ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 11/1 ojú ìwé 29
  • Alátakò Látijọ́ Kan Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Alátakò Látijọ́ Kan Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àbúrò Jésù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • ‘Inú Rere àti Ìṣòtítọ́ Tẹ́nì Kan Fi Hàn’
    Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • O Ha Ní Iye Ìwé Ìròyìn Pàtó Tí O Ń Gbà Bí?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Àwọn Ìwé Ìròyìn Ń Kéde Ìjọba Náà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 11/1 ojú ìwé 29

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Alátakò Látijọ́ Kan Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́

A TI gbọ́ púpọ̀ nípa ogun abẹ́lé ní Liberia. Ẹgbẹẹgbàárùn-ún ènìyàn ló kú, àwọn tó pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ sì sá lọ sígbèkùn. Láìka àwọn ìṣòro wọ̀nyí sí, àwọn ènìyàn olóòótọ́ ọkàn ń tẹ́wọ́ gba òtítọ́ nìṣó, bí ìrírí yìí ṣe fi hàn.

Nígbà tí James ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá ló ti ń kẹ́kọ̀ọ́ ní Ṣọ́ọ̀ṣì Lutheran. Lẹ́yìn tí ó di olóòtú ìwé ìròyìn kan tí ṣọ́ọ̀ṣì ń gbé jáde, ó lo ipò rẹ̀ láti máa kọ ọ̀rọ̀ lòdì sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó ṣe bẹ́ẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò bá Ẹlẹ́rìí kankan pàdé rí.

Láìpẹ́, James fi iṣẹ́ ìwé ìròyìn ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀, ó sì di onílé iṣẹ́ ìbùwọ̀ kan tó kẹ́sẹ járí. Bí ó ti jókòó síbi ìgbàlejò ilé iṣẹ́ ìbùwọ̀ rẹ̀ lọ́jọ́ kan, àwọn arábìnrin méjì tí wọ́n múra dáadáa kàn sí i. Nígbà tí ó rí ìmúra wọn tó mọ́ tónítóní, ó pè wọ́n wọlé. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sọ ohun tí wọ́n wá ṣe, ó ní, “Ọwọ́ mi dí púpọ̀ láti jíròrò.” Àwọn Ẹlẹ́rìí náà fi àsansílẹ̀ Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ̀ ọ́, ó gbà, kí wọ́n sá lè fi í sílẹ̀. Àwọn ìwé ìròyìn náà ń dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ fún oṣù 12, ṣùgbọ́n ó ń kó wọn sínú àpò oníláílọ́ọ̀nù kan láìtilẹ̀ yọ wọ́n kúrò nínú ìwé tí a fi wé wọn.

Ogun abẹ́lé ń lọ lọ́wọ́, nítorí náà, James kó owó àti àwọn ohun ìní mìíràn sínú àpò kan kí ó lè gbé e sá lọ ní gbàrà tí ogun bá dé. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan, ohun abúgbàù àfọwọ́jù kan bú lẹ́yìnkùlé rẹ̀, tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù ló nawọ́ gán àpò rẹ̀, tó sì sá láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là. Ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ará ìlú tí ń sá lọ, ó sì ní láti kọjá ibi mélòó kan tí wọ́n ti gbégi dí ọ̀nà. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń ja àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ará ìlú lólè, wọ́n sì ń pa wọ́n láìsí ìdí gúnmọ́ kankan níbẹ̀.

Níbi ìdánà kìíní, wọ́n béèrè ọ̀rọ̀ díẹ̀ lọ́wọ́ James, wọ́n sì ní kí ó tú àpò rẹ̀. Nígbà tó ṣe bẹ́ẹ̀, ó wo inú àpò rẹ̀, ohun tó rí sì yà á lẹ́nu. Ẹ̀rù bà á láti rí i pé àpò tí ó gbé kì í ṣe èyí tó fi di àwọn ohun ìní rẹ̀ sí. Nínú ìbẹ̀rù tó mú un, àpò tí àwọn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tí kò ṣí wò náà wà ló gbé. Àmọ́, nígbà tí sójà náà rí àwọn ìwé ìròyìn náà, tí wọ́n sì ka orúkọ rẹ̀ lára wọn, ó wí pé: “Óò, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ́. Ẹ̀yin kọ́ la ń wá, a mọ̀ pé ẹ kì í purọ́.” Lẹ́yìn tí sójà náà ti mú àwọn ìwé ìròyìn díẹ̀ nínú àpò náà, ó ní kí James máa lọ.

Bákan náà ló ṣẹlẹ̀ níbi ìdánà mẹ́sàn-án ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí àwọn ológun náà ń rò pé James jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n sì ń jẹ́ kí ó kọjá láìfarapa. James wá kún fún ọpẹ́ pé òun kò gbé àpò ohun ìní òun, nítorí pé, àwọn ohun tó ti rí fi hàn án pé, wọn ì bá ti pa á nítorí àwọn ohun ìní rẹ̀.

Nígbà tí ó jàjà dé ibi ìdánà tó kẹ́yìn tó sì bani lẹ́rù jù, jìnnìjìnnì bò ó bí ó ti rí òkú nílẹ̀ lọ dígbadìgba. Tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù, ó ké pe orúkọ Jèhófà. Ó gbàdúrà pé, bí Ọlọ́run bá lè ran òun lọ́wọ́ la àgbègbè tí wọ́n ti ń pànìyàn yìí já, òun yóò fi gbogbo ìyókù ìgbésí ayé òun sìn ín.

James gbé àpò rẹ̀ fún àwọn sójà náà, wọ́n sì tún wí pé: “Àwọn ènìyàn wọ̀nyí kọ́ la ń wá.” Wọ́n yíjú sí i, wọ́n sì wí pé: “Ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ ń gbé ní apá ìsàlẹ̀ òkè yìí. Lọ máa gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀.” Nígbà yìí, èrò James nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí ti yí padà pátápátá. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ló wá arákùnrin yẹn kàn, wọ́n sì ṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní lílo ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.a

Ní ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, ìgbóguntì kan mú kí ó sá kúrò ní àgbègbè náà. Lọ́tẹ̀ yìí, ìwé Walaaye Titilae rẹ̀ nìkan ló mú sá lọ! Láàárín oṣù 11 tó fi wà láìrí Àwọn Ẹlẹ́rìí, James kẹ́kọ̀ọ́ ìwé rẹ̀ nígbà márùn-ún. Nígbà tí ó wá ṣeé ṣe fún un níkẹyìn láti padà wọ̀lú, ó tún ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ nìṣó pẹ̀lú Ẹlẹ́rìí náà, ó sì tẹ̀ síwájú kíákíá. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ó ṣe batisí, ó sì ń fìṣòtítọ́ sìn pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ tẹ̀mí nísinsìnyí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́