ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/07 ojú ìwé 26-27
  • Ṣé Ẹ̀sìn Kristẹni Ti Kùnà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ẹ̀sìn Kristẹni Ti Kùnà?
  • Jí!—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀sìn Kristẹni Tí Wọ́n Yí Padà Ló Gbòde Kan
  • Kí Ni Jésù Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ẹ̀sìn Kristẹni Tòótọ́ Lóde Òní
  • Kí Nìdí Tí Onírúurú Ẹ̀sìn Kristẹni Fi Wà?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Àwọn Wo Ni Ojúlówó Kristẹni?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ta La Lè Kà sí Kristẹni?
    Jí!—2007
  • Báwo Ni O Ṣe Lè Rí Ìsìn Tòótọ́?
    Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
Àwọn Míì
Jí!—2007
g 1/07 ojú ìwé 26-27

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣé Ẹ̀sìn Kristẹni Ti Kùnà?

NǸKAN bí ìdá mẹ́tà àwọn tó ń gbé láyé ló sọ pé Kristẹni làwọn. Síbẹ̀ ó dà bíi pé ọ̀rọ̀ òṣèlú àti rògbòdìyàn ti pín ayé sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ ju bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ lọ. Ṣé ohun tó túmọ̀ sí ni pé nǹkan kan wà tó kù díẹ̀ káàtó nípa ẹ̀sìn Kristẹni tí Jésù dá sílẹ̀? Àbí ọwọ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi mú ẹ̀kọ́ Kristi ló kù díẹ̀ káàtó?

Àpilẹ̀kọ yìí á ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí Kristi fi kọ́ni gan-an àti àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ó tún máa ṣàgbéyẹ̀wò ohun kan tí ọ̀pọ̀ àwọn tó pera wọn ní Kristẹni gbà gbọ́, ìyẹn ohun kan tó lòdì sí ohun tí ẹ̀sìn Kristẹni dúró fún.

Ẹ̀sìn Kristẹni Tí Wọ́n Yí Padà Ló Gbòde Kan

Láàárín bí ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́rin lẹ́yìn ikú Kristi, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í yí ẹ̀sìn Kristẹni padà kó bàa lè di ẹ̀sìn táwọn èèyàn àgbègbè Ìjọba Róòmù fẹ́ràn. Àwọn tó wà nínú ẹ̀sìn Kristẹni aláfẹnujẹ́ yìí kì í wá ṣe àwọn àjèjì táwọn aráàlú kórìíra mọ́, wọ́n ti wá dẹni pàtàkì láàárín àwọn olóṣèlú, wọ́n ti dẹni tó gbajúmọ̀ láwùjọ lórílẹ̀-èdè Róòmù. Nígbà ti nǹkan ti yí padà báyìí, àwọn aṣáájú Ṣọ́ọ̀ṣì bí Augustine bẹ̀rẹ̀ sí í lo àǹfààní yìí láti máa kọ́ni pé Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n ti ń dúró dè látọjọ́ yìí ti dé. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn pé báwọn ṣe ń rọ́wọ́ mú nínú ẹ̀sìn àti òṣèlú yìí ló máa mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé. Bó ṣe di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹnu mọ́ ọn pé àwọn èèyàn lè máa bójú tó ọ̀ràn ayé nìyẹn.

Èyí ló mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa rò pé ó yẹ kí Kristẹni kan ní ipa táá máa kó nínú ètò òṣèlú láwùjọ. Ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn sì ni pé kẹ́nì kan tó jẹ́ Kristẹni bàa lè máa kópa tó jọjú láwùjọ, ó ní láti fi díẹ̀ lára ohun tó gbà gbọ́ sílẹ̀ tó bá di pé ó ta ko ohun tó bá àwùjọ ibi tó ń gbé mu. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fẹnu lásán tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Kristi pé ká ní ìfẹ́ ká sì jẹ́ ẹni àlàáfíà, ṣe ni wọ́n ń ti ogun tó ń pààyàn nípakúpa lẹ́yìn. Ohun náà ló fà á tó fi jẹ́ pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì á máa sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn wọn pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé tí wọ́n á sì tún máa ṣètìlẹ́yìn fún àwọn alákòóso tó ń fìyà jẹ àwọn aráàlú.

Irú ayédèrú ẹ̀sìn Kristẹni yìí kọ́ ni ẹ̀sìn tí Jésù dá sílẹ̀. Àwọn èèyàn fúnra wọn ló fọwọ́ ara wọn dá a sílẹ̀, òun sì ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni lóde òní ń ṣe. Irú ẹ̀sìn Kristẹni yìí ti kùnà nítorí pé lákòókò tá a wà yìí, àwọn èèyàn ò fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìlànà Bíbélì mọ́ láwọn ibi tí ẹ̀sìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti gbilẹ̀.

Kí Ni Jésù Fi Kọ́ni Gan-an?

Ó lè ya àwọn kan lẹ́nu tí wọ́n bá gbọ́ pé Jésù fúnra ẹ̀ sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun kò gbọ́dọ̀ jẹ́ “apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí [òun] kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:15, 16) Kí nìdí tí Jésù fi ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun má ṣe jẹ́ apá kan ayé? Ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù fẹ́ràn gan-an, ìyẹn àpọ́sítélì Jòhánù, sọ ìdí ẹ̀ fún wa. Ó kọ̀wé pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.”—1 Jòhánù 5:19.

Fún ìdí èyí, kì í ṣe ìjọba tàbí ẹgbẹ́ kankan tí èèyàn dá sílẹ̀ ni Kristi ní ká máa wò, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tí ẹ̀kọ́ ẹ̀ dá lé lórí ni pé Ìjọba Ọlọ́run ló máa mú kí ẹ̀tọ́ àti òdodo wà lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 6:10) Jésù gan-an alára ò tiẹ̀ bá wọn dédìí ọ̀ràn ìlú nígbà ayé ẹ̀. Kò bá wọn dá sí gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìṣèlú. (Jòhánù 6:15) Kò gbà kí wọ́n fi ìjà yanjú èdèkòyédè. (Mátíù 26:50-53; Jòhánù 18:36) Jésù ò gbé òfin orílẹ̀-èdè tàbí òfin míì tó yẹ kí wọ́n fi máa ṣètò ìlú kalẹ̀. Nínú gbogbo ọ̀ràn òṣèlú tó ń lọ nígbà tó wà láyé kò bá wọn pọ̀n sí apá kan. Bí àpẹẹrẹ, kò di ajàfẹ́tọ̀ọ́ táá máa jà fáwọn ẹrú, bẹ́ẹ̀ ni kò bá àwọn Júù dá sí ọ̀tẹ̀ tí wọ́n ń dí sáwọn ará Róòmù.

Àmọ́, ìyẹn ò sọ pé ṣe ni Jésù kọtí ọ̀gbọin sọ́rọ̀ àwọn èèyàn àtàwọn ìṣòro tó ń bá wọn fínra o. Jésù kọ́ni ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ nípa ojúṣe àwa èèyàn sí ọmọlàkejì wa. Ó rọ̀ wá pé ká máa san owó orí ó sì tẹnu mọ́ ọn pé ká máa tẹrí bá fáwọn tó bá wà nípò àṣẹ. (Mátíù 22:17-21) Ó kọ́ wa bá a ṣe lè máa fìfẹ́ bá àwọn tó jẹ́ aláìní lò. Ó tún kọ́ wa bá a ṣe lè máa fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n àti bá a ṣe lè máa fi ìyọ́nú bá àwọn èèyàn lò, ká máa dárí jini ká sì jẹ́ aláàánú. (Mátíù, orí 5 sí 7) Ó hàn gbangba pé orí ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti aládùúgbò ẹni ni ẹ̀kọ́ Kristi dá lé.—Máàkù 12:30, 31.

Ẹ̀sìn Kristẹni Tòótọ́ Lóde Òní

Báwo ló ṣe wá yẹ kí ọmọlẹ́yìn Kristi tòótọ́ máa hùwà o? Ṣe ló yẹ kó máa ṣe bí Jésù ṣe ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé á máa tẹ̀ lé gbogbo òfin ìlú, síbẹ̀ kò ní dá sí ohun tó ń lọ láwùjọ òṣèlú. (Jòhánù 12:47, 48) Kò ní pa àwọn ìlànà Kristẹni tó yẹ kó máa tẹ̀ lé tì kódà, nígbà tí nǹkan ò bá rọgbọ rárá. (1 Pétérù 2:21-23) Síbẹ̀, kò kàn ní máa ṣe bí òǹwòran tí ohun tó ń lọ ò kàn. Ẹni tó bá jẹ́ Kristẹni tòótọ́ á máa wá ire àwọn tó wà nítòsí ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe. (Mátíù 6:34) A tún máa lo okun àti gbogbo ohun tó bá ní láti máa fi ran àwọn èèyàn míì lọ́wọ́ kí wọ́n bàa lè máa láyọ̀ nínú ìgbésí ayé wọn. A máa ṣe bẹ́ẹ̀ nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ Kristi, kí wọ́n sì máa gbé níbàámu pẹ̀lú ẹ̀.—Jòhánù 13:17.

Orí èyí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dúró lé, wọ́n ń sapá láti máa fara wé Kristi nínú bí wọ́n ṣe ń bá àwọn èèyàn lò nílé lóko. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń tẹ̀ lé òfin gẹ́gẹ́ bí ọmọ onílùú, síbẹ̀ wọn ò dara pọ̀ mọ́ ayé. Bíi ti Jésù, wọn ò dá sí rògbòdìyàn àti àríyànjiyàn tó gba àárín àwọn olóṣèlú kan lásìkò tá à ń gbé yìí. Orí Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n gbé ìrètí wọn lé, wọ́n gbà pé òun ni ojútùú kan ṣoṣo fún ìṣòro tó ń kojú ayé. Ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ ń mú kí ìgbésí ayé èèyàn túbọ̀ láyọ̀ ó sì ń mú kí ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́. (Jòhánù 13:34, 35) Kò sóhun tó jọ ọ́ rárá, ẹ̀sìn Kristẹni ò kùnà.

ǸJẸ́ Ó TI ṢE Ọ́ RÍ BÍI KÓ O BÉÈRÈ PÉ?

◼ Ṣó yẹ káwọn Kristẹni máa dá sí ọ̀ràn ìṣèlú?—Jòhánù 6:15.

◼ Ṣé Kristi sọ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa fi ìjà yanjú èdè àìyedè?—Mátíù 26:50-53.

◼ Kí la fi lè dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀?—Jòhánù 13:34, 35.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]

EL COMERCIO, Quito, Ecuador

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́