Ọ̀nà 7
Jẹ́ Káwọn Ọmọ Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Lára Ẹ
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì? Ọ̀rọ̀ táwọn òbí ń sọ fáwọn ọmọ ní àyè tirẹ̀, àmọ́ nínú ìwà táwọn òbí bá ń hù làwọn ọmọ ti máa ń rí ẹ̀kọ́ kọ́ jù lọ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí lè sọ fáwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fáwọn ẹlòmíì kí wọ́n sì máa sọ òtítọ́. Àmọ́, báwọn òbí yìí kan náà bá ń pariwo léra wọn lórí tàbí tí wọ́n ń lọgun lé àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n sì ń purọ́ kí wọ́n bàa lè yọ ọrùn ara wọn kúrò nínú ohun tí wọ́n bá rí i pé kò rọrùn fáwọn láti ṣe, ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ kọ́ àwọn ọmọ wọn ni pe bó ṣe yẹ káwọn àgbà máa hùwà nìyẹn. Káwọn ọmọ máa fara wé àwọn òbí ni “ọ̀kan lára ọ̀nà tó lágbára jù lọ tí wọ́n ń gbà kẹ́kọ̀ọ́,” gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé kan, ìyẹn Dókítà Sal Severe ṣe sọ.
Ìṣòro tó wà ńbẹ̀: Aláìpé làwọn òbí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Lórí ọ̀ràn pé ká máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ tó ń tẹnu wa jáde, Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn kọ̀wé pé: “Ahọ́n, kò sí ẹnì kan nínú aráyé tí ó lè rọ̀ ọ́ lójú.” (Jákọ́bù 3:8) Láfikún sí ìyẹn, ó wọ́pọ̀ pé káwọn ọmọ máa tán àwọn òbí wọn ní sùúrù. Èèyàn jẹ́jẹ́ tó sì mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ ni Larry, ó sì tún jẹ́ bàbá àwọn ọmọbìnrin méjì. Ó sọ pé: “Ó máa ń yà mí lẹ́nu báwọn ọmọ mi ṣe tètè máa ń múnú bí mi.”
Ohun tó lè ràn yín lọ́wọ́: Gẹ́gẹ́ bí òbí, àpẹẹrẹ rere ni kẹ́ ẹ sapá láti jẹ́, kì í ṣe àpẹẹrẹ pípé. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tẹ́ ẹ bá sì ṣìwà hù, ẹ máa lò ó gẹ́gẹ́ bí àǹfààní láti kọ́ àwọn ọmọ yín lẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe kókó. Chris, tó jẹ́ bàbá àwọn ọmọbìnrin méjì sọ pé: “Bí mo bá bínú sáwọn ọmọ mi tàbí tí mo bá ṣe ìpinnu tí kò tù wọ́n lára, mo máa ń gbà pé mo ti ṣe àṣìṣe, màá sì bẹ̀ wọ́n. Èyí jẹ́ káwọn ọmọ mi mọ̀ pé àwọn òbí náà lè ṣe àṣìṣe àti pé gbogbo wa ló yẹ ká sapá kí ìwà wa bàa lè sunwọ̀n sí i.” Kostas, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, sọ pé: “Mo ti rí i pé nítorí pé mo máa ń tọrọ àforíjì nígbà tínú bá bí mi, àwọn ọmọ mi obìnrin ti kọ́ láti máa tọrọ àforíjì nígbà táwọn náà bá ṣe àṣìṣe.”
Jèhófà Ọlọ́run sọ pé: “Ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Nígbà tí ẹni tó wà nípò àṣẹ bá ń ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ohun tó ń sọ, tọmọdé tàgbà nìyẹn máa ń bí nínú. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó máa bí àwọn ọmọdé nínú ju àwọn àgbà lọ. Nítorí náà, lópin ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, o ò ṣe máa bí ara ẹ láwọn ìbéèrè bíi: Ká tiẹ̀ ni mi ò sọ gbólóhùn ọ̀rọ̀ kankan láti òwúrọ̀ títí ṣúlẹ̀, ẹ̀kọ́ wo làwọn ọmọ mi lè rí kọ́ nínú ìwà tí mò ń hù? Ṣé ẹ̀kọ́ tí mò ń kọ́ wọn bí mo bá ń bá wọn sọ̀rọ̀ náà nìyẹn?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]
“Ǹjẹ́ ìwọ, . . . ẹni tí ń kọ́ ẹlòmíràn, kò kọ́ ara rẹ?” —Róòmù 2:21
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Bí òbí ọmọ bá ń tọrọ àforíjì, ọmọ ẹ̀ náà á máa tọrọ àforíjì