ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 10/06 ojú ìwé 24-25
  • Ǹjẹ́ O Lè Ran Àwọn Òkú Lọ́wọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Lè Ran Àwọn Òkú Lọ́wọ́?
  • Jí!—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipò Táwọn Òkú Wà
  • Ìrètí Wo Ló Wà Fáwọn Òkú?
  • Ṣó Yẹ Kó O Máa Bẹ̀rù Àwọn Òkú?
    Jí!—2009
  • Ikú
    Jí!—2014
  • Ìrètí Wo Ló Wà fún Àwọn Tó Ti Kú?
    Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
  • Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Sáwọn Tó Ti Kú?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Jí!—2006
g 10/06 ojú ìwé 24-25

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ǹjẹ́ O Lè Ran Àwọn Òkú Lọ́wọ́?

“Láti ìjímìjí wá ni Ṣọ́ọ̀ṣì tí n . . . gba onírúurú àdúrà nítorí [àwọn òkú] . . . kó bàa lè jẹ́ pé nígbà tí àdúrà náà bá sọ wọ́n di mímọ́ tán, wọ́n á lè láǹfààní láti fi ojúyòójú rí Ọlọ́run.” —Ìwé “Catechism of the Catholic Church.”

GBOGBO èèyàn látinú onírúurú ẹ̀yà ló ń ṣàníyàn nípa ipò táwọn òkú wà. Bóyá ìwọ náà ti banú jẹ́ táwọn nǹkan sì ti tojú sú ọ nítorí pé èèyàn rẹ kan kú. O lè máa ṣe kàyéfì bóyá àwọn tó ti kú tún wà láàyè níbòmíì, bóyá wọ́n ń jìyà, bóyá wọ́n wà lálàáfíà ara, tàbí bóyá ohunkóhun wà tó o lè ṣe láti fi ràn wọ́n lọ́wọ́.

Ọ̀pọ̀ ẹlẹ́sìn ló gbà pé àwọn lè ran àwọn tó ti dolóògbé lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù gbà pé béèyàn àwọn kan bá kú, ọ̀nà kan táwọn lè gbà mú kí ọkàn òkú náà gúnlẹ̀ sí ibùgbé ayọ̀ ni pé káwọn sun ara òkú náà káwọn sì lọ fọ́n eérú rẹ̀ sínú Odò Ganges. Lápá Ìlà Oòrùn Éṣíà, àwọn ẹlẹ́sìn Búdà máa ń fi bébà ṣe ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ilé, aṣọ àti owó, wọ́n á sì sun ún nínú iná. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ló máa mú kẹ́ni tó kú lè rí irú àwọn ohun ìní bẹ́ẹ̀ lò láyé míì. Ní Áfíríkà, wọ́n máa ń ta ọtí sẹ́bàá sàréè, lérò pé ó lóore kan tí ọtí náà á ṣe fún òkú tí wọ́n sin síbẹ̀.

Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fi kọ́ni pé bí ẹnì kan bá kú láìronú pìwà dà “ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn” tó dá, ó ti fi àǹfààní àtirí ojúure Ọlọ́run du ara ẹ̀ nìyẹn. Wọ́n sì gbà pé “‘ọ̀run àpáàdì’ nirú ẹni bẹ́ẹ̀ wà.” Àmọ́, ó tún wá fi kọ́ni pé ẹnikẹ́ni tó bá rí ojúure Ọlọ́run lè máa wọ̀nà fún gbígbádùn “ayọ̀ lílékenkà tí ò láfiwé” lọ́run lọ́dọ̀ Ọlọ́run, lẹ́yìn tó bá ti di mímọ́ tí ò lálèébù kankan nìyẹn ṣá o. Kó sì tóó lè di mímọ́ rèé, á kọ́kọ́ jìyà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tó nídàáríjì nípa gbígbé ní pọ́gátórì níbi táá ti fara da “iná ti ń sọni di mímọ́.” Àmọ́ ní gbogbo ìgbà téèyàn bá fi wà ní pọ́gátórì yìí, ó ṣeé ṣe láti fi onírúurú àdúrà ràn án lọ́wọ́, ìyẹn àwọn àdúrà ẹ̀bẹ̀ tí Ṣọ́ọ̀ṣì bá gbà lórúkọ ẹni náà àti ààtò Máàsì tí wọ́n bá ṣe fún un. Àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí òkú ni wọ́n sì máa ń sanwó fún irú ààtò àdúrà àti Máàsì bẹ́ẹ̀.

Kò burú kéèyàn fẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti dín ìyà èyíkéyìí tí ì bá jẹ èèyàn ẹni tó ṣaláìsí kù. Àmọ́, bó bá jóòótọ́ lèèyàn lè ràn wọ́n lọ́wọ́, ǹjẹ́ Ọlọ́run ò ti ní í ṣàlàyé kedere nípa ọ̀nà téèyàn lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì fi kọ́ni lórí ọ̀ràn ríran àwọn òkú lọ́wọ́.

Ipò Táwọn Òkú Wà

Orí ìgbàgbọ́ nínú àìleèkú ọkàn, pé téèyàn bá kú apá kan wà lára ẹ̀ táá máa wà láàyè nìṣó, làwọn èèyàn gbé gbogbo nǹkan tá a ti mẹ́nu kàn pé wọ́n máa ń ṣe nítorí òkú yìí kà. Ṣé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nìyẹn? Ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá, wọn kò sì ní owó ọ̀yà mọ́, nítorí pé a ti gbàgbé ìrántí wọn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìfẹ́ wọn àti ìkórìíra wọn àti owú wọn ti ṣègbé nísinsìnyí, wọn kò sì ní ìpín kankan mọ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin nínú ohunkóhun tí a ó ṣe lábẹ́ oòrùn. Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é, nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù, ibi tí ìwọ ń lọ.” (Oníwàásù 9:5, 6, 10) Ipò òkú tí ọ̀pọ̀ jù lọ aráyé tó ti kú wà lọ̀rọ̀ Hébérù náà, Ṣìọ́ọ̀lù dúró fún.

Ní ti bóyá ẹni tó kú mọ nǹkan tàbí kò mọ nǹkan kan, onísáàmù tó kọ̀wé lábẹ́ ìmísí Ọlọ́run sọ pé: “Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.”—Sáàmù 146:4.

Gbólóhùn tí Bíbélì sọ yìí ò ṣeé já ní koro, ó sì bọ́gbọ́n mu. Àbí kí lo ti rò ó sí? Ṣé bàbá tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀ á fi wọ́n sílẹ̀ fún ìyà jẹ nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n jogún bá máa ń mú kí wọ́n ṣe ohun tí kò tọ́? (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Ó dájú pé kò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Kí ló wá máa mú kí Baba wa ọ̀run, tó nífẹ̀ẹ́ wa, ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀? Nígbà táwọn kan nílẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì ń tẹ̀ lé àṣà àwọn abọ̀rìṣà nípa sísun àwọn ọmọ wọn nínú iná kí wọ́n bàa lè fi wọ́n rúbọ sáwọn ọlọ́run èké, Jèhófà dá irú àṣà ìríra bẹ́ẹ̀ lẹ́bi, ó sọ pé ó jẹ́ ‘ohun tí òun kò pa láṣẹ tí kò sì wá sínú ọkàn-àyà òun.’—Jeremáyà 7:31.

Ikú ni àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀dá, kì í ṣe ìdálóró lẹ́yìn téèyàn bá kú. Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ni pé, “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú,” ó sì wá fi kún un pé, “ẹni tí ó bá ti kú ni a ti dá sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”—Róòmù 5:12; 6:7, 23.

Àwọn òkú ò sí níbi tí wọ́n ti ń jìyà o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ń sun oorun àsùnwọra, láìmọ adùn tàbí ìrora. Torí náà, kò sí iyàn jíjà níbẹ̀ pé gbogbo ipá táwọn èèyàn ń sà láti ran àwọn òkú lọ́wọ́ lòdì sí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni.

Ìrètí Wo Ló Wà Fáwọn Òkú?

Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé inú ipò àìmọ ohun tó ń lọ yẹn náà lèèyàn ẹ tó ti kú máa wà títí láé o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìrètí tó dáa wà fún wọn lọ́jọ́ iwájú.

Kó tó di pé Jésù jí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ dìde, ó sọ pé òun ń lọ “jí i kúrò lójú oorun.” (Jòhánù 11:11) Ní àkókò míì, ó ṣàlàyé pé “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Nígbà yẹn, Ọlọ́run á ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ táwọn tó bá jíǹde ti dá tẹ́lẹ̀ jì wọ́n, nítorí náà kò ní fìyà àwọn nǹkan tí wọ́n ti ṣe kí wọ́n tó kú jẹ wọ́n. Wọ́n á láǹfààní láti kọ́ béèyàn ṣeé gbádùn ìgbésí ayé gẹ́gẹ́ bí ẹni pípé. Àgbàyanu mà ni irú ìlérí bẹ́ẹ̀ yẹn jẹ́ o!

Bó bá wu ìwọ náà pé kí ìlérí yìí ṣẹ, má ṣe jáfara láti wádìí ẹ̀ wò bóyá o lè gbẹ́kẹ̀ lé e. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà á dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́.

ǸJẸ́ Ó TI ṢE Ọ́ BÍI KÓ O BÉÈRÈ PÉ?

◼ Ǹjẹ́ àwọn òkú mọ nǹkan kan?—Sáàmù 146:4; Oníwàásù 9:5, 6, 10.

◼ Ǹjẹ́ Ọlọ́run á gbà pé káwọn òkú máa joró nínú iná ọ̀rún àpáàdì?—Jeremáyà 7:31.

◼ Ǹjẹ́ ìrètí kankan wà fáwọn òkú?—Jòhánù 5:28, 29.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́