Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
July-Septemer 2008
Báwo Ni Ìgbéyàwó Rẹ Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí?
Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti ṣègbéyàwó ni wọ́n ní ibi tí bàtà ti ń ta wọ́n lẹ́sẹ̀. Àmọ́, kí lo lè ṣe tí ayọ̀ ìgbéyàwó rẹ ò fi ní pẹ̀dín, tọ́rọ̀ ìwọ àti ẹnì kejì rẹ ò sì ní máa já sí òní eré, ọ̀la ìjà? Bíbélì sọ àwọn ohun tó yẹ kó o ṣe.
6 Bí Ìgbéyàwó Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí
12 Ìgbà Wo Ló Tọ́ Kéèyàn Gbèjà Ara Ẹ̀?
23 Báwo Ni Ìjọsìn Ọlọ́run Ṣe Lè Gbádùn Mọ́ Mi?
26 Ibi Tí Mo Ti Kọ́kọ́ Gbọ́ Tí Wọ́n Pe Jèhófà
30 Ṣé Ilẹ̀ Ayé Lè Pèsè Ohun Tí Ìran Tó Ń Bọ̀ Lọ́jọ́ Iwájú Máa Nílò?
32 Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ̀mí Ọlọ́run Ń Darí Wa” ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Sá fún Ìbẹ́mìílò? 14
Ojúmìító ló ń sún ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n fi ń lọ́wọ́ sí onírúurú ìbẹ́mìílò. Àwọn ewu wo ló wà níbẹ̀? Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ìbẹ́mìílò?
Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló ń gbẹ̀mí ara wọn lọ́dọọdún, ọ̀kẹ́ àìmọye ló sì ń gbìyànjú ẹ̀. Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé bí ẹni tó bá ní ẹ̀dùn ọkàn ṣe lè borí rẹ̀.