ORÍ 32
Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Kó Sọ́wọ́ Àwọn Tó Ń Fipá Báni Lò Pọ̀?
Lọ́dọọdún, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni wọ́n máa ń fipá bá lò pọ̀ tàbí kí wọ́n bá wọn ṣèṣekúṣe, ìwádìí sì fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́ ni àwọn oníṣekúṣe bẹ́ẹ̀ máa ń fojú sí lára. Bí àpẹẹrẹ, àwọn olùwádìí kan sọ pé ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìdajì àwọn tí wọ́n fipá bá lò pọ̀ ni kò tíì tó ọmọ ọdún méjìdínlógún [18]. Torí bí ọ̀ràn ìṣekúṣe ṣe gbòde kan yìí, ó ṣe pàtàkì pé kó o mọ̀ nípa kókó yìí.
“Ó gbá mi mú, kí n tó mọ̀, ó ti fẹ̀yìn mi balẹ̀. Mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe kí n lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Mo gbìyànjú láti pariwo, àmọ́ ohùn mi ò jáde. Mo tì í, mo ta á nípàá, mo sì ha á léèékánná. Ó wá fọ̀bẹ ya mí lára. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ṣe ló rẹ̀ mí wá wọ̀ọ̀.”—Annette.
ÀWỌN tó máa ń bá àwọn èèyàn ṣèṣekúṣe ti gbòde kan báyìí, àwọn ọ̀dọ́ ló sì sábà máa ń kó sọ́wọ́ wọn jù. Àjèjì ló máa ń fipá bá àwọn ọ̀dọ́ kan ṣèṣekúṣe, bó ṣe rí fún Annette. Aládùúgbò ló sì máa ń bá àwọn míì ṣèṣekúṣe. Bọ́ràn ṣe rí nìyẹn fún ọmọbìnrin tó ń jẹ́ Natalie, tí ọ̀dọ́ kan tó ń gbé nítòsí ilé wọn bá ṣèṣekúṣe nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá péré. Ó sọ pé: “Ẹ̀rù bà mí, ojú sì tì mí gan-an tó fi jẹ́ pé mi ò lè sọ fún ẹnikẹ́ni nígbà tó kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀.”
Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló jẹ́ pé ẹnì kan nínú ìdílé wọn ló bá wọn ṣèṣekúṣe. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Carmen sọ pé: “Nígbà tí mo wà láàárín ọmọ ọdún márùn-ún sí méjìlá ni dádì mi ti máa ń bá mi ṣèṣekúṣe. Nígbà tí mo di ọmọ ogún [20] ọdún, mo sọ fún wọn pé ohun tí wọ́n ṣe fún mi kò dára. Wọ́n ní kí n máà bínú, àmọ́ lẹ́yìn oṣù mélòó kan, ṣe ni wọ́n lé mi jáde kúrò nílé.”
Ó túbọ̀ ń kọni lóminú bí àwọn aládùúgbò, àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ará ilé tó ń fipá bá àwọn tó sún mọ́ wọn ló pọ̀ ṣe gbòde kan lóde òní.a Àmọ́ kì í ṣe òní làwọn èèyàn ti ń han àwọn ọmọdé léèmọ̀. Kódà irú ìwàkíwà bẹ́ẹ̀ wáyé lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. (Jóẹ́lì 3:3; Mátíù 2:16) Àwọn àkókò lílekoko la wà yìí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò ní “ìfẹ́ni àdánidá,” ó sì túbọ̀ ń wọ́pọ̀ pé kí wọ́n máa fọgbọ́n tan àwọn ọmọbìnrin (àtàwọn ọmọkùnrin pàápàá) láti bá wọn ṣèṣekúṣe. (2 Tímótì 3:1-3) Òótọ́ ni pé béèyàn bá tiẹ̀ ṣọ́ ara rẹ̀, ìyẹn kò ní kéèyàn bọ́ pátápátá lọ́wọ́ àwọn tó ń fipá báni lò pọ̀, síbẹ̀ àwọn nǹkan kan wà tó o lè ṣe láti dáàbò bo ara rẹ. Wo àwọn ìmọ̀ràn yìí ná:
Ṣọ́ra. Tó o bá ń jáde nílé, kíyè sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níwájú rẹ, lẹ́yìn rẹ, àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì. Àwọn àgbègbè kan léwu gan-an, pàápàá lọ́wọ́ alẹ́. Tó bá ṣeé ṣe, yẹra fún àwọn àgbègbè bẹ́ẹ̀, tàbí kó o rí i pé kì í ṣe ìwọ nìkan lo dá gba ibẹ̀.—Òwe 27:12.
Má ṣe ohun tó máa kó ẹ sí wàhálà. Má ṣe máa tage, má sì wọṣọ tó máa fún mọ́ ẹ lára pinpin. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú káwọn èèyàn rò pé o nífẹ̀ẹ́ sí ìbálòpọ̀, tàbí pé o ò ní kọ̀ bí wọ́n bá fi lọ̀ ẹ́.—1 Tímótì 2:9, 10.
Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o ò gbàgbàkugbà láyè. Tó o bá lẹ́ni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra sọ́nà, ẹ jọ jíròrò àwọn ìwà tó yẹ àtèyí tí kò yẹ́.b Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jọ gbà pé ẹ ò ní gbàgbàkugbà láyé, ṣọ́ra fún àwọn ipò tó lè mú kó o dẹni tó lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe.—Òwe 13:10.
Má kàn dákẹ́. Kò sí ohun tó burú nínú kó o pariwo mọ́ ẹni náà pé, “Máà dán an wò!” tàbí “Mọ́wọ́ ẹ kúrò lára mi!” Má ṣe bẹ̀rù pé ẹni tó ò ń fẹ́ yẹn lè bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́ kó o wá torí ìyẹn gbà fún un. Tó bá sọ pé òun ò fẹ́ ẹ mọ́ torí pé o kò gbà fún òun, a jẹ́ pé kì í ṣe ẹni tó yẹ́ kó o fẹ́ nìyẹn! Ó ṣe tán, ọkùnrin tó jẹ́ èèyàn dáadáa lo máa fẹ́ fẹ́, ìyẹn ẹni tó máa fọ̀wọ̀ ẹ wọ̀ ẹ́, táá sì bọ̀wọ̀ fún ìlànà ìwà rere tó ò ń tẹ̀ lé.c
Ṣọ́ra bó o bá ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Má ṣe gbé àwọn ìsọfúnni tàbí àwọn fọ́tò ẹ tó máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ ibi tó o wà sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.d Bí ẹnì kan bá fi ọ̀rọ̀ tó lè mú kí ọkàn ẹ fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ sí ẹ, ohun tó dára jù ni pé kó o má ṣe fèsì. Àwọn tó máa ń fẹ́ bá àwọn tí wọ́n bá bá pàdé lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣèṣekúṣe kò ní lè ṣe ẹ́ ní nǹkan kan tí wọn kò bá rí èsì gbà.
Àwọn ìmọ̀ràn tá a sọ tán yìí kò ní jẹ́ kó o lè kó sọ́wọ́ àwọn tó ń báni ṣèṣekúṣe. (Òwe 22:3) Àmọ́ ká sòótọ́, nígbà míì, o lè bá ara rẹ nínú ipò tó ti máa ṣòro fún ẹ láti ṣe àwọn nǹkan kan tó yẹ kó o ṣe. Bí àpẹẹrẹ, kì í ṣe ìgbà gbogbo ni wàá rí ẹni tẹ́ ẹ jọ máa rìn, ó sì lè má ṣeé ṣe láti yẹra fún gbogbo àgbègbè eléwu. Ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé àgbègbè eléwu gan-an lò ń gbé.
Ó ṣeé ṣe kí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ jẹ́ kó o wá mọ̀ pé nǹkan búburú lè ṣẹlẹ̀ séèyàn nígbà míì, béèyàn bá tiẹ̀ jẹ́ ẹni tó máa ń ṣọ́ra gan-an pàápàá. Bóyá òjijì ni wọ́n yọ síwọ náà tí wọ́n sì fipá mú ẹ bíi ti Annette tá a sọ̀rọ̀ rẹ ní ìbẹ̀rẹ̀ orí yìí. Ọ̀rọ̀ tìẹ sì lè dà bíi ti Carmen, tí wọ́n fipá bá lò pọ̀ nígbà tó wà lọ́mọdé, bóyá nígbà yẹn kò sóhun tó o lè ṣe nípa ọ̀ràn náà, tàbí pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ kò tiẹ̀ yé ẹ rárá. Báwo lo ṣe lè borí ìdààmú ọkàn tó máa ń bá àwọn tí wọ́n fipá bá lò pọ̀?
Ohun Tó O Lè Ṣe Bí Ọkàn Ẹ Bá Ń Dá Ẹ Lẹ́bi
Ọkàn Annette ṣì máa ń dá a lẹ́bi nígbàkigbà tó bá rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i. Ó sọ pé: “Èmi gan-an ni mò ń dá wàhálà sílẹ̀ fún ara mi jù, gbogbo ìgbà ni mo máa ń ronú nípa bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò jà fitafita tó láti gba ara mi lọ́wọ́ ọkùnrin náà. Ohun tó sì fà á ni pé, gbàrà tó ti gún mi lọ́bẹ ni ẹ̀rù ti bà mí. Kò sì sóhun tí mo tún lè ṣe mọ́, àmọ́ mo máa ń rò ó pé ó ṣì yẹ kí n ṣe nǹkan kan.”
Ọkàn Natalie náà máa ń dá a lẹ́bi. Ó sọ pé: “Mo ti máa ń fọkàn tán àwọn èèyàn jù. Àwọn òbí mi ti sọ fún èmi àti àbúrò mi pé ká jọ máa wà pa pọ̀ nígbà tá a bá ń ṣeré níta, àmọ́ mi ò gbọ́. Mo gbà pé èmi ni mo jẹ́ kí aládùúgbò wa lè ráyè fipá bá mi lò pọ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ká ìdílé wa lára, mo sì gbà pé èmi ni mo fa ẹ̀dùn ọkàn tó bá wọn. Kò sígbà tí ọkàn mi kì í dá mi lẹ́bi ohun tó ṣẹlẹ̀ náà.”
Tó bá jẹ́ pé bí ọkàn Annette àti Natalie ṣe ń dá wọn lẹ́bi náà ni ọkàn rẹ ṣe ń dá ẹ lẹ́bi, kí lohun tó o lè ṣe nípa rẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, fi í sọ́kàn pé níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ṣe ni wọ́n fipá bá ẹ lò pọ̀, o kò mọ̀ọ́mọ̀ lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe náà. Àwọn èèyàn kan máa ń fojú kéré ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń sọ pé “ọkùnrin ni ọkùnrin á máa jẹ́” àti pé ẹ̀bi àwọn tí wọ́n fipá bá lò pọ̀ ni. Àmọ́, kò sẹ́nì kan tó yẹ kí wọ́n fipá bá lò pọ̀. Tó bá jẹ́ pé wọ́n ti fipá bá ẹ lò pọ̀ rí, jẹ́ kó yé ẹ pé kì í ṣe ẹ̀bi rẹ rárá!
Lóòótọ́, ó rọrùn láti kàn ka ohun tá a sọ yìí pé “kì í ṣe ẹ̀bi rẹ rárá,” àmọ́ ó lè má rọrùn fún ẹ láti gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Àwọn kan máa ń bo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn mọ́ra, tí ọkàn wọn á wá máa dá wọn lẹ́bi, ọ̀rọ̀ yẹn á sì máa bà wọ́n nínú jẹ́. Àmọ́, tó o bá dákẹ́, tó ò sọ̀rọ̀, tá ni ọ̀rọ̀ náà máa dùn, ìwọ àbí ẹni tó fipá bá ẹ lò pọ̀? Dípò tí wàá kàn fi dákẹ́, ohun míì wà tó o lè ṣe, táá ṣe ẹ́ láǹfààní.
Sọ Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ sí Ẹ
Bíbélì sọ nípa Jóòbù ọkùnrin olódodo náà pé, nígbà tí ìṣòro tó dé bá a dójú ẹ̀ tán, ó sọ pé: “Èmi yóò tú ìdàníyàn nípa ara mi jáde. Èmi yóò sọ̀rọ̀ nínú ìkorò ọkàn mi!” (Jóòbù 10:1) Ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní tíwọ náà bá ṣe bẹ́ẹ̀. Tó o bá lè sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ fún ẹnì kan tó o fọkàn tán, wàá rí i pé bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ọ̀rọ̀ náà lè fúyẹ́ lọ́kàn rẹ, ara á sì tù ẹ́.
Tó o bá wá jẹ́ Kristẹni, ó ṣe pàtàkì pé kó o sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ náà fún àwọn alàgbà. Ọ̀rọ̀ ìtùnú tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ yìí máa sọ fún ẹ á jẹ́ kó o mọ̀ pé ọrùn ẹni tó fipá bá ẹ lò pọ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ wà, kì í ṣe ìwọ. Bí Annette ṣe wá lóye ọ̀ràn náà nìyẹn. Ó sọ pé: “Mo sọ ọ̀rọ̀ náà fún ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ kan, ó sì rọ̀ mí pé kí n sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún àwọn alàgbà kan nínú ìjọ wa. Inú mi dùn pé mo ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n pè mí jókòó tí wọ́n sì sọ àwọn ohun tó tù mí nínú, pé ohun tó ṣẹlẹ̀ náà kì í ṣe ẹ̀bi mi. Wọ́n ní mi ò jẹ̀bi lọ́nàkọnà.”
Tó o bá ń sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ àti bó ṣe rí lára rẹ, ìyẹn kò ní jẹ́ kí inú máa bí ẹ, o ò sì ní máa kórìíra ara rẹ. (Sáàmù 37:8) Ó tún lè jẹ́ kí ọkàn rẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ wá fúyẹ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tó ti ṣẹlẹ̀. Ẹ̀yìn ìgbà tí Natalie sọ nípa bí wọ́n ṣe fipá bá a lò pọ̀ fún àwọn òbí rẹ̀ ni ara tó tù ú. Ó sọ pé: “Wọn kò fi mí sílẹ̀, wọ́n fún mi níṣìírí pé kí n sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí, ìyẹn ló jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà fúyẹ́ lọ́kàn mi, tí ìbínú mi sì rọ̀.” Natalie tún rí i pé àdúrà tu òun nínú. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ṣèrànwọ́ fún mi gan-an, pàápàá láwọn àkókò tí mi ò lè sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ẹnikẹ́ni. Nígbà tí mo bá ń gbàdúrà, mo máa ń sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára mi gan-an. Ó mú kí n ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn.”e
Ìwọ náà máa rí i pé “ìgbà mímúláradá” wà. (Oníwàásù 3:3) Gbára lé àwọn ọ̀rẹ́ tó ń dúró tini, tí wọ́n ń hùwà bí àwọn alàgbà tí Bíbélì fi wé “ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò.” (Aísáyà 32:2) Máa tọ́jú ara rẹ dáadáa, kó o sì rí i pé ò ń ṣe ohun tó máa múnú rẹ dùn. Máa sùn dáadáa. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, gbára lé Jèhófà, Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, tí yóò mú ayé tuntun wá láìpẹ́, nínú èyí tó jẹ́ pé “àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò, ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà ni yóò ni ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 37:9.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn míì wà tó jẹ́ pé ẹni tó ń fẹ́ wọn sọ́nà ló fipá bá wọn lò pọ̀, irú bíi pé kí ọkùnrin fipá bá ọmọbìnrin tó ń fẹ́ lò pọ̀ tàbí kó bá a lò pọ̀ lẹ́yìn tó ti rọ ọ́ lóògùn yó.
b Wo Orí 4 nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì, fún àlàyé síwájú sí i.
c Ìmọ̀ràn kan náà ni ọmọkùnrin kan máa tẹ̀ lé bí ọmọbìnrin kan bá ń rọ̀ ọ́ pé kó bá òun lò pọ̀.
d Wo Orí 11 nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì, fún àlàyé síwájú sí i.
e Nígbà míì, ìdààmú ọkàn tó pọ̀ gan-an máa ń bá àwọn tí wọ́n fipá bá lò pọ̀. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó máa dára kí wọ́n rí dókítà. Wo Orí 13 àti 14 nínú ìwé yìí, fún àlàyé síwájú sí i nípa bó o ṣe lè borí ìdààmú ọkàn.
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, . . . aláìní ìfẹ́ni àdánidá, . . . aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere.”—2 Tímótì 3:1-3.
ÌMỌ̀RÀN
Tí wọ́n bá ti fipá bá ẹ lò pọ̀ rí, kọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó lè tù ẹ́ nínú sílẹ̀ tí wàá máa rántí. Lára irú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bẹ́ẹ̀ ni Sáàmù 37:28; 46:1; 118:5-9; Òwe 17:17; àti Fílípì 4:6, 7.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, mẹ́sàn-an nínú mẹ́wàá àwọn ọ̀dọ́mọdé tí wọ́n fipá bá lò pọ̀ ló mọ ẹni tó fipá bá wọn lò pọ̀.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Tí ọkàn mi bá ń dá mi lẹ́bi nípa ohun tó ṣẹlẹ̀, màá ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Tí wọ́n bá fipá bá ẹ lò pọ̀, àǹfààní wo ló wà nínú pé kó o sọ ọ́ síta?
● Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí ìwọ àti sí àwọn míì tó o bá dákẹ́, tó ò sọ ohun tó ṣe ẹ́ fáwọn èèyàn?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 232]
“Kì í rọrùn rárá kéèyàn máa sọ fáwọn èèyàn pé wọ́n fipá bá òun lò pọ̀, àmọ́ ohun tó dára pé kó o ṣe nìyẹn. Bó o bá sọ fáwọn tó yẹ kó o sọ fún, ìyẹn lè mú kó o borí ẹ̀dùn ọkàn tó bá ẹ, o ò ní bínú mọ́, wàá sì lè máa bá ìgbésí ayé rẹ lọ.”—Natalie
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 230]
“Tó O Bá Nífẹ̀ẹ́ mi . . . ”
Àwọn èèyàn kan wà tó jẹ́ pé àwọn kì í fipá bá àwọn ọmọbìnrin lò pọ́, ṣe ni wọ́n máa ń dọ́gbọ́n rọ̀ wọ́n títí wọ́n á fi bá wọn ṣèṣekúṣe. Báwo ni wọ́n ṣe máa ń ṣe é? Lára ohun tí wọ́n máa ń sọ ni pé, “Ayé ń ṣerú ẹ̀,” “Kò sẹ́ni tó máa mọ̀,” tàbí, bó ṣe wà ní Orí 24 nínú ìwé yìí, kí wọ́n sọ pé, “tó o bá nífẹ̀ẹ́ mi, wàá gbà fún mi.” Má ṣe jẹ́ kí ọmọkùnrin kankan tàn ẹ́ jẹ pé ìbálòpọ̀ lèèyàn fi ń mọ ìfẹ́. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ẹni tó bá sọ bẹ́ẹ̀ wulẹ̀ ń wá ọ̀nà tó máa fi tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn ni. Kò ro tìẹ rárá, kò sì ro dáadáa fún ẹ. Àmọ́ ọkùnrin tó jẹ́ èèyàn dáadáa máa fi ohun tó o fẹ́ ṣáájú tirẹ̀, ó sì máa fi hàn pé òun ṣe tán láti tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 10:24) Ọkùnrin tó jẹ́ èèyàn dáadáa kò ní máa wo àwọn ọmọbìnrin bíi pé kóun ṣáà ti máa bá wọn lò pọ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ka “àwọn ọ̀dọ́bìnrin [sí] arábìnrin pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.”—1 Tímótì 5:1, 2.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 233]
Ẹ̀dùn ọkàn tí ìfipábánilòpọ̀ máa ń fà kọjá ohun tó o lè dá bójú tó. O ò ṣe sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí fún ẹnì kan kí wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?