Ìtọ́sọ́nà Tó Ju Ọgbọ́n Àdámọ́ni Lọ
“Bó bá jẹ́ pé ohun táwọn èèyàn bá ṣáà ti fẹ́ ló kù tí wọ́n ń hù níwà báyìí, láìsí ìlànà kankan tí wọ́n á gbé ìwà wọn kà láti fi pinnu bóyá ó tọ́ tàbí kò tọ́, a jẹ́ pé ó di dandan kí òfin wà táá máa yẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ wò.” —Ọ̀MỌ̀WÉ DANIEL CALLAHAN.
Ọ̀RỌ̀ tó ń jà gùdù lọ́kàn Ọ̀mọ̀wé Callahan ti kúrò lọ́rọ̀ àhesọ, nítorí pé lápá ibi púpọ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àìsí ìwà ọmọlúwàbí ti mú kó di dandan fáwọn alákòóso láti gbé àìlóǹkà òfin kalẹ̀ nítorí àtikiwọ́ ìwà ọ̀daràn bọlẹ̀. Níbi Àpérò Àwọn Ìyá Lórílẹ̀-Èdè Nàìjíríà, tó jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ tó wáyé, ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ nípa ibi tí orílẹ̀-èdè náà ń dorí kọ. Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìṣèlú tàbí ti àìríná àìrílò ló ní lọ́kàn, “ìṣòro kan tó le ju ìwọ̀nyẹn lọ” ló ní lọ́kàn, ìyẹn ni “àfẹ́kù tó ti bá ìwà rere láàárín ẹbí àti ará, níbi iṣẹ́, láwùjọ àti jákèjádò orílẹ̀-èdè náà.”
Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Britain, nínú èyí tí wọ́n ti fọ̀rọ̀ wá àwọn ìyá tó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán ó lé mẹ́rìndínlógójì [1,736] lẹ́nu wò, wọ́n rí i pé “àjọṣepọ̀ tẹbí tará tó ti máa ń wà nígbà kan rí ti ròkun ìgbàgbé nítorí pé ìwà rere ti ń kúrò lójú ajọ̀, àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ sì ń pọ̀ sí i.” Ìwà rere ti ń kógbá sílé lórílẹ̀-èdè Ṣáínà náà. Ìwé ìròyìn Time sọ pé láti kékeré làwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ ti máa ń ní ìbálòpọ̀, wọn kì í sì í fi mọ sọ́dọ̀ ẹnì kan ṣoṣo. Ọ̀dọ́bìnrin kan tiẹ̀ wà níbẹ̀ táwọn ọkùnrin tó ń bá a sùn lé ní ọgọ́rùn-ún, ó wá ń ṣe fọ́ńté pé: “Èmi ni mo nira mi, ohun tó bá sì wù mí ni mo lè fira mi ṣe.”
Àfẹ́kù tó bá ìwà rere ò ṣàì dé ọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ náà. Ọ̀gbẹ́ni Javed Akbar sọ nínú ìwé ìròyìn ilẹ̀ Kánádà náà, Toronto Star, pé: “Àwọn èèyàn ò tún rí àwọn aṣáájú wọn bí àwòkọ́ṣe mọ́.” Ó tún wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé “ó dà bíi pé kò sí ìwà rere kankan mọ́ lọ́wọ́” àwọn olóṣèlú, àwọn ọ̀gá iléeṣẹ́ àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn pàápàá.
Kí Ló Mú Kí Àfẹ́kù Bá Ìwà Rere?
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló fà á tí àfẹ́kù fi bá ìwà rere. Ọ̀kan lára ẹ̀ ni ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ tó gbayé kan tó yàtọ̀ sí ìwà rere tó ti wà látayébáyé. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga kan ní Gúúsù ilẹ̀ Amẹ́ríkà, wọ́n rí i pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn ló ronú pé “olúkúlùkù èèyàn ló yẹ kó máa dá pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́.”
Òǹkọ̀wé lórí ọ̀ràn ìṣèlú Zbigniew Brzezinski tún mẹ́nu kan ohun mìíràn tó yàtọ̀. Ó kọ̀wé pé láwùjọ òde òní, “àwọn èèyàn ò mọ méjì ju pé ibi táyé bá ṣáà ti báni la ti í jẹ ẹ́, ohun tó sì fà á ni pé kò sẹ́nikẹ́ni tó ṣe tán láti báni láwọ́ ẹ̀jẹ̀, ọwọ́ epo ló kù táráyé ń báni lá.” Òótọ́ ni pé híhùwà béèyàn ṣe fẹ́, ìwọra àti títẹ́ ìfẹ́ ẹni lọ́rùn lè máa jẹ́ kóríyá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ ṣé wọ́n máa ń fúnni ní ojúlówó ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn, ṣé wọ́n sì ń jẹ́ kí àjọṣe ẹni pẹ̀lú tàwọn ẹlòmíì sunwọ̀n si?
Jésù sọ pé: “A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mátíù 11:19) Ṣé jíjó tí ìwà rere ń jó rẹ̀yìn ń mú káwọn èèyàn túbọ̀ máa láyọ̀, àbí ṣe ló ń mú kí ọkàn wọn túbọ̀ máa balẹ̀? Ẹ jẹ́ ká tibi tó ń yọrí sí wò ó. Ó ti mú kí àìfọkàntánni máa pọ̀ sí i, ó ti fa àìbalẹ̀ ọkàn, ó ti ba tẹbí tọ̀rẹ́ jẹ́, ó ti yọrí sí káwọn ọmọ dọmọ òrukàn, ó ti fa àrùn ìbálòpọ̀ tó ń jà káyé, ó ti yọrí sí gbígboyún, lílo oògùn olóró àti híhùwà ipá. Bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, ó wá ṣe kedere pé aráyé ò lè nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sì lè kẹ́sẹ járí, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni ìbànújẹ́ àti ìkùnà á máa pọ̀ sí i.—Gálátíà 6:7, 8.
Lẹ́yìn ti Jeremáyà, tí í ṣe wòlíì Ọlọ́run, ti rí wàhálà tó jọ èyí nígbà tó wà láyé, ó sọ ohun tójú rẹ̀ rí nínú àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn, Ọlọ́run ò dá wa nídàá pé ká máa dá wà, ká sì máa dá pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí ò tọ́. Ó ṣe tán, ohun tó dà bí èyí tó tọ́ lójú wa, lè jẹ́ ohun tó léwu gan-an. Bíbélì sọ nínú ìwé Òwe 14:12 pé: “Ọ̀nà kan wà tí ó dúró ṣánṣán lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ikú ni òpin rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.”
Ọ̀tá Ilé!
Kí ni ọ̀kan lára ìdí tá a fi nílò ìtọ́sọ́nà lórí àwọn ọ̀ràn tó bá jẹ mọ́ ìwà híhù? Ìdí ni pé ọkàn-àyà wa lè tàn wá jẹ. Bíbélì ṣáà sọ nínú Jeremáyà 17:9 pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà. Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n?” Bó o bá mọ ẹnì kan tó jẹ́ aládàkàdekè, tí ò sì bèṣù bẹ̀gbà, ṣé wàá fọkàn tán irú ẹni bẹ́ẹ̀? Ó dájú pé o ò ní í fọkàn tán an! Síbẹ̀, kò sí ọkàn-àyà ẹnikẹ́ni nínú wa tí ò lè rí bí Bíbélì ṣe sọ yẹn. Ìdí ẹ̀ nìyẹn tí Ọlọ́run fi kìlọ̀ fún wa ní tààràtà ṣùgbọ́n lọ́nà tó fi ìfẹ́ hàn pé: “Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ́ arìndìn, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fi ọgbọ́n rìn ni ẹni tí yóò sá àsálà.”—Òwe 28:26.
Òkodoro ọ̀rọ̀ gbáà mà lèyí o. Dípò tá a ó fi máa gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn-àyà wa tó jẹ́ aláìpé, ó pọn dandan pé ká jẹ́ kí ọgbọ́n Ọlọ́run máa darí wa, a ó sì máa tipa bẹ́ẹ̀ gba ara wa lọ́wọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà. Ó ṣe tán, ọgbọ́n tó ṣeyebíye yìí wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo ẹni tó bá fi tọkàntọkàn fẹ́ ẹ. “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni.”—Jákọ́bù 1:5.
“Fi Gbogbo Ọkàn-Àyà Rẹ” Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọlọ́run
Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá wa, ó sọ pé: “Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; olódodo àti adúróṣánṣán ni.” (Diutarónómì 32:4) Bẹ́ẹ̀ ni, ṣe ni Jèhófà dà bí àpáta tó borí ilẹ̀ bámúbámú. A lè gbára lé e pátápátá bá a bá nílò ìtọ́sọ́nà tó jíire tó sì lè mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn, láìka ohun yòówù tí ì báà máa ṣẹlẹ̀ sí. Òwe 3:5, 6 sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”
Bó ṣe yẹ kí ọ̀rọ̀ rí nìyẹn, àbí ta lẹni tó lè fún wa ní ìtọ́sọ́nà tó sàn ju ti Ẹlẹ́dàá wa lọ, ẹni tó mọ iye “gbogbo irun orí [wa] gan-an”? (Mátíù 10:30) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó ti fi hàn pé ojúlówó ọ̀rẹ́ lòun jẹ́ fún wa, ẹni tó fẹ́ràn wa tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kì í fi í firọ́ pé òótọ́ fún wa, àní nígbà tó bá tiẹ̀ dà bíi pé òótọ́ á korò létí wa pàápàá.—Sáàmù 141:5; Òwe 27:6.
Tún kíyè sí i pé Jèhófà kì í fipá mú wa láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fìfẹ́ sọ fún wa nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Èmi, Jèhófà, ni . . . Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn. Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.” (Aísáyà 48:17, 18) Ṣó wù ẹ́ pé kó o sún mọ́ irú Ọlọ́run bí èyí? Kì í tún wá ṣèyẹn nìkan, Ọlọ́run yìí mú kó ṣeé ṣe fáwa èèyàn láti kọ́ lára ọgbọ́n rẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní ìmísí, ìyẹn ni Bíbélì Mímọ́, ìwé tó jẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà síbi tí ò sí lágbàáyé!—2 Tímótì 3:16.
Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Tànmọ́lẹ̀ Sípa Ọ̀nà Rẹ
Onísáàmù kọ̀wé nípa Ìwé Mímọ́ pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.” (Sáàmù 119:105) Bí fìtílà bá tan iná sí ẹsẹ̀ wa, a ó máa rína rí ewu tó bá sún mọ́ wa, ìmọ́lẹ̀ tó sì tàn sí òpópónà á jẹ́ ká máa rína rí ibi tá à ń tọ̀. Lọ́rọ̀ kan, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè dáàbò bò wá kó sì pa wá mọ́ nínú ewu jálẹ̀ ìgbésí ayé wa nípa ríràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu àtèyí tó máa jẹ́ kó hàn nínú ohun gbogbo tá a bá ń ṣe pé ọmọlúwàbí ni wá, ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú.
Àpẹẹrẹ irú èyí la lè rí nínú ìwàásù tí Jésù ṣe lórí òkè. Nínú àsọyé kúkúrú yẹn, èyí tó wà nínú Mátíù orí 5 sí orí 7, níbẹ̀ ni Jésù Kristi ti sọ̀rọ̀ nípa ayọ̀, ìfẹ́, ìkórìíra, àánú, ìwà rere, àdúrà, ìlépa ọrọ̀ àti ọ̀pọ̀ kókó ọ̀rọ̀ mìíràn tó ṣe pàtàkì fún wa lónìí bó ti ṣe pàtàkì fáwọn èèyàn nígbà náà lọ́hùn-ún. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ kún fún ọgbọ́n tó jinlẹ̀ débi pé “háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.” (Mátíù 7:28) O ò kúkú ṣe wá àkókò díẹ̀ láti fi kà nípa ìwàásù náà. Ó ṣeé ṣe kó wọ ìwọ náà lọ́kàn.
“Máa Bá A Nìṣó ní Bíbéèrè” fún Ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run
Òótọ́ ni pé kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti máa ṣe ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run. Kódà, Bíbélì fi ìjàkadì lòdì sí ẹ̀ṣẹ̀ tó ń lọ ní inú wa lọ́hùn-ún wé ogun. (Róòmù 7:21-24) Àmọ́, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, a lè ṣẹ́ irú ogun bẹ́ẹ̀. Jésù ṣáà sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí . . . Nítorí pé olúkúlùkù ẹni tí ń béèrè ń rí gbà, àti olúkúlùkù ẹni tí ń wá kiri ń rí.” (Lúùkù 11:9, 10) Bẹ́ẹ̀ ni, bí ẹnikẹ́ni bá ń fi tọkàntọkàn rìn lójú ọ̀nà tóóró tó lọ síbi ìyè, Jèhófà ò ní fi onítọ̀hún sílẹ̀ láé.—Mátíù 7:13, 14.
Gbé àpẹẹrẹ ti Frank yẹ̀ wò. Sìgá ti di bárakú fún un nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn tó ti ka 2 Kọ́ríńtì 7:1 tó sì ti fẹnu ara ẹ̀ jẹ́wọ́ pé “ẹ̀gbin ti ẹran ara” ni àṣà náà já sí lójú Ọlọ́run, ó pinnu pé òun ò ní fẹnu kan sìgá mọ́. Àmọ́, kò rọrùn fún un láti mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀, tó sì ń wá àmukù sìgá tó máa mu káàkiri!
Ìwà tó ń tàbùkù síni tí Frank hù yìí gan-an ló jẹ́ kó rí i pé àṣe òun ti dẹrú sìgá. (Róòmù 6:16) Nítorí náà, ó gbàdúrà tọkàntọkàn fún ìrànlọ́wọ́, kì í pa ìpàdé jẹ kó bàa lè gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ àwọn ará nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń dara pọ̀ mọ́, kò sì mu sìgá mọ́.—Hébérù 10:24, 25.
Jẹ́ Kí Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run Máa Jẹ Ẹ́ Lọ́kàn
Ńṣe ni Frank wulẹ̀ jẹ́ ọkàn lára ọ̀pọ̀ èèyàn tí ìrírí wọn fi hàn pé ìtọ́sọ́nà tí Bíbélì ń fúnni ò láfiwé. Ìyẹn ìtọ́sọ́nà tó dá lórí ìwà tó yẹ ká máa hù àti ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìjọsìn wa àti bó ṣe yẹ ká máa fàwọn ìtọ́ni náà sílò. Abájọ nígbà náà tí Jésù fi sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.”—Mátíù 4:4.
Bá a bá ń fi òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ṣeyebíye sọ́kàn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà la máa gbà jàǹfààní. Ọpọlọ wa á silé, ọkàn wa ò ní kó sókè, àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run ò ní bà jẹ́, ara wa á sì dá ṣáṣá. Sáàmù 19:7, 8 sọ pé: “Òfin Jèhófà pé, ó ń mú ọkàn padà wá [tàbí, sọjí]. . . . Àwọn àṣẹ ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Jèhófà dúró ṣánṣán, wọ́n ń mú ọkàn-àyà yọ̀; àṣẹ Jèhófà mọ́, ó ń mú kí ojú mọ́lẹ̀ [rekete pé ìrètí ń bẹ, àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ láti ṣe sì dájú ṣáká].”
Jèhófà ń tipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe ju wíwulẹ̀ jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ka máa hù níwà, ká sì máa gbé ìgbésí ayé tó sàn jù lọ nísinsìnyí. Ó tún ń jẹ́ ká mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Aísáyà 42:9) Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí á ṣe fi hàn, ọjọ́ ọ̀la yẹn á dára fún gbogbo ẹní bá gbà kí Ọlọ́run máa darí òun.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Ohun Tó Ń Darí Ìwà Tó Ò Ń Hù
Ẹ̀rí ọkàn jẹ́ ẹ̀bùn pàtàkì kan táwa èèyàn ní. Ẹ̀rí ọkàn yìí ló máa ń mú kí àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà, tó fi mọ́ àwọn tí wọ́n ti gbé ṣáájú àkókò tá a wà yìí ní ìlànà ìwà híhù tó jọra lọ́nà tó pọ̀. (Róòmù 2:14, 15) Àmọ́ ṣá o, ẹ̀rí ọkàn wa kì í ṣe atọ́nà tí kì í kùnà. Àwọn ohun tó lè mú kó ṣini lọ́nà wà, ìyẹn àwọn bí ìgbàgbọ́ òdì tí ẹ̀sìn ń fi kọ́ni, ẹ̀kọ́ tá a gbé karí ọgbọ́n èèyàn, ẹ̀tanú àtàwọn èrò òdì. (Jeremáyà 17:9; Kólósè 2:8) Nítorí náà, bó ṣe pọn dandan pé kí awakọ̀ òfuurufú máa rí i pé òun ń tún ohun èlò tó ń tọ́ òun sọ́nà lójú òfuurufú ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí ọkàn tó ń darí ìwà tá à ń hù àti ọwọ́ tá a fi ń mú ìjọsìn Ọlọ́run, ká sì tún máa tọ́ ọ sọ́nà, kó bàa lè máa ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà òdodo Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ “Ẹni tí ń fún wa ní ìlànà àgbékalẹ̀.” (Aísáyà 33:22) Ńṣe làwọn ìlànà Ọlọ́run, tó jẹ́ ìlànà pípe máa ń wúlò títí lọ gbére, wọn ò dà bí àwọn ìlànà táwọn èèyàn ń tẹ̀ lé, èyí tó máa ń yí padà láti ìran dé ìran. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ṣáà sọ pé: “Èmi ni Jèhófà; èmi kò yí padà.”—Málákì 3:6.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
Ohun Tó Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Ṣàṣeyọrí Ká sì Tún Láyọ̀
BÁ A ṢE LÈ MÁA LÁYỌ̀
“Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.”—MÁTÍÙ 5:3.
“Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—ÌṢE 20:35.
“Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”—LÚÙKÙ 11:28.
BÓ O ṢE LÈ DẸNI TÓ ṢE É GBÁRA LÉ
“Kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.”—ÉFÉSÙ 4:25.
“Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́.” —ÉFÉSÙ 4:28.
“Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin.”—HÉBÉRÙ 13:4.
BÓ O ṢE LÈ NÍ ÀJỌṢE TÓ DÁA PẸ̀LÚ ÀWỌN ẸLÒMÍÌ
“Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”—MÁTÍÙ 7:12.
“Kí [ọkọ] máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; . . . kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”—ÉFÉSÙ 5:33.
‘Ẹ máa bá a lọ ní dídárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì.’—KÓLÓSÈ 3:13.
BÓ O ṢE LÈ MÁA YẸRA FÚN AÁWỌ̀ ÀTI BÓ O ṢE LÈ MÁA YANJÚ RẸ̀
“Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.”—RÓÒMÙ 12:17.
“Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. . . . Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 13:4, 5.
“Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú.”—ÉFÉSÙ 4:26.