Ojú Ìwòye Bíbélì
Ta La Lè Kà sí Kristẹni?
“LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ mi, ẹni tó bá ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ ni wọ́n máa ń kà sí Kristẹni.” Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Kingsley lórílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà ló sọ bẹ́ẹ̀. Ọmọkùnrin míì tó ń jẹ́ Raad, láti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé sọ pé: “Láàárín àwọn èèyàn tiwa, àwọn tí wọ́n máa ń kà sí Kristẹni làwọn èèyàn tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àṣà òyìnbó, ìyẹn ni pé, tí wọ́n ń múra bíi tiwọn, tí wọ́n ń ṣe irú ayẹyẹ tí wọ́n ń ṣe, tí wọ́n sì ń fi àwọn obìnrin sáyè tí òyìnbó fi wọ́n sí.”
Àmọ́, ṣé ẹní bá ṣáà ti ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ tó sì ń tẹ̀ lé irú àwọn àṣà kan tó wọ́pọ̀ láwùjọ la lè pè ní Kristẹni? Ṣé kò kúkú sàn kí ọ̀rọ̀ náà “Kristẹni” túmọ̀ sí irú ọ̀nà ìgbésí ayé kan tó bá ìṣesí àti ìwà tí Kristi wàásù rẹ̀ mu tó sì ṣe rẹ́gí pẹ̀lú àpẹẹrẹ tóun fúnra ẹ̀ fi lélẹ̀? Báwo lẹ̀sìn Kristẹni tiẹ̀ ṣe rí nígbà tí wọ́n dá a sílẹ̀ gan-an?
Ẹ̀sìn Kristẹni Nígbà Àtijọ́—Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Ló Jẹ́
Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Ọ̀rẹ́ mi ni yín, bí ẹ bá ń ṣe ohun tí mo ń pa láṣẹ fún yín.” (Jòhánù 15:14) Níwọ̀n bí ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ti kan gbogbo apá ìgbésí ayé wọn, látìbẹ̀rẹ̀ wá ni wọ́n ti ka ẹ̀sìn wọn sí “Ọ̀nà Náà.” (Ìṣe 9:2) Kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà táwọn èèyàn fi “tipasẹ̀ ìdarí àtọ̀runwá” pè wọ́n ní “Kristẹni.” (Ìṣe 11:26) Orúkọ tuntun tí wọ́n ń jẹ́ yìí túmọ̀ sí pé wọ́n gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ọlọ́run, tó jẹ́ kí ìfẹ́ inú Bàbá rẹ̀ ọ̀run di mímọ̀ fún aráyé. Gbígbà tí wọ́n gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ọlọ́run yìí mú kí wọ́n máa gbé ìgbé ayé tó yàtọ̀ sí tàwọn èèyàn tó yí wọn ká.
Ẹ̀kọ́ Kristi ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni, èyí tó túmọ̀ sí pé kí wọ́n máa sá fún “àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìwà àìníjàánu, ìbọ̀rìṣà, bíbá ẹ̀mí lò, ìṣọ̀tá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, owú, ìrufùfù ìbínú, asọ̀, . . . mímu àmuyíràá, àwọn àríyá aláriwo, àti nǹkan báwọ̀nyí.” (Gálátíà 5:19-21; Éfésù 4:17-24) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì létí pé àwọn kan lára wọn ti lọ́wọ́ nínú irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ rí. Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín mọ́, ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti polongo yín ní olódodo ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi.”—1 Kọ́ríńtì 6:9-11.
Nínú ìwé The Rise of Christianity tí Ọ̀gbẹ́ni E. W. Barnes kọ, ó sọ pé: “Nínú àwọn àkọsílẹ̀ ìgbà àtijọ́ tó ṣeé gbára lé, a sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn Kristẹni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn tí ò fàyè gba ìwàkiwà tó sì ń pa òfin mọ́. Àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn náà máa ń wọ́nà láti jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè rere àti olùṣòtítọ́. Wọ́n kì í dá àṣìṣe àti ìwà ibi táwọn abọ̀rìṣà ń hù láre. Lẹ́nì kọ̀ọ̀kan sì rèé, wọ́n kì í bá àwọn aládùúgbò wọn fa wàhálà, wọ́n sì máa ń fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ tó ṣeé finú hàn. A ti kọ́ wọn láti jẹ́ ẹni tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, ọ̀ṣìṣẹ́ kára àti aláìlábòsí. Bí ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ta-ní-máa-mú-mi tiẹ̀ gbilẹ̀, aláìlábòsí àti olóòótọ́ ni wọ́n máa ń jẹ́, àyàfi bí wọn ò bá fi ìlànà tí wọ́n kọ́ sílò ló kù. Wọn ò gba ìṣekúṣe láyè, wọ́n ní ọ̀wọ̀ fún ètò ìgbéyàwó, ọkọ àtaya ń fi inú kan bára wọn lò.” Díẹ̀ lára ohun tó lè mú ká ka èèyàn sí Kristẹni nígbà tí ẹ̀sìn náà kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.
Àmì pàtàkì mìíràn tá a tún mọ̀ mọ́ àwọn Kristẹni ìgbà ìjímìjí ni pé wọ́n ní ìtàra fún iṣẹ́ ìjíhìn rere. Kristi pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19, 20) Jean Bernardi, ọ̀jọ̀gbọ́n kan nílé ẹ̀kọ́ gíga Sorbonne University, nílùú Paris, lórílẹ̀-èdè Faransé, sọ pé: “Lílọ ló yẹ káwọn [Kristẹni] máa lọ síbi gbogbo àti sọ́dọ̀ olúkúlùkù èèyàn láti bá wọn sọ̀rọ̀. Lójú pópó àti láwọn ìlú ńlá, ní gbàgede ìlú àti nínú ilé àwọn èèyàn. Yálà àwọn èèyàn tẹ́wọ́ gbà wọ́n tàbí wọn ò tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Kí wọ́n bàa lè dé ọ̀dọ̀ àwọn òtòṣì àtàwọn olówó tí ohun ìní wọn ò jẹ́ kí wọ́n ráyè fún nǹkan míì mọ́. . . . Wọ́n gbọ́dọ̀ rìnrìn àjò lójú ọ̀nà, nínú ọkọ̀ ojú omi, kí wọ́n sì dé ìpẹ̀kun ayé.”
Ẹ̀sìn Kristẹni Tòótọ́ Lónìí
Ó yẹ ká mọ àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ́ ọ̀nà ìgbésí ayé wọn tó yàtọ̀ gedegbe, bó ṣe rí gẹ́lẹ́ ní ọ̀rúndún kìíní. Nítorí èyí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sa gbogbo ipá wọn láti rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ àwọn ìlànà táwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi lélẹ̀. Àwọn ẹlòmíì sì máa ń kíyè sí i pé lóòótọ́ ni wọ́n ń gbé ìgbé ayé wọn ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Bíbélì.
Bí àpẹẹrẹ, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé kárí ayé ni wọn ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí “ọ̀kan lára àwọn àwùjọ ẹlẹ́sìn tí ìwà wọn dára jù lọ lágbàáyé.” Ìwé ìròyìn Deseret News ti ìlú Salt Lake City, ní ìpínlẹ̀ Utah kíyè sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì sọ pé “ìdílé wọn máa ń wà pa pọ̀ bí òṣùṣù ọwọ̀, wọ́n ṣeé fọkàn tán láwùjọ, wọ́n sì máa ń ṣiṣẹ́ kára.” Ìwé ìròyìn náà wá fi kún un pé: “Àwọn tó jẹ́ ara ẹ̀sìn yìí máa ń gbé ìgbésí ayé tó yẹ ọmọlúwàbí. Wọ́n gbà pé àwọn nǹkan tó lè ba àjọṣe èèyàn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ làwọn nǹkan bíi sìga mímu, ọtí àmujù, lílo oògùn olóró, tẹ́tẹ́ títa, ìṣekúṣe àti bíbẹ́yà kan náà lò pọ̀. Wọ́n máa ń fi ìwà àìlábòsí àti àìṣèmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ kọ́ni.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí tún máa ń fọwọ́ tó ṣe pàtàkì mú ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí olùfìtara jíhìn rere. Nígbà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia ń sọ̀rọ̀ nípa èyí, ó sọ pé: “Ohun tó jẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe jù lọ fún Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan ni pé . . . kóun jẹ́rìí nípa Jèhófà kóun sì kéde Ìjọba Rẹ̀ tó ń bọ̀. . . . Bó ṣe wù kó rí, kéèyàn tó lè jẹ́ Ẹlẹ́rìí tòótọ́, ó gbọ́dọ̀ máa wàásù lọ́nà tó múná dóko.”
Dájúdájú, wíwulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kọ́ ló ń sọ èèyàn di Kristẹni tòótọ́. Jésù alára sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ayédèrú Kristẹni máa wà. (Mátíù 7:22, 23) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pè ẹ pé kó o wá kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Jésù fi kọ́ni kó o sì máa fi ṣèwà hù. Ohun tó lè sọ ẹ́ di Kristẹni gan-an nìyẹn. Jésù ṣáà sọ pé: “Bí ẹ bá mọ nǹkan wọ̀nyí, aláyọ̀ ni yín bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.”—Jòhánù 13:17.
ǸJẸ́ Ó TI ṢE Ọ́ RÍ BÍI KÓ O BÉÈRÈ PÉ?
◼ Àwọn wo ni Jésù sọ pé wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ òun?—Jòhánù 15:14.
◼ Irú ìwà wo ló yẹ káwọn Kristẹni sá fún?—Gálátíà 5:19-21.
◼ Iṣẹ́ wo làwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ máa lọ́wọ́ sí?—Mátíù 28:19, 20.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Olùfìtara jíhìn rere làwọn Kristẹni tòótọ́, bí wọ́n sì ṣe rí láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá nìyẹn