ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwex àpilẹ̀kọ 12
  • ‘Inú Rere àti Ìṣòtítọ́ Tẹ́nì Kan Fi Hàn’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Inú Rere àti Ìṣòtítọ́ Tẹ́nì Kan Fi Hàn’
  • Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Bára Mi Ò Bá Yá?
    Jí!—2008
  • Alátakò Látijọ́ Kan Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ohun Tó Lè Tù Wá Nínú Kí Àjíǹde Tó Dé
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Ailabosi Fi Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa Hàn Lọna Rere
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
ijwex àpilẹ̀kọ 12
Ọkùnrin kan ń rìn jáde látinú ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta kọfí, ó sì gbàgbé báàgì rẹ̀ sórí àga.

‘Inú Rere àti Ìṣòtítọ́ Tẹ́nì Kan Fi Hàn’

Danielle tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní South Africa rí báàgì tí oníbàárà kan gbàgbé sí ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta kọfí. Pọ́ọ̀sì kan wà nínú báàgì náà, owó àti àwọn káàdì tí wọ́n fi ń rajà láwìn sì wà nínú ẹ́. Danielle fẹ́ dá báàgì náà pa dà fẹ́ni tó ni ín, torí náà, ó wo inú rẹ̀ bóyá òun á rí àdírẹ́sì tàbí nọ́ńbà fóònù onítọ̀hún, ṣùgbọ́n orúkọ ọkùnrin kan ló rí níbẹ̀. Ó gbìyànjú láti kàn sí ọkùnrin náà nípasẹ̀ báńkì rẹ̀ àmọ́ pàbó ló já sí. Ló bá kúkú pe nọ́ńbà fóònù tó rí lára rìsíìtì dókítà kan tó wà nínú báàgì náà. Olùgbàlejò tó gbé fóònù nílé ìwòsàn náà gbà láti fún un ní nọ́ńbà fóònù ọkùnrin tó ni báàgì náà.

Ó ya ọkùnrin náà lẹ́nu nígbà tí wọ́n tẹ̀ ẹ́ láago láti ọ́fíìsì dókítà rẹ̀, tí wọ́n sì sọ fún un pé Danielle ti rí báàgì rẹ̀, ó sì fẹ́ dá a pa dà. Nígbà tó wá gba báàgì náà, Danielle àti bàbá rẹ̀ kí i, wọ́n sì lo àǹfààní yẹn láti sọ ohun tó mú kí wọ́n sapá tó bẹ́ẹ̀ láti wá a kàn. Wọ́n ṣàlàyé pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn, ìlànà Bíbélì làwọn sì ń tẹ̀ lé. Ìdí nìyẹn táwọn fi máa ń ṣòótọ́ ní gbogbo ìgbà.​—⁠Hébérù 13:⁠18.

Wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, ọkùnrin náà tẹ àtẹ̀jíṣẹ́ sí Danielle àti bàbá rẹ̀, ó tún dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn pé wọ́n dá báàgì àti pọ́ọ̀sì òun pa dà. Ohun tó kọ ni pé: “Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ yín pé ẹ wá mi kàn. Inú mi dùn láti rí ìwọ àti bàbá rẹ, mi ò sì jẹ́ gbàgbé bó o ṣe jẹ́ onínúure àti ọmọlúwàbí. Kí èmi náà lè fi ìmoore hàn, màá fẹ́ láti fi ohun kan ta ẹ́ lọ́rẹ. Mo mọ̀ pé ẹ máa ń fara yín jìn gan-an kẹ́ ẹ lè ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé yín lọ́wọ́. Ìwà dáadáa tí Danielle hù, tí kò sì sọ nǹkan oní-nǹkan di tiẹ̀ fi hàn pé èèyàn rere àti ẹni àpọ́nlé ni yín. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ ṣeun, àdúrà mi ni pé kí Ọlọ́run bù kún iṣẹ́ ìránṣẹ́ tẹ́ ẹ̀ ń ṣe.”

Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, bàbá Danielle tún bá ọkùnrin náà sọ̀rọ̀. Ọkùnrin náà wá sọ pé ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, òun rí pọ́ọ̀sì kan tó sọ nù. Ó ní òun rí pọ́ọ̀sì kan nílẹ̀ níbi tí òun ti ń rajà. Nígbà tóun wá rí obìnrin tó ni pọ́ọ̀sì náà, tóun sì dá a pa dà, òun ṣàlàyé ìdí tóun fi ṣe bẹ́ẹ̀ fún obìnrin náà. Ó ní òun sọ fún obìnrin náà pé lẹ́nu àìpẹ́ yìí, òun sọ báàgì nù, ẹnì kan sì dá a pa dà fún òun, ìdí nìyẹn tóun náà fi dá pọ́ọ̀sì rẹ̀ pa dà. Ó wá sọ pé: “Tá a bá fi inúure àti ìṣòtítọ́ hàn sẹ́nì kan, ó ṣeé ṣe kóun náà fi hàn sí ẹlòmíì, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kára tu àwọn tó wà láyìíká rẹ̀.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́