Àtúnyẹ̀wò Fún Ìdílé
Kí Ni Kò Sí Nínú Àwòrán Yìí?
Ka Dáníẹ́lì 6:1-24. Kó o sì wo àwòrán yìí. Àwọn nǹkan wo ni kò sí nínú àwòrán náà? Kọ ìdáhùn rẹ sórí ìlà tó wà nísàlẹ̀ yìí, kó o ya èyí tó kù lára àwòrán náà, kó o sì kùn ún.
1. ․․․․․
2. ․․․․․
FÚN ÌJÍRÒRÒ:
Kí nìdí tí wọ́n fi ju Dáníẹ́lì sí ibí yìí? Ǹjẹ́ wọ́n ti fìyà jẹ ọ́ rí torí pé o ṣe ohun tó tọ́? Ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀. Kí nìdí tó fi yẹ kéèyàn máa ṣe ohun tó tọ́, láìka ohun tó lè jẹ́ àbájáde rẹ̀?
AMỌ̀NÀ: Ka 1 Pétérù 2:19-21.
KÍ LO MỌ̀ NÍPA ÀPỌ́SÍTÉLÌ MÁTÍÙ?
3. Orúkọ wo la tún mọ Mátíù sí?
AMỌ̀NÀ: Ka Mátíù 9:9; Máàkù 2:14.
․․․․․
4. Kí ni Mátíù yááfì kó tó lè di ọmọlẹ́yìn Jésù?
AMỌ̀NÀ: Ka Lúùkù 5:27, 28.
․․․․․
FÚN ÌJÍRÒRÒ:
Àwọn nǹkan wo lo lè yááfì tó o bá fẹ́ di ọmọlẹ́yìn Jésù? Kí ni díẹ̀ lára àwọn èrè tó o máa rí gbà?
AMỌ̀NÀ: Ka Máàkù 10:28-30.
NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, kó o sì kọ (àwọn) ẹsẹ Bíbélì tó yẹ sínú àlàfo.
OJÚ ÌWÉ 16 Kí ló yẹ ká ní tí ọwọ́ wa lè tẹ̀? 1 Kọ́ríńtì 9:________
OJÚ ÌWÉ 18 Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá ń dúró de ẹ̀fúùfù tá a sì ń wo àwọsánmà? Oníwàásù 11:________
OJÚ ÌWÉ 14 Kò sẹ́ni tó lè wá sọ́dọ̀ baba bí kò ṣe nípasẹ̀ ta ni? Jòhánù 14:________
OJÚ ÌWÉ 15 Àwọn wo ló yẹ ká máa gbàdúrà fún? Jákọ́bù 5:________
ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ
1. Àwọn kìnnìún.
2. Ańgẹ́lì.
3. Léfì.
4. Ó fi gbogbo nǹkan tó ní sílẹ̀.