Ọ̀nà 3
Lo Àṣẹ Rẹ Gẹ́gẹ́ Bí Òbí
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì? Ìwádìí fi hàn pé “àwọn òbí kan wà tí wọ́n jẹ́ onífẹ̀ẹ́, ṣùgbọ́n tí wọn ò gbàgbàkugbà, ìyẹn ni pé wọn kì í fọ̀rọ̀ àwọn ọmọ wọn ṣeré, síbẹ̀ wọn ò gba gbẹ̀rẹ́. Irú ọmọ táwọn òbí bẹ́ẹ̀ bá tọ́ máa ń ṣe dáadáa nílé ìwé, wọn máa ń lè bẹ́gbẹ́ pé, wọ́n máa ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, wọ́n sì máa ń láyọ̀ ju àwọn ọmọ táwọn òbí wọn ń gbọ̀jẹ̀gẹ́ tàbí tí wọ́n le koko jù,” gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Parents tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn òbí ṣe sọ.
Ìṣòro tó wà ńbẹ̀: Láti kékeré títí dìgbà táwọn ọmọ á fi fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ogún ọdún, wọn ò ní yé máa wá ọgbọ́n tí wọ́n fi lè máa tàpá sí àṣẹ ẹ̀yin tẹ́ ẹ jẹ́ òbí wọn kí wọ́n bàa lè ṣe bí wọ́n ṣe fẹ́. Ọ̀gbẹ́ni John Rosemond, tó ṣe ìwé Parent Power!, tó dá lórí àṣẹ òbí lórí ọmọ, sọ pé: “Àwọn ọmọ tètè máa ń mọ̀ bí ẹ̀rù bá ń ba àwọn òbí wọn láti lo àṣẹ wọn g̣ẹ́gẹ́ bí òbí, wọ́n sì máa ń mọ ìgbà tó ṣeé ṣe kí wọ́n fàyè gbà wọ́n. Tó bá dọ̀rọ̀, ‘Àṣẹ ta ló máa ṣẹ nínú ilé?’ àfi káwọn òbí yáa tètè fìdí àṣẹ wọn gẹ́gẹ́ bí òbí múlẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwọn ọmọ á gbà á mọ́ wọn lọ́wọ́.”
Ohun tó lè ràn yín lọ́wọ́: Má ṣe jẹ́ kó máa ṣe ẹ́ bíi pé àwọn ọmọ ẹ á máa sá fún ẹ tàbí pé wàá bà wọ́n lọ́kàn jẹ́ bó o bá ń lo àṣẹ rẹ gẹ́gẹ́ bí òbí. Jèhófà Ọlọ́run tó dá ètò ìdílé sílẹ̀ ò ní í lọ́kàn pé káwọn ọmọ àtàwọn òbí jọ máa du àṣẹ mọ́ra wọn lọ́wọ́ nínú ilé. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn òbí ló gbé àṣẹ lé lọ́wọ́ pé kí wọ́n máa darí àwọn ọmọ wọn. Ó sọ fáwọn ọmọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín.”—Éfésù 3:14, 15; 6:1-4.
Ẹ lè lo àṣẹ yín gẹ́gẹ́ bí òbí láì le koko ju bó ṣe yẹ lọ. Ọ̀nà wo lẹ lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Nípa títẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà ni. Ó lágbára láti fipá mú àwa èèyàn tá a jẹ́ ọmọ rẹ̀ láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀, síbẹ̀ ńṣe ló máa ń pẹ̀tù sí wa nínú nípa yíyìn wá bá a bá ṣe ohun tó dáa. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò.” (Aísáyà 48:18) Jèhófà ò fẹ́ kó jẹ́ pé ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì lá á mú ká máa ṣègbọràn sóun, bí kò ṣe ìfẹ́ tá a ní fún un. (1 Jòhánù 5:3) Kò béèrè ohun tó ju agbára wa lọ lọ́wọ́ wa, ó sì mọ̀ pé fún àǹfààní tara wa náà ni bá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó gbé kalẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká máa hùwà.—Sáàmù 19:7-11.
Báwo lo ṣe lè nígboyà tó o fi máa lè lo àṣẹ rẹ gẹ́gẹ́ bí òbí lọ́nà tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì? Àkọ́kọ́, ó gbọ́dọ̀ dá ẹ lójú pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó o ṣe nìyẹn. Èkejì, ó gbọ́dọ̀ dá ẹ lójú pé ohun tó dáa jù lọ fún ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ ni pé kẹ́ ẹ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ka máa hùwà.—Róòmù 12:2.
Àwọn nǹkan wo gan-an lo gbọ́dọ̀ ṣe kó o bàa lè máa lo àṣẹ rẹ gẹ́gẹ́ bí òbí?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 23]
“Bá àwọn ọmọ rẹ wí, wọn . . . yóò sì mú ọkàn rẹ yọ̀.”—Òwe 29:17, Bíbélì New Revised Standard Version