Ṣé Ìlépa Owó Ń Kó Ìdààmú Bá Ẹ?
BÓ O bá di olówó lọ́la, kí ni wàá ṣe? Ṣé wàá bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́ kó o lè máa gbádùn ara ẹ? Àbí wàá fiṣẹ́ ẹ silẹ̀, tíwọ àtìdílé ẹ, àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ á sì máa gbádùn ara yín? Àbí ṣe ni wàá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbé ayé tó o mọ̀ pé á máa mú ẹ láyọ̀? Ibi tọ́rọ̀ náà tiẹ̀ wá wà ni pé ọ̀pọ̀ àwọn tó di ọlọ́rọ̀ kì í ṣe ohun tó jọ gbogbo èyí tá à ń sọ yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo àkókò tó kù kí wọ́n lò láyé ni wọ́n fi máa ń wá owó kún owó, yálà kí wọ́n bàa lè san gbèsè tó wà lọ́rùn wọn tàbí kí wọ́n lè túbọ̀ lówó sí i.
Àmọ́, àwọn kan tí wọ́n ń wá owó kún owó lọ́nà yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé ìfẹ́ ọrọ̀ ń ṣe àwọn bí àárẹ̀, ó ń kó bá ìdílé àwọn, ó sì ń sọ àwọn ọmọ àwọn dí oníwàkiwà. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í ki àwọn èèyàn nílọ̀ nínú àwọn ìwé, nínú onírúurú àpilẹ̀kọ, nínú àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n àti eré sinimá pé kí wọ́n yé kẹ́ra wọn bà jẹ́ àmọ́ kí wọ́n kúkú máa gbé ìgbé ayé tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì.” Ìwádìí síwájú sí i fi hàn pé bí lílépa ohun ìní bá gbani lọ́kàn jù, ó lè kó àárẹ̀ bá ọpọlọ, ó lè máa kóni láyà sókè, ó sì lè máa múni ṣàárẹ̀.
Àmọ́ ṣá o, pé ewu wà nínú kéèyàn nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ kì í ṣe ohun tuntun. Léyìí tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn, Bíbélì sọ pé: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—1 Tímótì 6:9, 10.
Ṣóòótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ yìí? Ṣó dájú pé àwọn tó bá ń fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn wá owó àti ohun ìní máa ń jìyà nídìí ẹ̀? Àbí gbogbo ohun tí wọ́n ń wá lọwọ́ wọn máa ń tẹ̀, ìyẹn ọrọ̀, ìlera àti ilé aláyọ̀? Ẹ jẹ́ ká máa bọ́rọ̀ bọ̀.