ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 10/07 ojú ìwé 26
  • Máa Gbọ́ Àwọn Ọmọ Ẹ Lágbọ̀ọ́yé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Gbọ́ Àwọn Ọmọ Ẹ Lágbọ̀ọ́yé
  • Jí!—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Lo Ṣe Lè Borí Èrò Òdì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Ní Láárí
    Jí!—1997
  • Ẹ̀yin Òbí Àtẹ̀yin Ọmọ, Ẹ Máa Fìfẹ́ Bá Ara Yín Sọ̀rọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ẹ̀yin Òbí—ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Tìfẹ́tìfẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Jí!—2007
g 10/07 ojú ìwé 26

Ọ̀nà 6

Máa Gbọ́ Àwọn Ọmọ Ẹ Lágbọ̀ọ́yé

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì? Àwọn ọmọ máa ń fẹ́ káwọn tó ṣe pàtàkì jù lọ sáwọn, ìyẹn àwọn obí wọn, máa gbọ́ wọn lágbọ̀ọ́yé. Bó bá ti dàṣà àwọn òbí láti máa ta ko àwọn ọmọ nígbàkigbà tí wọ́n bá sọ bí nǹkan ṣe rí lọ́kàn wọn, agbára káká làwọn ọmọ á fi máa fẹ́ láti sọ tinú wọn, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì pé bóyá làwọn lè dánú rò, àti pé bóyá làwọn lè mọ bó ṣe ń ṣe àwọn.

Ìṣòro tó wà ńbẹ̀: Nígbà táwọn ọmọdé bá ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn, wọ́n sábà máa ń sọ ọ́ ní àsọdùn. Òótọ́ sì ni pé díẹ̀ lára ohun táwọn ọmọ máa ń sọ kì í fàwọn òbí lọ́kàn balẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ kan tí gbogbo nǹkan ti tojú sú lè sọ pé, “Ayé ti sú mi jọ̀ọ́.”a Báwọn òbí náà á bá sì fèsì, wọ́n lè sọ pé: “Áà, o ò ní kí Ọlọ́run máà jẹ́ káyé sú ẹ!” Àwọn òbí lè máa ṣe kàyéfì pé báwọn bá gbà pé bí ọmọ ṣe sọ̀rọ̀ gan-an lọ̀rọ̀ rí, ńṣe ló máa dà bí ìgbà táwọn ń bá irú ọmọ bẹ́ẹ̀ pọ́n jẹ̀bẹ̀ lákìísà.

Ohun tó lè ràn yín lọ́wọ́: Ìmọ̀ràn Bíbélì tẹ́ ẹ ó máa fi sílò lèyí tó sọ pé, “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Kíyè sí i pé Jèhófà Ọlọ́run gan-an gbà pé àwọn nǹkan kan wà tó máa ń mu àwọn ìránṣẹ́ òun tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ lómi, ìyẹn ló ṣe jẹ́ kí wọ́n kọ ọ́ sílẹ̀ nínú Bíbélì. (Jẹ́nẹ́sísì 27:46; Sáàmù 73:12, 13) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àdánwò tó gọntíọ kojú Jóòbù, ó sọ pé ó sàn fóun láti kú ju kóun wà láàyè.—Jóòbù 14:13.

Ó dájú gbangba pé Jóòbù sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tó kù díẹ̀ káàtó. Àmọ́, dípò kí Jèhófà dá ọ̀rọ̀ mọ́ Jóòbù lẹ́nu pé kò rí bó ṣe sọ ọ́, ńṣe ló fọ̀wọ̀ Jóòbù wọ̀ ọ́ nípa bó ṣe fara balẹ̀ jẹ́ kó sọ tinú rẹ̀ jáde. Lẹ́yìn tí Jèhófà ti jẹ kó sọ tẹnu rẹ̀ tán, ló tó wá tún èrò rẹ̀ ṣe. Irú èyí ló mú kí baálé ilé kan tó jẹ́ Kristẹni sọ pé, “Níwọ̀n bí Jèhófà ti máa ń yọ̀ǹda fún mi láti sọ èrò mi jáde fóun nínú àdúrà, mo lérò pé ìwà ìrẹ́jẹ gbáà ni bí èmi pẹ̀lú ò bá yọ̀ǹda fáwọn ọmọ mi láti máa sọ tinú wọn fún mi, yálà rere tàbí búburú.”

Torí náà, nígbà míì tó bá ṣe ẹ́ bíi kó o sọ fọ́mọ ẹ pé, “Ọ̀rọ̀ ò rí bó o ṣe sọ ọ́ yẹn” tàbí “Mo rò pé o ò mọ ohun tó ò ń sọ ṣá,” rántí ọ̀rọ̀ Jésù náà pé: “Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.” (Lúùkù 6:31) Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká sọ pé bóyá nítorí àṣìṣe kan tó o ṣe, àwọn kan ti dà ẹ́ ríborìbo níbi iṣẹ́ tàbí kí wọ́n ti ṣe ohun tó ò lérò pé wọ́n lè ṣe. Lo bá sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ fún ọ̀rẹ́ rẹ kan, o sì tún wá fi kún un pé ọ̀rọ̀ ibi iṣẹ́ náà ti sú ẹ. Kí ni wàá retí pé kí ọ̀rẹ́ rẹ ṣe? Ṣé wàá retí pé kó sọ fún ẹ pé ọ̀rọ̀ ò rí bó o ṣe sọ ọ́ yẹn, kó sì yára máa fi hàn ẹ́ pé ọwọ́ ẹ ni ẹ̀bi gbogbo ọ̀rọ̀ náà wà? Àbí ṣe ni wàá fẹ́ kí ọ̀rẹ́ ẹ náà sọ pé: “Ìyẹn mà dẹ̀ ga o. Ìwọ gan-an là bá máa kí kú ìrọ́jú”?

Kò síyè méjì pé àtọmọdé àtàgbà ló máa gba ìmọ̀ràn bí wọ́n bá rí i pé ẹni tó ń fáwọn nímọ̀ràn lóye ohun tó ń ṣe àwọn àti pé ìṣòro táwọn ń dojú kọ yé e. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ọkàn-àyà ọlọ́gbọ́n ń mú kí ẹnu rẹ̀ fi ìjìnlẹ̀ òye hàn, èyí sì ń fi ìyíniléròpadà kún ètè rẹ̀.”—Òwe 16:23.

Báwo lo ṣe lè máa rí i dájú pé ẹni tó o fún nímọ̀ràn fọwọ́ pàtàkì mú un?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Báwọn ọmọ ẹ bá sọ pẹ́nrẹ́n pé àwọn á gbẹ̀mí ara àwọn, má ṣe fọwọ́ kékeré mú ohun tí wọ́n sọ o.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 26]

“Nígbà tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀ràn kí ó tó gbọ́ ọ, èyíinì jẹ́ ìwà òmùgọ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ àti ìtẹ́lógo.”—Òwe 18:13

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́