ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/07 ojú ìwé 3
  • Àgbàyanu Lọgbọ́n Tó Ń Darí Àwọn Ẹyẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àgbàyanu Lọgbọ́n Tó Ń Darí Àwọn Ẹyẹ
  • Jí!—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Ju Ọgbọ́n Àdámọ́ni Lọ
  • Ẹyẹ Arctic Tern
    Jí!—2017
  • Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́ Lára Àwọn Ẹyẹ Ojú Ọ̀run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Wíwo Ẹyẹ—Ìgbòkègbodò Àfipawọ́ Tí Gbogbo Ènìyàn Nífẹ̀ẹ́ Sí Ni Bí?
    Jí!—1998
Jí!—2007
g 7/07 ojú ìwé 3

Àgbàyanu Lọgbọ́n Tó Ń Darí Àwọn Ẹyẹ

“Àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ báwọn ẹyẹ ṣe ń ṣí kiri lohun àgbàyanu jù lọ nínú ìṣẹ̀dá.”—ÌWÉ COLLINS ATLAS OF BIRD MIGRATION.

NÍ ỌJỌ́ kẹsàn-án, oṣù Kejìlá, ọdún 1967, awakọ̀ òfuurufú kan rí agbo àwọn ẹyẹ ògbùgbú kan báyìí tí wọ́n tó ọgbọ̀n tí wọ́n ń fò lọ síhà orílẹ̀-èdè Ireland. Èyí tí wọ́n fi fò ròkè lálá tó igba mọ́kànlélógójì [8,200] mítà, èyí tó ga tó ilé alájà ọgọ́rùn-ún lọ́nà mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n. Kí ló fà á tí wọ́n fi fò ròkè lálá lọ síbi tó tutù tó láti mú kí nǹkan dì gbagidi ní ìgbà ogójì? Ìdí ni pé níbẹ̀ ni wọ́n ti máa ń bọ́ sọ́wọ́ ẹ̀fúùfù lẹlẹ táá túbọ̀ gbé wọn ròkè, débi tí wọ́n á fi máa rìnrìn-àjò tó tó igba kìlómítà ní wákàtí kan. Bí wọ́n bá fò wálẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n á kàgbákò ìjì tó ń fẹ́ gbùgbù-gbàgbà àti òjò yìnyín tòun ti ìrì dídì. Àwọn tó ń ṣèwádìí tiẹ̀ fojú bù ú pé wákàtí méje péré làwọn ẹyẹ náà fi máa ń rìnrìn àjò láti orílẹ̀-èdè Iceland sí orílẹ̀-èdè Ireland. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀ọ́dúnrún lé lẹ́gbẹ̀rún [1,300] kìlómítà, ìyẹn ẹgbẹ̀rin ibùsọ̀, làwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì yìí fi jìnnà síra.

Kò sí ẹlẹgbẹ́ ẹyẹ arctic tern lára àwọn ẹyẹ aṣíkiri tó wà lágbàáyé. Apá àríwá ilẹ̀ ayé ló máa ń pamọ sí, bó bá wá di ìgbà òtútù, á fò lọ sí apá Gúúsù ilẹ̀ ayé. Lọ́dọọdún, ẹyẹ òkun kélébé yìí máa ń rìnrìn-àjò ọ̀kẹ́ méjì [40,000] sí ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ [50,000] kìlómítà, ká ṣáà sọ pé ó máa ń fò yí ayé po!

Àríwá ilẹ̀ Yúróòpù làwọn ẹyẹ àkọ̀ máa ń pamọ tiwọn sí, bó bá sì dìgbà òjò wọ́n á fò lọ sí orílẹ̀-èdè South Africa, tó tó ẹgbàá méjìlá kìlómítà ní àlọ àtàbọ̀. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹyẹ yìí máa ń fò gba ilẹ̀ Ísírẹ́lì kọjá ní àkókò ìwọ́wé àti ní àkókò ìrúwé, àwọn èèyàn sì ti mọ̀ wọ́n mọ irú ìrìn-àjò yìí látìgbà tí wọ́n ti ń kọ Bíbélì.—Jeremáyà 8:7.

Ta ló dá irú ọgbọ́n yìí mọ́ àwọn ẹyẹ? Ó ti tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùndínlógójì [3,500] ọdún sẹ́yìn báyìí tí Ọlọ́run ti bi Jóòbù tó jẹ́ olódodo ní ìbéèrè yìí pé: “Ṣé òye rẹ ni ó mú kí àṣáǹwéwé ròkè lálá, tí ó fi na ìyẹ́ apá rẹ̀ sí ẹ̀fúùfù gúúsù? Tàbí ṣé nípa àṣẹ ìtọ́ni rẹ ni idì fi ń fò lọ síhà òkè, tí ó sì fi ń kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí òkè fíofío?” Nígbà tí Jóòbù máa fèsì, ńṣe ló fìyìn fún Ọlọ́run nítorí agbára àgbàyanu tó fi jíǹkí àwọn ẹyẹ àtàwọn ẹranko.—Jóòbù 39:26, 27; 42:2.

Ó Ju Ọgbọ́n Àdámọ́ni Lọ

Kì í ṣe ọgbọ́n àdámọ́ni ló ń darí àwa èèyàn tá a pabanbarì jù lọ lára àwọn ohun tí Ọlọ́run dá. A lómìnira àtiṣe ohun tá a bá fẹ́, a ní ẹ̀rí ọkàn, a sì lè fi ìfẹ́ hàn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27; 1 Jòhánù 4:8) Nítorí gbogbo ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fi jíǹkí wa yìí, a lè ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu tí kò ní kótìjú bá wa. Ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé béèyàn ò bá ní ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ kó sì tún jẹ́ ẹni tó lè fi nǹkan du ara ẹ̀, kò ní lè ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀.

Nítorí náà, bí wọ́n bá fìwà ọmọlúwàbí tàbí ìlànà Ọlọ́run kọ́ ẹnì kan látìgbà tó ti wà lọ́mọ ọwọ́, dandan ni kí ìṣesí tàbí ìwà ẹni bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí tẹni tí wọn ò firú ẹ̀ kọ́. Ìdí nìyẹn tí ohun tó tọ́ lójú ẹnì kan fi lè ṣàìtọ́ lójú ẹlòmíì, tí ohun tó ṣètẹ́wọ́gbà lójú ẹnì kan sì lè má ṣètẹ́wọ́gbà lójú ẹlòmíì. Bákan náà sì tún ni ohun táwọn èèyàn fi yàtọ̀ síra yìí lè fa èdè àìyédè, àìgbagbẹ̀rẹ́ àti ìkórìíra, á tiẹ̀ tún burú bí ọ̀rọ̀ àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni àti ọ̀ràn ẹ̀sìn bá tún wá lọ wọ̀ ọ́.

Ẹ wá wo báyé ì bá ṣe dáa tó bó bá jẹ́ pé ìlànà kan náà tó bá ìwà ọmọlúwàbí mu tí kò sì tako Bíbélì ló ń darí gbogbo ẹ̀dá tó wà láyé, bó ṣe jẹ́ pé ìlànà kan náà tó ń darí àgbáyé ni gbogbo wa ń tẹ̀ lé! Ṣé a wá rẹ́ni tó lágbára àti òye tó ṣeé gbé irú ìlànà tá á wúlò nílé lóko bẹ́ẹ̀ kalẹ̀ ni? Bírú ẹni bẹ́ẹ̀ bá sì wà, ṣó ṣe tán láti gbé ìlànà náà kalẹ̀, àbí ó tiẹ̀ ti gbé e kalẹ̀? A óò tú iṣu àwọn ìbéèrè wọ̀nyí désàlẹ̀ ìkòkò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́