ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 10/06 ojú ìwé 23
  • Ṣé Ohun Tó Bá Wù Ọ́ Lo Lè Gbà Gbọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ohun Tó Bá Wù Ọ́ Lo Lè Gbà Gbọ́?
  • Jí!—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé—Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?—Apá 2
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ǹjẹ́ Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Bá Bíbélì Mu?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ẹfolúṣọ̀n Ń Jẹ́jọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ṣó Yẹ Kí N Gba Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Gbọ́?
    Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè
Àwọn Míì
Jí!—2006
g 10/06 ojú ìwé 23

Ṣé Ohun Tó Bá Wù Ọ́ Lo Lè Gbà Gbọ́?

ṢÉ O rò pé ó ní ohun tí Ọlọ́run tìtorí ẹ̀ dá ayé? Bí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tó ń kọ́ni pé ńṣe lèèyàn hú yọ bá jóòótọ́, a jẹ́ pé gbólóhùn tó wà nínú ìwé ìròyìn Scientific American tọ̀nà nìyẹn. Gbólóhùn náà kà pé: “Òye tá a ní nípa ẹfolúṣọ̀n ní báyìí fi hàn pé . . . kò sí ìdí kankan téèyàn torí ẹ̀ wà láàyè.”

Ronú lórí ohun tí gbólóhùn yẹn túmọ̀ sí. Bí kò bá sí ìdí kankan téèyàn torí ẹ̀ wà láàyè, a jẹ́ pé gbogbo ohun tó o tìtorí ẹ̀ wà láyé ò ju kó o kàn wá ohun rere díẹ̀ ṣe, bó bá sì ṣeé ṣe káwọn ìran tó ń bọ̀ lẹ́yìn ẹ jogún àwọn ànímọ́ àdánidá kan lọ́wọ́ ẹ. Bí ikú bá sì dé, a jẹ́ pé tonítọ̀hún tán títí ayérayé nìyẹn. Ó wá túmọ̀ sí pé ọpọlọ rẹ, bó o ṣe mọnú rò, àti ṣíṣe àṣàrò lórí ohun tí ìgbésí ayé já mọ́, á wulẹ̀ wá di ohun àkọsẹ̀bá lásán.

Kò tán síbẹ̀. Ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn tó gbà gbọ́ nínú ẹfolúṣọ̀n ń sọ ni pé kò sí Ọlọ́run, àti pé bó bá wà, kò ní dá sí ọ̀ràn àwa ẹ̀dá. Bí èyíkéyìí nínú ohun tí wọ́n sọ yìí bá jóòótọ́, a jẹ́ pé bọ́jọ́ iwájú wa ṣe máa rí dọwọ́ àwọn olóṣèlú, àwọn ọ̀mọ̀wé, àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn nìyẹn. Bá a bá sì fojú ohun táwọn wọ̀nyí ti ṣe kọjá wò ó, a jẹ́ pé ńṣe ni gbogbo ìdàrúdàpọ̀, ìforígbárí àti ìwà ìbàjẹ́ tó ń dààmú aráyé á máa bá a lọ. Àní sẹ́, bó bá jẹ́ pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, a jẹ́ pé kò sóun tó ní kéèyàn má máa gbé ayé níbàámu pẹ̀lú àkọmọ̀nà tó lè bani láyé jẹ́ tó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.”—1 Kọ́ríńtì 15:32.

Ohun kan wà tá a fẹ́ kó o mọ̀ dájú. Ìyẹn sì ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò fara mọ́ ọn pé kéèyàn máa gbé ìgbé ayé jẹ́-n-jayé-òní. Bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò fara mọ́ ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tó mú káwọn èèyàn máa ronú lọ́nà yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ inú Bíbélì. (Jòhánù 17:17) Nítorí náà, wọ́n nígbàgbọ́ nínú ohun tó sọ nípa bá a ṣe dé ilé ayé, pé: “Ọ̀dọ̀ rẹ [Ọlọ́run] ni orísun ìyè wà.” (Sáàmù 36:9) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ní ìtumọ̀ pàtàkì tó pọ̀.

Asán kọ́ layé. Ẹlẹ́dàá wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó dáa lọ́kàn fún gbogbo àwọn tó bá yàn láti máa gbé lọ́nà tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. (Oníwàásù 12:13) Lára ohun tó ní lọ́kàn ni ìlérí tó ṣe pé ká lè máa gbé nínú ayé tí kò ti ní sí ìdàrúdàpọ̀, ìforígbárí àti ìwà ìbàjẹ́, kódà níbi tí ẹnikẹ́ni ò ti ní í máa kú. (Aísáyà 2:4; 25:6-8) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé lè jẹ́rìí sí i pé kò sí ohunkóhun tó lè mú kí ìgbésí ayé nítumọ̀ bíi kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run kó sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó ṣe lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀!—Jòhánù 17:3.

Ohun tó o bá gbà gbọ́ ṣe pàtàkì gan-an ni, nítorí pé ó lè sọ bí ayọ̀ rẹ ṣe máa kún tó nísinsìnyí kó sì sọ bóyá o máa wà láàyè lọ́jọ́ iwájú. Ọwọ́ ẹ lọ̀rọ̀ náà kù sí. Ẹ̀rí tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i wà pé ẹnì kan ní láti wà tó ṣẹ̀dá ayé wa yìí. Ṣó wá yẹ kó o nígbàgbọ́ nínú èrò orí tó gbà pé àwọn ẹ̀rí yìí ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, àmọ́ tí kò ṣàlàyé ìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Àbí wàá kúkú gba ohun tí Bíbélì sọ pé látọwọ́ Ẹlẹ́dàá àgbàyanu kan ni ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ ti wá, Ẹlẹ́dàá náà sì ni Jèhófà Ọlọ́run, tó “dá ohun gbogbo”?—Ìṣípayá 4:11.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́