ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 10/10 ojú ìwé 15
  • “Ó Lè Jẹ́ Orin Ló Máa Ṣèrànwọ́”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ó Lè Jẹ́ Orin Ló Máa Ṣèrànwọ́”
  • Jí!—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Yẹra fún Ẹ̀mí Ayé Tó O Bá Ń Ṣètò Ìgbéyàwó
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Mo Bá Ní Àìsàn Tí Mò Ń Bá Fínra? (Apá 2)
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Jẹ́ Ká Jọ Kọ Orin Ìjọba Náà
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Orin Tuntun
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
Àwọn Míì
Jí!—2010
g 10/10 ojú ìwé 15

“Ó Lè Jẹ́ Orin Ló Máa Ṣèrànwọ́”

● Orílẹ̀-èdè Philippines ni Juliana, obìnrin àgbàlagbà kan tó jẹ́ Kristẹni ń gbé. Ó ní àìsàn ọpọlọ tó máa ń mú kí àwọn arúgbó gbàgbé ọ̀pọ̀ nǹkan, ìyẹn àìsàn tí wọ́n ń pè ní Alzheimer. Àìsàn yìí ti wọ̀ ọ́ lára débi pé tó bá rí àwọn ọmọ rẹ̀, kì í dá wọn mọ̀. Síbẹ̀, kò sígbà tí mo bá wà ládùúgbò yẹn tí mi ò ní dé ọ̀dọ̀ Juliana.

Orí ìdùbúlẹ̀ ni Juliana máa ń wà tọ̀sán-tòru, ńṣe ló kàn máa ń yọjú lójú fèrèsé ṣáá. Kì í rọrùn fún mi rárá nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ rẹ̀, torí kò dá mi mọ̀ mọ́. Ṣe ló máa ń wò mí roro, síbẹ̀ ó máa ń hàn lójú rẹ̀ pé kò dá mi mọ̀. Mo bi í pé, “Ṣé o ṣì máa ń ronú nípa Jèhófà?” Mo wá sọ ìrírí kan fún un, lẹ́yìn náà mo bí i ní àwọn ìbéèrè míì, síbẹ̀, kò jọ pé ó lóye ohun tí mò ń sọ rárá. Ni mo bá torin bẹnu. Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà múnú mi dùn gan-an ni!

Juliana bojú wò mí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ orin náà pẹ̀lú mi! Kò pẹ́ tí mo fi dákẹ́ torí mi ò mọ gbogbo ọ̀rọ̀ orin náà lórí, ní èdè ìbílẹ̀ Tagalog. Àmọ́ Juliana kò dákẹ́, ṣe ló ń kọrin náà lọ ní tiẹ̀. Ó rántí ìlà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí orin náà ní. Mo yáa ní kí ẹni tá a jọ wà níbẹ̀ bá mi yá ìwé orin lọ́dọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń gbé nítòsí. Kíá ló sì lọ gbà á wá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ nọ́ńbà orin náà, mo kàn ṣàdédé rí i pé ibẹ̀ gan-an ni mo ṣí. Bó ṣe di pé àwa méjèèjì jọ kọ gbogbo orin náà nìyẹn! Nígbà tí mo bi Juliana bóyá ó rántí àwọn orin míì, ṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í kọ orin àtijọ́ kan, ìyẹn orin ìfẹ́ ní èdè Filipino.

Mo wá sọ fún un pé, “Rárá o, kì í ṣe orin tí wọ́n máa ń kọ lórí rédíò ni mò ń sọ, àmọ́ orin tí wọ́n ń kọ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.”a Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ orín míì látinú ìwé orin wa, òun náà sì bá mi kọ ọ́. Mo rí i pé inú rẹ̀ dùn gan-an ni. Ó rẹ́rìn-ín dénú, kò sì wò mí bí ẹni tí kò mọ̀ mí mọ́.

Àwọn aládùúgbò tó ń gbọ́ orin náà sáré bọ́ síta, wọ́n fẹ́ mọ ibi tí orin náà ti ń wá. Wọ́n dúró sójú fèrèsé, wọ́n ń wò wá, wọ́n sì ń fetí sí orin tí à ń kọ. Ó wú mi lórí gan-an láti rí bí orin náà ṣe wọ Juliana lọ́kàn! Ó ti jẹ́ kó rántí àwọn ọ̀rọ̀ orin náà.

Ìrírí yìí kọ́ mi pé, a kò mọ ohun tó máa ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ní ìṣòro láti lóye nǹkan tàbí tí wọ́n ò tiẹ̀ lè sọ̀rọ̀ rárá. Ó lè jẹ́ orin ló máa ṣèrànwọ́.

Kò pẹ́ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni Juliana kú. Ìgbà tí mò ń gbọ́ àwọn orin amóríyá tuntun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe lọ́dún 2009, ni mo rántí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Bó o bá fẹ́ àwọn orin aládùn yìí, o lè bi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ibi tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe ìpàdé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́