Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
Ṣàlàyé Àwòrán Yìí
1. Nínú àkọsílẹ̀ tó wà nínú Mátíù 25:31-46, ta ló ni orúkọ oyè náà “Ọmọ ènìyàn”?
AMỌ̀NÀ: Ka Mátíù 16:13-17.
․․․․․
2. Kí ló ń fi hàn bóyá ẹnì kan jẹ́ àgùntàn tàbí ewúrẹ́?
․․․․․
3. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́?
․․․․․
FÚN ÌJÍRÒRÒ:
Àwọn wo gan-an ni Jésù pè ní “àwọn arákùnrin mi”? Báwo lo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́?
Nínú Ìtẹ̀jáde Yìí
Dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, kó o sì kọ (àwọn) ẹsẹ Bíbélì tó yẹ sínú àlàfo.
OJÚ ÌWÉ 3 Kí làwọn apẹ̀gàn á máa sọ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn? 2 Pétérù 3:․․․
OJÚ ÌWÉ 7 Ìgbà wo ni ìparun òjijì máa dé? 1 Tẹsalóníkà 5:․․․
OJÚ ÌWÉ 14 Kí nìdí tí olórí ìdílé fi gbọ́dọ̀ máa pèsè nípa tara fún ìdílé rẹ̀? 1 Tímótì 5:․․․
OJÚ ÌWÉ 23 Irú ìwà wo ló yẹ ká máa hù? Hébérù 13:․․․
Àwọn Wo Ló Wà Lára Ìdílé Jésù?
Kọ́kọ́ wo ohun tá a kọ síwájú amọ̀nà. Ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí. Lẹ́yìn náà, kọ orúkọ tó tọ̀nà sínú àlàfo.
4. ․․․․․
AMỌ̀NÀ: Èmi ni baba ńlá Ábúráhámù.
5. ․․․․․
AMỌ̀NÀ: Èmi àti ìdílé mi fi ìlú Úrì sílẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Kénáánì.
Ka Jẹ́nẹ́sísì 11:31.
6. ․․․․․
AMỌ̀NÀ: Jèhófà yí orúkọ mi padà torí ó sọ pé màá di “baba ogunlọ́gọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè.”
Ka Jẹ́nẹ́sísì 17:5.
ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ
1. Jésù.
2. Ọ̀nà tó bá gbà hùwà sáwọn arákùnrin Jésù nípa tẹ̀mí.
3. Àwọn àgùntàn jogún ìyè àìnípẹ̀kun; àwọn ewúrẹ́ kọjá lọ sínú ìparun àìnípẹ̀kun.
4. Náhórì.—Lúùkù 3:34.
5. Térà.—Lúùkù 3:34.
6. Ábúráhámù.—Lúùkù 3:34.