Ojú Ìwòye Bíbélì
Irú Ẹni Wo Ni Ọlọ́run?
BÍBÉLÌ ṣàlàyé pé: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí, àwọn tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:19-24) Òótọ́ pọ́ńbélé yìí jẹ́ ká mọ bí Ọlọ́run ṣe rí, ìyẹn ni pé ó jẹ́ ẹ̀mí! (Jòhánù 4:19-24) Àmọ́, Bíbélì ṣàpèjúwe ẹ̀ bí ẹnì kan. Jèhófà lorúkọ rẹ̀.—Sáàmù 83:18.
Àwọn kan tó máa ń ka Bíbélì sọ pé bí Ọlọ́run ṣe rí ò yé àwọn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹni ẹ̀mí, tí ò ṣeé fojú rí ni Ọlọ́run, kí nìdí tí ọ̀pọ̀ ẹsẹ Bíbélì fi máa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ bí ẹni pé ó ní ojú, etí, imú, ọkàn, apá, ọwọ́, ìka àti ẹsẹ̀?a Àwọn kan lè sọ pé bí àwa èèyàn ni Ọlọ́run ṣe rí torí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run dá àwa èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀. Bá a bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ, ọ̀rọ̀ yẹn á yé wa yékéyéké.—Jẹ́nẹ́sísì 1:26.
Kí Wá Nìdí Tí Wọ́n Fi Ṣàpèjúwe Ẹ̀ bí Èèyàn?
Ká lè lóye irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, ó mí sáwọn tó kọ Bíbélì láti ṣàpèjúwe òun bí èèyàn. Àwọn ọ̀mọ̀wé pàápàá máa ń fi àwọn ẹ̀yà ara èèyàn ṣàpèjúwe àwọn nǹkan aláìlẹ́mìí lọ́pọ̀ ìgbà. Èyí fi hàn pé àwọn èdè táwa èèyàn ń sọ ò ní àwọn ọ̀rọ̀ tó kún tó láti fi ṣàpèjúwe Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́. Káwa èèyàn bàa lè lóye irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ làwọn tó kọ Bíbélì fi ṣàpèjúwe ẹ̀ lọ́nà tó máa gbà yé wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì pe Ọlọ́run ní “Àpáta,” “oòrùn” tàbí “apata,” tá a sì mọ̀ pé ó wulẹ̀ fi ṣàpèjúwe ẹ̀ ni, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ ká máa wò ó bíi pé Ó ní ojú, imú tàbí àwọn ẹ̀yà ara míì bíi tàwa èèyàn torí pé Bíbélì fi wọ́n ṣàpèjúwe rẹ̀.—Diutarónómì 32:4; Sáàmù 84:11.
Bákan náà, kó bàa lè yé wa pé àwa èèyàn pàápàá láwọn ànímọ́ kan tó jọ ti Jèhófà dé ìwọ̀n àyè kan ni Bíbélì fi sọ pé Ọlọ́run dá èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀. Ó ṣe kedere nígbà náà pé, àwa èèyàn kì í ṣe ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ sì ni Ọlọ́run pàápàá ò ní ìrísí èèyàn.
Ṣé Ọkùnrin ni Ọlọ́run àbí Obìnrin?
Bá ò ṣe gbọ́dọ̀ máa ronú pé Ọlọ́run ní ọwọ́, ẹsẹ̀ àtàwọn ẹ̀yà ara míì bíi tàwa èèyàn la ò ṣe gbọ́dọ̀ máa ronú pé ọkùnrin ni Ọlọ́run torí pé Bíbélì lo àwọn èdè tí wọ́n máa ń lo fún ọkùnrin nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Àwọn ẹ̀dá tó ṣeé fojú rí nìkan la lè pinnu bóyá wọ́n jẹ́ akọ tàbí abo, ìyẹn sì tún fi hàn pé àwọn èdè táwa èèyàn ń sọ ò kún tó láti fi ṣàpèjúwe Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè.
Bíbélì pe Ọlọ́run ní “Baba,” ìyẹn sì jẹ́ ká rí i pé a lè fi Ẹlẹ́dàá wa wé bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, tó ń dáàbò bò wọ́n, tó sì ń bójú tó wọn. (Mátíù 6:9) Èyí ò wá túmọ̀ sí pé ọkùnrin tàbí obìnrin ni Ọlọ́run àtàwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó wà lọ́run. Ti pé ẹnì kan jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin ò sí lọ́rọ̀ tiwọn. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọ́n máa jẹ́ ajogún pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba ọ̀run, ó jẹ́ ká rí i pé wọn ò ní jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin mọ́ lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá ti ṣe wọ́n lógo gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ tẹ̀mí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán wọn létí pé “kò [ní] sí akọ tàbí abo” láàárín wọn mọ́ nígbà tí Ọlọ́run bá ṣe wọ́n lógo gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ tẹ̀mí. Bíbélì tún ṣàpèjúwe wọn gẹ́gẹ́ bí “ìyàwó” Ọ̀dọ́ Àgùntàn, ìyẹn Jésù Kristi. Gbogbo èyí fi hàn pé bí Bíbélì ṣe lo àwọn ẹ̀yà ara èèyàn láti fi ṣàpèjúwe Ọlọ́run àti bó ṣe fi ṣàpèjúwe Jésù, tó jẹ́ Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, àtàwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó kù ò túmọ̀ sí pé lóòótọ́ ni wọ́n ní irú àwọn ẹ̀yà ara bẹ́ẹ̀.—Gálátíà 3:26, 28; Ìṣípayá 21:9; 1 Jòhánù 3:1, 2.
Torí pé àwọn tó kọ Bíbélì mọ ojúṣe ọkùnrin, wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run bíi pé ọkùnrin ni. Wọ́n mọ̀ pé ọkùnrin tó bá ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ bí iṣẹ́, ń fara wé Jèhófà, tó jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ àti bàbá tó nífẹ̀ẹ́ àwa ọmọ rẹ̀ tá a wà lórí ilẹ̀ ayé.—Málákì 3:17; Mátíù 5:45; Lúùkù 11:11-13.
Ànímọ́ Títayọ tí Ọlọ́run Ní
Ẹni ẹ̀mí ni Ọlọ́run tó jẹ́ Aláṣẹ gíga jù lọ, síbẹ̀ kò yara ẹ̀ láṣo, kì í ṣẹni táwa èèyàn ò lè mọ̀ nípa ẹ̀ tàbí ẹni tí kò ṣeé bá sọ̀rọ̀. Jíjẹ́ tó jẹ́ ẹni ẹ̀mí ò ṣèdíwọ́ fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí nǹkan tó tọ́ láti mọ̀ nípa ìfẹ́, ọgbọ́n, agbára àti ìdájọ́ òdodo rẹ̀, ìyẹn ló sì fi irú ẹni tó jẹ́ hàn gẹ́gẹ́ bá a ti ń rí i nínú àwọn nǹkan tó dá.—Róòmù 1:19-21.
Síbẹ̀, ìfẹ́ tó jẹ́ ànímọ́ títayọ tí Ọlọ́run ní ló jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́. Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní ta yọ débi pé Bíbélì pe òun fúnra rẹ̀ ní ìfẹ́. (1 Jòhánù 4:8) Orí ìfẹ́ yìí ló gbé àwọn ànímọ́ míì tó ní kà, irú bí àánú, ìdáríjì àti ìpamọ́ra. (Ẹ́kísódù 34:6; Sáàmù 103:8-14; Aísáyà 55:7; Róòmù 5:8) Ọlọ́run ìfẹ́ ni Jèhófà lóòótọ́, ó sì ń pe àwa èèyàn pé ká sún mọ́ òun. Jòhánù 4:23.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí àpẹẹrẹ, wo Jẹ́nẹ́sísì 8:21; Ẹ́kísódù 3:20; 15:8; 31:18; 1 Sámúẹ́lì 8:21; Jóòbù 40:9; Sáàmù 10:17; 18:9; 34:15; Òwe 27:11; Ìsíkíẹ́lì 8:17; Sekaráyà 14:4; Lúùkù 11:20; Jòhánù 12:38; Róòmù 10:21; àti Hébérù 4:13.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
◼ Kí lorúkọ Ọlọ́run?—Sáàmù 83:18.
◼ Ibo la ti lè ráwọn ànímọ́ Ọlọ́run lọ́nà tó fara hàn kedere?—Róòmù 1:19-21.
◼ Èwo ló ta yọ lára àwọn ànímọ́ Ọlọ́run?—1 Jòhánù 4:8.