni jẹ́ torí pé ó ń fi àwọn àṣà ìsìn kọni dípò àṣẹ Ọlọ́run.—Máàkù 7:7, 8.
Ọlọ́run kórìíra àgàbàgebè inú ẹ̀sìn. (Títù 1:16) Kí àwọn èèyàn tó lè sún mọ́ Ọlọ́run, ó yẹ kí ìsìn tí wọ́n ń ṣe yí ìgbésí ayé wọn pa dà sí rere. Kì í kàn ṣe kí wọ́n máa ṣe ààtò ẹ̀sìn tàbí kí wọ́n máa fi ẹnu lásán jọ́sìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí lójú ara rẹ̀ bá dà bí olùjọsìn ní irú ọ̀nà kan, síbẹ̀ tí kò kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu, ṣùgbọ́n tí ó ń bá a lọ ní títan ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ, ọ̀nà ìjọsìn ọkùnrin yìí jẹ́ ìmúlẹ̀mófo. Ọ̀nà ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú ìwòye Ọlọ́run àti Baba wa ni èyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara ẹni mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé.” (Jákọ́bù 1:26, 27) “Ìsìn mímọ́” ni Bíbélì Mímọ́ pe irú ìjọsìn tó mọ́ yìí, tí kò sì ní àgàbàgebè nínú.
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run tòótọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ.