Bó O Ṣe Lè Ran Ọmọbìnrin Rẹ Lọ́wọ́ Láti Múra Sílẹ̀ De Ìgbà Tó Máa Bẹ̀rẹ̀ sí Í Ṣe Nǹkan Oṣù
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tọ́mọ bá bẹ̀rẹ̀ sí í bàlágà. Ọ̀kan lára ìyípadà tó máa ń mú káwọn ọmọbìnrin mọ̀ pé àwọn ti ń bàlágà ni pé wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe nǹkan oṣù.
NÍGBÀ táwọn ọmọbìnrin kan bá kọ́kọ́ rí nǹkan oṣù wọn, oríṣiríṣi nǹkan ló máa ń wá sí wọn lọ́kàn. Ó lè kó ṣìbáṣìbo bá wọn, bíi tàwọn nǹkan míì tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí ọmọbìnrin tó ń bàlágà. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń ba àwọn ọmọbìnrin lẹ́rù nígbà tí wọ́n bá kọ́kọ́ rí nǹkan oṣù, bóyá nítorí pé ọ̀tọ̀ ni nǹkan tí wọ́n sọ fún wọn nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì máa ń jẹ́ pé wọn ò gbọ́ nípa rẹ̀ rí.
Nǹkan sábà máa ń rọrùn nígbà táwọn ọmọbìnrin tí wọ́n ti sọ fún bọ́rọ̀ náà ṣe máa ń rí bá kọ́kọ́ rí nǹkan oṣù wọn. Àmọ́, ìwádìí fi hàn pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́bìnrin ni kì í gbára dì. Nínú ìwádìí kan táwọn tó kópa níbẹ̀ wá láti orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélógún, nǹkan bí ìdámẹ́ta lára àwọn tí wọ́n wádìí lọ́dọ̀ wọn ló sọ pé àwọn ò gbọ́ nípa bí ìgbà téèyàn bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ nǹkan oṣù ṣe máa ń rí káwọn tó bẹ̀rẹ̀ sí í rí i. Nítorí pé àwọn ọmọbìnrin náà ò mọ̀ nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀, nígbà tí nǹkan oṣù wọn dé, wọn ò mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe.
Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tó ń sọ pé ohun tójú àwọn rí nígbà táwọn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe nǹkan oṣù kò dáa ló jẹ́ àwọn tí wọn ò tíì mọ nǹkan kan nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Nínú ìwádìí míì, nígbà táwọn obìnrin ń sọ̀rọ̀ nípa bí ìbẹ̀rẹ̀ nǹkan oṣù ṣe máa ń rí, àwọn èdè bí “ẹ̀rù,” “ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀,” “ìtìjú” àti “ìjayà” ni wọ́n fi ń ṣàpèjúwe rẹ̀.
Ṣé ẹ mọ̀ pé béèyàn bá rí ẹ̀jẹ̀, ẹ̀rù sábà máa ń bà á, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìgbà tíbì kan bá ń dun èèyàn tàbí téèyàn bá ṣèṣe lẹ̀jẹ̀ sábà máa ń jáde lára. A wá lè rí ìdí tó fi jẹ́ pé tí kì í bá ṣe pé wọ́n ṣàlàyé fún ọmọbìnrin nípa rẹ̀ dáadáa tàbí kó ti gbára dì tẹ́lẹ̀, ohun táwọn èèyàn gbà gbọ́ láìwádìí, èrò èké, tàbí àìmọ̀kan-mọ̀kàn lè mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í rò pé òun ti kárùn tàbí pé òun ti ṣèṣe lòun ṣe ń rí ẹ̀jẹ̀, ó tiẹ̀ lè kà á sóhun ìtìjú.
Ó yẹ kí ọmọ rẹ obìnrin mọ̀ pé bí ẹ̀jẹ̀ ṣe máa ń dà lásìkò nǹkan oṣù jẹ́ ara nǹkan tó yẹ kó máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ọmọbìnrin tí ara wọn dá. Ìwọ gẹ́gẹ́ bí òbí sì lè mú ìbẹ̀rù tàbí àníyàn kúrò lọ́kàn rẹ̀. Lọ́nà wo?
Iṣẹ́ Ńlá Lòbí Ní Láti Ṣe Lórí Ẹ̀
Oríṣiríṣi ọ̀nà lèèyàn ti lè gbọ́ nípa nǹkan oṣù. Èèyàn lè gbọ́ nípa ẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn olùkọ́ nílé ìwé, àwọn oníṣègùn, èèyàn lè rí i kà látinú ìwé tí wọ́n kọ lórí ẹ̀, ó sì lè jẹ́ látinú àwọn fíìmù tó ń kọ́mọ lẹ́kọ̀ọ́ pàápàá. Ọ̀pọ̀ òbí ló ti rí i pé ìsọfúnni pàtàkì wà láwọn ibi wọ̀nyẹn nípa ọ̀rọ̀ nǹkan oṣù àti béèyàn ṣe lè máa wà ní mímọ́ tónítóní lásìkò tó bá ń ṣe nǹkan oṣù. Síbẹ̀, àwọn ìbéèrè kan wà táwọn ọmọbìnrin máa ń béèrè, àmọ́ tí wọn ò lè rí ìdáhùn sí láwọn ibi tá a mẹ́nu kàn yẹn. Kódà, báwọn ọmọbìnrin bá mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe nígbà tí nǹkan oṣù wọn bá dé, wọn kì í mọ ohun tí wọ́n lè ṣe sí oríṣiríṣi nǹkan táá máa dà wọ́n láàmú àti bí ara wọn á ṣe máa ṣe nígbà tí wọ́n bá ń ṣe nǹkan oṣù.
Àwọn ìyá àgbà, àwọn àǹtí àtàwọn ìyá ní pàtàkì jù lọ lè túbọ̀ ṣàlàyé ọ̀pọ̀ nǹkan sí i fáwọn ọmọbìnrin kí wọ́n sì dúró tì wọ́n láti fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọbìnrin sábà máa ń gbà pé ọ̀dọ̀ ìyá àwọn ni ibi tó ṣe pàtàkì jù lọ táwọn ti lè rí ìsọfúnni nípa nǹkan oṣù.
Ṣáwọn bàbá náà ò lè dá sí i ni? Ojú sábà máa ń ti ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbìnrin láti bá bàbá wọn sọ̀rọ̀ nípa nǹkan oṣù. Àwọn kan ò fẹ́ káwọn bàbá àwọn bá àwọn dá sí i ní tààràtà. Ohun tí wọ́n fẹ́ ni pé kó máa ṣètìlẹ́yìn fáwọn kó sì máa fòye bá àwọn lò. Àwọn míì ò sì fẹ́ kí wọ́n bá àwọn dá sí i páàpáà.
Lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè, ńṣe làwọn ìdílé tí bàbá ti ń dá tọ́mọ túbọ̀ ń pọ̀ sí i láti bí ẹ̀wádún díẹ̀ sẹ́yìn báyìí.a Ìdí nìyí tó fi pọn dandan fáwọn bàbá láti wá ọ̀nà tí wọ́n á fi máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ nípa nǹkan oṣù fáwọn ọmọbìnrin wọn. Àwọn bàbá yìí gbọ́dọ̀ mọ àwọn nǹkan pàtàkì tó yẹ kéèyàn mọ̀ nípa nǹkan oṣù, àwọn ìnira tó lè máa kojú àwọn ọmọ wọn lákòókò yẹn àtàwọn ohun tó lè máa da ọkàn wọn láàmú. Àwọn bàbá kan lè lọ bá àwọn ìyá tó bí wọn tàbí àǹtí wọn láti lè gba ìmọ̀ràn tó wúlò lórí ọ̀ràn yìí.
Ìgbà Tó Yẹ Kí Ìjíròrò Náà Bẹ̀rẹ̀
Láwọn orílẹ̀-èdè tí ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ pọ̀ sí, bí Amẹ́ríkà, South Korea, àtàwọn ibì kan ní Ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù, ọjọ́ orí tí ọmọbìnrin ti sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í rí nǹkan oṣù wà láàárín ọdún méjìlá sí ọdún mẹ́tàlá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ míì lè tètè bẹ̀rẹ̀ bóyá láti nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́jọ tí ẹlòmíì sì lè pẹ́ tó ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún tàbí mẹ́tàdínlógún kó tó bẹ̀rẹ̀. Láwọn apá ibì kan nílẹ̀ Áfíríkà àti Éṣíà, ó jọ pé ọjọ́ orí táwọn ọmọbìnrin máa ń bẹ̀rẹ̀ nǹkan oṣù máa ń jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lobìnrin sábà máa ń jẹ́ kó tó máa rí nǹkan oṣù. Ara àwọn nǹkan tó lè fa ìyàtọ̀ nínú àkókò tó máa ń bẹ̀rẹ̀ ni àwọn nǹkan bí apilẹ̀ àbùdá èèyàn, béèyàn ṣe rí já jẹ tó, irú oúnjẹ tó ń jẹ, bó ṣe ń ṣeré ìdárayá tó àti irú ìgbésí ayé tó ń gbé.
Ó dáa kó o tètè bẹ̀rẹ̀ sí í bá ọmọ rẹ obìnrin sọ̀rọ̀ nípa nǹkan oṣù ṣáájú ìgbà táá kọ́kọ́ rí nǹkan oṣù rẹ̀. Torí náà, àtikékeré ló yẹ kéèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá ọmọbìnrin sọ̀rọ̀ nípa bí ara ẹ̀ á ṣe máa yí padà àti nípa nǹkan oṣù, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í bá a sọ ọ́ nígbà tó ṣì wà ní bí ọmọ ọdún mẹ́jọ pàápàá. O lè rò pé ó ti yá jù, àmọ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nígbà tí ọmọ rẹ ti wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́jọ sí mẹ́wàá lara ẹ̀ á ti máa bàlágà sínú nítorí pé omi inú ara tó ń fa ìbàlágà ti ń pọ̀ sí i lára ẹ̀. Wàá kíyè sí i pé àwọn nǹkan á máa yí padà lára ọmọbìnrin tó bá ti ń bàlágà, bíi kó bẹ̀rẹ̀ sí í gúnyàn kí ìrun ara rẹ̀ sì máa pọ̀ sí i. Ọ̀pọ̀ ọmọbìnrin á kàn dédé máa yára ga sí i, wọ́n á sì máa yára tẹ̀wọ̀n sí i bí wọ́n bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í rí nǹkan oṣù.
Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Sọ̀rọ̀ Nípa Rẹ̀
Bó bá ti ń kù díẹ̀ káwọn ọmọbìnrin bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe nǹkan oṣù, ni wọ́n á ti máa retí bó ṣe máa rí. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti gbọ́ káwọn ọmọbìnrin míì níléèwé máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Wọ́n lè láwọn ìbéèrè kan ṣùgbọ́n kí wọ́n má mọ bí wọ́n ṣe máa béèrè. Ojú sì lè máa tì wọ́n láti sọ̀rọ̀ nípa nǹkan oṣù.
Ohun tó ń ṣọmọ náà ló ń ṣòbí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnu àwọn ìyá ni ọmọ ti kọ́kọ́ sábà máa ń gbọ́ nípa nǹkan oṣù, ó sábà máa ń ṣe àwọn ìyá bíi pé kí wọ́n má sọ̀rọ̀ nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tàbí kí wọ́n máa rò pé kò bójú mu. Bóyá ohun tó ń ṣe ìwọ náà nìyẹn. Torí náà, báwo lo ṣe lè bá ọmọbìnrin rẹ sọ̀rọ̀ nípa nǹkan oṣù àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọmọbìnrin bá kọ́kọ́ rí nǹkan oṣù?
Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọbìnrin tí ọjọ́ orí wọn ò tíì pé ọdún mẹ́tàlá tí wọ́n ti ń sún mọ́ ẹni táá máa rí nǹkan oṣù tètè lóye àlàyé tó ṣe ṣàkó. Irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ lè dá lórí bí nǹkan oṣù ṣe máa ń wá, iye ọjọ́ tó máa ń lò àti bí ẹ̀jẹ̀ ṣe máa ń dà tó. Nípa bẹ́ẹ̀, ní gbàrà tó o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá ọmọ ẹ sọ̀rọ̀ nípa nǹkan oṣù, ì bá dáa jù kó o sọ̀rọ̀ lórí nǹkan tó ṣì máa ràn án lọ́wọ́ láti kojú àwọn nǹkan tó máa ń ṣèèyàn bí nǹkan oṣù bá bẹ̀rẹ̀. Láfikún sí i, o lè ní láti dáhùn àwọn ìbéèrè bíi: Báwo ló ṣe máa ń ṣèèyàn? tàbí Kí ni màá máa rí?
Bó bá yá, o wá lè bá ọ̀rọ̀ lọ síbi àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa nǹkan oṣù. A sábà máa ń rí àwọn ìwé tó ń kọ́ni nípa nǹkan oṣù lọ́dọ̀ òṣìṣẹ́ ìlera tàbí ní ibi ìkówèésí tàbí ilé ìtàwé. Irú àwọn ìwé tó ní ìsọfúnni nínú báyẹn lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀. Àwọn ọmọbìnrin kan lè fẹ́ ka ìwé náà fúnra wọn. Ó tẹ́ àwọn míì lọ́rùn pé kẹ́ ẹ jọ kà á.
Wá ibi tí kò sí ariwo tẹ́ ẹ ti lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Bẹ̀rẹ̀ láti ibi tó mọ níwọ̀n lórí ọ̀ràn dídàgbà àti dídi obìnrin. Bóyá o lè sọ pé: “Láìpẹ́ láìjìnnà, nǹkan kan á bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ sí ẹ èyí tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ọmọbìnrin. Ǹjẹ́ o mọ nǹkan náà?” Ìyá kan sì lè bẹ̀rẹ̀ sí í bá ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí òun alára rí, irú bíi kó sọ pé: “Nígbà tí mo wà bó o ṣe wà yìí, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ohun tó túmọ̀ sí láti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe nǹkan oṣù. Èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ níléèwé. Ṣáwọn ọ̀rẹ́ tiẹ̀ náà ti ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀?” Wádìí ohun tó ti mọ̀ nípa nǹkan oṣù tẹ́lẹ̀ kó o sì tọ́ ọ sọ́nà láwọn ibi tí kò bá yé e dáadáa. Fi sọ́kàn pé nígbà àkọ́kọ́ tó o bá dá ìjíròrò náà sílẹ̀, ìwọ lo máa sọ̀rọ̀ jù, ìyẹn bí kì í bá ṣèwọ nìkan lo máa sọ̀rọ̀ náà.
Ìwọ gẹ́gẹ́ bí obìnrin, ó dájú pé wàá ti ṣàníyàn nípa bí nǹkan oṣù ṣe máa ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tó o ṣì kéré, torí náà o lè sọ̀rọ̀ nípa ìrírí ara ẹ nígbà tó o bá ń bá a sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Kí ló yẹ kó o ti mọ̀ nígbà yẹn tó ò mọ̀? Kí ló wù ẹ́ kó o mọ̀? Ìsọfúnni wo ló ràn ẹ́ lọ́wọ́? Gbìyànjú láti sọ àǹfààní tó wà nínú nǹkan oṣù tó máa ń wá àtàwọn ìṣòro tó máa ń mú dání. Gbà á láàyè láti béèrè ìbéèrè.
Má Ṣe Dá Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Náà Dúró
Fọkàn sí i pé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo kọ́ ni ẹ̀kọ́ tí wàá kọ́ ọmọ lórí ọ̀rọ̀ nǹkan oṣù á parí, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tí wàá máa ṣe lemọ́lemọ́ ni. Má gbìyànjú àtisọ gbogbo ohun tó yẹ kó o sọ fún un lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Àlàyé tó pọ̀ jù lè ka ọmọbìnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà láyà. Díẹ̀díẹ̀ lọmọdé ń kẹ́kọ̀ọ́. Bákan náà, ó lè pọn dandan kó o tún ọ̀rọ̀ kan sọ lọ́pọ̀ ìgbà. Bí àwọn ọmọbìnrin bá ṣe ń dàgbà sí i, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í lóye kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa rẹ̀ sí i.
Ohun míì tó tún yẹ kó o rò ni pé ojú táwọn ọmọbìnrin fi ń wo ìbálòpọ̀ máa ń yí padà bí wọ́n bá ṣe ń dàgbà sí i. Tó bá ti ṣe díẹ̀ tí ọmọbìnrin rẹ ti ń ṣe nǹkan oṣù, àwọn nǹkan míì láá máa jẹ ẹ́ lọ́kàn, àwọn ìbéèrè míì láá sì máa ní. Torí náà, o ní láti máa bá a jíròrò nìṣó kó o sì máa dáhùn àwọn ìbéèrè tó bá ní. Àwọn nǹkan tó bá nítumọ̀, tọ́jọ́ orí ọmọbìnrin lè gbé tó sì yẹ kó o bá ẹni tó bá wà lọ́jọ́ orí ẹ̀ sọ, ló yẹ kó o tẹpẹlẹ mọ́.
Ìwọ Ni Kó O Dá Ọ̀rọ̀ Náà Sílẹ̀
Àmọ́ kí lo máa ṣe tó bá dà bíi pé ọmọbìnrin ẹ ò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ nípa nǹkan oṣù? Ó lè jẹ́ pé ó ń lọ́ tìkọ̀ láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó kà sí àṣírí ara ẹ̀ ni. Ó sì lè jẹ́ pé ó yẹ kó o fún un láàyè kí ọkàn rẹ̀ fi balẹ̀ débi táá fi mọ báá ṣe gbé ìbéèrè náà kalẹ̀. Kódà ó lè sọ pé òun ti mọ gbogbo ohun tó yẹ kóun mọ̀.
Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lọ́dọ̀ àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n ti tó ọmọ ọdún mọ́kànlá ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ náà ló wo ara wọn bí ẹni tó ti múra sílẹ̀ fún nǹkan oṣù. Àmọ́ nígbà tí wọ́n béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ wọn dáadáa, ó ṣe kedere pé ohun tí wọ́n mọ̀ ò tó nǹkan àti pé wọ́n ti ka oríṣiríṣi èrò òdì àti àròsọ táwọn èèyàn ń gbé kiri ládùúgbò wọn sí òótọ́. Torí náà, bí ọmọ ẹ bá tiẹ̀ sọ pé òun mọ bóun ṣe máa ṣe ọ̀rọ̀ ará òun tí nǹkan oṣù òun bá dé, ó ṣì yẹ kó o bá a jíròrò nípa ẹ̀.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwọ òbí lo máa ní láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò ráńpẹ́ lórí ọ̀rọ̀ nǹkan oṣù tí wàá sì máa bá a lọ nígbà tó bá yá. Ká sòótọ́, iṣẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí òbí ni. Bóyá ọmọ rẹ gbà lákòókò yẹn o tàbí kò gbà, ó nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ. Gbogbo ẹ̀ lè tojú sú ẹ tàbí kó dà bíi pé o ò tóótun, síbẹ̀ má juwọ́ sílẹ̀. Ní sùúrù. Bó pẹ́ bó yá, ọmọ ẹ ń bọ̀ wá mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ò ń ràn án lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de ìgbà táá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe nǹkan oṣù.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lórílẹ̀ èdè Japan, àwọn bàbá tó ń dá tọ́mọ pọ̀ gan-an ju ti tẹ́lẹ̀ lọ lọ́dún 2003. Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn ìdílé tí bàbá ti ń dá ọmọ tọ́ ló kó ìdá kan nínú mẹ́fà láàárín àwọn ìdílé olóbìí kan.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]
Ohun tó dáa jù ni pé kó o tètè máa bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa nǹkan oṣù kó tó di pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í rí i
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]
BÓ O ṢE LÈ BÁ ỌMỌBÌNRIN RẸ SỌ̀RỌ̀ NÍPA NǸKAN OṢÙ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
❖ Béèrè ohun tó ti mọ̀. Fa gbogbo èrò èké tó bá ti gbìn sọ́kàn tẹ́lẹ̀ tu lọ́kàn ẹ̀. Rí i dájú pé ẹ̀yin méjèèjì lẹ jọ mọ òótọ́ tó wà nídìí nǹkan oṣù.
❖ Sọ ìrírí ara ẹ fún un. Tó o bá ronú lórí ìrírí rẹ nígbà tó o kọ́kọ́ rí nǹkan oṣù tó o sì sọ bó ṣe ṣe ọ́ fún un, o lè tipa bẹ́ẹ̀ fún ọmọbìnrin rẹ ní ìrànlọ́wọ́ tó nílò.
❖ Sọ ohun tó nílò fún un. Lára àwọn ìbéèrè táwọn ọmọbìnrin sábà máa ń béèrè ni: “Kí ni kí n ṣe bó bá jẹ́ pé iléèwè ni mo ti rí nǹkan oṣù mi?” “Irú àwọn nǹkan wo ni mo lè máa lò láti fi ṣe nǹkan oṣù mi”? “Báwo ni màá ṣe máa lò wọ́n?”
❖ Lo ọ̀rọ̀ tó rọrùn láti ṣàlàyé òótọ́ tó wà nídìí ẹ̀. Sọ ọ́ lọ́nà tó máa bá ọjọ́ orí ọmọ rẹ mu àti lọ́nà táá fi yé e.
❖ Má fi mọ sórí ìjíròrò ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo. Rí i pé o ti ń bá ọmọbìnrin rẹ sọ̀rọ̀ nípa nǹkan oṣù kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í rí i, kó o sì rí i pé ìjíròrò náà ń tẹ̀ síwájú bó bá ṣe nílò rẹ̀ sí, lẹ́yìn tó bá ti bẹ̀rẹ̀ pàápàá.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Máa fi òye bá a lò. Ọmọbìnrin rẹ lè máà fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó kà sí àṣírí ara rẹ̀