ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/08 ojú ìwé 16-18
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Bára Mi Ò Bá Yá?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Bára Mi Ò Bá Yá?
  • Jí!—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jí!: Kí ló máa ń nira jù fún ẹ nínú ìṣòro tó o ní?
  • Jí!: Àwọn ìṣòro míì wo lo tún máa ń ní?
  • Jí!: Kí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹ láti máa bá ìṣòro rẹ yí?
  • Jí!: Ọ̀nà wo làwọn míì ti gbà fún ẹ níṣìírí?
  • Jí!: Kí ló ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣe sọ̀rètí nù?
  • ‘Inú Rere àti Ìṣòtítọ́ Tẹ́nì Kan Fi Hàn’
    Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Kí Nìdí Tí Mo Fi Ń Ṣàìsàn Tó Báyìí?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Kó Sọ́wọ́ Àwọn Tó Ń Fipá Báni Lò Pọ̀?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìfipá-Báni-Lòpọ̀?
    Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 4/08 ojú ìwé 16-18

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Ni Mo Lè Ṣe Bára Mi Ò Bá Yá?

“ẸWÀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn.” Ohun tí ìwé Òwe 20:29 sọ nìyẹn. Bí ara rẹ ò bá yá tàbí o ní àbùkù ara, o lè rò pé irú èèyàn bíi tìẹ kọ́ ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn ń sọ. Àmọ́, kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀! Ibi tọ́rọ̀ náà tiẹ̀ wà ni pé, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó lábùkù ara tàbí tí wọ́n ń ṣàìsàn tó le gan-an ti borí àwọn ìṣòro tó ga bí òkè. Jí! fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu mẹ́rin lára irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀.

Látìgbà tí wọ́n ti bí Hiroki tó wà lórílẹ̀-èdè Japan ló ti ní àrùn tí kì í jẹ́ kéèyàn séra ró, tí kì í sì í jẹ́ kéèyàn lè sọ̀rọ̀ dáadáa, ìyẹn cerebral palsy. Ó sọ pé: “Iṣan ọrùn mi ò lè gbé orí mi dúró, òdì kejì ohun tí mo bá sì fẹ́ kọ́wọ́ mi ṣe ló máa ń ṣe. Ńṣe ni wọ́n ń gbé mi ṣu gbé mi tọ̀.”

Orílẹ̀-èdè South Africa ni Natalie àti àbúrò rẹ̀ James wà , àmọ́ aràrá ni wọ́n, irú aràrá bíi tiwọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀. Natalie tún ní àrùn tó máa ń ba ọ̀pá ògóóró ẹ̀yìn jẹ́ ìyẹn, scoliosis. Ó sọ pé: “Wọ́n ti ṣiṣẹ́ abẹ́ ògóóró ẹ̀yìn fún mi nígbà mẹ́rin, àmọ́ nítorí pé ọ̀pá ẹ̀yìn mi tẹ̀ kọdọrọ, ẹ̀dọ̀fóró mi ò ṣiṣẹ́ dáadáa.”

Ìlú Britain ni Timothy wà. Ìgbà tó ti pọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni àyẹ̀wò ti fi hàn pé ó ní àrùn tó máa ń mú kó rẹni, tó máa ń mú kéèyàn wò sùn-ùn, kó má sì rí oorun sùn. Ó sọ pé: “Oṣù méjì ò tíì pé lẹ́yìn àyẹ̀wò náà tí ara mi tó jí pépé fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòjòjò débi pé mi ò lè dá dúró mọ́.”

Àyẹ̀wò fi hàn pé Danielle, tó wà nílẹ̀ Ọsirélíà, ní àrùn àtọ̀gbẹ nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún. Ó sọ pé: “Níwọ̀n bí kì í ti í hàn lójú pé àrùn àtọ̀gbẹ ń ṣèèyàn, àwọn kan ò mọ bó ṣe burú tó. Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé àrùn àtọ̀gbẹ lè pa mí.”

Bí ìwọ náà bá ní àbùkù ara tàbí bó bá jẹ́ pé irú àìsàn kan ń ṣe ẹ́, kò síyè méjì pé ọ̀rọ̀ tí Hiroki, Natalie, Timothy àti Danielle sọ á tù ẹ́ nínú. Bí ara tìẹ bá sì jí pépé, ọ̀rọ̀ wọn lè mú kó o túbọ̀ lóye bí nǹkan ṣe ń rí lára àwọn tó ní àbùkù ara tàbí tí wọ́n ń kojú àìsàn.

Jí!: Kí ló máa ń nira jù fún ẹ nínú ìṣòro tó o ní?

Natalie: Ní tèmi, báwọn èèyàn ṣe máa ń ṣe bí wọ́n bá rí mi ni ohun tó máa ń ṣòro fún mi láti mú mọ́ra. Kì í jẹ́ kára rọ̀ mí. Ó máa ń ṣe mí bíi pé èmi làwọn èèyàn ń wò ní gbogbo ìgbà ṣáá.

Danielle: Ní ti àrùn àtọ̀gbẹ tí mo ní yìí, olórí ìṣòro mi ni bí mo ṣe máa mọ ohun tí mo gbọ́dọ̀ jẹ, ìwọ̀n tí mo gbọ́dọ̀ jẹ, àtàwọn oúnjẹ tí mo gbọ́dọ̀ dín jíjẹ wọn kù. Bí mo bá ń jẹ irú oúnjẹ kan ní àjẹjù tàbí tí mi ò bá jẹ ẹ́ tó, ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀ mi á dín kù, ìyẹn sì lè jẹ́ kí n dákú lọ gbári.

Hiroki: Kẹ̀kẹ́ kan wà tí wọ́n dìídì ṣe fún mi, wákàtí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni mo sì fi máa ń jókòó sórí ẹ̀ lóòjọ́ láìlè yíra padà. N kì í sì í rí oorun sùn dáadáa. Bí nǹkan bá rọra sún kẹ́rẹ́ báyìí, mo ti ta jí.

Timothy: Ó kọ́kọ́ máa ń ṣòro fún mi gan-an láti gbà pé ara mi ò yá. Ipò tí mo wà máa ń mú kójú tì mí gan-an.

Jí!: Àwọn ìṣòro míì wo lo tún máa ń ní?

Danielle: Àrùn àtọ̀gbẹ máa ń mú kó rẹ̀ mí gan-an. Ó sì pọn dandan pé kí n máa sun oorun tó pọ̀ ju tàwọn tá a jọ jẹ́gbẹ́ lọ. Àti pé, àìsàn líle tí kò gbóògùn ni àrùn àtọ̀gbẹ.

Natalie: Ní tèmi, ìṣòro gbáà ni bí mo ṣe kúrú jẹ́ fún mi. Bí mo bá lọ rajà lásán, ọwọ́ mi kì í tó orí àtẹ. Wàhálà gbáà ló máa ń jẹ́ fún mi bí mo bá dá lọ.

Timothy: Ojoojúmọ́ ni mò ń fara da ìrora, àìmọye ìgbà sì ni mo máa ń sorí kọ́. Kí àìsàn yìí tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe mí, koko lara mi le. Mo níṣẹ́ lọ́wọ́, mo sì níwèé àṣẹ ìwakọ̀. Mo máa ń ṣeré ìdárayá bíi gbígbá bọ́ọ̀lù ẹlẹ́sẹ̀ àti aláfigigbá. Àmọ́, orí àga arọ ni mo wà báyìí.

Hiroki: Ọ̀rọ̀ sísọ ni ìṣòro tèmi. Ìṣòro yìí máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi, kì í sì í jẹ́ kí n fẹ́ láti dá ọ̀rọ̀ sísọ sílẹ̀. Nígbà míì sì rèé, ọwọ́ mi máa ń ṣàdédé jù fìrì táá sì ṣèèṣì gbá ẹlòmíì. Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, àtisọ pé “máà bínú,” á tún dọ̀ràn torí ìṣòro tí kì í jẹ́ kí n lè sọ̀rọ̀.

Jí!: Kí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹ láti máa bá ìṣòro rẹ yí?

Danielle: Mo máa ń gbìyànjú láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan rere tó ń ṣẹlẹ̀ sí mi lójoojúmọ́. Àwọn èèyàn mi máa ń fún mi láyọ̀, mo láwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n fẹ́ràn mi dénú nínú ìjọ, ju gbogbo ẹ̀ lọ, Jèhófà Ọlọ́run ń tì mí lẹ́yìn. Mo tún máa ń ka àwọn ìsọfúnni tọ́wọ́ mi bá tẹ̀ lórí àrùn àtọ̀gbẹ àti bí mo ṣe lè máa tọ́jú ara mi. Mo gbà pé kì í dé báni ká yẹrí, mo sì ń sa gbogbo ipá mi láti tọ́jú ara mi.

Natalie: Àdúrà máa ń fún mi lókun. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ni mo máa ń bójú tó àwọn ìṣòro mi. N kì í ráyè ro èròkerò torí pé mo máa ń jẹ́ kọ́wọ́ mi dí fún iṣẹ́. Mo sì láwọn òbí tó ṣeé fọ̀rọ̀ lọ̀.

Timothy: Ojoojúmọ́ ni mo máa ń ṣe ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn mi sí Jèhófà, ì báà tiẹ̀ jẹ́ fún àkókò díẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ ni mo kọ́kọ́ máa ń kà lárààárọ̀. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àdúrà ṣe pàtàkì fún mi, pàápàá nígbà tí mo bá rẹ̀wẹ̀sì.

Hiroki: Mo máa ń gbìyànjú kí n má ṣe da ara mi láàmú lórí ohun tí agbára mi ò ká. Bí ẹní ń fàkókò ṣòfò nìyẹn máa jẹ́. Dípò ìyẹn, mo máa ń ṣe gbogbo ohun tí mo bá lè ṣe láti mú kí àjọṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run túbọ̀ lágbára, n kì í sì í fi àìsàn mi kẹ́wọ́ láti má ṣe kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí oorun ò bá kùn mí, àǹfààní ló máa ń jẹ́ fún mi láti gbàdúrà.—Wo Róòmù 12:12.

Jí!: Ọ̀nà wo làwọn míì ti gbà fún ẹ níṣìírí?

Hiroki: Gbogbo ìgbà làwọn alàgbà máa ń yìn mí fún ìwọ̀nba tágbára mi bá ká láti ṣe. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú ìjọ tún máa ń mú mi lọ síbi ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn.—Wo Róòmù 12:10.

Danielle: Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ohun tó máa ń wọ̀ mí lọ́kàn jù lọ ni ìgbà táwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú ìjọ bá yìn mí látọkàn wá. Ìyẹn máa ń mú kí n mọ̀ pé wọ́n mọrírì mi, ó sì máa ń ràn mí lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó.

Timothy: Arábìnrin àgbàlagbà kan wà tó máa ń sapá gidigidi láti bá mi sọ̀rọ̀ láwọn ìpàdé. Mo ti rí ìṣírí àti ìmọ̀ràn tó wúlò gbà látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà àtàwọn ìyàwó wọn. Alàgbà kan, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, ti ràn mí lọ́wọ́ láti ní àwọn àfojúsùn tọ́wọ́ mi lè tẹ̀. Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan ní kí n jẹ́ ká jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, ó sì ṣètò pé ká jọ ṣiṣẹ́ níbi tí ilẹ̀ ti tẹ́jú, tí àga arọ tí mò ń lò á ti lè rìn geerege.—Wo Sáàmù 55:22.

Natalie: Bí mo bá ti ń wọnú Gbọ̀ngàn Ìjọba làwọn ará nínú ìjọ á ti máa fọ̀yàyà kí mi. Ìgbà gbogbo làwọn tó jẹ́ àgbà lára wọn máa ń rí ọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró sọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn náà ní ibi tí bàtà ti ń ta wọ́n lẹ́sẹ̀.—Wo 2 Kọ́ríńtì 4:16, 17.

Jí!: Kí ló ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣe sọ̀rètí nù?

Hiroki: Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn èèyàn tó ń láyọ̀ nítorí ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fún wọn lọ́jọ́ iwájú ni mò ń dara pọ̀ mọ́. Mímọ̀ tí mo mọ̀ pé mo jẹ́ ọ̀kan lára wọn máa ń ràn mí lọ́wọ́ láti má ṣe rẹ̀wẹ̀sì.—Wo 2 Kíróníkà 15:7.

Danielle: Mo máa ń ronú nípa àǹfààní tí mo ní láti lóye àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe. A ráwọn tí ara wọn le, síbẹ̀ ìgbésí ayé wọn ò tẹ́ wọn lọ́rùn tó tèmi.—Wo Òwe 15:15.

Natalie: Mo rí i pé ó ṣe pàtàkì fún mi láti máa báwọn èèyàn tó lọ́yàyà kẹ́gbẹ́. Mo máa ń ka ìrírí àwọn ẹlòmíì tí wọ́n ń sin Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń dojú kọ àdánwò, ìyẹn sì máa ń gbé mi ró. Bí mo bá sì lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, mo mọ̀ pé màá rí ohun tó máa gbé mi ró, màá sì rántí pé àǹfààní ńlá ni láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Wo Hébérù 10:24, 25.

Timothy: Gẹ́gẹ́ bí 1 Kọ́ríńtì 10:13 ṣe sọ, Jèhófà ò ní jẹ́ kí ohun tó ju agbára wa lọ ṣẹlẹ̀ sí wa. Ní tèmi o, bó bá dá Ẹlẹ́dàá mi lójú pé mo lè kojú àdánwò yìí, mi ò ní jà á níyàn rárá.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Orí àga arọ ni Hiroki àti Timothy wà. Bó bá jẹ́ pé orí àga arọ nìwọ náà wà, báwo lohun tí wọ́n sọ ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣe rẹ̀wẹ̀sì?

◼ Danielle sọ pé, “níwọ̀n bí kì í ti í hàn lójú pé àrùn àtọ̀gbẹ ń ṣèèyàn, àwọn kan ò mọ bó ṣe burú tó.” Ṣé àìsàn kan tí kì í hàn lójú ń ṣe ìwọ náà? Bírú àìsàn bẹ́ẹ̀ bá ń ṣe ẹ́, kí lo lè rí kọ́ látinú ọ̀rọ̀ tí Danielle sọ?

◼ Natalie sọ pé ọ̀kan lára ohun tó máa ń dun òun jù lọ ni báwọn èèyàn ṣe máa ń ṣe bí wọ́n bá rí òun. Báwo lo ṣe lè dá ẹnì kan bíi Natalie lọ́kàn le? Bó o bá ń ṣàìsàn tàbí tó o bá ní àbùkù ara tó ń mú kó o máa ronú bíi ti Natalie, báwo lo ṣe lè fara wé e kó o má bàa rẹ̀wẹ̀sì?

◼ Kọ orúkọ àwọn tó o mọ̀ pé wọ́n ní àbùkù ara tàbí tí wọ́n ń ṣàìsàn líle koko sínú àlàfo yìí.

․․․․․

◼ Báwo lo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?

․․․․․

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

Ìtùnú Látinú Bíbélì

◼ Jésù fi àánú gidigidi hàn sáwọn tó ń ṣàìsàn.—Máàkù 1:41.

◼ Wíwò tí Jésù wo “gbogbo onírúurú òkùnrùn àti gbogbo onírúurú àìlera ara” sàn, jẹ́ àpẹẹrẹ pé ó máa wo àwọn èèyàn sàn nínú Ìjọba Ọlọ́run.—Mátíù 4:23.

◼ Nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí,’” kò sì ní sí ìrora mọ́.—Aísáyà 33:24; Ìṣípayá 21:1-4.

◼ Ọlọ́run á sọ ikú pàápàá di “asán.”—1 Kọ́ríńtì 15:25, 26.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Hiroki, ọmọ ọdún 23, láti Japan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Natalie, ọmọ 20 ọdún, láti South Africa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Timothy, ọmọ 20 ọdún, láti Britain

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Danielle, ọmọ ọdún 24, láti Ọsirélíà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́