ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 10/10 ojú ìwé 3
  • Kí Lo Mọ̀ Nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Lo Mọ̀ Nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
  • Jí!—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ta ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ṣé Kristẹni Tòótọ́ Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ohun Tó Lè Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Ìhìn Rere Lórí Ìsokọ́ra Alátagbà Internet
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Àwọn Míì
Jí!—2010
g 10/10 ojú ìwé 3

Kí Lo Mọ̀ Nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Obìnrin kan tó ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ akọ̀ròyìn lórílẹ̀-èdè Denmark sọ pé: “Mo ti ka ọ̀pọ̀ nǹkan nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, mo gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àhesọ kan, mo sì ti gbọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fi ẹ̀tanú hàn. Nítorí èyí, ojú tí kò dáa ni mo fi ń wo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

NÍGBÀ tó yá, obìnrin yìí fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Ó sọ pé: “Ní gbàrà tí mo wọ ilé wọn, ńṣe ni èrò tí mo ní nípa wọn yí pa dà! Bóyá àwọn èèyàn ò mọ̀ wọ́n dáadáa tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ni gbogbo wa kàn ń sọ ohun tí ojú wa kò tó. Èmi náà mọ̀ pé mo jẹ̀bi ọ̀rọ̀ yìí. Mo wá rí i pé èrò tí mo ní nípa wọn kò tọ̀nà.”—Ìròyìn látọwọ́ Cecilie Feyling fún ìwé ìròyìn Jydske Vestkysten.

Nígbà tí olùdarí àwọn òṣìṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń ta ṣéènì ní ilẹ̀ Yúróòpù dòwò pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó rí i pé wọ́n máa ń ṣòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́. Èyí mú kó fẹ́ láti gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà síṣẹ́.

Òótọ́ ni pé, iṣẹ́ ìwàásù la fi ń dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ jù lọ. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń rí i pé àwọn kan ò fẹ́ kí wọ́n bá àwọn jíròrò Bíbélì, nígbà tó jẹ́ pé àwọn míì nífẹ̀ẹ́ sí ìjíròrò Bíbélì. Kódà, ó ju mílíọ̀nù méje àwọn èèyàn lọ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, ṣàṣà sì ni orílẹ̀-èdè tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò sí. Àwọn kan lára àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ náà sì ti dẹni tó ń kọ́ àwọn mìíràn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àjọ National Council of Churches sọ pé lára àwọn ẹ̀sìn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tí iye wọn pọ̀ jù lọ, mẹ́rin péré ni iye wọn ń pọ̀ sí i. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì wà lára àwọn ẹ̀sìn mẹ́rin yìí.

Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Báwo ni wọ́n ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ǹjẹ́ wọ́n máa ń retí pé káwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Ká tiẹ̀ sọ pé kò wù ẹ́ láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o lẹ́tọ̀ọ́ láti mọ ìdáhùn tó jẹ́ òótọ́ sí àwọn ìbéèrè yìí. Torí náà, má ṣe fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ àhesọ táwọn ẹlẹ́tanú ń sọ, ńṣe ni kó o wádìí kó o lè mọ òtítọ́. Òwe 14:15 sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”

Àdúrà wa ni pé kí ìwé ìròyìn Jí! yìí ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Kódà, ti pé ò ń ka ìwé ìròyìn yìí fi hàn pé o ní ọkàn tó dáa. Ohun kan tó o tún lè ṣe nìyí: Bó o ṣe ń ka àpilẹ̀kọ mẹ́rin tó tẹ̀ lé èyí àtàwọn àpótí tó wà níbẹ̀, gbé Bíbélì rẹ, kó o sì máa ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ náà.a Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, èyí fi hàn pé o jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti pé o ní “ọkàn-rere” gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ.—Ìṣe 17:11.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí o kò bá ní Bíbélì, o lè gba ọ̀kan lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bó o bá sì mọ bí wọ́n ṣe ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, o lè ka Bíbélì lórí ìkànnì wa ní oríṣiríṣi èdè, ìyẹn, www.watchtower.org. (Ní báyìí, kò tíì sí Bíbélì èdè Yorùbá níbẹ̀). Bákan náà, àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wà lórí Ìkànnì wa, ní èdè tó lé ní irinwó dín ogún [380].

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́