ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/07 ojú ìwé 26-27
  • Ṣé Ọ̀dẹ̀ Lẹní Bá Níwà Ìrẹ̀lẹ̀ àbí Ọlọgbọ́n?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ọ̀dẹ̀ Lẹní Bá Níwà Ìrẹ̀lẹ̀ àbí Ọlọgbọ́n?
  • Jí!—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Ìgbéraga àti Ìrẹ̀lẹ̀ Túmọ̀ sí Gan-an
  • Ọlọgbọ́n Lẹní Bá Níwà Ìrẹ̀lẹ̀
  • Ṣé bí Amọ̀ Rírọ̀ Lo Ṣe Rí àbí bí Amọ̀ Gbígbẹ?
  • Eeṣe Ti A Fi Nilati Gbé Irẹlẹ Wọ̀?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ní Ojúlówó Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Àwọn Àpẹẹrẹ Ìrẹ̀lẹ̀-Ọkàn Láti Ṣàfarawé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • “Ẹni Rírẹlẹ̀ ní Ọkàn-Àyà Ni Èmi”
    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
Àwọn Míì
Jí!—2007
g 4/07 ojú ìwé 26-27

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣé Ọ̀dẹ̀ Lẹní Bá Níwà Ìrẹ̀lẹ̀ àbí Ọlọgbọ́n?

BÁWỌN kan bá máa wí, wọ́n á ní agbéraga tàbí ẹni bá dára ẹ̀ lójú ju bó ṣe yẹ lọ ló yẹ kéèyàn máa fara wé. Béèyàn bá níwà ìrẹ̀lẹ̀ tó sì jẹ́ onínú tútù, wọ́n lè máa wò ó bí ọ̀dẹ̀. Wọ́n sì lè máa pè é ní ojo tàbí ẹrú ayé. Àmọ́, ṣé òótọ́ ni pé ọ̀dẹ̀ lẹní bá níwà ìrẹ̀lẹ̀? Ṣé a sì lè wá sọ pé ọlọgbọ́n lẹni tó bá ń gbéra ga? Kí ni Bíbélì sọ?

Ohun Tí Ìgbéraga àti Ìrẹ̀lẹ̀ Túmọ̀ sí Gan-an

Ọ̀kan lára ohun tí ìgbéraga túmọ̀ sí ni pé kéèyàn jọra ẹ̀ lójú. Irú ìgbéraga bẹ́ẹ̀ máa ń mú kéèyàn ronú pé èmi ni mo tó báyìí tí mo dà báyìí, ó máa ń mú kéèyàn rò pé kò sẹ́ni tó tó òun, bóyá nítorí ẹwà ara ẹ̀, ibi tó ti wá, ipò ẹ̀ láwùjọ, ẹ̀bùn tàbí ọrọ̀ tó ní. (Jákọ́bù 4:13-16) Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn tí wọ́n ń ‘wú fùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga.’ (2 Tímótì 3:4) Ìyẹn ni pé wọ́n ń ro ara wọn ju bó ti yẹ lọ, láìsí ìdí kankan tó fi yẹ kí wọ́n ronú lọ́nà bẹ́ẹ̀.

Àmọ́, ní tàwọn onírẹ̀lẹ̀, wọ́n kì í ro ara wọn ju bó ti yẹ lọ, bí wọ́n bá ṣe rí ni wọ́n máa ń sọ. Wọ́n mọ̀ pé ó níbi táwọn kù sí, wọ́n gbà pé àwọn rẹlẹ̀ sí Ọlọ́run àti pé aláìpé làwọn. (1 Pétérù 5:6) Kò wá mọ síbẹ̀, wọ́n tún mọ̀ pé àwọn míì láwọn ànímọ́ tó tayọ tàwọn, inú wọn sì máa ń dùn sírú àwọn bẹ́ẹ̀. (Fílípì 2:3) Nítorí bẹ́ẹ̀, wọn kì í fìbínú ṣe ìlara tàbí kí wọ́n máa jowú àwọn ẹlòmíì. (Gálátíà 5:26) Èyí wá mú kó ṣe kedere pé ojúlówó ìwà ìrẹ̀lẹ̀ máa ń mú kéèyàn lè báwọn ẹlòmíì gbé ní àlàáfíà, ó sì máa ń jẹ́ kí ọkàn balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, kéèyàn sì lè fara da ipò líle koko.

Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ ti Jésù yẹ̀ wò. Kó tó wá sáyé, ó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára lókè ọ̀run. Nígbà tó sì wà láyé, aláìlẹ́ṣẹ̀ àti ẹni pípé ni. (Jòhánù 17:5; 1 Pétérù 2:21, 22) Agbára tó ní ò láfiwé, òye àti ìmọ̀ tó ní sì tayọ ti ẹnikẹ́ni mìíràn. Síbẹ̀, kì í hùwà ṣekárími, ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ló máa ń hù nígbà gbogbo. (Fílípì 2:6) Kódà, ìgbà kan tiẹ̀ wà tó wẹ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀; ó sì fẹ́ràn àwọn ọmọdé gidigidi. (Lúùkù 18:15, 16; Jòhánù 13:4, 5) Kódà, ọmọdé kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù nígbà tó sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọ kékeré yìí ni ẹni tí ó tóbi jù lọ nínú ìjọba ọ̀run.” (Mátíù 18:2-4) Kò sírọ́ ńbẹ̀, lójú Jésù àti lójú Bàbá rẹ̀, ẹni bá níwà ìrẹ̀lẹ̀ lẹni ńlá, kì í ṣe agbéraga èèyàn.—Jákọ́bù 4:10.

Ọlọgbọ́n Lẹní Bá Níwà Ìrẹ̀lẹ̀

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù fi àpẹẹrẹ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ lélẹ̀, ìyẹn ò sọ ọ́ dí ẹni tó ń ṣe ojú ayé tàbí ẹni tó ń tijú akika. Ó máa ń fìgboyà sọ òtítọ́ ó sì dájú ṣáká pé kò bẹ̀rù èèyàn. (Mátíù 23:1-33; Jòhánù 8:13, 44-47; 19:10, 11) Ìdí ẹ̀ nìyẹn tá a fi rí lára àwọn alátakò ẹ̀ pàápàá tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún un. (Máàkù 12:13, 17; 15:5) Àmọ́ Jésù kì í jẹ gàba léni lórí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni ìwà ìrẹ̀lẹ̀, inúure àti ìfẹ́ tó ń fi hàn máa ń fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra. Wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ di ẹni tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ̀ lọ́kàn. Ọ̀rọ̀ àwọn agbéraga kì í wọ àwọn èèyàn lọ́kàn bẹ́ẹ̀ ṣá o. (Mátíù 11:28-30; Jòhánù 13:1; 2 Kọ́ríńtì 5:14, 15) Lónìí pàápàá, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ń fi ìdúróṣinṣin tẹrí ba fún Kristi nítorí pé wọ́n ní ìfẹ́ tòótọ́ fún un wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ gidigidi fún un.—Ìṣípayá 7:9, 10.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká máa hùwà ìrẹ̀lẹ̀ nítorí pé kì í nira fáwọn tó bá níwà ìrẹ̀lẹ̀ láti gbàmọ̀ràn, wọ́n sì máa ń dùn kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. (Lúùkù 10:21; Kólósè 3:10, 12) Bíi ti Ápólò, tó jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́ àti olùkọ́ni nínú ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, ó máa ń yá àwọn onírẹ̀lẹ̀ lára láti yí ojú tí wọ́n fi ń wo nǹkan padà bí wọ́n bá gbọ́ ohun mìíràn kan tó péye ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. (Ìṣe 18:24-26) Ẹ̀rù kì í sì í bà wọ́n láti béèrè ohun tí kò bá yé wọn. Àmọ́ ní tàwọn agbéraga, wọ́n kì í fẹ́ béèrè ohunkóhun, káwọn èèyàn má bàa mọ̀ pé ohun kan wà tí wọn ò mọ̀.

Kíyè sí àpẹẹrẹ ti ìwẹ̀fà ará Etiópíà kan ní ọ̀rúndún kìíní. Ìwẹ̀fà yìí ka apá ibi kan nínú Ìwé Mímọ́, àmọ́ ohun tó kà ò yé e. Ọmọ ẹ̀yìn náà, Fílípì, wá bi í pé: “Ní ti gidi, ìwọ ha mọ ohun tí o ń kà bí?” Ará Etiópíà náà wá dáhùn pé: “Ní ti tòótọ́, báwo ni mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ẹnì kan fi mí mọ̀nà?” Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ gbáà mà nìyẹn o. Pàápàá tó tún wá lọ jẹ́ pé àfàìmọ̀ ni ìwẹ̀fà náà ò fi ní í jẹ́ ẹni pàtàkì nílùú tó ti wá! Ọpẹ́lọpẹ́ pé ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ìyẹn ló sì mú kó ní òye tó jinlẹ̀ nípa Ìwé Mímọ́.—Ìṣe 8:26-38.

Ọ̀ràn ti ìwẹ̀fà ará Etiópíà yìí yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn akọ̀wé Júù àtàwọn Farisí, tí wọ́n ka ara wọn sí ògúnnágbòǹgbò nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn nígbà yẹn lọ́hùn-ún. (Mátíù 23:5-7) Dípò kí wọ́n rẹ ara wọn sílẹ̀ láti tẹ́tí sí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń fi wọ́n ṣẹlẹ́yà tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti wá ẹ̀sùn sí wọn lẹ́sẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ìwà ìgbéraga wọn ò jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe.— Jòhánù 7:32, 47-49; Ìṣe 5:29-33.

Ṣé bí Amọ̀ Rírọ̀ Lo Ṣe Rí àbí bí Amọ̀ Gbígbẹ?

Bíbélì fi Jèhófà wé amọ̀kòkò, ó sì fi àwa èèyàn wé amọ̀. (Aísáyà 64:8) Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ máa ń ran èèyàn lọ́wọ́ láti dà bí amọ̀ rírọ̀ lọ́wọ́ Ọlọ́run, irú ẹni tí Ọlọ́run lè fi mọ ohun èlò tó fani lọ́kàn mọ́ra; àmọ́ àwọn agbéraga dà bí amọ̀ gbígbẹ, tó ti le gbagidi tí ò wúlò fún ohunkóhun ju kéèyàn rún un wómúwómú lọ. Àpẹẹrẹ irú agbéraga ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ ni Fáráò ilẹ̀ Íjíbítì ìgbàanì tó yájú sí Jèhófà tó sì fi ìwàláàyè rẹ̀ dí i. (Ẹ́kísódù 5:2; 9:17; Sáàmù 136:15) Ikú Fáráò jẹ́ ká lóye ọ̀rọ̀ inú ìwé òwe lọ́nà tó ṣe kedere, èyí tó kà pé: “Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.”—Òwe 16:18.

Ohun tá à ń sọ kọ́ ni pé àwọn èèyàn Ọlọ́run kì í jà fitafita láti borí ẹ̀mí ìgbéraga o. Bí àpẹẹrẹ, àwọn àpọ́sítélì Jésù máa ń sábàá bára wọn jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù lọ láàárín wọn. (Lúùkù 22:24-27) Síbẹ̀, ìgbéraga ò mú kí wọ́n má fetí sí ọ̀rọ̀ Jésù, wọ́n sì yí ìwà wọn padà nígbà tó ṣe.

Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Ìyọrísí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.” (Òwe 22:4) Dájúdájú, èyí tó ohun téèyàn á torí ẹ̀ máa hùwà ìrẹ̀lẹ̀! Kì í ṣe nítorí pé ìwà ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ ànímọ́ tó fani mọ́ra tó sì ń fi hàn pé èèyàn kì í ṣe ọ̀lẹ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti rí ojú rere Ọlọ́run ká sì gba ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun.—2 Sámúẹ́lì 22:28; Jákọ́bù 4:10.

ǸJẸ́ Ó TI ṢE Ọ́ RÍ BÍI KÓ O BÉÈRÈ PÉ?

◼ Báwo ni ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ṣé ń mú kéèyàn fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́?—Ìṣe 8:26-38.

◼ Ṣó yẹ káwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run níwà ìrẹ̀lẹ̀?—Lúùkù 22:24-27.

◼ Báwo lọjọ́ iwájú àwọn oníwà ìrẹ̀lẹ̀ ṣe máa rí?—Òwe 22:4.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]

Àwọn ọmọdé máa ń fẹ́ láti wá sọ́dọ̀ Jésù nítorí pé ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́