ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwex àpilẹ̀kọ 11
  • Ìrìn Àjò Lágbègbè Odò Maroni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìrìn Àjò Lágbègbè Odò Maroni
  • Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Wọ́n Ṣe Múra Sílẹ̀ fún Ìrìn Àjò Náà
  • Wọ́n Gúnlẹ̀ sí Orílẹ̀-Èdè Àwọn Amerind
  • Wọ́n Kọjá sí Grand-Santi àti Apatou
  • “A Múra Tán Láti Ṣe É Lẹ́ẹ̀kan Sí I!”
  • Igbó Kìjikìji Amazon—Àròsọ Bò ó Mọ́lẹ̀
    Jí!—1997
  • Orísun Ìbànújẹ́ Lórí Igbó Kìjikìji Náà
    Jí!—1997
  • “Àwa Nìyí! Rán Wa!”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Wíwá Ojútùú Kiri
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
ijwex àpilẹ̀kọ 11
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń múra láti rìnrìn àjò, kí wọn lè wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn tó ń gbé létí odò Maroni.

Ìrìn Àjò Lágbègbè Odò Maroni

Yàtọ̀ sí kòókòó jàn-án-jàn-án tó wọ́pọ̀ nínú ìlú ńlá, àwọn èèyàn láti onírúurú ẹ̀yà àti èdè ló ń gbé inú igbó kìjikìji Amazon tó wà ní Gúúsù Amẹ́ríkà. Ní July 2017, àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́tàlá (13) rìnrìn àjò lọ sí Odò Maroni àti dé apá ìlà oòrùn àwọn ibi tí odò náà ṣàn gbà ní French Guiana. Kí nìdí tí wọ́n fi lọ? Láti lọ sọ ìrètí ọjọ́ iwájú tó wà nínú Bíbélì fún àwọn èèyàn ibẹ̀.

Bí Wọ́n Ṣe Múra Sílẹ̀ fún Ìrìn Àjò Náà

Ó ku oṣù kan kí ìrìn àjò ọlọ́jọ́ méjìlá (12) náà bẹ̀rẹ̀, wọ́n pe gbogbo àwọn tó máa lọ sí ìpàdé kan láti múra sílẹ̀. Winsley sọ pé “A kọ́ ẹ̀kọ́ nípa agbègbè yẹn àti ìtàn wọn, a sì tún jíròrò ọ̀nà tá a lè gbà múra sílẹ̀ fún ìrìn àjò náà.” Wọ́n fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní ohun èlò kan tí omi ò lè wọnú ẹ̀, tí wọ́n á lè fi ibùsùn àsorọ̀ àti àwọ̀n apẹ̀fọn sí. Wọ́n máa wọ ọkọ̀ òfúrufú lẹ́ẹ̀mẹjì, wọ́n sì tún máa lo ọ̀pọ̀ wákàtí nínú àwọn ọkọ̀ ojú omi kéékèèké.

Claude àti Lisette.

Claude àti Lisette

Báwo ló ṣe rí lára àwọn tó ń lọ? Inú Claude àti Lisette, tí wọ́n ti lé lẹ́ni ọgọ́ta ọdún (60) dùn gan-an nígbà tí wọ́n fún wọn láǹfààní yìí. Claude sọ pé: “Bí wọ́n bá gẹṣin nínú mi, wọn ò ní kọsẹ̀, àmọ́ ẹ̀rù ń bà mí torí onírúurú nǹkan tí mo ti gbọ́ tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn lórí omi.” Àmọ́ o, ọ̀tọ̀ lohun tó ń já Lisette láyà, ó sọ pé: “Bí màá ṣe sọ èdè Amerind ló ń kó mi lọ́kàn sókè.”

Ẹ̀rù ń ba Mickaël náà, ó sọ pé: “A ò mọ púpọ̀ nípa àwọn ẹ̀yà Wayana, torí náà mo ṣe ìwádìí lórí Íntánẹ́ẹ̀tì kí n lè kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ àti bí màá ṣe kí wọn lédè wọn.”

Shirley, tó jẹ́ pé òun àti ọkọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Johann, ni wọ́n jọ ń lọ ṣàkọsílẹ̀ àwọn èdè tí wọ́n ń sọ láwọn agbègbè odò yẹn. Ó sọ pé: “A wa àwọn fídíò jáde lórí ìkànnì jw.org ní ọ̀pọ̀ èdè tí wọ́n ń sọ níbẹ̀, a sì tún ra ìwé tó ń kọ́ni lédè Wayana.”

Wọ́n Gúnlẹ̀ sí Orílẹ̀-Èdè Àwọn Amerind

Ní Tuesday, July 4, àwùjọ náà wọ ọkọ̀ òfúrufú láti Saint-Laurent du Maroni dé Maripasoula, wọ́n sì balẹ̀ sí Maripasoula tó jẹ́ ìlú kékeré kan ní French Guiana.

Àwòrán Gúúsù Amerika pẹ̀lú odò Maroni àti àwọn ìlú tó wà létí ẹ̀ la sàmì sí láàárín. Àwọn ìlú náà (láti àríwá sí gúùsù) ni Saint-Laurent du Maroni, Apatou, Grand Santi, Maripasoula, àti Antécume Pata.

Fún odindi ọjọ́ mẹ́rin ni àwùjọ náà fi ń wàásù fáwọn ará abúlé tó wà ní apá òkè Odò Maroni, ọkọ̀ ojú omi tó ní ẹ́ńjìnnì tí wọ́n ń pè ní pirogues ni wọ́n fi ń ti ibì kan bọ́ sí òmíì. Roland tó jẹ́ ọ̀kan lára àwùjọ náà sọ pé: “A rí i pé àwọn Amerind nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an, ọ̀pọ̀ ìbéèrè ni wọ́n bi wá, àwọn kan sì fẹ́ ká máa bá wọn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Ní abúlé kan, Johann àti Shirley pàdé tọkọtaya kan tí ìbátan wọn kan ṣẹ̀ṣẹ̀ gbẹ̀mí ara ẹ̀. Johann sọ pé: “A fi fídíò A Native American Finds His Creator,” tó wà lórí ètò Tẹlifíṣọ̀n JW hàn wọ́n. Fídíò yẹn wọ tọkọtaya yìí lọ́kàn gan-an, wọ́n sì fún wa ní àdírẹ́sì tí wón fi ń gba lẹ́tà lórí Íntánẹ́ẹ̀tì (e-mail), torí ká lè máa bá ìjíròrò náà lọ.”

Ibi tó jìnnà jù lọ tí a dé ni apá òkè odò tí wọ́n ń pè ní Antécume Pata. Baálẹ̀ abúlé yìí gba àwọn Ẹlẹ́rìí tọwọ́tẹsẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wón, ó sì gbà wọ́n láyè láti so àwọn ibùsùn alásorọ̀ wọn mọ́gi láàárín abúlé. Wọ́n tún wẹ̀ lódò táwọn ará abúlé náà ti ń wẹ̀.

Lẹ́yìn náà, àwùjọ náà tẹkọ̀ létí lọ sí abúlé Twenké. Ìgbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n rí i pé àwọn ará abúlé náà ń ṣọ̀fọ̀ èèyàn wọn tó kú. Eric tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ṣètò ìrìn àjò náà sọ pé: “Olórí ẹ̀yà náà gbà wá láàyè láti rìn fàlàlà nínú abúlé náà ká lè tu àwọn tó ń sọ̀fọ̀ nínú. Olórí ẹ̀yà náà àti ìdílé rẹ̀ mọrírì àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a kà fún wọn látinú Bíbélì Wayana. A tún fi àwọn fídíò tó ń ṣàfihàn bí ìlérí àjíǹde tí Bíbélì sọ ṣe máa ṣẹ hàn wọ́n.”

Wọ́n Kọjá sí Grand-Santi àti Apatou

Ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ni ọkọ̀ òfúrufú fi rìn láti Maripasoula sí ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Grand-Santi. Lọ́jọ́ Tuesday àti Wednesday, àwọn arìnrìn-àjò náà wàásù ìròyìn ayọ̀ tó wà nínú Bíbélì fún àwọn ará ìlú náà. Lọ́jọ́ Thursday, àwọn Ẹlẹ́rìí náà tún rin ìrìn àjò míì, èyí tó gbà wọ́n tó wákàtí márùn-ún àtààbọ̀, wọ́n gba orí Odò Maroni lọ sí abúlé Apatou.

Àwòrán odò Maroni àti igbó Amazon tí a yà láti ojú òfurufú.

Odò Maroni àti igbó Amazon tó wà láàárín Maripasoula àti Grand-Santi

Nígbà tó ku ọjọ́ kan kí ìrìn àjò náà parí, àwọn èèyàn náà ṣèbẹ̀wò sí àwọn abúlé tó wà nínú igbó kìjikìji ti àwọn Maroon. Àtọmọdọ́mọ àwọn ará Áfíríkà làwọn Maroon tí wọ́n kó lẹ́rú wá sí Gúúsù Amẹ́ríkà ní àkókò ìjọba amúnisìn tó wáyé ní Suriname. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ké sí gbogbo èèyàn láti wá sí ìpàdé kan nínú igbó náà, lábẹ́ àtíbàbà ńlá kan tí wọ́n dìídìí ṣètò fún ìpàdé náà. Claude sọ pé: “Ọkàn wa kún fún ayọ̀ nígbà tí a rí ọ̀pọ̀ èèyàn tó wá, kẹ́ ẹ sì máa wò ó, òwúrọ̀ ọjọ́ yẹn la pè wọ́n.” Karsten tó jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ tó máa lọ sí irú ìrìn àjò yìí ló sọ àsọyé lédè Aukan, àkòrí rẹ̀ ni, “Ṣé Ìgbésí Ayé Ẹ̀dá Kò Jù Báyìí Náà Lọ?” Èèyàn mọ́kànléláàádọ́rùn-ún [91] ló pésẹ̀ sí ìpàdé náà, ọ̀pọ̀ abúlé ni wọ́n sì ti wá.

Àwọn èèyàn tó wá sí ìpàdé tí a ṣe lábẹ́ àtíbàbà ńlá kan nínú igbó.

“A Múra Tán Láti Ṣe É Lẹ́ẹ̀kan Sí I!”

Nígbẹ̀yìn, àwọn arìnrìn-àjò náà pa dà sí Saint-Laurent du Maroni. Ó ya gbogbo wọn lẹ́nu bí àwọn ará ìlú náà ṣe nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù náà, wọ́n gba ọ̀pọ̀ ìtẹ̀jáde, wọ́n sì wo onírúurú fídíò táwọ̀n Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.

Lisette sọ pé; “Mi ò lè sọ bínú mi ṣe dùn tó láti rin ìrìn àjò yìí.” Cindy náà gbà pẹ̀lú ẹ̀, ó sọ pé: “Tó bá ṣée ṣe láti tún ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i, màá bẹ̀bẹ̀ kí wọ́n fún mi lánfààní náà. Kí n sòótọ́, ìròyìn ò tó àfojúbà, ẹni bá débẹ̀ ló lè sọ.”

Ìrìn àjò yìí ló mú kí àwọn kan lára àwọn arìnrìn-àjò náà fẹ́ láti pa dà lọ síbẹ̀. Mickaël sọ pé: “A múra tán láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i!” Winsley ti pa dà sí Saint-Laurent du Maroni. Claude àti Lisette, tí wọ́n ti lé ní ẹni ọgọ́ta (60) ọdún sì ti wà ní Apatou báyìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́